ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ February 2014
Ẹ̀dà yìí jíròrò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń múni lórí yá tó wà nínú Sáàmù 45. Ó tún máa jẹ́ ká mọyì bí Jèhófà ṣe jẹ́ Olùpèsè, Aláàbò wa àti Ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́.
Ẹ Yin Kristi, Ọba Ògo!
Ọ̀nà wo ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amóríyá tó wà nínú Sáàmù 45 gbà kàn wá lónìí?
Ẹ Yọ̀ Nítorí Ìgbéyàwó Ọ̀d Àgùntàn!
Ta ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà máa gbé níyàwó? Báwo ni Kristi ṣe ti ń múra rẹ̀ sílẹ̀ fún ìgbéyàwó náà? Àwọn wo ló máa bá wọn yọ ayọ̀ ìgbéyàwó náà?
Ọlọ́run San Opó Sáréfátì Lẹ́san Torí Ìgbàgbọ́ Rẹ̀
Àjíǹde ọmọkùnrin opó náà jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó tí ì fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun jù lọ. Kí la rí kọ́ nínú ohun tí obìnrin yìí ṣe?
Jèhófà —Olùpèsè àti Aláàbò Wa
Mọyì Jèhófà tó jẹ́ Baba wa ọ̀run. Kọ́ bó o ṣe lè túbọ̀ ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà tó jẹ́ Olùpèsè Atóbilọ́lá àti Aláàbò.
Jèhófà —Ọ̀rẹ́ Wa Tímọ́tímọ́
Kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ábúráhámù àti Gídíónì, tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ Jèhófà Ọlọ́run. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà?
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ló mú kí àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní máa “fojú sọ́nà” fún Mèsáyà?
“Máa Rí Adùn Jèhófà”
Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbànì mọyì ètò tí Jèhófà ṣe fún ìjọsìn tòótọ́. Kí ló máa mú káwa náà mọyì ìjọsìn tòótọ́ lónìí?
LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA
Sinimá Tó Dá Lórí Ìṣẹ̀dá Ti Pé Ọgọ́rùn-ún Ọdún Báyìí
Ó ti pé ọgọ́rùn-ún ọdún tá a kọ́kọ́ gbé sinimá “Photo-Drama of Creation” jáde, káwọn èèyàn lè gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì.