Ǹjẹ́ Ò Ń Bá Ètò Jèhófà Rìn Bó Ṣe Ń Tẹ̀ Síwájú?
“Ojú Jèhófà ń bẹ lára àwọn olódodo.” —1 PÉT. 3:12.
JÈHÓFÀ nìkan ló tọ́ ká máa gbógo fún pé òun ló dá ìjọ Kristẹni ti ọ̀rúndún kìíní sílẹ̀, òun náà sì ni ọpẹ́ yẹ fún mímú ìjọsìn tòótọ́ pa dà bọ̀ sípò láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, ètò kan tí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tó wà ní ọ̀rúndún kìíní jẹ́ apá kan rẹ̀ ni Jèhófà fi rọ́pò orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà kí wọ́n lè máa gbé orúkọ rẹ̀ ga. Ọlọ́run ṣe ojúure sí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kó jọ sínú ètò rẹ̀ yìí lọ́nà àkànṣe, wọ́n sì la ìparun Jerúsálẹ́mù já lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni. (Lúùkù 21:20, 21) Ńṣe ni àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní yẹn jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn nǹkan tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní. Ètò àwọn nǹkan Sátánì yìí máa tó wá sópin, àmọ́ ètò Ọlọ́run máa la àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí já. (2 Tím. 3:1) Kí ló mú kó dá wa lójú pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ máa rí?
2. Kí ni Jésù sọ nípa “ìpọ́njú ńlá,” báwo ló sì ṣe máa bẹ̀rẹ̀?
2 Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀ tá ò lè fojú rí àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan, ó sọ pé: “Ìpọ́njú ńlá yóò wà, irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.” (Mát. 24:3, 21) Ìpọ́njú tí kò sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yìí máa bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Jèhófà bá lo àwọn olóṣèlú láti pa “Bábílónì Ńlá” tí í ṣe ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé run. (Ìṣí. 17:3-5, 16) Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?
ÌGBÌDÁNWÒ SÁTÁNÌ MÁA YỌRÍ SÍ OGUN AMÁGẸ́DỌ́NÌ
3. Lẹ́yìn tí ìsìn èké bá ti pa run, báwo ni Sátánì ṣe máa gbìdánwò láti kọ lu àwọn èèyàn Jèhófà?
3 Lẹ́yìn tí ìsìn èké bá ti pa run, Sátánì àtàwọn onírúurú ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ máa kọ lu àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ìwé Mímọ́ ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù,” ó sọ pé: “Ìwọ yóò wá bí ìjì. Ìwọ yóò rí bí àwọsánmà láti bo ilẹ̀ náà, ìwọ àti gbogbo àwùjọ ọmọ ogun rẹ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ.” Torí pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ní àwọn ẹgbẹ́ ológun àti pé àwa la jẹ́ èèyàn àlàáfíà jù lọ láyé, wọ́n máa gbà pé wẹ́rẹ́ báyìí làwọn máa yanjú wa. Àmọ́, ńṣe ni wọ́n máa kan ìdin nínú iyọ̀!—Ìsík. 38:1, 2, 9-12.
4, 5. Kí ni Jèhófà máa ṣe nígbà tí Sátánì bá gbìdánwò láti pa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ run?
4 Kí ni Ọlọ́run máa ṣe nígbà tí Sátánì bá ń sapá láti pa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ run? Jèhófà máa gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀, yóò sì lo ọlá àṣẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Jèhófà máa kà á sí pé òun lẹni tó bá kọ lu àwọn ìránṣẹ́ òun kọ lù. (Ka Sekaráyà 2:8.) Nípa bẹ́ẹ̀, Baba wa ọ̀run máa gbé ìgbésẹ̀ lọ́gán kó lè dá wa nídè. Ìdáǹdè yìí ló máa wá yọrí sí ìparun ayé Sátánì nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, ìyẹn “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.”—Ìṣí. 16:14, 16.
5 Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan sọ nípa ogun Amágẹ́dọ́nì pé: “‘Ìjà kan wà tí Jèhófà ní pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè. Òun alára yóò wọnú ìdájọ́ pẹ̀lú gbogbo ẹran ara. Ní ti àwọn ẹni burúkú, òun yóò fi wọ́n fún idà,’ ni àsọjáde Jèhófà. Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Wò ó! Ìyọnu àjálù kan ń jáde lọ láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè, ìjì líle sì ni a ó ru dìde láti apá jíjìnnàréré jù lọ ní ilẹ̀ ayé. Àwọn tí Jèhófà pa yóò sì wà dájúdájú ní ọjọ́ yẹn láti ìpẹ̀kun kan ilẹ̀ ayé títí lọ dé ìpẹ̀kun kejì ilẹ̀ ayé. A kì yóò pohùn réré ẹkún nítorí wọn, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò kó wọn jọpọ̀ tàbí kí a sin wọ́n. Bí ajílẹ̀ lórí ilẹ̀ ni wọn yóò dà.’” (Jer. 25:31-33) Amágẹ́dọ́nì ló máa mú ètò àwọn nǹkan búburú yìí wá sópin. Àfẹ́kù á bá ayé Sátánì, àmọ́ mìmì kan ò ní mi apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà.
ÌDÍ TÍ ÈTÒ JÈHÓFÀ FI Ń GBÈRÚ LÓNÌÍ
6, 7. (a) Ibo ni àwọn tó para pọ̀ jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti wá? (b) Àwọn ìbísí wo ló ti wáyé láwọn ọdún àìpẹ́ yìí?
6 Ètò Ọlọ́run ń jàjàyè ó sì ń gbèrú lórí ilẹ̀ ayé torí pé àwọn tí Ọlọ́run yọ́nú sí ló wà nínú ètò náà. Bíbélì mú kó dá wa lójú pé: “Ojú Jèhófà ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn.” (1 Pét. 3:12) Lára àwọn olódodo yìí ni “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó “jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà.” (Ìṣí. 7:9, 14) Àwọn tó là á já yìí kì í wulẹ̀ ṣe “ogunlọ́gọ̀” lásán. “Ogunlọ́gọ̀ ńlá” ni wọ́n, ìyẹn ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn. Ǹjẹ́ ìwọ náà ń rí ara rẹ láàárín ogunlọ́gọ̀ ńlá tó la “ìpọ́njú ńlá” já yìí?
7 Ibo làwọn tó para pọ̀ jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá ti wá? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jésù sọ pé ó máa jẹ́ apá kan àmì wíwàníhìn-ín òun. Ó sọ pé: ‘A ó wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.’ (Mát. 24:14) Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, iṣẹ́ yìí ló gbawájú lára iṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run ń ṣe. Látàrí bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń wàásù tá a sì ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ kárí ayé, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti wá mọ bí wọ́n ṣe lè máa jọ́sìn Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòh. 4:23, 24) Bí àpẹẹrẹ, ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún iṣẹ́ ìsìn 2003 títí dé 2012, àwọn tó ju mílíọ̀nù méjì, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méje ó lé méje [2,707,000] ló ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Ní báyìí, àwa Ẹlẹ́rìí tá a wà kárí ayé ti lé ní mílíọ̀nù méje àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [7,900,000], ọ̀kẹ́ àìmọye ló sì ń dara pọ̀ mọ́ wa, pàápàá jù lọ nígbà Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún. Kì í ṣe pé à ń fi iye tá a jẹ́ yangàn, torí a mọ̀ pé ‘Ọlọ́run ló ń mú kí ó dàgbà.’ (1 Kọ́r. 3:5-7) Bó ti wú kó rí, ó ṣe kedere pé ńṣe ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ń pọ̀ sí i tó sì tún ń gbèrú lọ́dọọdún.
8. Kí ló ń mú kí ètò Jèhófà máa bí sí i lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lóde òní?
8 Ohun tó ń mú kí àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa pọ̀ sí i lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń ti àwa Ẹlẹ́rìí rẹ̀ lẹ́yìn. (Ka Aísáyà 43:10-12.) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ìbísí yìí máa wáyé, ó sọ pé: “Ẹni tí ó kéré yóò di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré yóò sì di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè. Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò mú un yára kánkán ní àkókò rẹ̀.” (Aísá. 60:22) Ìgbà kan wà tí àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró dà bí “ẹni kékeré,” àmọ́ wọ́n ń pọ̀ níye bí àwọn míì tó jẹ́ ara Ísírẹ́lì tẹ̀mí ṣe ń wá sínú ètò Ọlọ́run. (Gál. 6:16) Torí pé Jèhófà ń bù kún wọn bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, ìbísí náà ò dúró bí wọ́n ṣe ń kó àwọn tó jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá jọ.
OHUN TÍ JÈHÓFÀ FẸ́ KÁ MÁA ṢE
9. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ tí Ọlọ́run ṣèlérí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè jẹ́ tiwa?
9 Yálà a jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró tàbí a wà lára ogunlọ́gọ̀ ńlá, ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ tí Ọlọ́run ṣèlérí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè jẹ́ tiwa. Àmọ́ o, kó tó lè jẹ́ tiwa, a gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn ohun tí Jèhófà fẹ́. (Aísá. 48:17, 18) Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n wà lábẹ́ Òfin Mósè. Ọ̀kan lára ìdí tí Ọlọ́run fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin ni pé kó lè dáàbò bò wọ́n. Torí bẹ́ẹ̀, ó fún wọn láwọn ìlànà tó gbámúṣé tí wọ́n lè máa tẹ̀ lé lórí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀, òwò ṣíṣe, ọmọ títọ́, bí wọ́n ṣe lè jẹ́ kí àjọṣe àárín ara wọn dán mọ́rán àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (Ẹ́kís. 20:14; Léf. 19:18, 35-37; Diu. 6:6-9) Tí àwa náà bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, a máa gbádùn irú àǹfààní kan náà yìí, a ò sì ní ka ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀ sí ẹrù ìnira. (Ka 1 Jòhánù 5:3.) Kódà, bí Òfin ṣe dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà Ọlọ́run ṣe máa dáàbò bò wá tá a bá ń fi wọ́n sílò. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún máa mú ká jẹ́ “onílera nínú ìgbàgbọ́.”—Títù 1:13.
10. Kí nìdí tó fi yẹ ká ya àkókò sọ́tọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ṣíṣe Ìjọsìn Ìdílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀?
10 Onírúurú ọ̀nà ni apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà gbà ń tẹ̀ síwájú. Bí àpẹẹrẹ, lemọ́lemọ́ ni òye wa nípa òtítọ́ Bíbélì túbọ̀ ń ṣe kedere. Bó sì ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn, torí pé “ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ mímọ́lẹ̀ yòò, tí ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, títí di ọ̀sán gangan.” (Òwe 4:18) Àmọ́, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ mò ń lóye àwọn àtúnṣe tí ètò Ọlọ́run ń ṣe sí òye tá a ní nípa àwọn ẹ̀kọ́ inú Ìwé Mímọ́? Ṣé ó ti di àṣà mi pé kí n máa ka Bíbélì lójoojúmọ́? Ṣé mo máa ń hára gàgà láti ka àwọn ìwé wa? Ṣé èmi àtàwọn tá a jọ wà nínú ìdílé mi máa ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀?’ Èyí tó pọ̀ jù lọ lára wa ló máa gbà pé àwọn nǹkan yìí kò ṣòro láti ṣe. Àmọ́, ohun tó sábà máa ń gbà ni pé ká ya àkókò sọ́tọ̀ láti máa ṣe wọ́n. Ẹ sì wo bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ látinú Ìwé Mímọ́, ká máa fi ohun tá a kọ́ sílò, ká sì máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, pàápàá jù lọ ní báyìí tí ìpọ́njú ńlá túbọ̀ ń sún mọ́lé!
11. Àǹfààní wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rí nínú àwọn ayẹyẹ tí wọ́n máa ń ṣe nígbà yẹn? Àǹfààní wo làwọn ìpàdé àti onírúurú àpéjọ tá à ń ṣe lónìí ń ṣe wá?
11 Ire wa ni ètò Jèhófà ń wá bó ṣe ń rọ̀ wá pé ká fi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sílò, èyí tó sọ pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” (Héb. 10:24, 25) Àwọn ayẹyẹ ọdọọdún àtàwọn ìkórajọ míì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe láti jọ́sìn Ọlọ́run máa ń mú kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Síwájú sí i, àwọn ayẹyẹ àkànṣe, bí Àjọyọ̀ Àtíbàbà tí wọ́n ṣe lọ́jọ́ Nehemáyà mú kí inú àwọn èèyàn náà dùn gan-an. (Ẹ́kís. 23:15, 16; Neh. 8:9-18) Irú àǹfààní yìí náà la máa ń rí ní àwọn ìpàdé àti onírúurú àpéjọ wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa lo àwọn ìṣètò yìí dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ká lè ní ìlera tó jí pépé nípa tẹ̀mí, ká sì lè láyọ̀.—Títù 2:2.
12. Báwo ló ṣe yẹ kí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run rí lára wa?
12 Torí pé a wà nínú ètò Ọlọ́run, a láyọ̀ pé à ń lọ́wọ́ nínú “iṣẹ́ mímọ́ ti ìhìn rere Ọlọ́run.” (Róòmù 15:16) Bá a ṣe ń lọ́wọ́ nínú “iṣẹ́ mímọ́” yìí ń mú ká jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” pẹ̀lú Jèhófà, tí ó jẹ́ “Ẹni Mímọ́.” (1 Kọ́r. 3:9; 1 Pét. 1:15) Iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tá à ń ṣe ń mú ká máa ya orúkọ mímọ́ Jèhófà sí mímọ́. Ó sì dájú pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ló jẹ́ pé a fi “ìhìnrere ológo ti Ọlọ́run aláyọ̀” yìí sí ìkáwọ́ wa.—1 Tím. 1:11.
13. Tá a bá fẹ́ ní ìlera tó jí pépé nípa tẹ̀mí ká sì máa wà láàyè, kí la gbọ́dọ̀ máa ṣe?
13 Ọlọ́run fẹ́ ká rọ̀ mọ́ òun ká sì máa kọ́wọ́ ti onírúurú ìgbòkègbodò tó ń lọ nínú ètò òun ká bàa lè gbádùn ìlera tó jí pépé nípa tẹ̀mí. Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Èmi ń fi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ṣe ẹlẹ́rìí lòdì sí yín lónìí, pé èmi ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, ìbùkún àti ìfiré; kí o sì yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè nìṣó, ìwọ àti ọmọ rẹ, nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nípa fífetí sí ohùn rẹ̀ àti nípa fífà mọ́ ọn; nítorí òun ni ìyè rẹ àti gígùn ọjọ́ rẹ, kí ìwọ lè máa gbé lórí ilẹ̀ tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù láti fi fún wọn.” (Diu. 30:19, 20) Tá a bá fẹ́ máa wà láàyè nìṣó, ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà, ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ká máa ṣègbọràn sí i, ká sì rọ̀ mọ́ ọn.
14. Ojú wo ni arákùnrin kan fi wo apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Ọlọ́run?
14 Arákùnrin Pryce Hughes, tó rọ̀ mọ́ Ọlọ́run láìyẹsẹ̀ tí kò sì jẹ́ kí ètò Ọlọ́run ya òun sílẹ̀ lẹ́sẹ̀ kan, kọ̀wé nígbà kan pé: ‘Mo dúpẹ́ gidigidi pé mo jẹ́ kí ohun tí mo mọ̀ nípa ète Jèhófà nígbà yẹn lọ́hùn-ún ṣáájú ọdún 1914 máa darí mi . . . Bí ohunkóhun bá wà tó ṣe pàtàkì sí mi jù lọ, ọ̀ràn rírọ̀ mọ́ apá tó ṣeé fojú rí lára ètò Jèhófà ni. Látinú ìrírí tí mo ní nígbà yẹn lọ́hùn-ún ni mo ti mọ̀ pé kò bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn máa gbára lé ìrònú ẹ̀dá èèyàn. Gbàrà tí mo ti mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni mo ti pinnu láti dúró ti ètò tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Àbí, ọ̀nà míì wo lèèyàn tún lè gbà rí ojú rere Jèhófà àti ìbùkún rẹ̀?’
MÁA BÁ ÈTÒ JÈHÓFÀ RÌN BÓ ṢE Ń TẸ̀ SÍWÁJÚ
15. Sọ àpẹẹrẹ kan látinú Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ ká mọ ojú tó yẹ ká fi máa wo àtúnṣe tó ń bá òye wa nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì.
15 Bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bá máa rí ojúure Jèhófà àti ìbùkún rẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa kọ́wọ́ ti ètò rẹ̀ lẹ́yìn ká sì mọyì àwọn àtúnṣe tó ń bá òye wa nípa àwọn ẹ̀kọ́ inú Ìwé Mímọ́. Wò ó báyìí ná: Lẹ́yìn ikú Jésù, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kristẹni kan wà tí wọ́n jẹ́ Júù tí wọ́n ní ìtara fún Òfin, tó sì ṣòro fún wọn láti jáwọ́ nínú rẹ̀. (Ìṣe 21:17-20) Àmọ́, nígbà tí wọ́n gba lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù, wọ́n gbà pé a ti sọ àwọn di mímọ́, kì í ṣe nípasẹ̀ àwọn ẹbọ “tí a ń rú ní ìbámu pẹ̀lú Òfin” bí kò ṣe “nípasẹ̀ ìfirúbọ ara Jésù Kristi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé.” (Héb. 10:5-10) Kò sí àní-àní pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù yẹn ló yí èrò wọn pa dà tí wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Ó ṣe pàtàkì pé kí àwa náà máa kẹ́kọ̀ọ́ taápọntaápọn ká sì ṣe tán láti yí èrò wa pa dà bí àtúnṣe tó wáyé bá kan òye tá a ní nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàbí iṣẹ́ ìwàásù wa.
16 Ìbùkún tí kò lópin ni gbogbo àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àti ètò rẹ̀ máa rí gbà. Àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ adúróṣinṣin máa ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ní ti pé wọ́n máa jẹ́ ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run. (Róòmù 8:16, 17) Tá a bá sì ní ìrètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé, ẹ wo bó ṣe máa gbádùn mọ́ wa tó láti gbé nínú Párádísè! Torí pé a wà nínú ètò Jèhófà, ayọ̀ wa ò lẹ́gbẹ́ bá a ṣe ń sọ fún àwọn èèyàn nípa ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí! (2 Pét. 3:13) Ìwé Sáàmù 37:11 sọ pé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” Àwọn èèyàn “yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn” wọ́n á sì gbádùn “iṣẹ́ ọwọ́ wọn.” (Aísá. 65:21, 22) Kò ní sí ìnilára, ipò òṣì àti ebi mọ́. (Sm. 72:13-16) Bábílónì Ńlá ò tún ní tan ẹnikẹ́ni jẹ mọ́, torí pé kò tiẹ̀ ní sí mọ́. (Ìṣí. 18:8, 21) Ọlọ́run máa jí àwọn òkú dìde, á sì fún wọn láǹfààní láti wà láàyè títí láé. (Aísá. 25:8; Ìṣe 24:15) Ẹ wo àwọn ohun àgbàyanu tó ń dúró de ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà! Kí ìmúṣẹ àwọn ìlérí tó wà nínú Ìwé Mímọ́ yìí tó lè ṣojú wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ká máa bá ètò Ọlọ́run rìn bó ṣe ń tẹ̀ síwájú, ká má sì ṣe jẹ́ kó yà wá sílẹ̀ lẹ́sẹ̀ kan.
17. Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká ní tó bá kan ìjọsìn Jèhófà àti ètò rẹ̀?
17 Níwọ̀n bí òpin ètò nǹkan ìsinsìnyí ti sún mọ́lé gan-an, ǹjẹ́ ká túbọ̀ di ìgbàgbọ́ wa mú ṣinṣin, ká sì máa fi hàn pé a ní ìmọrírì tó jinlẹ̀ fún ètò tí Ọlọ́run ṣe láti máa jọ́sìn rẹ̀. Irú ẹ̀mí tí Dáfídì, onísáàmù náà ní nìyẹn. Ó sọ pé: “Ohun kan ni mo béèrè lọ́wọ́ Jèhófà. Ìyẹn ni èmi yóò máa wá, kí n lè máa gbé inú ilé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé mi, kí n lè máa rí adùn Jèhófà kí n sì lè máa fi ẹ̀mí ìmọrírì wo tẹ́ńpìlì rẹ̀.” (Sm. 27:4) Ǹjẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa rọ̀ mọ́ Ọlọ́run, ká máa kẹ́sẹ̀ rìn pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀ ká sì máa rìn pẹ̀lú ètò Jèhófà bí ètò náà ṣe ń tẹ̀ síwájú.