Ọlọ́run Ètò Ni Jèhófà
“Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run rúdurùdu, bí kò ṣe ti àlàáfíà.”—1 KỌ́R. 14:33.
LÉTÒLÉTÒ ni Jèhófà, Ẹlẹ́dàá ọ̀run àti ayé máa ń ṣe nǹkan. Ẹni tó kọ́kọ́ dá ni Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí. Ọlọ́run pè é ní “Ọ̀rọ̀ náà” torí pé òun ni olórí agbọ̀rọ̀sọ rẹ̀. Ọjọ́ pẹ́ tí Ọ̀rọ̀ yìí ti ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà, torí Bíbélì sọ pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni Ọ̀rọ̀ náà wà, Ọ̀rọ̀ náà sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run.” Bíbélì tún sọ fún wa pé: “Ohun gbogbo di wíwà nípasẹ̀ rẹ̀ [ìyẹn Ọ̀rọ̀ náà], àti pé láìsí i, àní ohun kan kò di wíwà.” Ní nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún ó lé díẹ̀ sẹ́yìn, Ọlọ́run rán Ọ̀rọ̀ náà wá sáyé gẹ́gẹ́ bí ẹni pípé, ó sì fòótọ́ inú ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀. Òun la wá mọ̀ sí Jésù Kristi.—Jòh. 1:1-3, 14.
1, 2. (a) Ta ni Jèhófà kọ́kọ́ dá, iṣẹ́ wo ló sì fún un ṣe? (b) Kí ló fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì wà létòlétò?
2 Kó tó di pé Ọmọ Ọlọ́run yìí wá sáyé, tọkàntọkàn ló fi ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́.” (Òwe 8:30) Jèhófà lò ó láti dá ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì míì ní ọ̀run. (Kól. 1:16) Àkọsílẹ̀ Bíbélì kan sọ nípa àwọn áńgẹ́lì tó dá yìí pé: “Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún [Jèhófà], ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì ń dúró níwájú rẹ̀.” (Dán. 7:10) Bíbélì pe ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ní “ẹgbẹ́ ọmọ ogun” Jèhófà tó wà létòlétò.—Sm. 103:21.
3. Báwo ni àwọn ìràwọ̀ àti àwọn pílánẹ́ẹ̀tì ṣe pọ̀ tó? Báwo ni Ọlọ́run ṣe ṣètò wọn?
3 Kí la lè sọ nípa àwọn ohun tó ṣeé fojú rí tí Ọlọ́run dá, irú bí àìlóǹkà ìràwọ̀ àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì? Nígbà tí ìwé kan tí wọ́n pè ní Chronicle, tí wọ́n ṣe jáde ní ìlú Houston, tó wà ní ìpínlẹ̀ Texas, ń sọ̀rọ̀ nípa iye ìràwọ̀ tó wà, ó sọ pé ìwádìí tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé wọ́n tó “ọgọ́rùn-ún mẹ́ta bílíọ̀nù lọ́nà bílíọ̀nù lọ́nà ẹgbẹ̀rún, tàbí ká kúkú sọ pé ìlọ́po mẹ́ta iye ìràwọ̀ táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti sọ pé ó wà tẹ́lẹ̀.” Ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe rẹ̀ báyìí ná, ká sọ pé bílíọ̀nù mẹ́fà èèyàn ló wà láyé. Bí ìròyìn náà ṣe sọ, ńṣe làwọn ìràwọ̀ tó wà ní ìsálú ọ̀run dà bí iye gbogbo èèyàn tó wà láyé ní ìlọ́po mílíọ̀nù lọ́nà mílíọ̀nù lọ́nà àádọ́ta. Àwọn ìràwọ́ yìí ò fọ́n káàkiri ojú sánmà lọ́nà rúdurùdu. Bí wọ́n ṣe wà ní ẹyọ ẹyọ, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọlọ́run tún tò wọ́n pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìṣùpọ̀ ìràwọ̀. Nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ kọ̀ọ̀kan, a lè rí àìmọye bílíọ̀nù tàbí bílíọ̀nù lọ́nà mílíọ̀nù ìràwọ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ pílánẹ́ẹ̀tì tó rí róbótó bí ayé wa yìí. Ọlọ́run sì tún to èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ yìí pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbájọ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀.
4. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti gbà pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé máa wà létòlétò?
4 Bí àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ tó wà lọ́run ṣe wà létòlétò, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ìràwọ̀, òṣùpá, oòrùn àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì wà létòlétò. (Aísá. 40:26) Nígbà náà, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Jèhófà máa mú kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé wà létòlétò. Kò fẹ́ kí wọ́n máa ṣe nǹkan lọ́nà rúdurùdu, ìyẹn sì ṣe pàtàkì gan-an torí pé wọ́n ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ pàtàkì láti ṣe. Tá a bá wo àwọn iṣẹ́ ribiribi táwọn olùjọsìn Jèhófà ti fi òótọ́ ọkàn ṣe láyé àtijọ́ àti lóde òní, ẹ̀rí tó dájú fi hàn pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn àti pé kì í ṣe “Ọlọ́run rúdurùdu, bí kò ṣe ti àlàáfíà.”—Ka 1 Kọ́ríńtì 14:33, 40.
ÀWỌN ÈÈYÀN ỌLỌ́RUN WÀ LÉTÒLÉTÒ LÁYÉ ÀTIJỌ́
5. Kí ló fa ìdíwọ́ fún ètò tí Ọlọ́run ṣe láti fi èèyàn kún ilẹ̀ ayé?
5 Nígbà tí Jèhófà dá àwọn èèyàn àkọ́kọ́, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́n. 1:28) Ọlọ́run fẹ́ kí ẹ̀dá èèyàn máa pọ̀ sí i lọ́nà tó wà létòlétò kí wọ́n lè kún orí ilẹ̀ ayé kí wọ́n sì mú kí Párádísè wọn gbòòrò dé orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé. Àmọ́ àìgbọràn Ádámù àti Éfà fa ìdíwọ́ ráńpẹ́ fún ètò tí Ọlọ́run ṣe yẹn. (Jẹ́n. 3:1-6) Nígbà tó yá, “Jèhófà rí i pé ìwà búburú ènìyàn pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ ayé, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ́ kìkì búburú ní gbogbo ìgbà.” Èyí ló fà á tí “ilẹ̀ ayé sì wá bàjẹ́ ní ojú Ọlọ́run tòótọ́, ilẹ̀ ayé sì wá kún fún ìwà ipá.” Torí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run pinnu pé òun máa fi ìkún omi pa àwọn èèyàn búburú yẹn run.—Jẹ́n. 6:5, 11-13, 17.
6, 7. (a) Kí nìdí tí Nóà fi rí ojúure Jèhófà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn aláìṣòótọ́ tó wà nígbà ayé Nóà?
6 Àmọ́, “Nóà rí ojú rere ní ojú Jèhófà” torí pé ó “jẹ́ olódodo” tó “fi ara rẹ̀ hàn ní aláìní-àléébù láàárín àwọn alájọgbáyé rẹ̀.” Torí pé “Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn,” Jèhófà fún un ní ìtọ́ni pé kí ó kan ọkọ̀ áàkì ńlá kan. (Jẹ́n. 6:8, 9, 14-16) Ọlọ́run ní kí ó kan ọkọ̀ náà lọ́nà tí yóò fi lè lò ó láti gba ẹ̀mí àwọn èèyàn àtàwọn ẹranko là. Nóà ṣègbọràn, ó “ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Jèhófà ti pa láṣẹ fún un.” Torí pé ìdílé rẹ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó parí iṣẹ́ kíkan ọkọ̀ náà láìsí ìkọlùkọgbà. Lẹ́yìn tí wọ́n ti kó àwọn ohun alààyè wọnú áàkì tí àwọn náà sì ti wọlé, “Jèhófà ti ilẹ̀kùn” ọkọ̀ náà.—Jẹ́n. 7:5, 16.
7 Nígbà tí Ìkún Omi dé lọ́dún 2370 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Jèhófà “nu gbogbo ohun tí ó wà lórí ilẹ̀ kúrò,” ṣùgbọ́n ó pa Nóà àti ìdílé rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin tí wọ́n jọ wà nínú áàkì mọ́. (Jẹ́n. 7:23) Àtọ̀dọ̀ Nóà, àwọn ọmọ rẹ̀ àtàwọn ìyàwó wọn ni gbogbo àwa tá a wà láyé lónìí ti ṣẹ̀ wá. Àmọ́ gbogbo àwọn aláìṣòótọ́ tí kò sí nínú áàkì náà ṣègbé torí pé wọ́n kọ̀ láti tẹ́tí sí Nóà tó jẹ́ “oníwàásù òdodo.”—2 Pét. 2:5.
8. Kí ló fi hàn pé gbogbo nǹkan wà létòlétò nílẹ̀ Ísírẹ́lì nígbà tí Ọlọ́run sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí?
8 Ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn Ìkún Omi, Ọlọ́run kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan. Wọ́n sì gbọ́dọ̀ wà létòlétò ní gbogbo ọ̀nà, pàápàá jù lọ nínú ìjọsìn wọn. Bí àpẹẹrẹ, yàtọ̀ sí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àìmọye àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì, wọ́n tún ní “àwọn ìránṣẹ́bìnrin tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn àfètòṣe ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.” (Ẹ́kís. 38:8) Àmọ́, nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n wọ ilẹ̀ Kénáánì, ìran àwọn èèyàn náà hùwà àìṣòdodo, Ọlọ́run sì sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin kì yóò wọ ilẹ̀ náà tí mo gbé ọwọ́ mi sókè ní ìbúra láti máa gbé pẹ̀lú yín, àyàfi Kálébù ọmọkùnrin Jéfúnè àti Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì” torí pé àwọn méjì yìí ló mú ìròyìn rere wá lẹ́yìn tí wọ́n ti lọ ṣe amí Ilẹ̀ Ìlérí náà. (Núm. 14:30, 37, 38) Nígbà tó yá, Ọlọ́run fún Mósè ní ìtọ́ni pé kí ó yan Jóṣúà láti gbapò rẹ̀, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. (Núm. 27:18-23) Nígbà tí Jóṣúà ti múra tán láti kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ Kénáánì, Jèhófà sọ fún un pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára. Má gbọ̀n rìrì tàbí kí o jáyà, nítorí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí o bá lọ.”—Jóṣ. 1:9.
9. Ojú wo ni Ráhábù fi wo Jèhófà àti àwọn èèyàn rẹ̀?
9 Kò sí àní-àní pé Jèhófà Ọlọ́run wà pẹ̀lú Jóṣúà ní gbogbo ibi tó lọ. Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì pàgọ́ sí ìtòsí ìlú Jẹ́ríkò tó wà lágbègbè Kénáánì. Lọ́dún 1473 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Jóṣúà rán àwọn ọkùnrin méjì pé kí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ Jẹ́ríkò, nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n lọ sí ilé Ráhábù aṣẹ́wó. Obìnrin yìí fi wọ́n pa mọ́ lórí òrùlé ilé rẹ̀, kò jẹ́ kí ọwọ́ àwọn tí ọba Jẹ́ríkò rán sí wọn tẹ̀ wọ́n. Ráhábù sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ amí náà pé: “Mo mọ̀ pé Jèhófà yóò fi ilẹ̀ yìí fún yín dájúdájú . . . , nítorí a ti gbọ́ bí Jèhófà ti gbẹ omi Òkun Pupa táútáú kúrò níwájú yín . . . àti ohun tí ẹ ṣe sí àwọn ọba méjì ti àwọn Ámórì.” Ó fi kún un pé: “Jèhófà Ọlọ́run yín ni Ọlọ́run nínú ọ̀run lókè àti lórí ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀.” (Jóṣ. 2:9-11) Torí pé Ráhábù fara mọ́ ètò Jèhófà tó wà nígbà yẹn, Ọlọ́run rí sí i pé wọ́n dá ẹ̀mí òun àtàwọn ìdílé rẹ̀ sí nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa Jẹ́ríkò run. (Jóṣ. 6:25) Ráhábù lo ìgbàgbọ́, ó bẹ̀rù Jèhófà, ó sì bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn Ọlọ́run.
ÈTÒ ỌLỌ́RUN Ń TẸ̀ SÍWÁJÚ NÍ Ọ̀RÚNDÚN KÌÍNÍ
10. Kí ni Jésù sọ fún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù tó wà nígbà ayé rẹ̀? Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀?
10 Lásìkò tí Jóṣúà jẹ́ aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ọ̀kọ̀ọ̀kan ni wọ́n ń ṣẹ́gun àwọn ìlú tó wà nílẹ̀ Kénáánì tí wọ́n sì ń gba ilẹ̀ wọn. Àmọ́ kí ló wá ṣẹlẹ̀ nígbà tó yá? Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, ńṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń tara bọ rírú òfin Ọlọ́run. Nígbà tí Jèhófà fi máa rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé, bí àwọn èèyàn náà ṣe ń ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run tí wọ́n sì ń kọtí ikún sí àwọn agbọ̀rọ̀sọ rẹ̀ ti burú débi pé Jésù pe Jerúsálẹ́mù ní “olùpa àwọn wòlíì.” (Ka Mátíù 23:37, 38.) Ọlọ́run kọ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù sílẹ̀ torí ìwà àìṣòótọ́ tí wọ́n hù sí i. Torí bẹ́ẹ̀, Jésù sọ fún wọn pé: “A ó gba ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ jáde.”—Mát. 21:43.
11, 12. (a) Kí ló fi hàn ní ọ̀rúndún kìíní pé Jèhófà mú ìbùkún rẹ̀ kúrò lórí orílẹ̀-èdè àwọn Júù tó sì fi fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kó jọ? (b) Àwọn wo ni àwọn tí Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ kó jọ sínú ètò rẹ̀ tó fọwọ́ sí?
11 Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, Jèhófà ta orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó ti di aláìṣòótọ́ nù. Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé lórí ilẹ̀ ayé kò ní sí àwọn ìránṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin nínú ètò rẹ̀ mọ́. Jèhófà darí ìbùkún rẹ̀ sórí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kó jọ sínú ètò rẹ̀ tó ń tẹ̀ síwájú, tí wọ́n ń fi ẹ̀kọ́ Jésù Kristi sílò tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Àwọn tí Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ kó jọ sínú ètò rẹ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, nǹkan bí ọgọ́fà [120] ọmọ ẹ̀yìn Jésù pé jọ sí Jerúsálẹ́mù, ó sì ṣẹlẹ̀ pé “lójijì, ariwo kan dún láti ọ̀run gan-an gẹ́gẹ́ bí ti atẹ́gùn líle tí ń rọ́ yìì, ó sì kún inú gbogbo ilé” tí wọ́n wà. Lẹ́yìn náà, “àwọn ahọ́n bí ti iná sì di rírí fún wọn, ó sì pín káàkiri, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì bà lé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, gbogbo wọ́n sì wá kún fún ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi onírúurú ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ti ń yọ̀ǹda fún wọn láti sọ̀rọ̀ jáde.” (Ìṣe 2:1-4) Ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu yìí jẹ́ ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé Jèhófà ń ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kó jọ sínú ètò rẹ̀ lẹ́yìn.
12 Ní ọjọ́ ayọ̀ yẹn, “nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọkàn ni a sì fi kún” àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù. Síwájú sí i, “Jèhófà ń bá a lọ láti mú àwọn tí a ń gbà là dara pọ̀ mọ́ wọn lójoojúmọ́.” (Ìṣe 2:41, 47) Iṣẹ́ tí àwọn oníwàásù ọ̀rúndún kìíní yẹn ṣe gbéṣẹ́ gan-an débi pé “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń bá a lọ ní gbígbilẹ̀, iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ń di púpọ̀ sí i ṣáá ní Jerúsálẹ́mù.” Kódà, ‘ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn àlùfáà bẹ̀rẹ̀ sí í di onígbọràn sí ìgbàgbọ́ náà.’ (Ìṣe 6:7) Ọ̀pọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ ló tipa bẹ́ẹ̀ tẹ́wọ́ gba òtítọ́ tí àwọn tó wà nínú ètò Ọlọ́run yẹn ń wàásù rẹ̀. Nígbà tó yá, Jèhófà tún fi irú ẹ̀rí kan náà hàn pé òun ṣì wà lẹ́yìn wọn nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í mú kí “àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè” wá sínú ìjọ Kristẹni.—Ka Ìṣe 10:44, 45.
13. Iṣẹ́ wo ni àwọn tó wà nínú ètò Ọlọ́run ń ṣe nígbà yẹn?
13 Kò sí iyè méjì nípa iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi lọ́wọ́. Jésù alára ti fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wọn, torí pé kò pẹ́ lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi ló bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nípa “Ìjọba ọ̀run.” (Mát. 4:17) Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé káwọn náà máa wàásù. Ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ ó jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.’ (Ìṣe 1:8) Ó dájú pé àwọn tó di ọmọlẹ́yìn Kristi nígbà yẹn lóye ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ní Áńtíókù ti Písídíà, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà fìgboyà sọ fún àwọn Júù tó ń ta kò wọ́n pé: “Ó pọndandan kí a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín. Níwọ̀n bí ẹ ti ń sọ́gọ rẹ̀ dànù kúrò lọ́dọ̀ yín, tí ẹ kò sì ka ara yín yẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, wò ó! a yíjú sí àwọn orílẹ̀-èdè. Ní ti tòótọ́, Jèhófà ti pàṣẹ fún wa ní ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé: ‘Mo ti yàn ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, fún ọ láti jẹ́ ìgbàlà títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.’” (Ìṣe 13:14, 45-47) Láti ọ̀rúndún kìíní wá ni apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Ọlọ́run ti ń mú kí àwọn èèyàn mọ ètò tí Ọlọ́run ti ṣe kí wọ́n lè rí ìgbàlà.
Ọ̀PỌ̀ ṢÈGBÉ, ÀMỌ́ ÀWỌN ÌRÁNṢẸ́ ỌLỌ́RÙN LÀ Á JÁ
14. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù tó wà ní ọ̀rúndún kìíní? Àwọn wo ló là á já?
14 Kì í ṣe gbogbo àwọn Júù ló tẹ́tí sí ìhìn rere, àjálù sì rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí wọn, torí pé Jésù ti kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé. Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àárín rẹ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àwọn ibi ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀.” (Lúùkù 21:20, 21) Ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ sì rí bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́. Torí ìdìtẹ̀ àwọn Júù, àwọn ọmọ ogun Róòmù yí ìlú Jerúsálẹ́mù ká lábẹ́ ìdarí Cestius Gallus lọ́dún 66 Sànmánì Kristẹni. Àmọ́, ṣàdédé ni àwọn ọmọ ogun yẹn pa dà síbi tí wọ́n ti wá, ìyẹn sì fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù láǹfààní láti kúrò ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà. Bí òpìtàn kan tó ń jẹ́ Yùsíbíọ̀sì ṣe sọ, ọ̀pọ̀ lára wọn sá lọ sí Pẹ́là tó wà ní ìlú Pèríà, ní òdì kejì odò Jọ́dánì. Ní ọdún 70 Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ ogun Róòmù pa dà wá, lábẹ́ ìdarí Ọ̀gágun Titus, wọ́n sì pa Jerúsálẹ́mù run. Ṣùgbọ́n, ní ti àwọn Kristẹni adúróṣinṣin, wọ́n là á já torí pé wọ́n fetí sí ìkìlọ̀ Jésù.
15. Lójú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni ẹ̀sìn Kristẹni ti gbilẹ̀?
15 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi fojú winá ìnira, inúnibíni àtàwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ míì, ẹ̀sìn Kristẹni gbilẹ̀ gan-an ní ọ̀rúndún kìíní. (Ìṣe 11:19-21; 19:1, 19, 20) Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe dáadáa gan-an nípa tẹ̀mí torí pé Ọlọ́run bù kún wọn.—Òwe 10:22.
16. Kí àwọn Kristẹni lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lè máa ṣe dáadáa nínú ìjọsìn Ọlọ́run, kí ni wọ́n gbọ́dọ̀ máa ṣe?
16 Ó gba ìsapá gan-an kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan tó lè máa ṣe dáadáa nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Ó ṣe pàtàkì kí olúkúlùkù máa kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ dáadáa, kó máa lọ sípàdé déédéé láti jọ́sìn Ọlọ́run, kó sì máa fìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Irú àwọn ìgbòkègbodò yìí ló mú kí ìṣọ̀kan wà láàárín àwọn èèyàn Jèhófà ìgbà yẹn tí wọ́n sì ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló sì rí fún àwa èèyàn Jèhófà lónìí. Àwọn tó dara pọ̀ mọ́ àwọn ìjọ tó wà létòlétò nígbà yẹn jàǹfààní gan-an torí pé tọkàntọkàn ni àwọn alábòójútó àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ fi ń ràn wọ́n lọ́wọ́. (Fílí. 1:1; 1 Pét. 5:1-4) Ẹ sì wo bí inú àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò bíi Pọ́ọ̀lù, á ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n ń bẹ àwọn ìjọ wò! (Ìṣe 15:36, 40, 41) Ohun ìwúrí gbáà ló jẹ́ pé kò sí ìyàtọ̀ rárá nínú bí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe ń jọ́sìn àti bí àwa náà ṣe ń jọ́sìn lónìí. A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà mú kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wà létòlétò nígbà yẹn, ó sì tún ṣe bẹ́ẹ̀ lóde òní! *
17. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
17 Bí ayé Sátánì yìí ṣe ń lọ sí òpin lọ́jọ́ ìkẹyìn yìí, ńṣe ni apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò kan ṣoṣo tí Jèhófà ń lò láyé àtọ̀run ń yára tẹ̀ síwájú láìsọsẹ̀. Ṣé ò ń kẹ́sẹ̀ rìn pẹ̀lú ètò náà, àbí o ti jẹ́ kó fi ẹ́ sílẹ̀? Ǹjẹ́ o tiẹ̀ ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí? Wàá mọ bó o ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
^ ìpínrọ̀ 16 Wo àwọn àpilẹ̀kọ tá a pè ní, “Àwọn Kristẹni Ń Jọ́sìn ní Ẹ̀mí àti Òtítọ́” àti “Wọ́n Ń Bá A Lọ ní Rírìn Nínú Òtítọ́” nínú Ilé Ìṣọ́ July 15, 2002. A ti tẹ kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Ọlọ́run ti òde òní jáde nínú ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom.