Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ran Àwọn Mìíràn Lọ́wọ́ Láti Lo Ẹ̀bùn Wọn ní Kíkún

Ran Àwọn Mìíràn Lọ́wọ́ Láti Lo Ẹ̀bùn Wọn ní Kíkún

“Èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” —SM. 32:8.

NÍGBÀ tí àwọn òbí bá ń wo bí àwọn ọmọ wọn ṣe ń ṣeré, ó máa ń yà wọ́n lẹ́nu láti mọ̀ pé àwọn ọmọ náà ní àwọn ẹ̀bùn àbínibí kan. Ṣé ìwọ náà ti kíyè sí i pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nìyẹn? Ọmọ kan lè fẹ́ràn láti máa bẹ́ káàkiri tàbí kó máa ṣeré ìdárayá, àmọ́ kí ara àbúrò rẹ̀ balẹ̀, kó mọ ayò ta, kó fẹ́ràn láti máa ya àwòrán tàbí kó ní ẹ̀bùn iṣẹ́ ọwọ́. Àmọ́, ẹ̀bùn yòówù kí àwọn ọmọ wọn ní, inú àwọn òbí máa ń dùn gan-an láti mọ ohun táwọn ọmọ náà lè ṣe.

1, 2. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé?

2 Inú Jèhófà náà máa ń dùn gan-an bó ṣe ń wo àwọn ọmọ rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Ó máa ń wo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ òde òní gẹ́gẹ́ bí “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Hág. 2:7) Ohun pàtàkì tó mú kí wọ́n ṣeyebíye lójú rẹ̀ ni pé wọ́n ní ìgbàgbọ́, wọ́n sì jẹ́ olùfọkànsìn. Àmọ́, o lè ti kíyè sí i pé àwọn tá a jọ jẹ́ ará náà ní onírúurú ẹ̀bùn. Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́ làwọn kan, àwọn míì ò sì kẹ̀rẹ̀ tó bá di ká ṣètò nǹkan. Ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin ni wọ́n tètè máa ń lóye èdè ilẹ̀ òkèèrè ti wọ́n sì máa ń lò wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àwọn míì sì wà tí wọ́n jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ tó bá di pé ká fún àwọn èèyàn níṣìírí tàbí ká tọ́jú àwọn aláìsàn. (Róòmù 16:1, 12) Ǹjẹ́ inú wa ò dùn pé a wà nínú ìjọ pẹ̀lú irú àwọn Kristẹni bẹ́ẹ̀?

3. Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 3 Àmọ́, àwọn ará wa kan wà tí wọ́n lè máà tíì mọ ọ̀nà tí wọ́n lè gbà lo ẹ̀bùn wọn nínú ìjọ, títí kan àwọn ọ̀dọ́kùnrin àtàwọn arákùnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi. Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lo ẹ̀bùn wọn ní kíkún? Kí nìdí tó fi yẹ ká sapá láti mọ ibi tí wọ́n dáa sí, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ máa wò wọ́n bí Jèhófà ṣe ń wò wọ́n?

JÈHÓFÀ MÁA Ń RÍ IBI TÍ ÀWỌN ÌRÁNṢẸ́ RẸ̀ DÁA SÍ

4, 5. Báwo ni ohun tó wà nínú Àwọn Onídàájọ́ 6:11-16 ṣe fi hàn pé Jèhófà máa ń rí ẹ̀bùn tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní?

4 Àwọn àkọsílẹ̀ inú Bíbélì kan mú kó ṣe kedere pé kì í ṣe pé Jèhófà máa ń rí ibi táwọn ìránṣẹ́ dáa sí nìkan ni, ó tún máa ń rí ohun tí wọ́n lè fi ẹ̀bùn tí wọ́n ní ṣe. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ọlọ́run yan Gídíónì pé kó gba àwọn èèyàn òun kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Mídíánì tí wọ́n ń ni wọ́n lára, ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún un nígbà tí áńgẹ́lì náà kí i pé: “Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ akíkanjú, alágbára ńlá.” Ó jọ pé nígbà tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, Gídíónì ò tiẹ̀ rí ara rẹ̀ bí “alágbára ńlá.” Ọ̀rọ̀ tó sọ fi hàn pé àwọn nǹkan kan wà tí kò dá a lójú àti pé ó ka ara rẹ̀ sí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan. Àmọ́, nínú ìjíròrò wọn, ó ṣe kedere pé ojú tí Jèhófà fi wo Gídíónì tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ yìí sàn ju ojú tó fi wo ara rẹ̀ lọ.—Ka Àwọn Onídàájọ́ 6:11-16.

5 Jèhófà fọkàn tán Gídíónì pé ó máa dá Ísírẹ́lì nídè torí pé Jèhófà ti kíyè sí ẹ̀bùn tó ní. Ohun kan ni pé áńgẹ́lì Jèhófà ti kíyè sí bí Gídíónì ṣe ń fi gbogbo agbára rẹ̀ pa ọkà àlìkámà. Àmọ́ ohun míì wà tí áńgẹ́lì náà kíyè sí. Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ìta gbangba ni àwọn àgbẹ̀ ti sábà máa ń pa ọkà, níbi tí atẹ́gùn á ti fẹ́ ìyàngbò tàbí èèpo ọkà náà dà nù. Àmọ́ ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé ńṣe ni Gídíónì ń pa ọkà náà ní ìkọ̀kọ̀ kí àwọn ará Mídíánì má bàa gba ìwọ̀nba ohun tó rí kórè. Ẹ ò rí i pé ọgbọ́n gidi nìyẹn! Abájọ tó fi jẹ́ pé lójú Jèhófà, kì í ṣe pé Gídíónì jẹ́ àgbẹ̀ tó níṣọ̀ọ́ra nìkan ni, àmọ́ ó tún jẹ́ ọlọgbọ́n. Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà rí ẹ̀bùn tó ní, ó sì yàn án pé kó bá òun ṣiṣẹ́.

6, 7. (a) Báwo ni ojú tí Jèhófà fi wo Ámósì ṣe yàtọ̀ sí ojú tí àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi wò ó? (b) Kí ló fi hàn pé Ámósì kì í ṣe púrúǹtù?

6 Bákan náà, ọ̀rọ̀ ti Ámósì jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń kíyè sí ẹ̀bùn tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn lè máa wo irú ẹni bẹ́ẹ̀ bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan tàbí ẹni tó tutù jù léèyàn. Ámósì sọ pé darandaran àti olùrẹ́ ọ̀pọ̀tọ́ igi síkámórè ni òun, ìyẹn èso táwọn èèyàn kà sí oúnjẹ àwọn òtòṣì. Nígbà tí Jèhófà yan Ámósì pé kó lọ kìlọ̀ fún ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ti Ísírẹ́lì tí wọ́n ti ya abọ̀rìṣà pé ohun tí wọ́n ń ṣe ò dáa, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan lè ti ronú pé kì í ṣe irú rẹ̀ ló yẹ kó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run.—Ka Ámósì 7:14, 15.

7 Abúlé kan tó wà ní ibi àdádó ni Ámósì ti wá, àmọ́ kì í ṣe aláìmọ̀kan torí pé ó ní òye nípa àṣà àtàwọn alákòóso ìgbà ayé rẹ̀. Ó dájú pé ó mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ó sì ṣeé ṣe kó mọ̀ nípa àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká torí àjọṣe tó máa ń ní pẹ̀lú àwọn oníṣòwò arìnrìn-àjò. (Ámósì 1:6, 9, 11, 13; 2:8; 6:4-6) Àwọn ọ̀mọ̀wé òde òní kan tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì sọ pé Ámósì mọ̀wé kọ gan-an ni. Wòlíì náà máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ṣòroó lóye àmọ́ tó jinlẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó lo àfiwé, ó sì tún fi ọ̀rọ̀ dárà lọ́nà tó jáfáfá. Ká sòótọ́, bí Ámósì ṣe fi ìgboyà bá àlùfáà Amasááyà oníwà àìdáa sọ̀rọ̀ fi hàn pé ẹni tó tọ́ ni Jèhófà yàn, ó sì lè lo àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ tó dà bí èyí tó fara sin tẹ́lẹ̀.—Ámósì 7:12, 13, 16, 17.

8. (a) Kí ni Jèhófà mú kó dá Dáfídì lójú? (b) Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 32:8 ṣe lè fi àwọn tó bá ń ṣiyè méjì nípa ara wọn tàbí tí wọ́n rò pé àwọn ò ní ẹ̀bùn èyíkéyìí lọ́kàn balẹ̀?

8 Láìsí àní-àní, Jèhófà máa ń kíyè sí ẹ̀bùn tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní. Ó mú kó dá Dáfídì Ọba lójú pé òun á máa ṣamọ̀nà rẹ̀, pẹ̀lú ‘ojú òun lára rẹ̀.’  (Ka Sáàmù 32:8.) Ǹjẹ́ inú rẹ ò dùn sí ohun tí Jèhófà sọ yìí? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè máa ṣiyè méjì nípa ara wa, Jèhófà lè mú ká ṣe ohun tó kọjá ibi tá a rò pé agbára wá mọ, ká sì ṣe àṣeyọrí tó pọ̀ ju bá a ṣe rò lọ. Bí olùkọ́ tó dáńgájíá ṣe máa ń ṣàlàyé ohun tó yẹ kí akẹ́kọ̀ọ́ mọ̀ fún un ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe máa ń ṣamọ̀nà wa ká lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní kíkún. Jèhófà sì tún lè lo àwọn ará wa láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè lo ẹ̀bùn wa ní kíkún. Lọ́nà wo?

IBI TÁWỌN ÈÈYÀN DÁRA SÍ NI KÓ O MÁA WÒ

9. Báwo la ṣe lè máa fi ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pọ́ọ̀lù gbà wá pé ká máa “mójú tó” ire àwọn ẹlòmíràn sílò?

9 Pọ́ọ̀lù rọ gbogbo àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa “mójú tó” ire àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. (Ka Fílípì 2:3, 4.) Kókó inú ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ni pé ká máa kíyè sí ẹ̀bùn táwọn ẹlòmíì ní ká sì mọyì wọn. Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa bí ẹnì kan bá yìn wá torí pé à ń tẹ̀ síwájú? Ká sòótọ́, orí wa máa ń wú, àá sì tún fẹ́ láti ṣe púpọ̀ sí i. Bákan náà, tá a bá fi hàn pé a mọyì àwọn ànímọ́ tó dáa tí àwọn ará wá ní, ó máa mú kí wọ́n ṣe púpọ̀ sí i, wọ́n á sì túbọ̀ máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.

10. Àwọn wo ló ṣe pàtàkì gan-an pé ká kíyè sí?

10 Àwọn wo ló ṣe pàtàkì gan-an pé ká kíyè sí? Òótọ́ ni pé gbogbo wa la nílò àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ látìgbàdégbà. Síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin àtàwọn arákùnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi mọ̀ ní ti gidi pé àwọn náà wúlò nínú ìjọ. Èyí á mú kí wọ́n rí i pé apá kan ìjọ làwọn náà jẹ́. Àmọ́, tá ò bá jẹ́ kí àwọn arákùnrin yẹn ní àwọn ojúṣe kan nínú ìjọ, ó lè sú wọn, wọ́n sì lè tipa bẹ́ẹ̀ pinnu pé kò sídìí táwọn á fi máa sapá káwọn lè tẹ̀ síwájú bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ṣe.—1 Tím. 3:1.

11. (a) Báwo ni alàgbà kan ṣe ran ọ̀dọ́kùnrin kan lọ́wọ́ láti borí ìtìjú? (b) Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú ìrírí Julien?

11 Alàgbà kan tó ń jẹ́ Ludovic, tó jàǹfààní látinú ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí i nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, sọ pé: “Nígbà tí mo bá fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sí arákùnrin kan, ìtẹ̀síwájú rẹ̀ máa ń yára kánkán.” Nígbà tí Arákùnrin Ludovic ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀dọ́kùnrin onítìjú kan tó ń jẹ́ Julien, ó sọ pé: “Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, Julien máa ń gbìyànjú láti pa ìtìjú tì, kóun náà ṣe bí àwọn míì ti ń ṣe, torí bẹ́ẹ̀ ó máa ń hùwà lọ́nà tó kù díẹ̀ káàtó. Àmọ́ mo rí i pé ó lọ́kàn tó dáa, ó sì ń fẹ́ láti ran àwọn míì lọ́wọ́ nínú ìjọ. Torí náà, dípò tí màá fi ní èrò òdì nípa rẹ̀, ibi tó dára sí ni mo gbájú mọ́, mo sì ń gbìyànjú láti fún un níṣìírí.” Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Julien tóótun gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ní báyìí ó ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé.

Ẹ RÀN WỌ́N LỌ́WỌ́ LÁTI LO Ẹ̀BÙN WỌN NÍ KÍKÚN

12. Irú ẹni wo la gbọ́dọ̀ jẹ́ ká tó lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti lo ẹ̀bùn rẹ̀ ní kíkún? Sọ àpẹẹrẹ kan.

12 Ohun kan dájú, ká tó lè ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè lo ẹ̀bùn wọn ní kíkún, a gbọ́dọ̀ máa lo ìfòyemọ̀. Bá a ṣe rí i nínú ìrírí ti Julien, kò yẹ kó jẹ́ pé kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn èèyàn nìkan la ó máa rí. Nípa bẹ́ẹ̀, àá lè fòye mọ àwọn ànímọ́ dáadáa tí wọ́n ní àti ẹ̀bùn àbínibí wọn, èyí tí a lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú sunwọ̀n sí i. Irú ojú tí Jésù fi wo àpọ́sítélì Pétérù náà nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pétérù máa ń hùwà bí ẹni tí kò ṣeé gbára lé láwọn ìgbà míì, Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ó máa dúró digbí bí àpáta.—Jòh. 1:42.

13, 14. (a) Báwo ni Bánábà ṣe lo ìfòyemọ̀ nínú ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́mọkùnrin náà, Máàkù? (b) Báwo ni ọ̀dọ́kùnrin kan ṣe jàǹfààní látinú irú ìrànlọ́wọ́ tí Máàkù rí gbà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

13 Bánábà lo irú ìfòyemọ̀ bẹ́ẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ tó wáyé nípa Jòhánù, tó tún ń jẹ́ Máàkù, tí í ṣe orúkọ àwọn ará Róòmù. (Ìṣe 12:25) Nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà jọ lọ, Máàkù wà pẹ̀lú wọn gẹ́gẹ́ bí “ẹmẹ̀wà” wọn, ó sì ṣeé ṣe kó máa bá wọn bójú tó àwọn nǹkan tara tí wọ́n bá nílò. Àmọ́, nígbà tí wọ́n dé Panfílíà, Máàkù  ṣàdédé pa dà lẹ́yìn wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, kò sí pẹ̀lú wọn nígbà tí wọ́n rìnrìn àjò gba àríwá lọ sí ibì kan táwọn ọlọ́ṣà pọ̀ sí. (Ìṣe 13:5, 13) Àmọ́, ó ṣe kedere pé Bánábà gbójú fo ìwà àìṣedéédéé Máàkù, lẹ́yìn ìgbà náà ló wá lo àǹfààní yẹn láti parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. (Ìṣe 15:37-39) Èyí ran ọ̀dọ́mọkùnrin náà lọ́wọ́ láti di ìránṣẹ́ Jèhófà tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀. Ó sì wá ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà ní àtìmọ́lé nílùú Róòmù, Máàkù wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì fi ìkíni ránṣẹ́ sí àwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè, Pọ́ọ̀lù sì sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní rere. (Kól. 4:10) Ẹ wo bí inú Bánábà ṣe máa dùn tó nígbà tí Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ tún sọ pé kí wọ́n jẹ́ kí Máàkù wá ran òun lọ́wọ́.—2 Tím. 4:11.

14 Arákùnrin Alexandre, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di alàgbà náà rántí bí òun ṣe jàǹfààní látinú ọgbọ́n tí arákùnrin kan fi bá òun lò. Ó ní: “Nígbà tí mo ṣì kéré, ó máa ń ṣòro fún mi gan-an láti gbàdúrà ní gbangba. Àmọ́, alàgbà kan ṣàlàyé bí mo ṣe lè máa múra ọkàn mi sílẹ̀ kí ara mi sì balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ tí mo bá fẹ́ gbàdúrà. Dípò tí ì bá fi máa pẹ́ mi sílẹ̀, lemọ́lemọ́ ló máa ń pè mí láti gbàdúrà ní ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Nígbà tó ṣe, mo wá túbọ̀ ní ìgboyà.”

15. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun mọrírì àwọn arákùnrin rẹ̀?

15 Tá a bá kíyè sí ànímọ́ rere tí arákùnrin kan ní, ǹjẹ́ a máa ń sọ fún un bá a ṣe mọyì ànímọ́ rere náà tó? Nínú ìwé Róòmù orí 16, ó ju ogún [20] èèyàn lọ tí Pọ́ọ̀lù dárúkọ tó sì kí nítorí àwọn ànímọ́ rere tí wọ́n ní, èyí tó mú kí wọ́n jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún un. (Róòmù 16:3-7, 13) Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù gbà pé òun ò tiẹ̀ tíì lálàá pé òun máa di Kristẹni nígbà tí Andironíkọ́sì àti Júníásì ti jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi. Nípa bẹ́ẹ̀, ó fi hàn pé òun mọyì ìfaradà wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Pọ́ọ̀lù tún sọ̀rọ̀ rere nípa ìyá Rúfọ́ọ̀sì, bóyá nítorí bí obìnrin náà ṣe máa ń fìfẹ́ bójú tó o.

Frédéric (tó wà lápá òsì) fún Rico níṣìírí pé kó má ṣe yẹ ìpinnu rẹ̀ pé Jèhófà lòun á máa sìn (Wo ìpínrọ̀ 16)

16 Ọ̀pọ̀ ohun rere ló máa ń tìdí rẹ̀ wá tá a bá ń gbóríyìn fún àwọn ọ̀dọ́. Àpẹẹrẹ kan ni ti ọ̀dọ́kùnrin kan tó wá láti ilẹ̀ Faransé, tó ń jẹ́ Rico. Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ̀dọ́kùnrin yìí torí pé bàbá rẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí kò fẹ́ kó ṣèrìbọmi. Rico rò pé òun ní láti dúró di ìgbà tí òun bá tójú bọ́ tàbí tí òun bá pé ọmọ ọdún méjìdínlógún kóun tó lè sin Jèhófà ní kíkún. Kò tún dùn mọ́ ọn nínú bí wọ́n ṣe ń fi ṣe ẹlẹ́yà nílé ẹ̀kọ́. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Frédéric, tí wọ́n ní kó máa bá ọmọkùnrin náà ṣèkẹ́kọ̀ọ́ sọ pé: “Mo gbóríyìn fún Rico torí pé ó ní láti jẹ́ pé ó ti ń fìgboyà ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ fáwọn èèyàn kí wọ́n tó lè ṣe àtakò bẹ́ẹ̀ sí i.” Ọ̀rọ̀ tí alàgbà yìí fi gbóríyìn fún Rico túbọ̀ mú kó pinnu pé òun á máa bá a nìṣó láti jẹ́ àpẹẹrẹ rere, ìyẹn sì jẹ́ kó túbọ̀ sún mọ́ bàbá rẹ̀. Rico ṣe ìrìbọmi nígbà tó pé ọmọ ọdún méjìlá.

Jérôme (tó wà lápá ọ̀tún) ran Ryan lọ́wọ́ láti di míṣọ́nnárì (Wo ìpínrọ̀ 17)

17 Ní gbogbo ìgbà tá a bá gbóríyìn fún àwọn tá a jọ jẹ́ ará torí iṣẹ́ kan tí wọ́n ṣe dáadáa tàbí nítorí ìsapá wọn, ńṣe là  ń fún wọn níṣìírí láti túbọ̀ máa sin Jèhófà. Sylvie, * tó ti ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní ilẹ̀ Faransé fún ọ̀pọ̀ ọdún ṣàlàyé pé àwọn arábìnrin náà lè máa fún àwọn arákùnrin níṣìírí. Ó ṣàlàyé pé àwọn obìnrin máa ń kíyè sí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan, wọ́n sí máa ń mọyì ìsapá táwọn ọkùnrin ń ṣe. Nípa báyìí, “àwọn náà lè fi ọ̀rọ̀ ìgbóríyìn tiwọn kún ti àwọn arákùnrin tó ní ìrírí.” Ó tún sọ pé: “Ńṣe ni mo ka gbígbóríyìn fúnni gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí mo gbọ́dọ̀ máa ṣe.” (Òwe 3:27) Jerôme, tó ń ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè French Guiana ti ran ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́kùnrin lọ́wọ́ débi tí àwọn náà fi di míṣọ́nnárì. Ó sọ pé: “Mo ti kíyè sí i pé tí mo bá gbóríyìn fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin torí àwọn ohun tí wọ́n ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tàbí torí pé ìdáhùn wọn nípàdé fọgbọ́n yọ, ó máa ń mú kí wọ́n túbọ̀ nígboyà. Látàrí ìyẹn, wọ́n máa ń fẹ́ láti sunwọ̀n sí i.”

18. Kí nìdí tó fi ṣàǹfààní pé kí ìwọ àtàwọn ọ̀dọ́kùnrin jọ máa ṣiṣẹ́?

18 A tún lè mú kí àwọn ará wa máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí tá a bá ń bá wọn ṣiṣẹ́. Alàgbà kan lè ní kí ọ̀dọ́kùnrin kan tó mọ kọ̀ǹpútà lò dáadáa máa bá òun tẹ àwọn ìsọfúnni kan jáde látorí ìkànnì jw.org, èyí tó máa wúlò fún àwọn àgbàlagbà tí wọn kò ní kọ̀ǹpútà. Tó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ohun kan wà tó o fẹ́ tún ṣe ní àyíká Gbọ̀ngàn Ìjọba, o ò ṣe pe ọ̀dọ́kùnrin kan kẹ́ ẹ lè jọ ṣe é? Tó o bá ń lo ìdánúṣe láwọn ọ̀nà yìí, wàá lè kíyè sí àwọn ọ̀dọ́, wàá lè gbóríyìn fún wọn, wàá sì rí bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú.—Òwe 15:23.

MÁA MÚRA SÍLẸ̀ DE ỌJỌ́ IWÁJÚ

19, 20. Kí nìdí tó fi yẹ ká ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú?

19 Nígbà tí Jèhófà yan Jóṣúà gẹ́gẹ́ bí aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Ó pàṣẹ fún Mósè pé kó fún Jóṣúà ní “ìṣírí” kó sì tún fún un “lókun.” (Ka Diutarónómì 3:28.) Ńṣe ni àwọn èèyàn ń rọ́ wá sínú àwọn ìjọ wa kárí ayé. Gbogbo àwọn ará tí wọ́n ní ìrírí pátá ló lè ran àwọn ará tó jẹ́ ọ̀dọ́ àti àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ láti mú ẹ̀bùn tí wọ́n ní dàgbà kí wọ́n sì lò ó ní kíkún, kì í ṣe àwọn alàgbà nìkan. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ló máa gba iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, nígbà tí àwọn míì á sì ‘tóótun láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn.’—2 Tím. 2:2.

20 Yálà a wà nínú ìjọ tí wọ́n ti dá sílẹ̀ tipẹ́ ni o tàbí a jẹ́ ara àwùjọ kékeré kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbèrú, ẹ jẹ́ ká ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ torí pé ẹyin ló ń bọ̀ wá di àkùkọ. Ohun pàtàkì tó sì máa mú ká fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a fẹ́ fìwà jọ Jèhófà tó jẹ́ pé ibi tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dára sí ló máa ń wá ní gbogbo ìgbà.

^ ìpínrọ̀ 17 A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.