Àwọn èèyàn Jèhófà “Kọ Àìṣòdodo Sílẹ̀ Ní Àkọ̀tán”
“Kí gbogbo ẹni tí ń pe orúkọ Jèhófà kọ àìṣòdodo sílẹ̀ ní àkọ̀tán.”—2 TÍM. 2:19.
ǸJẸ́ o ti rí i kí wọ́n kọ orúkọ Jèhófà sára ilé kan tó wà fún ìlò aráàlú tàbí sára ohun ìṣẹ̀ǹbáyé kan rí? Ó dájú pé ó máa yà ẹ́ lẹ́nu, inú rẹ á sì dùn. Ó ṣe tán, orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ yìí ṣe pàtàkì gan-an nínú ìjọsìn wa, torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá! Ní gbogbo ayé, kò sí àwùjọ míì lóde òní tí àwọn èèyàn mọ̀ mọ orúkọ Ọlọ́run bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Síbẹ̀, àwọn nǹkan wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe torí àǹfààní tá a ní láti máa jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run.
2. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe torí pé à ń jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run?
2 Ti pé à ń lo orúkọ Ọlọ́run kò tó láti mú ká rí ojú rere Jèhófà. A gbọ́dọ̀ máa fi àwọn ìlànà rẹ̀ ṣèwà hù. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi ń tẹ̀ ẹ́ mọ́ àwa èèyàn Jèhófà létí pé a gbọ́dọ̀ “yí padà kúrò nínú ohun búburú.” (Sm. 34:14) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mú kí ìlànà yìí túbọ̀ ṣe kedere nígbà tó kọ̀wé pé: “Kí gbogbo ẹni tí ń pe orúkọ Jèhófà kọ àìṣòdodo sílẹ̀ ní àkọ̀tán.” (Ka 2 Tímótì 2:19.) Torí pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn èèyàn mọ̀ dáadáa pé òótọ́ là ń pe orúkọ rẹ̀. Àmọ́, báwo la ṣe lè kọ àìṣòdodo sílẹ̀ lákọ̀tán?
“Ẹ KÚRÒ” NÍNÚ BÚBURÚ
3, 4. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló pẹ́ tí àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì ti ń fẹ́ láti lóye? Kí nìdí?
3 Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ ṣáájú ọ̀rọ̀ tó wà nínú 2 Tímótì 2:19 àtèyí tó sọ lẹ́yìn rẹ̀. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn mẹ́nu kan “ìpìlẹ̀ lílágbára ti Ọlọ́run” lẹ́yìn náà ló wá sọ nípa àwọn àkọlé méjì tí wọ́n kọ sára rẹ̀. Ó dájú pé ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù fà yọ látinú Númérì 16:5 ni àkọlé àkọ́kọ́ tó sọ pé, “Jèhófà mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀.” (Wo àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí.) Àkọlé kejì ni, “Kí gbogbo ẹni tí ń pe orúkọ Jèhófà kọ àìṣòdodo sílẹ̀ ní àkọ̀tán.” Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì ti ń fẹ́ láti lóye gbólóhùn kejì yìí. Kí nìdí?
4 Ó jọ pé apá ibòmíì nínú Bíbélì ni Pọ́ọ̀lù ti fa ọ̀rọ̀ yìí yọ. Síbẹ̀, kò jọ pé gbólóhùn kankan wà nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù tó bá ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù fà yọ yìí mu gẹ́lẹ́. Torí náà, kí ni àpọ́sítélì náà ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Kí gbogbo ẹni tí ń pe orúkọ Jèhófà kọ àìṣòdodo sílẹ̀ ní àkọ̀tán”? Kó tó di pé Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé ká kọ àìṣòdodo sílẹ̀, ó ti kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ kan, èyí tó fà yọ látinú Númérì orí 16, tó ti sọ̀rọ̀ nípa ìṣọ̀tẹ̀ Kórà. Àbí gbólóhùn kejì yìí ní í ṣe pẹ̀lú ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìdìtẹ̀ náà wáyé?
5-7. Àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Mósè tó jẹ́ ká mọ ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú 2 Tímótì 2:19? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
5 Bíbélì sọ pé àwọn ọmọ Élíábù, ìyẹn Dátánì àti Ábírámù lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Kórà láti dìtẹ̀ sí Mósè àti Áárónì. (Núm. 16:1-5) Wọ́n kan Mósè lábùkù lójú gbogbo èèyàn, wọ́n sì tàpá sí ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run fún un. Àárín àwọn èèyàn tó ń fi òótọ́ sin Jèhófà ni gbogbo àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn ń gbé, tí wọ́n sì ń wá bí wọ́n ṣe máa ba àjọṣe tí àwọn èèyàn náà ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Nígbà tó di ọjọ́ tí Jèhófà máa fi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn tó ń fi òótọ́ ọkàn sìn ín àtàwọn ọlọ̀tẹ̀ náà, ó fún wọn ní ìtọ́ni kan tó ṣe kedere.
6 Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: ‘Bá àpéjọ sọ̀rọ̀, pé, “Ẹ kúrò ní àyíká ibùgbé Kórà, Dátánì àti Ábírámù!”’ Lẹ́yìn ìyẹn, Mósè dìde, ó sì tọ Dátánì àti Ábírámù lọ, àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì sì bá a lọ. Nígbà náà ni ó bá àpéjọ sọ̀rọ̀, pé: ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kúrò níwájú àgọ́ àwọn ọkùnrin burúkú wọ̀nyí, kí ẹ má sì fara kan ohunkóhun tí ó jẹ́ tiwọn, kí a má bàa gbá yín lọ nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n kúrò níwájú ibùgbé Kórà, Dátánì àti Ábírámù, láti ìhà gbogbo.” (Núm. 16:23-27) Lẹ́yìn náà ni Jèhófà pa gbogbo àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà. Àmọ́, Jèhófà dá ẹ̀mí àwọn tó fi òótọ́ ọkàn jọ́sìn rẹ̀ sí, ìyẹn àwọn tí wọ́n kọ àìṣòdodo sílẹ̀ lákọ̀tán nípa kíkúrò láàárín àwọn èèyàn burúkú náà.
7 Jèhófà máa ń rí ohun tó wà nínú ọkàn. Ó ń kíyè sí ìdúróṣinṣin àwọn tó jẹ́ tirẹ̀. Síbẹ̀, ó yẹ kí àwọn adúróṣinṣin bẹ́ẹ̀ ṣe ìpinnu pàtó, kí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ pátápátá kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìṣòdodo yẹn. Ó ṣeé ṣe nígbà náà pé ohun tó wà nínú Númérì 16:5, 23-27, ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Kí gbogbo ẹni tí ń pe orúkọ Jèhófà kọ àìṣòdodo sílẹ̀ ní àkọ̀tán.” Ìparí èrò wa yìí bá a mú gan-an pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù ti kọ́kọ́ sọ pé “Jèhófà mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀.”—2 Tím. 2:19.
KỌ “ÌBÉÈRÈ ÒMÙGỌ̀ ÀTI TI ÀÌMỌ̀KAN” SÍLẸ̀
8. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kéèyàn kàn máa pe orúkọ Jèhófà tàbí kó jẹ́ apá kan ìjọ Kristẹni kò tó?
8 Bí Pọ́ọ̀lù ṣe mẹ́nu kan àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Mósè yẹn, ńṣe ló ń rán Tímótì létí pé ó ṣe pàtàkì pé kó ṣe ìpinnu pàtó tí kò ní jẹ́ kí àjọṣe tímọ́tímọ́ tó ní pẹ̀lú Jèhófà bà jẹ́. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ó dáa kéèyàn jẹ́ apá kan ìjọ, àmọ́ ìyẹn nìkan kò tó bó ṣe jẹ́ pé wíwulẹ̀ pe orúkọ Jèhófà lọ́jọ́ Mósè kò ní kí àwọn èèyàn náà ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Àwọn tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn gbọ́dọ̀ dìídì pinnu pé àwọn á kọ àìṣòdodo sílẹ̀ ní àkọ̀tán. Kí nìyẹn túmọ̀ sí fún Tímótì? Kí sì ni àwa èèyàn Jèhófà lóde òní rí kọ́ nínú ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ yẹn?
9. Àkóbá wo ni àwọn “ìbéèrè òmùgọ̀ àti ti àìmọ̀kan” ṣe fún ìjọ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní?
9 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa ní ìmọ̀ràn tó ṣe pàtó nípa irú àìṣòdodo tó yẹ kí àwa Kristẹni kọ̀ sílẹ̀ lákọ̀tán. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá wo àwọn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ ní àwọn ẹsẹ tó ṣáájú 2 Tímótì 2:19, àtèyí tó sọ lẹ́yìn rẹ̀, ó sọ fún Tímótì pé kó “má jà lórí ọ̀rọ̀” àti pé kó “máa yẹ àwọn òfìfo ọ̀rọ̀ sílẹ̀.” (Ka 2 Tímótì 2:14, 16, 23.) Àwọn ará kan nínú ìjọ ń gbé ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà lárugẹ. Bákan náà, ó tún jọ pé àwọn míì ti bẹ̀rẹ̀ sí í tan àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fa àríyànjiyàn kálẹ̀. Ká tiẹ̀ wá sọ pé irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kò ta ko Ìwé Mímọ́, wọ́n ń fa ìpínyà. Wọ́n máa ń dá awuyewuye àti àríyànjiyàn sílẹ̀, wọ́n sì máa ń ba àjọṣe alárinrin tó wà láàárín ìjọ jẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí wọ́n rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n yẹra fún àwọn “ìbéèrè òmùgọ̀ àti ti àìmọ̀kan.”
10 Lóde òní, àwọn apẹ̀yìndà ò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ mọ́ nínú ìjọ. Síbẹ̀, bí irú ẹ̀kọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu bẹ́ẹ̀ bá yọjú, ẹ jẹ́ ká dúró lórí ìpinnu wa pé ọ̀nà yòówù kí irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ gbà wá, a ò ní gbà á láyè. Kò ní bọ́gbọ́n mu pé ká máa bá àwọn apẹ̀yìndà fa ọ̀rọ̀, yálà lójúkojú, tàbí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tàbí lọ́nà èyíkéyìí mìíràn téèyàn ti lè bá ẹlòmíì sọ̀rọ̀. Kódà tá a bá rò pé ṣe la fẹ́ ran onítọ̀hún lọ́wọ́, ńṣe ni irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ á mú ká tàpá sí ìtọ́ni Ìwé Mímọ́ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ jíròrò rẹ̀ tán yìí. Nípa bẹ́ẹ̀, a kì í ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn apẹ̀yìndà, ńṣe la máa ń yẹra fún wọn, torí pé èèyàn Jèhófà ni wá.
11. Kí ló lè mú kéèyàn máa fa ọ̀rọ̀ lórí àwọn “ìbéèrè òmùgọ̀”? Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀?
11 Yàtọ̀ sí ìpẹ̀yìndà, àwọn nǹkan míì tún wà tó lè ba àlàáfíà ìjọ jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè àwọn “ìbéèrè òmùgọ̀ àti ti àìmọ̀kan” torí pé èrò tá a ní nípa eré ìnàjú yàtọ̀ síra. Àmọ́ o, tí àwọn kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ àwọn míì pé kí wọ́n lọ́wọ́ nínú eré ìnàjú tó lòdì sí ìlànà Jèhófà nípa ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́, àwọn alàgbà kò ní gbojú fo irú ìwà bẹ́ẹ̀ kìkì nítorí pé wọn ò fẹ́ bá ẹnikẹ́ni fa ọ̀rọ̀. (Sm. 11:5; Éfé. 5:3-5) Síbẹ̀, àwọn alàgbà máa ń ṣọ́ra kó má lọ di pé ojú ìwòye tara wọn ni wọ́n á máa gbé lárugẹ. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Ìwé Mímọ́ gba àwọn Kristẹni tó jẹ́ alábòójútó pé: “Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín, . . . kì í ṣe bí ẹní ń jẹ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run lórí, ṣùgbọ́n kí ẹ di àpẹẹrẹ fún agbo.”—1 Pét. 5:2, 3; ka 2 Kọ́ríńtì 1:24.
12, 13. (a) Ojú wo ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wo irú eré ìnàjú tí ẹnì kan bá yàn, ìlànà Bíbélì wo la sì ń tẹ̀ lé? (b) Báwo ni àwọn ìlànà tá a jíròrò ní ìpínrọ̀ 12 ṣe kan onírúurú ọ̀rọ̀ ara ẹni?
12 Tó bá di ọ̀rọ̀ eré ìnàjú, ètò Ọlọ́run kì í tanná wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fíìmù, géèmù orí kọ̀ǹpútà tàbí fóònù, ìwé tàbí orin kí wọ́n bàa lè pinnu èyí tí kò yẹ ká máa gbádùn. Kí nìdí tí wọ́n ò fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Bíbélì rọ̀ wá lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pé ká kọ́ “agbára ìwòye [wa] láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Héb. 5:14) Àwọn ìlànà tó ṣe kedere wà nínú Ìwé Mímọ́ tí Kristẹni kan lè gbé yẹ̀ wò tó bá fẹ́ yan eré ìnàjú. Ní gbogbo apá ìgbésí ayé wa, ó yẹ ká pinnu pé a ó máa “bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa dájú.” (Éfé. 5:10) Bíbélì kọ́ wa pé àwọn olórí ìdílé ní àṣẹ lórí ìdílé wọn, torí bẹ́ẹ̀ wọ́n lè yàn láti má ṣe fàyè gba àwọn eré ìnàjú kan nínú ìdílé wọn.—1 Kọ́r. 11:3; Éfé. 6:1-4.
13 Kì í ṣe ìgbà tá a bá fẹ́ yan àwọn eré ìnàjú nìkan làwọn ìlànà Bíbélì tá a jíròrò tán yìí wúlò. Wọ́n tún wúlò tó bá kan ọ̀rọ̀ aṣọ àti ìmúra, ọ̀rọ̀ ìlera àti irú oúnjẹ tó yẹ àtèyí tí kò yẹ, àtàwọn nǹkan míì tó jẹ́ èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́. Ìdí sì ni pé irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ lè fa àríyànjiyàn. Torí náà, tí àwọn nǹkan yìí kò bá ti tẹ ìlànà Ìwé Mímọ́ lójú, àwa èèyàn Jèhófà máa ń fọgbọ́n hùwà, a kì í lọ́wọ́ nínú àríyànjiyàn lórí àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Ìdí sì ni pé, “kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn.”—2 Tím. 2:24.
MÁ ṢE KẸ́GBẸ́ BÚBURÚ!
14. Àpèjúwe wo ni Pọ́ọ̀lù lò láti jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká má ṣe kẹ́gbẹ́ búburú?
14 Ọ̀nà míì wo ni àwọn “tí ń pe orúkọ Jèhófà” lè gbà “kọ àìṣòdodo sílẹ̀ ní àkọ̀tán”? Ọ̀nà náà ni pé kí wọ́n má ṣe ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn tó ń hùwà àìṣòdodo. Ó gbàfiyèsí pé Pọ́ọ̀lù tún lo àkàwé míì lẹ́yìn tó sọ̀rọ̀ nípa “ìpìlẹ̀ lílágbára ti Ọlọ́run.” Ó sọ̀rọ̀ nípa “ilé ńlá” kan tó jẹ́ pé kì í ṣe “àwọn ohun èlò wúrà àti fàdákà nìkan ni ó wà [nínú ilé náà] ṣùgbọ́n ti igi àti ohun èlò amọ̀ pẹ̀lú, àwọn kan sì wà fún ète ọlọ́lá ṣùgbọ́n àwọn mìíràn fún ète tí kò ní ọlá.” (2 Tím. 2:20, 21) Lẹ́yìn náà ló wá gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n “yẹra” tàbí kí wọ́n má ṣe ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn ohun èlò tó wà fún ète “tí kò ní ọlá.”
15, 16. Kí la lè rí kọ́ nínú àpèjúwe tí Pọ́ọ̀lù ṣe nípa “ilé ńlá”?
15 Kí ni ìtumọ̀ àpèjúwe náà? Nínú àpèjúwe tí Pọ́ọ̀lù ṣe, ó fi ìjọ Kristẹni wé “ilé ńlá” kan, ó sì fi àwọn ará tó wà nínú ìjọ wé “àwọn ohun èlò,” tàbí àwọn nǹkan tá a máa ń lò nínú ilé. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ohun tó lè ṣèpalára fún ìlera tàbí ìdọ̀tí lè kó èérí bá àwọn ohun èlò téèyàn ń lò nínú ilé. Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni onílé máa ya àwọn ohun èlò bẹ́ẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ohun èlò tó mọ́, bí irú èyí tó fi ń se oúnjẹ.
16 Bákan náà, àwa èèyàn Jèhófà lónìí ń sapá láti máa gbé ìgbé ayé tó mọ́. Torí bẹ́ẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ máa ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn kan nínú ìjọ tó ti mọ́ lára láti máa tàpá sí àwọn ìlànà Jèhófà. (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:33.) Tá a bá ní láti máa ṣọ́ra fún àwọn kan nínú ìjọ, ǹjẹ́ kò ni yẹ ká “yà kúrò,” lọ́dọ̀ àwọn tí kò sí nínú ìjọ, ká má sì ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú wọn? Ó ṣe tán, ọ̀pọ̀ nínú wọn jẹ́ ‘olùfẹ́ owó, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìdúróṣinṣin, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, àti olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.’—2 Tím. 3:1-5.
JÈHÓFÀ Ń BÙ KÚN ÀWỌN ÌPINNU WA
17. Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ adúróṣinṣin ṣe fi hàn láìkù síbì kan pé àwọn kò nífẹ̀ẹ́ sí àìṣòdodo?
17 Lọ́nà tó ṣe pàtó, Bíbélì sọ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe pinnu tí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ lọ́gán nígbà tí wọ́n sọ fún wọn pé kí wọ́n “kúrò ní àyíká ibùgbé Kórà, Dátánì àti Ábírámù.” Ìtàn náà sọ pé “lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n kúrò.” (Núm. 16:24, 27) Wọn ò lọ́ tìkọ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò fi nǹkan falẹ̀. Ìwé Mímọ́ tún sọ bí wọ́n ṣe fi hàn láìkù síbì kan pé àwọn kò nífẹ̀ẹ́ sí àìṣòdodo. Ó ní “wọ́n kúrò . . . láti ìhà gbogbo.” Torí pé àwọn èèyàn yẹn jẹ́ adúróṣinṣin, wọn kò fẹ́ fi ẹ̀mí ara wọn wewu. Ìgbọràn wọn kì í ṣe ojú ayé, tọkàntọkàn ni wọ́n fi ṣègbọràn. Wọ́n fi hàn pé ọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn wà, àwọn sì lòdì sí àìṣòdodo. Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ yìí?
18. Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó gba Tímótì níyànjú pé kó “sá fún àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn”?
18 Tó bá di pé ká má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, a ní láti gbé ìgbésẹ̀ láìjáfara àti láìsí iyè méjì. Ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tó gba Tímótì níyànjú pé kó “sá fún àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn.” (2 Tím. 2:22) Tímótì kì í ṣe ọmọdé nígbà tá à ń sọ yìí, ó ṣeé ṣe kó ti lé ní ọgbọ̀n [30] ọdún. Síbẹ̀, kì í ṣe àwọn ọmọdé nìkan ló máa ń ní ‘àwọn ìfẹ́-ọkàn tó ń bá ìgbà èwe rìn.’ Tí irú àwọn ìfẹ́ ọkàn bẹ́ẹ̀ bá wá sí Tímótì lọ́kàn, àfi kó yáa “sá” fún wọn. Lédè míì, Tímótì ní láti “kọ àìṣòdodo sílẹ̀ ní àkọ̀tán.” Ohun tó jọ èyí náà ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Bí ojú rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” (Mát. 18:9) Lónìí, ojú ẹsẹ̀ làwọn Kristẹni tó fi ìmọ̀ràn yìí sọ́kàn máa ń pinnu pé àwọn ò ní fàyè gba ohun tó lè ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Wọ́n sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ láìlọ́ tìkọ̀ àti láìfi nǹkan falẹ̀.
19. Báwo ni àwọn kan ṣe ń gbé ìgbésẹ̀ ní kánmọ́ lóde òní, kí ohunkóhun má bàa ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà jẹ́?
19 Àwọn kan tí wọ́n máa ń mu àmupara tàbí tí wọn ò lè ṣe kí wọ́n má mutí kí wọ́n tó di Ẹlẹ́rìí ti pinnu pé àwọn ò ní mu ọtí líle mọ rárá. Àwọn míì kì í lọ́wọ́ nínú àwọn eré ìnàjú kan bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ohun tó burú nínú àwọn eré ìnàjú náà. Ìdí tí wọ́n sì fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn eré ìnàjú náà lè mú kí ọkàn wọn fà sí ìwà búburú. (Sm. 101:3) Bí àpẹẹrẹ, kí arákùnrin kan tó di Ẹlẹ́rìí, ó gbádùn kó máa lọ sí òde ijó níbi tí ìwà ìṣekúṣe ti wọ́pọ̀. Àmọ́ lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó pinnu pé òun ò ní máa jó níbi ìkórajọ èyíkéyìí, títí kan ìkórajọ àwọn Ẹlẹ́rìí. Ìdí sì ni pé kò fẹ́ máa rántí àwọn ìwà rẹ̀ àtijọ́, kò sì fẹ́ kí èròkerò wá sọ́kàn òun. Ká sòótọ́, kò sí òfin tó sọ pé kí àwọn Kristẹni yẹra pátápátá fún ọtí, ijó tàbí àwọn nǹkan míì tí kò burú. Síbẹ̀, a retí pé kí gbogbo wa máa ṣe ìpinnu tó tọ́ ká sì máa gbé ìgbésẹ̀ pàtó tí kò ní jẹ́ kí àárín àwa àti Jèhófà bà jẹ́.
20. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má rọrùn láti “kọ àìṣòdodo sílẹ̀ ní àkọ̀tán,” kí ló fi wá lọ́kàn balẹ̀ tó sì ń tù wá nínú?
20 Ojúṣe ńlá ló já lé wa léjìká torí pé à ń jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ “kọ àìṣòdodo sílẹ̀ ní àkọ̀tán” ká sì “yí padà kúrò nínú ohun búburú.” (Sm. 34:14) Ká sòótọ́, kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ohun tó fi wá lọ́kàn balẹ̀ ni pé ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa ń nífẹ̀ẹ́ “àwọn tí í ṣe tirẹ̀” tí wọ́n sì rọ̀ mọ́ ìlànà òdodo rẹ̀.—2 Tím. 2:19; ka 2 Kíróníkà 16:9a.