Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Àìlera Ẹ̀dá Ni Ìwọ Náà Fi Ń Wò Ó?

Ṣé Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Àìlera Ẹ̀dá Ni Ìwọ Náà Fi Ń Wò Ó?

“Àwọn ẹ̀yà ara tí ó dà bí ẹni pé ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera jẹ́ kò-ṣeé-má-nìí.”—1 KỌ́R. 12:22.

KÒ SẸ́NI tí kì í ní àìlera. Òtútù, ọ̀fìnkìn àti ara ríro lè mú kó rẹ̀ wá débi pé ọwọ́ wa lè máà ran iṣẹ́ tá a máa ń ṣe déédéé. Jẹ́ ká wá sọ pé àárẹ̀ ara náà kò lọ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan, ọ̀sẹ̀ méjì, àti ọ̀pọ̀ oṣù lẹ́yìn náà. Nírú àkókò bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ inú rẹ kò ní dùn bí àwọn èèyàn bá fi ẹ̀mí ìgbatẹnirò hàn sí ẹ?

1, 2. Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù lè bá àwọn aláìlera kẹ́dùn?

2 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ bó ṣe máa ń rí lára bí ìdààmú bá báni tàbí tí ìṣòro téèyàn ń kojú nínú ìjọ tàbí lọ́dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́ bá mú kéèyàn rẹ̀wẹ̀sì tàbí di aláìlera. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Pọ́ọ̀lù rò pé agbára òun kò ní lè gbé e mọ́. (2 Kọ́r. 1:8; 7:5) Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbésí ayé rẹ̀ àti ìnira tó ti bá a gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni adúróṣinṣin, ó sọ pé: “Ta ní jẹ́ aláìlera, tí èmi kò sì jẹ́ aláìlera?” (2 Kọ́r. 11:29) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì ń sọ̀rọ̀ nípa onírúurú èèyàn tó wà nínú ìjọ, èyí tó fi wé àwọn ẹ̀yà ara, ó sọ pé àwọn tí “ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera jẹ́ kò-ṣeé-má-nìí.” (1 Kọ́r. 12:22) Kí ló ní lọ́kàn? Kí nìdí tó fi yẹ ká máa wo àwọn tó dà bíi pé wọ́n jẹ́ aláìlera bí Jèhófà ṣe ń wò wọ́n? Àǹfààní wo la sì máa rí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀?

 OJÚ TÍ JÈHÓFÀ FI Ń WO ÀÌLERA Ẹ̀DÁ

3. Kí ló lè nípa lórí ojú tá a fi ń wo àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ nínú ìjọ?

3 Inú ayé táwọn èèyàn ti ń bára wọn díje là ń gbé, ẹní bá jẹ́ ọ̀dọ́ tó sì lágbára àtiṣiṣẹ́ làwọn èèyàn sábà máa ń gbé lárugẹ. Kò sì sí ohun táwọn míì ò lè ṣe kí ọwọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n bá ń fẹ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ń pọ́n àwọn tí kò lágbára tó wọn lójú. Lóòótọ́, àwa kì í hu irú ìwà bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ a lè má mọ̀ pé a ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi ojú tí kò tọ́ wo àwọn tó máa ń nílò ìrànlọ́wọ́ nígbà gbogbo, títí kan àwọn ará bíi tiwa. Àmọ́, àwa náà lè dẹni tó ń fi irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn èèyàn wò wọ́n.

4, 5. (a) Báwo ni àpèjúwe tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 12:21-23 ṣe jẹ́ ká lóye ojú tí Jèhófà fi ń wo àìlera ẹ̀dá? (b) Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ran àwọn aláìlera lọ́wọ́?

4 A lè lóye ojú tí Jèhófà fi ń wo àìlera àwa ẹ̀dá látinú àpèjúwe kan tí Pọ́ọ̀lù ṣe nínú lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí àwọn ará Kọ́ríńtì. Ní orí kejìlá, Pọ́ọ̀lù rán wa létí pé àwọn ẹ̀yà ara wa tó dà bí èyí tí kò lọ́lá tàbí tó túbọ̀ jẹ́ aláìlera ní ipa tí àwọn náà ń kó. (Ka 1 Kọ́ríńtì 12:12, 18, 21-23.) Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n kan ti sọ pé bí Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàlàyé nípa àwọn ẹ̀yà ara wa kọ́ lọ̀rọ̀ rí. Àmọ́, ìwádìí tí àwọn tó mọ̀ nípa ẹ̀yà ara ṣe fi hàn pé àwọn ẹ̀yà ara kan táwọn èèyàn rò pé kò wúlò tẹ́lẹ̀ ni wọ́n ti wá rí i pé iṣẹ́ ribiribi ni wọ́n ń ṣe. * Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń sọ pé àwọn ò rí nǹkan tí èyí tó kéré jù lọ nínú ọmọ ìka ẹsẹ̀ wa wúlò fún; àmọ́, wọ́n ti wá rí i báyìí pé òun ni kì í jẹ́ ká ṣubú tá a bá dúró.

5 Àpèjúwe tí Pọ́ọ̀lù lò mú kó ṣe kedere pé gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ Kristẹni la wúlò. Jèhófà ò dà bíi Sátánì tó máa ń gbé ẹ̀wù ẹ̀tẹ́ wọ àwọn èèyàn, aṣọ iyì ni Jèhófà máa ń dà bo gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, torí ó mọ̀ pé gbogbo wọn, tó fi mọ́ àwọn aláìlera, jẹ́ “kò-ṣeé-má-nìí.” (Jóòbù 4:18, 19) Látàrí èyí, ó yẹ kí inú gbogbo wa máa dùn torí ipa tá à ń kó nínú ìjọ, ká sì máa láyọ̀ pé a jẹ́ ara ìjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà kárí ayé. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ìgbà tó o ran àgbàlagbà kan lọ́wọ́. Ó ṣeé ṣe kí ìyẹn mú kó o dẹ̀rìn rẹ. Oore ńlá ni àgbàlagbà yẹn máa ka ohun tó o ṣe fún un sí, ìyẹn á sì mú inú tìrẹ náà dùn. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Bó ṣe máa ń rí nìyẹn nígbà tá a bá ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, inú wa máa ń dùn bá a ṣe ń ṣoore, ó ń mú ká túbọ̀ máa ní sùúrù, ká túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn, ó sì ń mú kí òtítọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ nínú wa. (Éfé. 4:15, 16) Baba wa onífẹ̀ẹ́ mọ̀ pé bí àwọn tó wà nínú ìjọ bá mọyì ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì, láìka kùdìẹ̀-kudiẹ wọn sí, ìfẹ́ a gbilẹ̀ nínú ìjọ bẹ́ẹ̀ wọ́n á sì máa ṣe ohun gbogbo lọ́nà tó wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì.

6. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe máa ń lo gbólóhùn náà ‘àwọn tó ní okun’ àti ọ̀rọ̀ náà “aláìlera” nígbà míì?

6 Ó gba àfiyèsí pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì, ó lo àwọn ọ̀rọ̀ náà “aláìlera” àti “àìlera” nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ojú tí àwọn aláìgbàgbọ́ fi wo àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní àti ojú tó fi ń wo ara rẹ̀. (1 Kọ́r. 1:26, 27; 2:3) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ‘àwọn tó ní okun,’ kò sọ bẹ́ẹ̀ láti mú kí àwọn Kristẹni kan rò pé àwọn sàn ju àwọn míì. (Róòmù 15:1) Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé kí àwọn Kristẹni tó túbọ̀ nírìírí máa ṣe sùúrù fún àwọn tí ẹsẹ̀ wọn ò tíì múlẹ̀ ṣinṣin nínú òtítọ́.

ǸJẸ́ KÒ YẸ KÁ YÍ OJÚ TÁ A FI Ń WO NǸKAN PA DÀ?

7. Kí ló lè mú ká má fẹ́ ran àwọn míì lọ́wọ́?

7 Tá a bá ń ran àwọn “ẹni rírẹlẹ̀” lọ́wọ́ ńṣe là ń fara wé Jèhófà, èyí a sì mú ká rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run. (Sm. 41:1; Éfé. 5:1)  Àmọ́ ṣá o, tá a bá ń fi ojú tí kò tọ́ wo àwọn tí nǹkan kù díẹ̀ káàtó fún, a lè máa fà sẹ́yìn láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Bó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ńṣe la ò mọ ohun tá a máa sọ fún wọn ará lè máa tì wá ká sì tipa bẹ́ẹ̀ máa sá fún àwọn tí nǹkan ò rọgbọ fún. Ẹ gbọ́ ohun tí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Cynthia, * sọ lẹ́yìn tí ọkọ rẹ̀ pa á tì, ó ní: “Ó máa ń dunni wọra táwọn ará bá pani tì, tí wọn ò sì ṣe ohun téèyàn retí pé kí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ṣe. Owó fúnni kò tó èèyàn, pàápàá nígbà àdánwò.” Dáfídì tó gbé láyé nígbàanì mọ bó ṣe máa ń rí lára táwọn èèyàn bá pani tì.—Sm. 31:12.

8. Kí láá jẹ́ ká túbọ̀ máa ní ẹ̀mí ìgbatẹnirò fáwọn èèyàn?

8 Á túbọ̀ ṣeé ṣe fún wa láti máa ní ẹ̀mí ìgbatẹnirò fáwọn èèyàn tá a bá ń rántí pé ìṣòro ló sọ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ọ̀wọ́n kan di aláìlera. A rí lára wọn tí àìsàn ń bá jà, àwọn míì ń gbé pẹ̀lú ẹbí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, tàbí kí wọ́n ní ìsoríkọ́. Irú ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sí àwa náà lọ́jọ́ kan. Bí àpẹẹrẹ, àṣẹ kan wà tí Ọlọ́run pa fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó tó di pé wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òtòṣì àti aláìlera ni wọ́n nígbà tí wọ́n wà nílẹ̀ Íjíbítì, Ọlọ́run pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọ́dọ̀ “sé ọkàn-àyà [wọn] le” sí arákùnrin wọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́. Jèhófà fẹ́ kí wọ́n ka àwọn òtòṣì sí ẹni tó yẹ kí wọ́n ràn lọ́wọ́.—Diu. 15:7, 11; Léf. 25:35-38.

9. Kí ló yẹ kó jẹ wá lógún jù lọ tá a bá ń ran àwọn tó wà nínú ìnira lọ́wọ́? Ṣàpèjúwe.

9 Dípò tí a ó fi máa dá àwọn tó bára wọn nínú ipò tí kò bára dé lẹ́jọ́ tàbí ká máa fura sí wọn, ńṣe ló yẹ ká máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tù wọ́n nínú. (Jóòbù 33:6, 7; Mát. 7:1) Àpèjúwe kan rèé: Ká sọ pé jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí ọlọ́kadà kan, tí wọ́n sì gbé e dìgbàdìgbà lọ sílé ìwòsàn fún ìtọ́jú pàjáwìrì, ṣé ohun táwọn dókítà àti nọ́ọ̀sì á kọ́kọ́ fẹ́ mọ̀ ni pé bóyá òun ló fa jàǹbá náà? Ó tì o, ńṣe ni wọ́n á kọ́kọ́ fún un ní ìtọ́jú tó nílò. Bákan náà, bí ìṣòro bá sọ ará wa èyíkéyìí di aláìlera, bá a ṣe máa ràn án lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí ló yẹ kó jẹ wá lógún jù lọ.—Ka 1 Tẹsalóníkà 5:14.

10. Báwo ni àwọn kan tó dà bí aláìlera ṣe lè “jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́”?

10 Tá a bá ń fi ara balẹ̀ ronú lórí ìṣòro táwọn ará wa ní, a lè wá rí i pé wọ́n kì í ṣe aláìlera rárá. Bí àpẹẹrẹ, àwọn arábìnrin kan wà tí wọ́n ti ń fi ara da àtakò látọ̀dọ̀ ìdílé wọn fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ìṣòro ti lè sọ wọ́n di hẹ́gẹhẹ̀gẹ kí wọ́n má sì fi bẹ́ẹ̀ lókun. Síbẹ̀, tá a bá kíyè sí akitiyan wọn, a óò rí i pé wọ́n kì í ṣe aláìlera àti pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó ta yọ. Tó o bá sì rí òbí anìkàntọ́mọ tó ń wá sí ìpàdé déédéé pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ tó ní àti bó ṣe ń sin Ọlọ́run láìyẹsẹ̀ kì í wú ẹ lórí? Àwọn ọmọ tí kò tíì pé ogún ọdún tí wọ́n rọ̀ mọ́ òtítọ́ tí wọn ò sì kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ níléèwé ńkọ́? Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, irú àwọn ẹni tó jọ pé wọ́n jẹ́ aláìlera yìí náà “jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́” bíi tí àwọn míì lára wa tí nǹkan dẹrùn fún.—Ják. 2:5.

OJÚ TÍ JÈHÓFÀ FI Ń WO ÀWỌN ÈÈYÀN NI KÓ O MÁA FI WÒ WỌ́N

11, 12. (a) Kí láá mú ká máa fi ojú tó tọ́ wo àìlera ẹ̀dá? (b) Kí la rí kọ́ nínú ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá Áárónì lò?

11 Ohun táá mú ká lè máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo àìlera ẹ̀dá wò ó ni pé ká ṣe àgbéyẹ̀wò ọ̀nà tó gbà bójú tó ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kan. (Ka Sáàmù 130:3.) Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o wà pẹ̀lú Mósè nígbà tí Áárónì ṣe ọmọ màlúù oníwúrà yẹn, ojú wo lò bá fi wo àwáwí tí Áárónì ṣe? (Ẹ́kís. 32:21-24) Tàbí kẹ̀, kí lo máa sọ nípa ìwà tí Áárónì hù nígbà tí Míríámù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin sọ̀rọ̀ sí Mósè torí pé ìyàwó rẹ̀ kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì? (Núm. 12:1, 2) Kí lò bá ṣe nígbà tí Áárónì àti Mósè kò bọlá fún Jèhófà nígbà tí Ó pèsè omi fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́nà ìyanu ní Mẹ́ríbà?—Núm. 20:10-13.

 12 Nígbà tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé, Jèhófà ti lè yàn láti fìyà jẹ Áárónì lójú ẹsẹ̀. Àmọ́, ó fòye mọ̀ pé Áárónì kì í ṣe èèyàn burúkú àti pé òun kọ́ ló ni ẹ̀bi gbogbo ọ̀rọ̀ náà. Ó jọ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ àti ohun táwọn míì ṣe ló mú kí Áárónì ṣe ohun tí kò tọ́. Síbẹ̀, nígbà tí wọ́n fi àṣìṣe rẹ̀ hàn án, kò jiyàn ó sì fara mọ́ ìdájọ́ tí Jèhófà ṣe. (Ẹ́kís. 32:26; Núm. 12:11; 20:23-27) Torí náà, Jèhófà yàn láti ro ti ìgbàgbọ́ tí Áárónì ní àti bó ṣe fi ẹ̀mí ìrònúpìwàdà hàn. Ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà ṣì kà á sí pé Áárónì àti àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ bẹ̀rù òun.—Sm. 115:10-12; 135:19, 20.

13. Kí la lè ṣe táá jẹ́ ká mọ ojú tá a fi ń wo àìlera ẹ̀dá? Sọ àpẹẹrẹ kan.

13 Ká bàa lè ṣàtúnṣe tó máa mú kí èrò wa bá ti Jèhófà mu, ńṣe ló yẹ ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ojú tá a fi ń wo àwọn tó jọ pé wọ́n ní àìlera. (1 Sám. 16:7) Bí àpẹẹrẹ, kí la máa ṣe tá a bá kíyè sí i pé eré ìnàjú tí ọmọ kan tí kò tíì pé ogún ọdún yàn kù díẹ̀ káàtó tàbí tó bá ń hùwà ta-ni-yóò-mú-mi? Dípò tá ó fi máa ṣàríwísí irú ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀, a ò ṣe ronú nípa ọ̀nà tá a lè gbà ràn án lọ́wọ́ táá fi máa hùwà àgbà? A lè lo ìdánúṣe láti ṣèrànwọ́ fún ẹni tá a bá rí pé ó nílò ìrànlọ́wọ́, tá a bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni òye tá a ní á túbọ̀ jinlẹ̀, ìfẹ́ wa á sì máa pọ̀ sí i.

14 Ohun tó tún lè mú kí ojú tá a fi ń wo àwọn èèyàn sunwọ̀n sí i ni pé ká máa ṣàgbéyẹ̀wò ojú tí Jèhófà fi wo díẹ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá, ká wá bi ara wa pé kí la máa ṣe tó bá jẹ́ pé àwa ni. Ọ̀kan lára wọn ni Èlíjà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Èlíjà ti fi àìṣojo kojú àádọ́ta-lé-nírínwó [450] àwọn wòlíì Báálì, ó sá lọ nítorí Jésíbẹ́lì Ayaba nígbà tó gbọ́ pé ó ń gbèrò láti pa òun. Lẹ́yìn tó ti fi ẹsẹ̀ rin nǹkan bí àádọ́jọ [150] kìlómítà, ṣe ló tún forí lé inú aginjù.  Bí wòlíì yìí ṣe ń rìn nínú oòrùn tó ń mú ganrínganrín náà ti wá mú kó rẹ̀ ẹ́ gan-an. Torí náà, ó jókòó lábẹ́ igi, ó sì gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí òun kú.”—1 Ọba 18:19; 19:1-4.

Jèhófà rántí pé ó níbi tí agbára Èlíjà mọ ó sì rán áńgẹ́lì kan sí i láti wá mú un lọ́kàn le (Wo ìpínrọ̀ 14 àti 15)

14, 15. (a) Ojú wo ni Jèhófà fi wo Èlíjà nígbà tí ojora mú un láwọn àkókò kan? (b) Kí la lè rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Èlíjà?

15 Báwo ló ṣe rí lára Jèhófà nígbà tó bojú wolẹ̀ láti ọ̀run tó sì rí bí wòlíì rẹ̀ adúróṣinṣin ṣe kárí sọ? Ǹjẹ́ ó sọ pé kì í ṣe ìránṣẹ́ òun mọ́ torí pé ó sorí kọ́ fún ìgbà díẹ̀ tí ojora sì mú un? Rárá o! Jèhófà rántí pé ó níbi tí agbára Èlíjà mọ, ó sì rán áńgẹ́lì kan sí i. Ẹ̀ẹ̀mejì ni áńgẹ́lì náà rọ Èlíjà pé kó jẹun. Nípa bẹ́ẹ̀, ìrìn àjò tó máa rìn lẹ́yìn náà kò ní “pọ̀ jù fún [un].” (Ka 1 Àwọn Ọba 19:5-8.) Ẹ ò rí nǹkan, Jèhófà kọ́kọ́ tẹ́tí sí wòlíì rẹ̀, ó fún un ní oúnjẹ tó máa jẹ́ kó lè lókun, lẹ́yìn náà ló tó wá fún un ní ìtọ́ni nípa ìrìn àjò rẹ̀.

16, 17. Báwo la ṣe lè fìwà jọ Jèhófà ní ti bó ṣe bójú tó Èlíjà?

16 Báwo la ṣe lè fìwà jọ Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́? Ọ̀nà kan tá a lè gbà fìwà jọ ọ́ ni pé ká má ṣe máa fi ìwàǹwára gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn. (Òwe 18:13) Ó máa dára ká kọ́kọ́ fi ẹ̀mí ìgbatẹnirò hàn fún àwọn tó lè máa ronú pé àwọn “rẹlẹ̀ ní ọlá” látàrí ipò tí wọ́n bára wọn. (1 Kọ́r. 12:23) Ìyẹn ló máa mú ká lè pèsè irú ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò gan-an.

17 Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa Cynthia, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí, tí ọkọ rẹ̀ pa òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin méjì tì. Ó wá ku àwọn nìkan àti etí wọn. Kí ni àwọn kan tí wọ́n jọ jẹ́ ará ṣe? Ó ṣàlàyé pé: “Lẹ́yìn tá a ké sí wọn lórí fóònù tá a sì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wọn, kò pé wákàtí kan tí wọ́n ti dé ilé wa. Ńṣe ni wọ́n ń da omi lójú pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀. Wọ́n dúró tì wá fún nǹkan bí ọjọ́ méjì sí mẹ́ta. Torí pé oúnjẹ ò lọ lẹ́nu wa tí ẹ̀dùn ọkàn wa sì pọ̀, wọ́n mú wa lọ sílé wọn, a sì wà pẹ̀lú wọn fún ọjọ́ mélòó kan.” Ó ṣeé ṣe kí ìyẹn rán ẹ létí ohun tí Jákọ́bù sọ pé: “Bí arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan bá wà ní ipò ìhòòhò, tí ó sì ṣaláìní oúnjẹ tí ó tó fún òòjọ́, síbẹ̀ tí ẹnì kan nínú yín sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa lọ ní àlàáfíà, kí ara yín yá gágá, kí ẹ sì jẹun yó dáadáa,’ ṣùgbọ́n tí ẹ kò fún wọn ní àwọn ohun kò-ṣeé-má-nìí fún ara wọn, àǹfààní wo ni ó jẹ́? Bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú, ìgbàgbọ́, bí kò bá ní àwọn iṣẹ́, jẹ́ òkú nínú ara rẹ̀.” (Ják. 2:15-17) Ọpẹ́lọpẹ́ ìtìlẹ́yìn àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, Cynthia àtàwọn ọmọ rẹ̀ lókun débi pé ní oṣù mẹ́fà péré lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ tó gbò wọ́n jìgì náà wáyé, wọ́n ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.—2 Kọ́r. 12:10.

ÀǸFÀÀNÍ GBOGBO WA NI

18, 19. (a) Báwo la ṣe lè ran àwọn tí wọ́n ní àìlera fún ìgbà díẹ̀ lọ́wọ́? (b) Àwọn wo ló máa jàǹfààní tá a bá ń ran àwọn aláìlera lọ́wọ́?

18 A mọ̀ pé tí àìsàn tí ń tánni lókun bá ṣe èèyàn, ó lè pẹ́ díẹ̀ kí ara tó pa dà bọ̀ sípò. Bákan náà, ó lè pẹ́ díẹ̀ kí Kristẹni kan tí ìṣòro tàbí àdánwò ti sọ di aláìlera tó pa dà lókun nípa tẹ̀mí. Òótọ́ ni pé ó ṣe pàtàkì pé kí ẹni tá a jọ jẹ́ ará náà mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun nípasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́, àdúrà àtàwọn ìgbòkègbodò Kristẹni mìíràn. Àmọ́, ṣé a máa ní sùúrù fún un títí tó fi máa kọ́fẹ pa dà? Ní gbogbo àsìkò yẹn, ṣé a lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn? Ṣé a máa sapá ká lè ran àwọn tí wọ́n ní àìlera fún ìgbà díẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ pé a mọyì àwọn, kí wọ́n sì rí i pé àwọn jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún wa?—2 Kọ́r. 8:8.

19 Má ṣe gbàgbé pé bá a ṣe ń ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ará wa, bẹ́ẹ̀ là ń rí ayọ̀ téèyàn máa ń rí látinú fífúnni. Ó sì tún ń mú ká túbọ̀ máa ní ẹ̀mí ìgbatẹnirò àti sùúrù. Àmọ́ kò mọ síbẹ̀, ẹ̀mí ìfẹ́ àti ọ̀yàyà tó wà nínú ìjọ á máa pọ̀ sí i. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, à ń fara wé Jèhófà tó ka olúkúlùkù wa sí ẹni ọ̀wọ́n. Dájúdájú, gbogbo wa la gbà pé ó bọ́gbọ́n mú pé ká ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn tó ní ká máa “ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìlera.”—Ìṣe 20:35.

^ ìpínrọ̀ 4 Ọ̀gbẹ́ni Charles Darwin sọ nínú ìwé rẹ̀ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹ̀yà ara wa ni kò “wúlò.” Ọ̀kan lára àwọn agbátẹrù rẹ̀ tiẹ̀ sọ pé àìmọye irú àwọn ẹ̀yà ara yìí ló wà “tí wọ́n wulẹ̀ jẹ́ apá kan ẹ̀yà míì nínú ara,” irú bí apá kan tí wọ́n ń pè ní appendix àti ẹ̀yà kan tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú agbóguntàrùn inú ara, tí wọ́n ń pè ní thymus.—Ìwé The Descent of Man.

^ ìpínrọ̀ 7 A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.