Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà—Ọ̀rẹ́ Wa Tímọ́tímọ́

Jèhófà—Ọ̀rẹ́ Wa Tímọ́tímọ́

“[Ábúráhámù] sì di ẹni tí a ń pè ní ‘ọ̀rẹ́ Jèhófà.’”—JÁK. 2:23.

1. Torí pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán rẹ̀, kí lohun tá a lè ṣe?

ÀWỌN èèyàn sábà máa ń sọ pé: “Ẹní bíni là á jọ.” Òótọ́ sì lọ̀rọ̀ yẹn, torí pé ọ̀pọ̀ ọmọ ló jọ òbí wọn dáadáa. Ó ṣe tán, ara bàbá àti ìyá ni ohun tó pilẹ̀ ọmọ ti wá. Jèhófà, Baba wa ọ̀run ni Olùfúnni ní ìyè. (Sm. 36:9) Àwa èèyàn tá a jẹ́ ọmọ rẹ̀ náà sì jọ ọ́ dé ìwọ̀n àyè kan. Torí pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán rẹ̀, a lè ronú ká sì parí èrò sí ibì kan pàtó. A lè yan ẹni tí a ó máa bá ṣọ̀rẹ́.—Jẹ́n. 1:26.

2. Kí ló lè mú kí Jèhófà di Ọ̀rẹ́ wa?

2 Jèhófà lè jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́. Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa àti ìgbàgbọ́ táwa náà ní nínú òun àti Ọmọ rẹ̀ ló mú ká jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀. Jésù sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 3:16) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká gbé méjì nínú wọn yẹ̀ wò.

“ÁBÚRÁHÁMÙ Ọ̀RẸ́ MI”

3, 4. Tó bá kan ti jíjẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà, sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín Ábúráhámù àti àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀.

3 Jèhófà pe baba ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní “Ábúráhámù ọ̀rẹ́ mi.” (Aísá. 41:8) Ìwé 2 Kíróníkà 20:7 náà pe Ábúráhámù ní  olùfẹ́ Ọlọ́run. Kí ló mú kí ọkùnrin olóòótọ́ yẹn ní àjọṣe tó tọ́jọ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá rẹ̀? Ìgbàgbọ́ tí Ábúráhámù ní nínú Ọlọ́run ni.—Jẹ́n. 15:6; ka Jákọ́bù 2:21-23.

4 Látìgbà tí àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ti di orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní ìgbàanì ni Jèhófà ti jẹ́ Baba àti Ọ̀rẹ́ fún wọn. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé àǹfààní tí wọ́n ní yẹn bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Ohun tó sì fà á ni pé wọn ò lo ìgbàgbọ́ nínú ìlérí Jèhófà mọ́.

5, 6. (a) Kí ló mú kí Jèhófà di Ọ̀rẹ́ rẹ? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò?

5 Bó o bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, wàá sì túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Rántí ìgbà tó o kẹ́kọ̀ọ́ pé Ẹni gidi ni Ọlọ́run àti pé o lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́. O tún mọ̀ pé gbogbo wa la ti bí sínú ẹ̀ṣẹ̀ torí àìgbọràn Ádámù. Ó wá yé ẹ pé aráyé lápapọ̀ ti di àjèjì sí Ọlọ́run. (Kól. 1:21) Lẹ́yìn náà lo wá mọ̀ pé Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ kì í ṣe ẹni tí kò ṣeé sún mọ́ tí ọ̀rọ̀ wa kò jẹ lógún. Nígbà tá a kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹbọ ìràpadà tí Ọlọ́run pèsè nípasẹ̀ Jésù, tá a sì lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà yẹn, a bẹ̀rẹ̀ sí í bá Ọlọ́run dọ́rẹ̀ẹ́.

6 Ní báyìí tá a ti rántí bí nǹkan ṣe rí sẹ́yìn, ó dára ká bi ara wa pé: ‘Ṣé àjọṣe èmi àti Ọlọ́run túbọ̀ ń lágbára àbí kò yàtọ̀ sí ìgbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí òtítọ́? Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ tí mo ní nínú Jèhófà àti ìfẹ́ tí mo ní fún Ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n yìí ń jinlẹ̀ sí i lójoojúmọ́?’ Ẹlòmíì tó tún ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà láyé ìgbàanì ni Gídíónì. Ẹ jẹ́ ká wá gbé àpẹẹrẹ rere tó fi lélẹ̀ yẹ̀ wò ká sì fi ohun tá a bá kọ́ níbẹ̀ sọ́kàn.

“JÈHÓFÀ JẸ́ ÀLÀÁFÍÀ”

7-9. (a) Ìrírí àgbàyanu wo ni Gídíónì ní, kí sì nìyẹn mú kó ṣe? (Wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Báwo la ṣe lè bá Jèhófà dọ́rẹ̀ẹ́?

7 Àsìkò tí nǹkan ò fara rọ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, lẹ́yìn tí wọ́n ti wọ Ilẹ̀ Ìlérí ni Gídíónì Onídàájọ́ sin Jèhófà. Ìwé Onídàájọ́ orí 6 sọ pé áńgẹ́lì Jèhófà lọ bá Gídíónì ní Ọ́fírà. Nígbà yẹn, ewu ńlá làwọn ará Mídíánì tó wà nítòsí jẹ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé dípò kí Gídíónì lọ pa ọkà ní pápá gbalasa, ibi ìfúntí wáìnì ló ti pa á. Ìdí sì ni pé á lè sáré tọ́jú ọkà ṣíṣeyebíye náà pa mọ́ báwọn ọ̀tá bá dé. Ó ya Gídíónì lẹ́nu pé áńgẹ́lì tó fara hàn án pè é ní “akíkanjú, alágbára ńlá.” Torí náà, ó béèrè lọ́wọ́ áńgẹ́lì náà bóyá òótọ́ ni Jèhófà tó dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì máa ran àwọn lọ́wọ́ báyìí. Áńgẹ́lì tí Jèhófà Ẹlẹ́dàá rán sí Gídíónì yìí wá mú kó dá Gídíónì lójú pé òótọ́ ni Jèhófà ń tì í lẹ́yìn.

8 Gídíónì ń ṣiyè méjì pé báwo lòun á ṣe ‘gba Ísírẹ́lì là kúrò lọ́wọ́ Mídíánì.’ Jèhófà dá a lóhùn pé: “Nítorí pé èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, dájúdájú, ìwọ yóò sì ṣá Mídíánì balẹ̀ bí ẹni pé ọkùnrin kan ṣoṣo ni.” (Oníd. 6:11-16) Ó dájú pé Gídíónì ṣì ń ṣiyè méjì nípa bí ọ̀ràn náà ṣe máa rí, ó wá ní kí áńgẹ́lì náà fún òun ní àmì kan. Kíyè sí i nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ yìí pé ó dá Gídíónì lójú pé Jèhófà jẹ́ Ẹni gidi.

9 Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà fún ìgbàgbọ́ Gídíónì lókun ó sì mú kó túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Gídíónì se oúnjẹ ó sì gbé e síwájú áńgẹ́lì náà. Áńgẹ́lì náà fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ kan oúnjẹ náà, iná sì jó oúnjẹ náà run lọ́nà ìyanu, ìgbà yẹn ni Gídíónì wá mọ̀ ní tòótọ́ pé aṣojú Jèhófà ni áńgẹ́lì náà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ya Gídíónì lẹ́nu, ó wá sọ pé: “Págà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, nítorí ìdí náà pé mo ti rí áńgẹ́lì Jèhófà lójúkojú!” (Oníd. 6:17-22) Àmọ́, ǹjẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn mú kí àárín Gídíónì àti Ọlọ́run bà jẹ́? Rárá o! Ńṣe ló mú kí okùn ọ̀rẹ́ wọn yi sí i. Gídíónì wá mọ Jèhófà débi pé ó ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. Ohun tó mú ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni orúkọ tí Gídíónì fi pe pẹpẹ tó mọ síbi tí áńgẹ́lì náà ti bá a sọ̀rọ̀. Ó pe pẹpẹ náà ní, “Jèhófà-ṣálómù,” èyí tó túmọ̀ sí “Jèhófà Jẹ́ Àlàáfíà.” (Ka Onídàájọ́ 6:23, 24, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.) Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí ohun tí Jèhófà ń ṣe fún wa  lójoojúmọ́, àá rí i pé ojúlówó Ọ̀rẹ́ ló jẹ́. Tá a ba ń gbàdúrà sí Ọlọ́run déédéé, àlàáfíà wa á máa pọ̀ sí i, okùn ọ̀rẹ́ wá á sì máa yi sí i.

TA NI YÓÒ JẸ́ ‘ÀLEJÒ NÍNÚ ÀGỌ́ JÈHÓFÀ’?

10. Gẹ́gẹ́ bí Sáàmù 15:3, 5 ṣe sọ, kí ni Jèhófà sọ pé ká ṣe ká tó lè jẹ́ ọ̀rẹ́ òun?

10 Àmọ́ o, kí Jèhófà tó lè jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa, àwọn ohun kan wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú orin ti Dáfídì kọ nínú Sáàmù 15, ó sọ àwọn nǹkan tá a gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè jẹ́ ‘àlejò nínú àgọ́ Jèhófà,’ ìyẹn ni pé ká tó lè jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. (Sm. 15:1) Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa méjì lára wọn. Èkínní, ká má máa fi ọ̀rọ̀ èké bani jẹ́. Èkejì, ká máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo. Nígbà tí Dáfídì ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó yìí, ó sọ nípa àlejò tó wà nínú àgọ́ Jèhófà pé: “Kò lo ahọ́n rẹ̀ ní fífọ̀rọ̀ èké bani jẹ́ . . . Kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sí aláìmọwọ́-mẹsẹ̀.”—Sm. 15:3, 5.

11. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa fọ̀rọ̀ èké ba ẹnikẹ́ni jẹ́?

11 Nínú sáàmù míì, Dáfídì kìlọ̀ pé: “Máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ahọ́n rẹ kúrò nínú ohun búburú.” (Sm. 34:13) Tá ò bá fetí sí ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí yìí, àárín àwa àti Baba wa ọ̀run tó jẹ́ olódodo kò ní gún mọ́. Ká sòótọ́, ara ohun tá a mọ̀ mọ Sátánì tó jẹ́ olórí ọ̀tá Jèhófà ni pé ó máa ń fi ọ̀rọ̀ èké bani jẹ́. Ọ̀rọ̀ náà “Èṣù” wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́.” Tá a bá ń kó ara wa níjàánu ní ti ọ̀rọ̀ tá à ń sọ nípa àwọn èèyàn, àá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Ó yẹ ká fiyè sí kókó yìí, pàápàá tó bá kan ojú tá a fi ń wo àwọn ọkùnrin tá a yàn sípò nínú ìjọ.—Ka Hébérù 13:17; Júúdà 8.

12, 13. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo? (b) Tá a bá ń hùwà láìṣàbòsí, ipa wo ló máa ní lórí àwọn èèyàn?

12 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tún máa ń hùwà láìṣàbòsí, wọn kì í sì í kóni nífà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní gbígbàdúrà fún wa, nítorí àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé a ní ẹ̀rí-ọkàn aláìlábòsí, gẹ́gẹ́ bí a ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Héb. 13:18) Torí pé a ti pinnu pé a ó máa “hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo,” a kì í kó àwọn ará wa nífà. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá gbé iṣẹ́ fún wọn, a máa ń rí i dájú pé a kò rẹ́ wọn jẹ àti pé à ń fún wọn ní iye tá a jọ ṣàdéhùn. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, òótọ́ inú la fi ń bá gbogbo èèyàn lò, yálà àwọn tá a gbà síṣẹ́ tàbí àwọn míì. Tó bá sì jẹ́ ará ló gbà wá ṣíṣẹ́, a máa ń ṣọ́ra kó má di pé à ń retí ohun tó pọ̀ jù lọ́dọ̀ rẹ̀ torí pé a jọ jẹ́ ará.

13 Àwọn ará ìta tó ti da nǹkan pọ̀ pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń sọ̀rọ̀ tó fi hàn pé wọ́n mọrírì wa gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀gá ilé iṣẹ́ ìkọ́lé kan kíyè sí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pa ọ̀rọ̀ wọn mọ́. Ó sọ pé: “Ẹ kì í yẹ àdéhùn rárá.” (Sm. 15:4) Irú ìwà yìí ni kì í jẹ́ kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà bà jẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń fi ìyìn fún Baba wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa.

RAN ÀWỌN MÍÌ LỌ́WỌ́ KÍ WỌ́N LÈ DI Ọ̀RẸ́ JÈHÓFÀ

À ń ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 14 àti 15)

14, 15. Báwo la ṣe lè ran àwọn tá à ń bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà?

14 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn tá à ń bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lè gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà, wọn ò kà á sí Ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́. Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́? Ẹ jẹ́ ká ronú lórí ìtọ́ni tí Jésù fún àádọ́rin [70] lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tó rán wọn ní méjì méjì pé kí wọ́n lọ wàásù. Ó sọ pé: “Ibi yòówù tí ẹ bá ti wọ ilé kan, ẹ kọ́kọ́ sọ pé: ‘Àlàáfíà fún ilé yìí o.’ Bí ọ̀rẹ́ àlàáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e. Ṣùgbọ́n bí kò bá sí, yóò padà sọ́dọ̀ yín.” (Lúùkù 10:5, 6) Èyí fi hàn pé tá a bá ń hùwà bí ọ̀rẹ́ sáwọn èèyàn, wọ́n lè dẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́. Ní ti àwọn tó ń ṣàtakò sí wa ńkọ́? Bí  wọ́n bá tiẹ̀ ń bínú sí wa tẹ́lẹ̀, wọ́n lè pèrò dà kí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ wa nígbà míì, tá a bá hùwà bí ọ̀rẹ́ sí wọn.

15 Tá a bá pàdé àwọn tó ti jingíri sínú ìsìn èké tàbí tí wọ́n ń lọ́wọ́ sí àwọn àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, a ṣì máa ń hùwà bí ọ̀rẹ́ sí wọn, a kì í sì í bá wọn fa ìjàngbọ̀n. Àwọn kan wà tó jẹ́ pé bí nǹkan ṣe ń lọ láwùjọ ti tojú sú wọn. Èyí ti wá mú kí wọ́n fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i nípa Ọlọ́run tá à ń sìn. Bí irú wọn bá wá sáwọn ìpàdé wa, a máa fọ̀yàyà kí wọn káàbọ̀. Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ tó gbádùn mọ́ni nípa irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ wà nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà.”

BÁ A ṢE Ń BÁ Ọ̀RẸ́ WA TÍMỌ́TÍMỌ́ ṢIṢẸ́

16. Ọ̀nà wo la gbà jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà àti “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” pẹ̀lú rẹ̀?

16 Tí àwọn èèyàn kan bá jọ ń ṣiṣẹ́, wọ́n máa ń di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Àǹfààní ló jẹ́ fún gbogbo àwa tá a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà pé a jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run àti “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” pẹ̀lú rẹ̀. (Ka 1 Kọ́ríńtì 3:9.) Bá a sì ṣe ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, bẹ́ẹ̀ là ń ní òye tó pọ̀ sí i nípa àwọn ànímọ́ àgbàyanu tí Baba wa ọ̀run ní. A sì tún ń rí bí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́.

17. Báwo ni oúnjẹ tẹ̀mí tá à ń gbádùn ní àwọn àpéjọ wa ṣe fi hàn pé Ọ̀rẹ́ wa ni Jèhófà?

17 Bá a bá ṣe túbọ̀ ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, bẹ́ẹ̀ náà la ó ṣe túbọ̀ máa rí i pé à ń sún mọ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, à ń rí bí Jèhófà ṣe ń sọ ìmọ̀ràn àwọn tó ń ṣe àtakò sí wa dòfo. Ẹ jẹ́ ká rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ láwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn. Ǹjẹ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà darí wa ò ti wá ṣe kedere sí wa? Ó ń yà wá lẹ́nu gan-an bá a ṣe ń rí oúnjẹ tẹ̀mí tó gbámúṣé gbà déédéé. Àwọn àsọyé, àṣefihàn àti ìrírí tá à ń gbádùn ní àwọn àpéjọ wa ń jẹ́ ká rí i pé Baba wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa mọ àwọn ìṣòro àti àìní wa dunjú. Nínú lẹ́tà ìmọrírì tí ìdílé kan kọ nípa àpéjọ kan, ìdílé náà sọ pé: “Ó dájú pé ohun tá a gbádùn ní àpéjọ náà wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin. A rí bí Jèhófà ṣe fẹ́ràn wa tó lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀, tó sì ń fẹ́ ká ṣàṣeyọrí.” Lẹ́yìn tí tọkọtaya kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Jámánì ti lọ sí àkànṣe àpéjọ kan ní orílẹ̀-èdè Ireland, wọ́n dúpẹ́ torí bí àwọn ará ṣe fọ̀yàyà kí wọn káàbọ̀ tí wọ́n sì bójú tó wọn. Wọ́n wá fi kún ọ̀rọ̀ wọn pé: “Ṣùgbọ́n Jèhófà àti ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi Ọba la fi ọpẹ́ wa tó ga jù lọ fún. Àwọn ló ní ká wá dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ará kárí ayé, tó jẹ́ orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo tó wà ní ìṣọ̀kan yìí. Ìṣọ̀kan wa kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán, ojoojúmọ́ là ń gbádùn rẹ̀. Gbogbo ìgbà ni àwọn ohun tá a rí ní àkànṣe àpéjọ tó wáyé ní ìlú Dublin á máa rán wa létí àǹfààní iyebíye tá a ní pé àwa àti ẹ̀yin jọ ń sin Ọlọ́run wa alágbára.”

 ÀWỌN Ọ̀RẸ́ MÁA Ń BÁRA WỌN SỌ̀RỌ̀

18. Kí la lè bi ara wa tó bá kan bá a ṣe ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀?

18 Bí àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ bá ń bára wọn sọ̀rọ̀ dáadáa, ńṣe ni okùn ọ̀rẹ́ wọn á túbọ̀ máa yi. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé pẹ̀lú bí Íńtánẹ́ẹ̀tì àtàwọn ilé iṣẹ́ tẹlifóònù ṣe wọ́pọ̀ lóde ìwòyí, àwọn èèyàn sábà máa ń bára wọn sọ̀rọ̀ lórí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì àti nípasẹ̀ àtẹ̀jíṣẹ́. Àmọ́, tá a bá fìyẹn wé bíbá Jèhófà tó jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ sọ̀rọ̀, a lè bi ara wa pé, báwo ni mo ṣe ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ lemọ́lemọ́ tó? Ó dájú pé “Olùgbọ́ àdúrà” ni Jèhófà. (Sm. 65:2) Àmọ́, ẹ̀ẹ̀melòó la máa ń lo ìdánúṣe láti bá a sọ̀rọ̀?

19. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ tó bá ṣòro fún wa láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún Baba wa ọ̀run?

19 Ó máa ń ṣòro fáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan láti sọ ohun tó ń dùn wọ́n lọ́kàn fún Ọlọ́run. Síbẹ̀, ohun tí Jèhófà fẹ́ ká máa ṣe nìyẹn tá a bá ń gbàdúrà. (Sm. 119:145; Ìdárò 3:41) Kódà tá ò bá mọ bá a ṣe máa ṣàlàyé ohun tó wà lọ́kàn wa fún Ọlọ́run, a ṣì lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù pé: “Ìṣòro ohun tí àwa ì bá máa gbàdúrà fún bí ó ti yẹ kí a ṣe ni àwa kò mọ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa pẹ̀lú àwọn ìkérora tí a kò sọ jáde. Síbẹ̀síbẹ̀, ẹni tí ń wá inú ọkàn-àyà mọ ohun tí ẹ̀mí túmọ̀ sí, nítorí ó ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú Ọlọ́run fún àwọn ẹni mímọ́.” (Róòmù 8:26, 27) Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Jóòbù, Sáàmù àti Òwe, a ó lè máa sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wa gan-an fún Jèhófà.

20, 21. Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Fílípì 4:6, 7 ṣe tù wá nínú?

20 Bí ìdààmú ọkàn bá dé bá wa, ẹ jẹ́ ká fi ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ sí àwọn ará tó wà ní Fílípì sílò. Ó sọ pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.” Tá a bá sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lọ́kàn wa fún Ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ yìí, ó dájú pé a máa rí ìtùnú gbà, ọkàn wa á sì balẹ̀ torí Pọ́ọ̀lù fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílí. 4:6, 7) Ǹjẹ́ ká túbọ̀ máa mọyì “àlàáfíà Ọlọ́run” tí kò láfiwé tó sì dájú pé ó ń ṣọ́ ọkàn àti èrò orí wa.

Báwo ni àdúrà ṣe ń mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run túbọ̀ lágbára? (Wo ìpínrọ̀ 21)

21 Àdúrà máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè bá Jèhófà dọ́rẹ̀ẹ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa “gbàdúrà láìdabọ̀.” (1 Tẹs. 5:17) Ǹjẹ́ kí ohun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tán yìí mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run túbọ̀ lágbára, kó sì mú ká túbọ̀ pinnu pé a ó máa fi ìlànà òdodo rẹ̀ darí ìgbésí ayé wa. Ẹ sì jẹ́ ká máa wá àkókò láti ṣàṣàrò lórí àwọn ìbùkún tá à ń gbádùn torí ó dájú pé Jèhófà ni Baba wa, Òun ni Ọlọ́run wa àti Ọ̀rẹ́ wa.