Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí A Ṣe Lè Sin Jèhófà Kí Àwọn Ọjọ́ Oníyọnu Àjálù Tó Dé

Bí A Ṣe Lè Sin Jèhófà Kí Àwọn Ọjọ́ Oníyọnu Àjálù Tó Dé

“Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá.”—ONÍW. 12:1.

1, 2. (a) Ìmọ̀ràn wo ni Ọlọ́run mí sí Sólómọ́nì láti gba àwọn ọ̀dọ́? (b) Kí nìdí tí àwọn tó wà láàárín àádọ́ta sí ọgọ́ta ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ fi máa nífẹ̀ẹ́ sí ìmọ̀ràn Sólómọ́nì?

ỌLỌ́RUN mí sí Sólómọ́nì Ọba láti sọ fún àwọn ọ̀dọ́ pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá . . . ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin, kí àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù tó bẹ̀rẹ̀ sí dé.” Kí ni “àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù” tàbí àwọn ọjọ́ oníwàhálà tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí? Sólómọ́nì fi ewì tó fani mọ́ra gan-an ṣàlàyé bí ọjọ́ ogbó ṣe kún fún ìyọnu. Ó ní ọwọ́ á máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, ẹsẹ̀ á máa gbò yèpéyèpé, eyín á ká, ojú á máa wò bàìbàì, etí ò ní fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ràn mọ́, orí á di kìkì ewú, ẹ̀yìn á sì tẹ̀ kòlòbà. Kò yẹ kí ẹnikẹ́ni máa ronú pé ó dìgbà tí òun bá dé irú ipò yìí kóun tó bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà.—Ka Oníwàásù 12:1-5.

2 Ara ọ̀pọ̀ Kristẹni tí ọjọ́ orí wọn wà láàáarín àádọ́ta [50] sí ọgọ́ta [60] ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ṣì ń ta kébékébé. Irun wọn lè ti máa funfun díẹ̀díẹ̀, àmọ́ ó ṣeé ṣe kí ara wọn má tíì di hẹ́gẹhẹ̀gẹ bí èyí tí Sólómọ́nì ṣàpèjúwe rẹ̀. Ǹjẹ́ àwọn Kristẹni tó ti dàgbà yìí lè jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí Sólómọ́nì láti gba  àwọn ọ̀dọ́ pé, kí wọ́n “rántí Ẹlẹ́dàá [wọn] Atóbilọ́lá”? Kí ni ìmọ̀ràn yẹn túmọ̀ sí?

3. Kí ló túmọ̀ sí pé ká rántí Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá?

3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe ká ti máa sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó dára ká máa sinmẹ̀dọ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti ronú jinlẹ̀ ká lè túbọ̀ mọrírì bí Ẹlẹ́dàá wa ṣe tóbi lọ́lá tó. Ṣé bá a ṣe wà láàyè yìí ò tó ohun ìyanu ni? Àwámárìídìí làwọn iṣẹ́ àrà tí Ọlọ́run ṣe jẹ́ fáwa èèyàn. Àwọn nǹkan tí Jèhófà pèsè fún wa pọ̀ débi pé a lè gbádùn ìgbésí ayé wa ní onírúurú ọ̀nà. Tá a bá ń ronú lórí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, ojoojúmọ́ la ó túbọ̀ máa mọyì ìfẹ́, ọgbọ́n àti agbára rẹ̀. (Sm. 143:5) Àmọ́, rírántí Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá tún gba pé ká máa ronú nípa ojúṣe wa sí i. Tá a bá ń ronú bẹ́ẹ̀, ó dájú pé a máa fẹ́ láti fọpẹ́ fún Ẹlẹ́dàá wa nípa ṣíṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé wa.—Oníw. 12:13.

ÀǸFÀÀNÍ ÀRÀ-Ọ̀TỌ̀ TÁWỌN ÀGBÀ NÍ

4. Ìbéèrè wo làwọn Kristẹni tó ti ń sìn tipẹ́ lè bi ara wọn, kí sì nìdí?

4 Tó bá ti pẹ́ tó o ti ń sin Jèhófà, ìbéèrè pàtàkì kan wà tó yẹ kó o bi ara rẹ. Ìbéèrè náà ni pé, ‘Ní báyìí tí mo ṣì ní agbára àti okun díẹ̀, kí ni máa fi ìyókù ayé mi ṣe?’ Pẹ̀lú ìrírí tó o ti ní gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, o ní àwọn àǹfààní kan táwọn míì ò ní. O lè sọ àwọn nǹkan tó o ti kọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà fáwọn ọ̀dọ́. O lè fún àwọn míì lókun nípa sísọ àwọn ìrírí tó o ti ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run fún wọn. Dáfídì Ọba tiẹ̀ gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún òun láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Ọlọ́run, ìwọ ti kọ́ mi láti ìgbà èwe mi wá. . . . Àní títí di ọjọ́ ogbó àti orí ewú, Ọlọ́run, má fi mí sílẹ̀, títí èmi yóò fi lè sọ nípa apá rẹ fún ìran náà, fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀, nípa agbára ńlá rẹ.”—Sm. 71:17, 18.

5. Báwo làwọn Kristẹni tó ti pẹ́ nínú ètò ṣe lè fi àwọn ohun tí wọ́n ti mọ̀ kọ́ àwọn míì?

5 Báwo lo ṣe lè jẹ́ káwọn míì jàǹfààní látinú ọgbọ́n tó o ti ní látọdún yìí wá? Ṣé o lè ní kí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run wá sílé rẹ kẹ́ ẹ lè jọ gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ tó ń gbéni ró? Ṣé o lè ní kí wọ́n bá ẹ jáde òde ẹ̀rí kí wọ́n lè rí bó o ṣe máa ń láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Élíhù ìgbàanì sọ pé: “Àwọn ọjọ́ ni kí ó sọ̀rọ̀, ògìdìgbó ọdún sì ni ó yẹ kí ó sọ ọgbọ́n di mímọ̀.” (Jóòbù 32:7) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn àgbà obìnrin tó wà nínú ìjọ pé kí wọ́n fún àwọn míì níṣìírí nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu àti àpẹẹrẹ wọn. Ó sọ pé: “Kí àwọn àgbàlagbà obìnrin jẹ́ . . . olùkọ́ni ní ohun rere.”—Títù 2:3.

RONÚ NÍPA OHUN TÓ O LÈ FI RAN ÀWỌN MÍÌ LỌ́WỌ́

6. Kí nìdí tí àwọn Kristẹni tó ti ń sìn tipẹ́ kò fi gbọ́dọ̀ máa rò pé àwọn ò lè ran àwọn míì lọ́wọ́?

6 Tó o bá jẹ́ Kristẹni tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè fi ran àwọn míì lọ́wọ́. Ronú nípa àwọn nǹkan tó ti yé ẹ báyìí àmọ́ tó jẹ́ pé o kò mọ̀ ní ọgbọ̀n [30] tàbí ogójì [40] ọdún sẹ́yìn. Tó o bá ń ṣe àwọn ìpinnu tó kan ìgbésí ayé rẹ̀, o ti mọ bó o ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò lọ́nà jíjáfáfá. Ó dájú pé o ti mọ bó o ṣe lè mú kí òtítọ́ Bíbélì wọ àwọn èèyàn lọ́kàn. Tó o bá jẹ́ alàgbà, o mọ bó o ṣe lè ran àwọn ará tí wọ́n bá ṣi ẹsẹ̀ gbé lọ́wọ́. (Gál. 6:1) Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó o ti mọ béèyàn ṣe máa ń bójú tó àwọn ìgbòkègbodò ìjọ, tàbí kó o ti sìn ní onírúuru ẹ̀ka tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ àpéjọ tàbí iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. O lè mọ béèyàn ṣe ń rọ àwọn dókítà láti lo onírúurú ìtọ́jú ìṣègùn tí kò la fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára lọ. Kódà, tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ńṣe lo ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, o ti ní ìrírí tó ṣeyebíye nígbèésí ayé. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ti tọ́ àwọn ọmọ dàgbà, wàá ti ní ọgbọ́n téèyàn fi ń bójú tó nǹkan. Ẹ̀yin àgbà tẹ́ ẹ wà nínú ìjọ lè jẹ́ orísun ìṣírí ńláǹlà fún àwọn èèyàn Jèhófà tẹ́ ẹ bá ń kọ́ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tẹ́ ẹ̀ ń múpò iwájú, tẹ́ ẹ sì ń gbé wọn ró.—Ka Jóòbù 12:12.

7. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó wúlò wo làwọn Kristẹni tó ti dàgbà lè fún àwọn ọ̀dọ́?

7 Báwo lo ṣe lè túbọ̀ lo ìrírí tó o ní láti  ran àwọn míì lọ́wọ́? Bóyá o lè fi béèyàn ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti béèyàn ṣe ń darí rẹ̀ han àwọn ọ̀dọ́. Tó o bá jẹ́ àgbà obìnrin, ǹjẹ́ o lè dábàá ọ̀nà tí àwọn abiyamọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́mọ fi lè máa lọ́wọ́ déédéé nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń tọ́mọ lọ́wọ́? Tó o bá jẹ́ àgbà ọkùnrin, ǹjẹ́ o lè kọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin bí wọ́n ṣe lè máa fi ìtara sọ àsọyé àti bí wọ́n ṣe lè máa wàásù ìhìn rere lọ́nà tó túbọ̀ já fáfá? Ṣé o lè jẹ́ kí wọ́n mọ bó o ṣe máa ń fún àwọn àgbàlagbà níṣìírí nípa tẹ̀mí nígbà tó o bá bẹ̀ wọ́n wò? Bó ò bá tiẹ̀ lè ta kébékébé bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, ọ̀pọ̀ àǹfààní lo ṣì ní láti dá àwọn ọ̀dọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹwà àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn, ọlá ńlá àwọn arúgbó sì ni orí ewú wọn.”—Òwe 20:29.

ṢÉ O LÈ LỌ SÌN NÍBI TÍ WỌ́N TI NÍLÒ ÀWỌN ONÍWÀÁSÙ PÚPỌ̀ SÍ I?

8. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà tó di àgbàlagbà?

8 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi gbogbo agbára rẹ̀ sin Ọlọ́run nígbà tó di àgbàlagbà. Nígbà tó fi máa di nǹkan bí ọdún 61 Sànmánì Kristẹni, tí wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n nílùú Róòmù, ó ti ṣiṣẹ́ kára gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì, ó sì ti fara dà á fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ó sì lè jókòó sílùú Róòmù tó bá fẹ́, kó máa wàásù níbẹ̀. (2 Kọ́r. 11:23-27) Kò sí àní-àní pé inú àwọn ará tó wà ní ìlú ńlá náà á dùn pé kó ṣì máa ṣètìlẹ́yìn fún àwọn. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù rí i pé iṣẹ́ ṣì ń bẹ láti ṣe láwọn ilẹ̀ òkèèrè. Torí náà, ó mú Tímótì àti Títù, ó sì padà sẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì rẹ̀. Ó lọ sí Éfésù, lẹ́yìn náà ó kọjá sí Kírétè, ó sì ṣeé ṣe kó dé Makedóníà. (1 Tím. 1:3; Títù 1:5) A ò mọ̀ bóyá ó dé ilẹ̀ Sípéènì, àmọ́ ó ní in lọ́kàn pé òun máa débẹ̀.—Róòmù 15:24, 28.

9. Ìgbà wo ló ṣeé ṣe kí Pétérù lọ síbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

9 Ó ṣeé ṣe kí àpọ́sítélì Pétérù náà ti lé ní àádọ́ta [50] ọdún nígbà tó lọ síbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Tó bá jẹ́ pé ọjọ́ orí rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ti Jésù nígbà tó wà láyé tàbí pé ó ju Jésù lọ díẹ̀, a jẹ́ pé á ti tó ẹni àádọ́ta ọdún nígbà tí òun àtàwọn àpọ́sítélì yòókù jọ ṣèpàdé ní Jerúsálẹ́mù lọ́dún 49 Sànmánì Kristẹni. (Ìṣe 15:7) Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ṣe ìpàdé yẹn ni Pétérù lọ sí Bábílónì kó lè máa gbé níbẹ̀. Kí nìdí? Ó dájú pé torí kó lè wàásù fáwọn Júù tó pọ̀ rẹpẹtẹ lágbègbè náà ló ṣe lọ síbẹ̀. (Gál. 2:9) Ibẹ̀ ló wà tí Ọlọ́run fi mí sí i láti kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́, ní nǹkan bí ọdún 62 Sànmánì Kristẹni. (1 Pét. 5:13) Kò rọrùn láti máa gbé nílẹ̀ àjèjì, àmọ́ Pétérù ò jẹ́ kí ara tó ti ń dara àgbà mú kóun pàdánù ayọ̀ tó wà nínú fífi gbogbo ara sin Jèhófà.

10, 11. Sọ ìrírí ẹnì kan tó lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i lẹ́yìn tó ti dàgbà.

10 Lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tí ọjọ́ orí wọ́n wà láàárín àádọ́ta [50] sí ọgọ́ta [60] ọdún àtàwọn tó ti jù bẹ́ẹ̀ lọ ti rí i pé ipò àwọn ti yí pa dà àti pé ó ṣeé ṣe fáwọn láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà láwọn ọ̀nà míì. Àwọn kan lára wọn sì ti lọ síbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Àpẹẹrẹ kan ni ti Arákùnrin Robert tó sọ pé: “Èmi àtìyàwó mi ti ń sún mọ́ ọgọ́ta ọdún nígbà tá a rí i pé àǹfààní ṣì wà fún wa láti ṣe púpọ̀ sí i. Ọmọ kan ṣoṣo tá a bí ti ń dá gbé, a ò ní àwọn òbí àgbà tó nílò ìtọ́jú mọ́, wọ́n sì fi ogún kékeré kan sílẹ̀ fún wa. Mo ṣírò rẹ̀ pé tá a bá ta ilé wa, àá lè san èyí tó kù lára owó tá a yá ní báńkì, àá sì lè máa gbọ́ bùkátà ara wa títí tí wọ́n á fi bẹ̀rẹ̀ sí í san owó ìfẹ̀yìntì mi. A gbọ́ pé ní orílẹ̀-èdè Bòlífíà, àwọn tó ń fẹ́ ká máa báwọn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pọ̀ gan-an, nǹkan ò sì wọ́n níbẹ̀. Torí náà, a pinnu láti kó lọ síbẹ̀. Ibi tá a kó lọ yẹn ò tètè mọ́ wa lára. Níbẹ̀, àwọn nǹkan yàtọ̀ pátápátá sí bó ṣe rí níbi tá a ti wá ní Amẹ́ríkà ti Àríwá. Àmọ́, Jèhófà bù kún ìsapá wa.”

11 Arákùnrin Robert fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ìgbòkègbodò ìjọ là ń lo gbogbo àkókò wa  fún báyìí. Lára àwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ṣèrìbọmi. Ìdílé kan wà tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọn ò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ, abúlé tí wọ́n ń gbé sì jìnnà gan-an sí wa. Àmọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ìdílé yẹn máa ń rin ìrìn-àjò tí kò rọrùn náà wá sígboro láti wá bá wa ṣèpàdé. Ẹ wo bí inú wa ti dùn tó bá a ṣe ń rí i tí ìdílé yìí ń tẹ̀ síwájú, tí ọmọkùnrin wọn àgbà sì tún gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà!”

IṢẸ́ WÀ LÁWỌN ÌJỌ TÍ WỌ́N TI Ń SỌ ÈDÈ ILẸ̀ ÒKÈÈRÈ

12, 13. Sọ ìrírí Kristẹni kan tó bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà láwọn ọ̀nà míì lẹ́yìn tó ti fẹ̀yìn tì.

12 Àwọn ìjọ àtàwọn àwùjọ tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè lè jàǹfààní púpọ̀ látinú àpẹẹrẹ àwọn àgbà ọkùnrin àti obìnrin. Ó sì tún máa ń dùn mọ́ni láti lọ ṣiṣẹ́ nírú ìpínlẹ̀ ìwàásù bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Arákùnrin Brian sọ pé: “Nígbà tí mo pé ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin [65], ìyẹn ọjọ́ orí ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, èmi àti ìyàwó mi ò lè ṣe tó bá a ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́. Àwọn ọmọ wa ti wà láyè ara wọn, a ò sì fi bẹ́ẹ̀ rí àwọn olùfìfẹ́hàn tá a lè máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá, mo bá ọ̀dọ́kùnrin ará Ṣáínà kan pàdé, yunifásítì kan tó wà lágbègbè wa ló ti ń ṣe ìwádìí. Mo ní kó wá sípàdé wa, ó sì wá. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mélòó kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í mú ará ìlú rẹ̀ kan tí wọ́n jọ wà ní yunifásítì wá. Ní ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà, ó mú ẹnì kẹta wá, lẹ́yìn náà ó tún mú ẹnì kẹrin wá.

13 “Nígbà tí ẹnì karùn-ún lára àwọn tí wọ́n jọ ń ṣèwádìí sọ pé kí n máa bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́, mo ronú pé, ‘Ti pé mo ti di ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin [65] ò ní kí n fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.’ Mo wá bi ìyàwó mi tí mo gba ọdún méjì péré lọ́wọ́ rẹ̀, bóyá ó máa kọ́ èdè Ṣáínà. Ohùn tí wọ́n ti gbà sílẹ̀ la fi kọ́ èdè náà. Ìyẹn sì jẹ́ ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn. Ṣe ló dà bí ìgbà tá a pa dà di èwe látìgbà tá a ti ń wàásù níbi tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè. Ní báyìí, àwọn ará Ṣáínà tá a ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jẹ́ méjìléláàádọ́fà [112]! Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn ti wá sípàdé. Ọ̀kan lára wọn tiẹ̀ ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà nínú ìjọ wa.”

O lè má tíì dàgbà jù láti mú iṣẹ́ ìsìn rẹ gbòòrò sí i (Wo ìpínrọ̀ 12 àti 13)

 MÁA FAYỌ̀ ṢE GBOGBO OHUN TÓ O LÈ ṢE

14. Kí ló lè mú kí inú àwọn Kristẹni tó ti dàgbà máa dùn? Báwo ni àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́ ìṣírí fún wọn?

14 Bó tílẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ Kristẹni tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín àádọ́ta ọdún sí ọgọ́ta ọdún ló ní àǹfààní láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, síbẹ̀ kì í ṣe gbogbo wọn ló lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ara àwọn kan kò fi bẹ́ẹ̀ le, àwọn míì sì láwọn òbí àgbà tàbí àwọn ọmọ tí wọ́n ń tọ́jú. Àmọ́ ohun tó lè mú kí inú yín máa dùn ni pé Jèhófà mọrírì ohun yòówù tẹ́ ẹ bá lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Torí náà, dípò tí wàá fi máa banú jẹ́ torí ohun tí o kò lè ṣe, ńṣe ni kó o máa fayọ̀ ṣe ìwọ̀nba tó o lè ṣe. Ronú nípa àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ó ju ọdún kan lọ tó fi wà látìmọ́lé, tí kò lè rin ìrìn-àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ mọ́. Àmọ́ nígbàkigbà táwọn èèyàn bá wá kí i, ó máa ń sọ ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ fún wọn, ó sì máa ń fún ìgbàgbọ́ wọn lókun.—Ìṣe 28:16, 30, 31.

15. Kí nìdí tá a fi mọyì àwọn Kristẹni tó jẹ́ àgbàlagbà?

15 Jèhófà tún mọrírì ohun táwọn àgbàlagbà lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sólómọ́nì ṣàlàyé pé nígbà tí àìlera ọjọ́ ogbó bá ti dé, nǹkan kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn. Síbẹ̀ Jèhófà mọyì ohun táwọn Kristẹni tó ti dàgbà ń gbé ṣe kí wọ́n lè máa yìn ín lógo. (Lúùkù 21:2-4) Àwọn ará pẹ̀lú mọrírì àpẹẹrẹ ìṣòtítọ́ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà láàárín wọn, tí wọ́n ti ń sìn láti ọ̀pọ̀ ọdún wá.

16. Àwọn àǹfààní wo ni kò ṣeé ṣe fún Ánà tó jẹ́ àgbàlagbà láti ní, àmọ́ kí ló ṣe láti sin Ọlọ́run?

16 Bíbélì ròyìn pé títí dọjọ́ ogbó ni obìnrin àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Ánà fi ń sin Jèhófà láìyẹsẹ̀. Ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84] ni obìnrin opó náà nígbà tí wọ́n bí Jésù. Kò pẹ́ láyé débi tí ì bá fi láǹfààní láti di ọmọlẹ́yìn Jésù, tí Ọlọ́run ì bá fi fi ẹ̀mí yàn án, tàbí tí ì bá fi ní àǹfààní láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Síbẹ̀, ó gbádùn sísin Ọlọ́run ní àwọn ọ̀nà mìíràn. Bíbélì sọ pé: ‘Kì í pa wíwà ní tẹ́ńpìlì jẹ, ó sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ lóru àti lọ́sàn-án.’ (Lúùkù 2:36, 37) Bí àlùfáà ṣe ń sun tùràrí nínú tẹ́ńpìlì láràárọ̀ àti lálaalẹ́, Ánà máa ń wà láàárín èrò tó kóra jọ ní àgbàlá tẹ́ńpìlì á sì máa fọkàn gbàdúrà jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ fún nǹkan bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú. Bó ṣe rí Jésù nígbà tó wà lọ́mọ jòjòló, ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í “sọ̀rọ̀ nípa ọmọ náà fún gbogbo àwọn tí ń dúró de ìdáǹdè Jerúsálẹ́mù.”—Lúùkù 2:38.

17. Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn Kristẹni tó ti dàgbà tàbí tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lera láti máa kópa nínú ìsìn tòótọ́?

17 Lónìí, ó yẹ ká wà lójúfò ká lè máa ran àwọn ará tó ti dàgbà tàbí tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lera lọ́wọ́. Ó lè má ṣeé ṣe fún àwọn kan láti wá sípàdé ìjọ àtàwọn àpéjọ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń wù wọn gan-an pé kí wọ́n wà níbẹ̀. Láwọn àgbègbè kan, ìfẹ́ táwọn ìjọ ní sí irú àwọn àgbàlagbà bẹ́ẹ̀ ti mú kí wọ́n ṣètò fún wọn láti máa gbádùn àwọn ìpàdé látorí tẹlifóònù. Èyí lè má ṣeé ṣe láwọn ibòmíì. Síbẹ̀, àwọn ará tí wọn kò lè lọ sípàdé lè máa kọ́wọ́ ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, àdúrà wọn ń mú káwọn nǹkan máa lọ geerege nínú ìjọ.—Ka Sáàmù 92:13, 14.

18, 19. (a) Kí nìdí tí àwọn Kristẹni tó ti dàgbà fi lè má mọ báwọn ṣe jẹ́ ìṣírí tó fáwọn míì? (b) Àwọn wo ló lè fi ìmọ̀ràn náà, “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá” sílò?

18 Àwọn Kristẹni tó ti dàgbà lè má mọ̀ báwọn ṣe jẹ́ ìṣírí tó fáwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé adúróṣinṣin ni Ánà ní gbogbo ọdún tó fi máa ń lọ sí tẹ́ńpìlì yẹn, bóyá ló mọ̀ pé ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà àpẹẹrẹ òun ń bọ̀ wá fún àwọn míì ní ìṣírí. Àkọsílẹ̀ bí Ánà ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà wà nínú Ìwé Mímọ́. Ìwọ ńkọ́? Àkọsílẹ̀ bí ìwọ náà ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run wà lọ́kàn àwọn ará bíi tìrẹ. Abájọ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi sọ pé: “Orí ewú jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo”!—Òwe 16:31.

19 Ó níbi tí agbára olúkúlùkù wa mọ tó bá di pé ká ṣiṣẹ́ sin Jèhófà. Àmọ́, ẹ jẹ́ kí àwa tá a ṣì lè ta kébékébé fi ọ̀rọ̀ tó ní ìmísí Ọlọ́run náà sọ́kàn pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá . . . kí àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù tó bẹ̀rẹ̀ sí dé.”—Oníw. 12:1.