Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọlọ́run San Opó Sáréfátì Lẹ́san Torí Ìgbàgbọ́ Rẹ̀

Ọlọ́run San Opó Sáréfátì Lẹ́san Torí Ìgbàgbọ́ Rẹ̀

OPÓ aláìní kan gbá ọmọkùnrin kan ṣoṣo tó bí mọ́ra. Bí àlá ni ọ̀rọ̀ náà rí lójú rẹ̀, torí pé kò tíì pẹ́ sígbà yẹn tó gbé òkú ọmọ náà sọ́wọ́. Àmọ́ ní báyìí, ńṣe ni inú rẹ̀ ń dùn bó ṣe ń wo ẹ̀rín lẹ́nu ọmọ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jíǹde yìí. Ẹni tó dé bá a lálejò wá sọ fún un pé, “Wò ó, ọmọkùnrin rẹ yè.”

Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún sẹ́yìn ni àjíǹde tó pabanbarì yìí wáyé. O lè kà nípa rẹ̀ nínú 1 Àwọn Ọba orí 17. Èlíjà tí í ṣe wòlíì Ọlọ́run ni àlejò náà. Ta wá ni ìyá ọmọ tó jíǹde náà? Opó kan tí Bíbélì kò sọ orúkọ rẹ̀ tó ń gbé ní ìlú Sáréfátì ni. Àjíǹde ọmọ rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó tíì fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun jù lọ. Bá ó ṣe máa gbé ìtàn obìnrin náà yẹ̀ wò, a máa rí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì díẹ̀ kọ́.

ÈLÍJÀ RÍ OPÓ TÓ NÍ ÌGBÀGBỌ́

Jèhófà ti pinnu pé òun máa mú kí ọ̀dá dá fún àkókò gígùn nígbà ìṣàkóso Áhábù, ọba búburú tó jẹ lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn tí Èlíjà ti sọ pé ọ̀dá máa dá, Ọlọ́run fi í pa mọ́ kí Áhábù má bàa rí i. Ó wá ń bọ́ wòlíì náà lọ́nà ìyanu nípa mímú kí àwọn ẹyẹ ìwò máa gbé búrẹ́dì àti ẹran wá fún un. Jèhófà wá sọ fún Èlíjà pé: “Dìde, lọ sí Sáréfátì, èyí tí ó jẹ́ ti Sídónì, kí o sì máa gbé níbẹ̀. Wò ó! Dájúdájú, èmi yóò pàṣẹ fún obìnrin kan níbẹ̀, tí ó jẹ́ opó, pé kí ó máa pèsè oúnjẹ fún ọ.”—1 Ọba 17:1-9.

Nígbà tí Èlíjà dé Sáréfátì, ó rí opó aláìní kan tó ń ṣa igi jọ. Àbí obìnrin yìí ló máa pèsè oúnjẹ fún wòlíì náà? Báwo ni obìnrin náà ṣe máa rí oúnjẹ fún un, nígbà tó jẹ́ pé aláìní lòun fúnra rẹ̀? Láìka ohun tó ṣeé ṣe kí Èlíjà máa rò lọ́kàn, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá obìnrin náà sọ̀rọ̀. Ó ní: “Jọ̀wọ́, fi ohun èlò bu òfèrè omi kan wá fún mi kí n lè mu.” Bó ṣe ń lọ bu omi náà wá, Èlíjà tún sọ pé: “Jọ̀wọ́, bá mi mú oúnjẹ díẹ̀ lọ́wọ́.” (1 Ọba 17:10, 11) Kò ṣòro fún opó náà láti fún àlejò yìí lómi, ṣùgbọ́n bí yóò ṣe rí búrẹ́dì tó máa fún un nìṣòro.

 Obìnrin opó náà wá fèsì pé: “Bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti ń bẹ, èmi kò ní àkàrà ribiti kankan, bí kò ṣe ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun nínú ìṣà títóbi àti òróró díẹ̀ nínú ìṣà kékeré; sì kíyè sí i, èmi ń ṣa igi díẹ̀ jọ, èmi yóò sì wọlé lọ ṣe nǹkan kan fún ara mi àti ọmọkùnrin mi, àwa yóò sì jẹ ẹ́, a ó sì kú.” (1 Ọba 17:12) Ẹ jẹ́ ká ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí ọ̀rọ̀ tí wọ́n jọ sọ yìí túmọ̀ sí.

Opó náà rí i pé ọmọ Ísírẹ́lì tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni Èlíjà. Èyí ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ tó sọ pé “bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti ń bẹ.” Ó jọ pé bí obìnrin náà tilẹ̀ mọ àwọn nǹkan kan nípa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kò mọ̀ ọ́n débi tó fi lè sọ pé “Ọlọ́run mi” nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà. Sáréfátì ni opó náà ń gbé, ìyẹn ìlú kan “tí ó jẹ́ ti” Sídónì tó wà ní Fòníṣíà. Ó tún ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn tó ń bọ òrìṣà Báálì ni wọ́n ń gbé ní Sáréfátì. Bó ti wù kó rí, Jèhófà rí ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa opó náà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárín àwọn abọ̀rìṣà ni opó Sáréfátì tó jẹ́ aláìní náà ń gbé, ó lo ìgbàgbọ́. Nítorí ti wòlíì Èlíjà àti nítorí ti opó náà fúnra rẹ̀ ni Jèhófà ṣe rán Èlíjà sí i. A lè rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kan fà yọ nínú èyí.

Ẹ̀kọ́ náà ni pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú tí wọ́n ti ń bọ òrìṣà Báálì ni Sáréfátì, kì í ṣe gbogbo àwọn tó ń gbé nílùú náà ni ìwà wọn burú jáì. Bí Jèhófà ṣe rán Èlíjà sí opó yìí fi hàn pé Ó máa ń kíyè sí àwọn èèyàn tó lọ́kàn tó dára àmọ́ tí wọn ò tíì máa sìn Ín. Kódà, “ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù [Ọlọ́run], tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:35.

Mélòó lára àwọn èèyàn tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ rẹ ló dà bí opó Sáréfátì yìí? Bí wọ́n bá tilẹ̀ wà láàárín àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn èké, ó lè máa wù wọ́n láti ṣe ìsìn tòótọ́. Wọ́n lè má fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Jèhófà, torí náà wọ́n máa nílò ẹni táá ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe ìsìn tòótọ́. Ǹjẹ́ ò ń wá irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, tó o bá sì rí wọn ṣé o máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́?

“KỌ́KỌ́ ṢE ÀKÀRÀ RIBITI KÉKERÉ KAN FÚN MI”

Fara balẹ̀ ronú lórí ohun tí Èlíjà ní kí opó náà ṣe. Ńṣe ni opó náà ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún Èlíjà pé lẹ́yìn tí òun bá ti wá oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo fún òun àti ọmọkùnrin òun, àwọn á jẹ ẹ́, àwọn á sì kú. Síbẹ̀, kí ni Èlíjà sọ? Ó sọ pé: “Má fòyà. Wọlé lọ, ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Kìkì pé kí o kọ́kọ́ ṣe àkàrà ribiti kékeré kan fún mi lára ohun tí ó wà níbẹ̀, kí o sì mú un jáde tọ̀ mí wá, lẹ́yìn ìgbà náà, o lè ṣe nǹkan kan fún ara rẹ àti ọmọkùnrin rẹ. Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Ìṣà títóbi ti ìyẹ̀fun kì yóò ṣófo, ìṣà kékeré ti òróró kì yóò sì gbẹ, títí di ọjọ́ tí Jèhófà yóò mú kí eji wọwọ dé sórí ilẹ̀.’”—1 Ọba 17:11-14.

Àwọn kan ì bá ti sọ pé, ‘Kí n gbé oúnjẹ tó kù fún wa sílẹ̀ fún ẹ? Àwàdà lásán lò ń ṣe.’ Àmọ́ opó yẹn ò sọ bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ mọ Jèhófà, ó gba ohun tí Èlíjà sọ gbọ́, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ fún un. Ẹ ò rí i pé ìdánwò ìgbàgbọ́ tó gadabú nìyẹn, ẹ sì wo ìpinnu ọlọgbọ́n tó ṣe!

Ìgbàgbọ́ tí opó náà ní nínú Jèhófà, Ọlọ́run Èlíjà ló mú kí Ọlọ́run dá ẹ̀mí òun àti ọmọ rẹ̀ sí

Ọlọ́run ò fi opó aláìní yẹn sílẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Èlíjà ṣe sọ, Jèhófà sọ oúnjẹ tí kò tó nǹkan náà di púpọ̀, débi pé Èlíjà, opó náà àti ọmọ rẹ̀ rí oúnjẹ jẹ títí tí òjò fi rọ̀. Ní tòótọ́, “ìṣà títóbi ti ìyẹ̀fun náà kò ṣófo, ìṣà kékeré ti òróró náà kò sì gbẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó sọ nípasẹ̀ Èlíjà.” (1 Ọba 17:16; 18:1) Ká  ní obìnrin yẹn ò ṣe ohun tí Èlíjà sọ fún un ni, ó lè jẹ́ pé àkàrà ribiti tó fi ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun àti òróró díẹ̀ ṣe yẹn lòun àti ọmọ rẹ̀ ì bá jẹ kẹ́yìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó lo ìgbàgbọ́, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà, ó sì kọ́kọ́ wá oúnjẹ fún Èlíjà.

Ẹ̀kọ́ kan tí èyí kọ́ wa ni pé Ọlọ́run máa ń bù kún àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́. Tó o bá dojú kọ ìdánwò ìwà títọ́ tó o sì lo ìgbàgbọ́, Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ó máa jẹ́ Olùpèsè, Olùdáàbòbò àti Ọ̀rẹ́ rẹ kó bàa lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara da àdánwò rẹ.—Ẹ́kís. 3:13-15.

Ní ọdún 1898, ẹ̀kọ́ tí ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower fà yọ nínú ìtàn opó náà ni pé: “Bí obìnrin náà bá ní ìgbàgbọ́ tó mú kó ṣègbọràn, nígbà náà Olúwa máa kà á sí ẹni tó yẹ kí òun ràn lọ́wọ́ nípasẹ̀ Wòlíì náà; bí kò bá lo ìgbàgbọ́, ó ṣeé ṣe ká rí opó míì tó máa ṣe bẹ́ẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ tiwa náà ṣe rí nìyẹn, bí ojúmọ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe ń mọ́, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń mú ká gba ibi tó ti lè dán ìgbàgbọ́ wa wò kọjá. Tá a bá wá lo ìgbàgbọ́, a máa rí ìbùkún gbà; àmọ́ tá ò bá lo ìgbàgbọ́, ìbùkún náà kò ní tẹ̀ wá lọ́wọ́.”

Tá a bá dojú kọ àwọn àdánwò pàtó kan, ó pọn dandan ká wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run nínú Ìwé Mímọ́ àti nínú àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Lẹ́yìn náà, ká wá tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà láìka bó ti wù kó ṣòro tó. Ó dájú pé Jèhófà máa bù kún wa tá a bá ṣe ohun tí òwe tó fa ọgbọ́n yọ yìí sọ, pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”—Òwe 3:5, 6.

‘ṢÓ O WÁ PA ỌMỌKÙNRIN MI NI?’

Ó ṣì ku ohun kan tó máa dán ìgbàgbọ́ opó náà wò. Bíbélì sọ pé: “Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí pé ọmọkùnrin obìnrin náà, ìyá ilé náà, dùbúlẹ̀ àìsàn, àìsàn rẹ̀ sì wá le tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò fi ṣẹ́ ku èémí kankan nínú rẹ̀ mọ́.” Abiyamọ tó ń ṣọ̀fọ̀ yìí ń fẹ́ mọ ohun tó fa àjálù tó dé bá òun, ó wá bi Èlíjà pé: “Kí ní pa tèmi tìrẹ pọ̀, ìwọ ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́? Ṣe ni o tọ̀ mí wá láti mú ìṣìnà mi wá sí ìrántí àti láti fi ikú pa ọmọkùnrin mi.” (1 Ọba 17:17, 18) Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ kíkorò yẹn túmọ̀ sí?

Ṣé obìnrin náà rántí ẹ̀ṣẹ̀ kan tó ń da ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ láàmú ni? Àbí ńṣe ló rò pé ẹ̀san Ọlọ́run ló ké tí ọmọ òun fi kú àti pé Èlíjà ni Ọlọ́run rán pé kó wá pa ọmọ náà? Bíbélì ò sọ fún wa, àmọ́ ohun kan ṣe kedere: Opó náà kò fi ẹ̀sùn ìwà àìṣòdodo èyíkéyìí kan Ọlọ́run.

Ó dájú pé ó máa ya Èlíjà lẹ́nu pé ọmọ opó náà kú àti pé obìnrin náà rò pé bí òun ṣe wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ló mú kí ọ̀fọ̀ náà ṣẹ òun. Lẹ́yìn tí Èlíjà ti gbé ọmọ tí ara rẹ̀ rọ jọwọrọ náà lọ sí ìyẹ̀wù òrùlé, ó ké pe Jèhófà pé: “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, ṣé opó tí mo ń ṣe àtìpó lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìwọ yóò tún mú èṣe wá bá, nípa fífi ikú pa ọmọkùnrin rẹ̀?” Wòlíì náà ronú pé àwọn èèyàn máa kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run tó bá lọ yọ̀ǹda pé kírú ìyà yìí tún jẹ obìnrin náà. Kò sì fẹ́ káwọn èèyàn ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣe tán, èèyàn dáadáa ní obìnrin yìí, òun ló sì gba òun sílé. Torí náà, Èlíjà bẹ Jèhófà pé: “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́, mú kí ọkàn ọmọ yìí padà wá sínú rẹ̀.”—1 Ọba 17:20, 21.

“WÒ Ó, ỌMỌKÙNRIN RẸ YÈ”

Jèhófà gbọ́ àdúrà wòlíì náà. Ó ṣe tán, opó náà ló ti ń ṣètọ́jú wòlíì rẹ̀, ó sì ti lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Ọlọ́run yọ̀ǹda kí àìsàn ọmọ náà yọrí sí ikú torí ó mọ̀ pé àjíǹde kan máa tó wáyé, èyí tó sì máa mú kí àwọn ìran tó ń bọ̀ lẹ́yìn ní ìrètí nínú àjíǹde. Àjíǹde yìí sì ni àkọ́kọ́ nínú Ìwé Mímọ́. Nígbà tí Èlíjà gbàdúrà, Jèhófà jí ọmọ náà dìde. Ẹ wo bí inú opó náà ṣe máa dùn tó nígbà tí Èlíjà sọ pé: “Wò ó, ọmọkùnrin rẹ yè”! Lẹ́yìn yẹn ni opó náà wá sọ fún Èlíjà pé: “Mo mọ̀ wàyí, ní tòótọ́, pé ìwọ jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run àti pé ọ̀rọ̀ Jèhófà ní ẹnu rẹ jẹ́ òótọ́.”—1 Ọba 17:22-24.

Ibi ti 1 Àwọn Ọba orí 17 bá ọ̀rọ̀ obìnrin náà dé nìyí tí kò fi sọ nǹkan kan nípa rẹ̀ mọ́. Àmọ́, tá a bá rántí pé Jésù sọ̀rọ̀ obìnrin náà ní rere, a máa gbà pé ó ṣeé ṣe kí obìnrin náà sin Jèhófà títí tó fi kú. (Lúùkù 4:25, 26) Ìtàn obìnrin náà kọ́ wa pé Ọlọ́run máa ń bù kún àwọn tó bá ń ṣe dáadáa sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. (Mát. 25:34-40) Ó fi hàn pé Ọlọ́run máa ń pèsè fún àwọn adúróṣinṣin, kódà lábẹ́ àwọn ipò tó le koko. (Mát. 6:25-34) Ìtàn yìí tún jẹ́ ká rí i pé ó wu Jèhófà láti jí àwọn òkú dìde ó sì lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Ìṣe 24:15) Láìsí àní-àní, gbogbo èyí jẹ́ ìdí tó dára tó fi yẹ ká máa rántí opó Sáréfátì.