Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Baba Kú, àmọ́ Baba Kù

Baba Kú, àmọ́ Baba Kù

ÌLÚ Graz ní orílẹ̀-èdè Austria ni wọ́n bí bàbá mi sí ní ọdún 1899, torí náà ọ̀dọ́ ni wọ́n nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní jà. Ṣùgbọ́n, gẹ́rẹ́ tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1939 ni wọ́n fipá mú bàbá mi wọ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Jámánì. Ojú ogun yẹn ni wọ́n kú sí lọ́dún 1943 nígbà tí wọ́n ń jà ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Bí mo ṣe di ọmọ aláìníbaba nìyẹn nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún méjì péré. Mi ò gbọ́njú mọ̀ wọ́n rárá, ó sì máa ń dùn mi gan-an pé mi ò ní bàbá, pàápàá nígbà tí mo bá rí i pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọkùnrin tá a jọ wà níléèwé ló ní bàbá. Àmọ́, nígbà tó kù díẹ̀ kí n pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa Baba wa ọ̀run, Baba tó ju baba lọ, tí kì í kú. Èyí sì tù mí nínú gan-an.—Háb. 1:12.

ÌGBÀ TÍ MO WÀ NÍNÚ ẸGBẸ́ “BOY SCOUTS”

Ìgbà tí mi ò tíì pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún àti ìgbà tí mo wà ní kékeré

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méje, mo wọ ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń pè ní “Boy Scouts.” Ẹgbẹ́ kan tó wà kárí ayé ni ẹgbẹ́ Síkáòtù yìí. Ọ̀gágun Robert Stephenson Smyth Baden-Powell ti ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló dá ẹgbẹ́ náà sílẹ̀ nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, lọ́dún 1908. Ní ọdún 1916, ó dá ẹgbẹ́ síkáòtù kékeré sílẹ̀ fáwọn ọmọkùnrin tó jẹ́ ẹgbẹ́ mi, ìyẹn ló pè ní “Wolf Cubs” (tàbí “Cub Scouts”).

Mo máa ń gbádùn àwọn ìpàgọ́ tá a máa ń lọ ṣe nínú igbó láwọn òpin ọ̀sẹ̀, àá sùn nínú àtíbàbà, àá wọ aṣọ ẹgbẹ́ wa, àá sì máa yan bí ológun bí wọ́n ṣe ń lu ìlù fún wa. Èyí tó tiẹ̀ tún gbádùn mọ́ mi jù ni ìgbà tí mo bá wà pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wa yòókù, títí kan ìgbà tá a bá ń kọrin tá a sì ń jó yíká iná níbi tá a pàgọ́ sí, tá a sì tún ń ṣe onírúurú eré nínú igbó. A tún kọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run dá, èyí sì mú kí n mọyì àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Ẹlẹ́dàá wa.

Wọ́n máa ń sọ fún àwa Síkáòtù pé ká máa ṣe ohun rere lójoojúmọ́. Àkọmọ̀nà àwa tá a wà nínú ẹgbẹ́ náà nìyẹn. Tá a bá ń kíra wa, a tún máa ń sọ pé “Má Ṣe Túra Sílẹ̀.” Ọ̀rọ̀ yẹn máa ń dùn mọ́ mi. Nínú gbogbo àwa bí ọgọ́rùn-ún tá à ń kóra wa kiri yẹn, bí ìdajì ló jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, ìdajì jẹ́ ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì, ẹnì kan ṣoṣo sì jẹ́ ẹlẹ́sìn Búdà.

Láti ọdún 1920 ni ìpàdé gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ Síkáòtù tó wà kárí ayé ti máa ń wáyé láàárín ọdún mélòó kan síra. Mo lọ sí ìkeje irú ìpàdé yẹn, tí wọ́n pè ní “World Scout Jamboree,” èyí tó wáyé ní Bad Ischl lórílẹ̀-èdè Austria ní oṣù August ọdún 1951. Mo tún lọ sí ìkẹsàn-án irú rẹ̀ tó wáyé ní Sutton Park, nítòsí ìlú Birmingham, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ní oṣù August ọdún 1957. Gbogbo àwa Síkáòtù tá a ti orílẹ̀-èdè àti ìpínlẹ̀ márùndínláàádọ́rùn-ún [85] wá síbẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33,000]. Àwọn èèyàn tó tó ọ̀kẹ́ mẹ́tàdínlógójì o lé ẹgbàárún [750,000] ló wá wò wá níbẹ̀, títí kan Ọbabìnrin Elizabeth ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Lójú mi, ṣe ló dà bí ẹgbẹ́ ará kan tó kárí ayé. Mi ò mọ̀ pé màá ṣì wá mọ̀ nípa ẹgbẹ́ ará kan tó kárí ayé lọ́nà tó kàmàmà jùyẹn lọ, ìyẹn ẹgbẹ́ ará tẹ̀mí.

 MO BÁ ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ PÀDÉ FÚN ÌGBÀ ÀKỌ́KỌ́

Rudi Tschiggerl, ọ̀gá àwọn tó ń ṣe ìpápánu nílé oúnjẹ ló kọ́kọ́ wàásù fún mi

Ní ìgbà ìrúwé ọdún 1958, ó ku díẹ̀ kí n parí iṣẹ́ ní òtẹ́ẹ̀lì kan tó ń jẹ́ Grand Hotel Wiesler ní ìlú Graz lórílẹ̀-èdè Austria níbi tí mo ti ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń dá oníbàárà lóhùn nílé oúnjẹ. Ibẹ̀ ni ọkùnrin kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tó sì tún jẹ́ ọ̀gá àwọn tó ń ṣe ìpápánu nílé oúnjẹ náà ti jẹ́rìí fún mi lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà, orúkọ rẹ̀ ni Rudolf Tschiggerl. Mi ò tíì gbọ́ ohunkóhun nípa òtítọ́ rí. Ọ̀rọ̀ nípa Mẹ́talọ́kan ló kọ́kọ́ bá mi sọ, ó sì jẹ́ kó yé mi pé kì í ṣe ẹ̀kọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni. Mo bá a jiyàn pé Mẹ́talọ́kan wa kí n lè fi yé e pé ohun tó sọ kò tọ̀nà. Mo fẹ́ràn ọkùnrin tá a jọ ń ṣiṣẹ́ yìí, mo sì ronú pé máa yí i lérò pa dà kó lè pa dà sínú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì.

Rudolf, tá a sábà máa ń pè ní Rudi, fún mi ní Bíbélì kan. Àmọ́ mo fárígá pé ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹ̀dà ti Kátólíìkì. Kò pẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì náà tí mo fi rí i pé Rudi ti fi ìwé àṣàrò kúkúrú kan tí Watchtower Society ṣe sínú rẹ̀. Mi ò nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó ṣe yẹn rárá torí mo rò pé ó lè jẹ́ pé awúrúju ni ohun tó wà nínú ìwé náà. Àmọ́ ó wù mí ká jọ máa jíròrò Bíbélì. Rudi fi ọgbọ́n bá mi lò, kò sì fún mi ní ìtẹ̀jáde kankan mọ́. Látìgbà yẹn, ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan la máa ń jíròrò látinú Bíbélì, nígbà míì a máa ṣe é dòru ni, ìyẹn sì bá a nìṣó fún bí oṣù mẹ́ta.

Lẹ́yìn tí mo parí iṣẹ́ tí mò ń kọ́ ní òtẹ́ẹ̀lì tó wà ní ìlú wa ní Graz, ìyà mi tún ní kí n lọ kàwé sí i níbi téèyàn ti lè kọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe àbójútó òtẹ́ẹ̀lì. Ìdí nìyẹn tí mo fi kó lọ síbi tí ilé ẹ̀kọ́ náà wà ní ìlú Bad Hofgastein tó wà ní àfonífojì kan níbi àwọn òkè Alps. Ilé ẹ̀kọ́ náà máa ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú Grand Hotel tó wà ní ìlú Bad Hofgastein, torí náà mo máa ń lọ ṣiṣẹ́ níbẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kí n lè mọ púpọ̀ sí i nípa ohun tí mò ń kọ́ ní kíláàsì.

ARÁBÌNRIN MÉJÌ TÓ JẸ́ MÍṢỌ́NNÁRÌ BẸ̀ MÍ WÒ

Ilse Unterdörfer àti Elfriede Löhr bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ọdún 1958

Àṣé Rudi ti fi àdírẹ́sì iléèwé ti mo wà ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní ìlú Vienna, ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà níbẹ̀ sì ti fi ránṣẹ́ sí àwọn obìnrin méjì kan tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì. Orúkọ wọn ni Ilse Unterdörfer àti Elfriede Löhr. * Ọjọ́ kan ni olùgbàlejò wa ní òtẹ́ẹ̀lì wá sọ fún mi pé àwọn obìnrin méjì kan wà níta nínú ọkọ̀, tí wọ́n fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀. Ó kọ́kọ́ yà mí lẹ́nu torí mí ò tiẹ̀ mọ̀ wọ́n rí rárá. Àmọ́ mo lọ bá wọn. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, mo gbọ́ pé wọ́n wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí tó máa ń kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ láti ibì kan síbòmíì nígbà tí ìjọba Násì lórílẹ̀-èdè Jámánì fi òfin de iṣẹ́ wa kí Ogun Àgbáyé Kejì tó bẹ̀rẹ̀. Kí ogún yẹn tiẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ pàápàá ni àwọn ọlọ́pàá inú ti orílẹ̀-èdè Jámánì (Gestapo) ti mú wọn, tí wọ́n sì rán wọn lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà ní Lichtenburg. Lẹ́yìn náà ni wọ́n wá kó wọn lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Ravensbrück tó wà nítòsí Berlin nígbà tí ogun ń lọ lọ́wọ́.

Mo fi ọ̀wọ̀ tó yẹ wọ àwọn arábìnrin méjèèjì yẹn torí pé wọ́n tó mi bí lọ́mọ. Ìdí ẹ̀ nìyẹn tí mi ò fi fẹ́ fi àkókò wọn ṣòfò nípa bíbá wọn jíròrò, kó máà wá lọ jẹ́ pé lẹ́yìn bí ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù mélòó kan màá wá sọ fún wọn pé mi ò kẹ́kọ̀ọ́ mọ́. Torí náà, mo béèrè lọ́wọ́ wọn bóyá wọ́n lè bá mi wá àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ èrò tiwọn lórí ẹ̀kọ́ Kátólíìkì nípa bí àwọn àpọ́sítélì ṣe tò tẹ̀ léra. Mo sọ fún wọn pé màá mu un lọ sọ́dọ̀ àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì wa, a ó sì jọ jíròrò rẹ̀. Mo ronú pé ọ̀nà yẹn ni màá gbà mọ òtítọ́.

 MO KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍPA BABA MÍMỌ́ TÒÓTỌ́ TÓ WÀ NÍ Ọ̀RUN

Nínú ẹ̀kọ́ Kátólíìkì nípa bí àwọn àpọ́sítélì ṣe tò tẹ̀ léra wọ́n sọ pé bẹ̀rẹ̀ látorí àpọ́sítélì Pétérù ni àwọn póòpù ti bẹ̀rẹ̀ sí í tò tẹ̀ léra, tí wọ́n sì ń bá a lọ ní ṣísẹ́-n-tẹ̀lé látìgbà náà wá. (Ńṣe ni ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ṣi ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 16:18, 19 túmọ̀.) Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì tún fi kọ́ni pé póòpù ò lè ṣàṣìṣe nínú àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn tó bá ń sọ̀rọ̀ ex cathedra, tàbí nígbà tó bá ń ṣojú fún Ọlọ́run. Mo gba èyí gbọ́, mo sì ronú pé tí póòpù, tí àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì máa ń pè ní Baba Mímọ́, ò bá lè ṣàṣìṣe nínú ẹ̀kọ́ ìsìn, tó sì jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ ni Ọlọ́run jẹ́ Mẹ́talọ́kan, a jẹ́ pé òótọ́ ni ohun tó sọ. Àmọ́ tó bá lè ṣàṣìṣe, a jẹ́ pé ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan lè máà jóòótọ́. Abájọ tó fi jẹ́ pé ẹ̀kọ́ Kátólíìkì nípa bí àwọn àpọ́sítélì ṣe tò tẹ̀ léra ni ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ fún ọ̀pọ̀ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ohun ni wọ́n fi lè pinnu yálà àwọn ẹ̀kọ́ Kátólíìkì tó kù tọ̀nà tàbí wọn kò tọ̀nà!

Nígbà tí mo dé ọ̀dọ̀ àlùfáà, kò lè dáhùn àwọn ìbéèrè mi. Ńṣe ló fa ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípá ẹ̀kọ́ Kátólíìkì nípa bí àwọn àpọ́sítélì ṣe tò tẹ̀ léra yọ níbi ìkówèésí rẹ̀. Ó ní kí n mú un lọ sílé. Nígbà tí mo délé, mo kà á, àmọ́ ńṣe ni ìbéèrè tí mo ní tún wá pọ̀ sí i. Nígbà tí àlùfáà náà wá rí i pé òun ò lè dáhùn àwọn ìbéèrè mi, ó sọ pé: “Mi ò lè yí ẹ lérò pa dà, ìwọ náà ò sì lè yí mi lérò pa dà. . . . Ọlọ́run á ràn ẹ́ lọ́wọ́!” Kò sì fẹ́ ní ìjíròrò kankan pẹ̀lú mi mọ́.

Ìgbà yẹn gan-an ni mo pinnu pé màá jẹ́ kí Ilse àti Elfriede kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n kọ́ mi ní ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Baba Mímọ́ tòótọ́ tó wà ní ọ̀run, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run. (Jòh 17:11) Nígbà yẹn kò tíì sí ìjọ kankan ní àgbègbè yẹn, torí náà ilé àwọn olùfìfẹ́hàn kan ni àwọn arábìnrin méjì yẹn ti máa ń ṣe ìpàdé, àwọn ló sì ń darí ìpàdé náà. Ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló máa ń wá. Torí pé kò sí ọkùnrin kankan tó ti ṣèrìbọmi tó lè mú ipò iwájú, ńṣe ni àwọn arábìnrin méjèèjì máa ń gbé ọ̀pọ̀ ohun tó yẹ ká kọ́ ní ìpàdé náà kalẹ̀ lọ́nà ìjíròrò láàárín ara wọn. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, arákùnrin kan máa ń ti ibòmíì wá sọ àsọyé fún wa ní ibì kan tí a háyà.

MO BẸ̀RẸ̀ SÍ Í WÀÁSÙ

Arábìnrin Ilse àti Elfriede bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní oṣù October ọdún 1958, mo sì ṣèrìbọmi ní oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà ní oṣù January ọdún 1959. Kí n tó ṣèrìbọmi, mo bi àwọn arábìnrin yẹn pé ṣé mo lè bá wọn lọ sóde ẹ̀rí kí n lè rí bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù. (Ìṣe 20:20) Lẹ́yìn tí mo ti bá wọn lọ sóde ẹ̀rí fún ìgbà àkọ́kọ́, mo bi wọ́n bóyá wọ́n lè fún mi ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tèmi. Wọ́n sì yan abúlé kan fún mi. Mo máa ń dá lọ sí abúlé náà, màá wàásù láti ilé dé ilé, màá sì tún lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn. Alábòójútó àyíká kan tó wá bẹ̀ wá wò lẹ́yìn ìgbà yẹn ni arákùnrin tí mo kọ́kọ́ bá jáde òde ẹ̀rí.

Nígbà tí mo parí ẹ̀kọ́ tí mò ń kọ́ nípa àbójútó òtẹ́ẹ̀lì lọ́dún 1960, mo pa dà sí ìlú wa, kí n lè ran àwọn èèyàn mi lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ títí di bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí kò tíì sí ìkankan nínú wọn tó wá sin Jèhófà, ṣùgbọ́n a rí lára wọn tó máa ń tẹ́tí sílẹ̀ nígbà míì.

MO BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ ÌSÌN ALÁKÒÓKÒ KÍKÚN

Ìgbà tí Gerrit Lösch wà lọ́mọdé rèé

Ní ọdún 1961 wọ́n ka lẹ́tà kan tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti fi gba àwọn ìjọ níyànjú pé kí wọ́n gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Mi ò tíì níyàwó, mo sì ní ìlera tó dáa, torí náà mo rí i pé kò sí ohun tó ń dí mi lọ́wọ́ láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Mo bá alábòójútó àyíká wa tó ń jẹ́ Kurt Kuhn sọ̀rọ̀. Mo sọ fún un pé mo fẹ́ fi oṣù mélòó kan ṣiṣẹ́ kí n lè rówó ra ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ kan táá wúlò fún mi lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Mo ni: “Àbí kí lẹ ti rí i sí? Ó wá bi mí pé: “Ǹjẹ́ Jésù àti àwọn àpọ́sítélì nílò ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kí wọ́n tó lè ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún?” Ọ̀rọ̀ náà yé mi kọjá ibi tó sọ ọ́ dé. Láìjáfara mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò bí mo ṣe máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Àmọ́, torí pé wákàtí méjìlá [12] ni  mo fi ń ṣiṣẹ́ lóòjọ́ fún ọjọ́ mẹ́fà lọ́sẹ̀ ní òtẹ́ẹ̀lì tí mo ti ń ṣiṣẹ́, mo rí i pé ó yẹ kí n kọ́kọ́ ṣe àwọn ìyípadà kan.

Mo bi ọ̀gá mi bóyá ó lè jẹ́ kí n máa ṣiṣẹ́ wákàtí mẹ́wàá lóòjọ́ fún ọjọ́ mẹ́fà lọ́sẹ̀. Ó gbà, kò sì dín owó tó ń sàn fún mi kù. Nígbà tó tún ṣe díẹ̀ mo bẹ́ẹ̀ bóyá ó lè jẹ́ kí n máa ṣiṣẹ́ wákàtí mẹ́jọ lóòjọ́ fún ọjọ́ mẹ́fà. Ó gbà, kò sì tún dín owó tó ń san fún mi kù. Nígbà tó tún yá, mo lọ bá a pé kó jẹ́ kí n máa ṣiṣẹ́ fún wákàtí mẹ́fà lóòjọ́ fún ọjọ́ mẹ́fà lọ́sẹ̀. Ọ̀gá mi tún gbà. Àmọ́ ohun tó yà mí lẹ́nu ni pé kò dín kọ́bọ̀ kù nínú owó oṣù mi! Ó jọ pé ńṣe ni ọ̀gá mi ò fẹ́ kí n kúrò níbi iṣẹ́ náà. Nígbà tí àkókò tí mo fi ń ṣiṣẹ́ ti wá dín kù báyìí, ó ṣeé ṣe fún mi láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Nígbà yẹn, ọgọ́rùn-ún [100] wákàtí ni wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé.

Lẹ́yìn oṣù mẹ́rin tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àti ìránṣẹ́ ìjọ nínú ìjọ kékeré kan tó wà ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Carinthia, nílùú Spittal an der Drau. Nígbà yẹn, àádọ́jọ [150] wákàtí ni wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lóṣù. Èmi nìkan ni aṣáájú-ọ̀nà tó wà níbẹ̀, àmọ́ mo mọrírì bí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Gertrude Lobner tó ń sìn gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ ìránṣẹ́ ìjọ ṣe ń tì mí lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. *

BÍ ÀYÍPADÀ KAN ṢE Ń DÉ LÒMÍÌ Ń DÉ

Ní ọdún 1963, wọ́n ní kí n máa sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká. Láwọn ìgbà míì mo máa ń wọ ọkọ̀ ojú irin tí mo bá ń lọ sí àwọn ìjọ, mo sì máa ń gbé àwọn àpótí tó wúwo. Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ará ni kò ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, torí náà kò sí ẹni táá wá gbé mi ní ibùdókọ̀. Kó má bàa dà bíi pé mò ń ṣe “ṣekárími,” mi kì í gbé takisí lọ sáwọn ibi tí mo bá máa dé sí, ńṣe ni mo máa ń fẹsẹ̀ rìn lọ síbẹ̀.

Lọ́dún 1965, wọ́n pè mí sí kíláàsì kọkànlélógójì [41] ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Mi ò tíì níyàwó nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn tá jọ wà ní kíláàsì náà ni kò sì tíì ṣègbéyàwó. Lọ́jọ́ tá a kẹ́kọ̀ọ́ yege, ó yà mí lẹ́nu pé ìlú mi ní Austria ni wọ́n rán mi pa dà sí pé kí n máa bá iṣẹ́ alábòójútó àyíká nìṣó níbẹ̀. Àmọ́ kí n tó kúrò ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tá a ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ yẹn, wọ́n ní kí n bá alábòójútó àyíká kan lọ sí àwọn ìjọ tó máa bẹ̀ wò láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́rin. Inú mi dùn pé mo láǹfààní láti bá Arákùnrin Anthony Conte ṣiṣẹ́ torí ó nífẹ̀ẹ́ èèyàn, ó fẹ́ràn iṣẹ́ ìwàásù gan-an, ó sì jáfáfá lẹ́nu rẹ̀. A jọ sìn ní àríwá New York ní àgbègbè Cornwall.

Ọjọ́ tá a ṣègbéyàwó

Nígbà tí mo pa dà dé Austria, wọ́n rán mi lọ sí àyíká kan, ibẹ̀ ni mo ti pàdé Tove Merete, arábìnrin kan tó rẹwà gan-an, kò sì tíì lọ́kọ. Látìgbà tó ti wà ní ọmọ ọdún márùn-ún ni àwọn òbí rẹ̀ ti ń kọ ọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tí àwọn ará bá bi wá pé báwo la ṣe pàdé ara wa, a máa ń dápàárá pé, “Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló rán mi lọ síbi tó wà.” Oṣù April ọdún 1967 la ṣègbéyàwó, ìyẹn ọdún kan lẹ́yìn tá a pàdé. Wọ́n sì ní ká jọ máa bá iṣẹ́ arìnrìn-àjò nìṣó.

Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, mo wá mọ̀ pé Jèhófà gbà mi ṣe ọmọ rẹ̀ tí a fi ẹ̀mí bí látàrí inú rere onífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àtìgbà yẹn ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí i ní àjọṣe tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Baba mi ọ̀run pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tó ń “ké jáde pé: ‘Ábà, Baba!’” bó ṣe wà nínú Róòmù 8:15.

Èmi àti ìyàwó mi wà lẹ́nu iṣẹ́ àyíká àti àgbègbè títí di ọdún 1976. Nígbà míì ní àsìkò òtútù, àwọn yàrá tí kò ní ohun tó ń múlé móoru tó sì tutù nini la máa ń sùn. Nígbà tá a jí ní ọjọ́ kan, a rí i pé èémí wa ti mú  kí apá òkè bùláńkẹ́ẹ̀tì tá a fi bora gan paali ó sì ti funfun! La bá pinnu láti máa gbé ẹ̀rọ amúlémóoru kékeré dání kí òtútù tó ń mú wa má bàa máa pọ̀ jù. Láwọn ibòmíì, tá a bá fẹ́ lọ sílé ìwẹ̀ lálẹ́, ńṣe là máa ń rìn gba inú yìnyín kọjá lọ sínú balùwẹ̀ tí wọ́n kọ́ sí ẹ̀yìnkùlé, èyí tí afẹ́fẹ́ tútù sábà máa ń fẹ́ yẹ́ẹ́ gba inú rẹ̀ kọjá. Torí pé a kò ní ilé tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún wa ní àyíká yẹn, tó bá di ọjọ́ Monday ńṣe la máa ń dúró síbi tá a ti ṣèbẹ̀wò lọ́sẹ̀ yẹn. Tó bá wá di àárọ̀ Tuesday a máa lọ sí ìjọ míì tá a fẹ́ bẹ̀ wò.

Mo láyọ̀ láti sọ pé láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, aya mi ọ̀wọ́n ti jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún mi. Ó dìídì fẹ́ràn iṣẹ́ ìwàásù gan-an ni, mi ò sì fìgbà kan rọ̀ ọ́ rí kó tó di pé ó jáde òde ẹ̀rí. Ó tún nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn sì máa ń jẹ ẹ́ lógún. Ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà lèyí jẹ́ fún mi.

Ní ọdún 1976 wọ́n ní ká wá máa sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Austria tó wà ní Vienna, wọ́n sì yàn mí gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. Nígbà yẹn, ẹ̀ka ọ́fíìsì Austria ló ń bojú tó iṣẹ́ náà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tó wà ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù, ó sì ń rí sí bá a ṣe ń fi ọgbọ́n kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wọ àwọn orílẹ̀-èdè yẹn. Arákùnrin Jürgen Rundel ló ń mú ipò iwájú nínú bá a ṣe ń kó ìwé ránṣẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì máa ń lo ìdánúṣe. Mo láǹfààní láti bá a ṣiṣẹ́. Nígbà tó sì yá, wọ́n ní kí n máa ṣe kòkáárí iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè sí mẹ́wàá lára èdè tí wọ́n ń sọ ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù. Arákùnrin Jürgen àti ìyàwó rẹ̀ Gertrude ṣì ń bá a nìṣó gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní orílẹ̀-èdè Jámánì. Láti ọdún 1978, ẹ̀ka ọ́fíìsì Austria bẹ̀rẹ̀ sí í fi ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà to àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé ìròyìn, wọ́n á sì wá fi ẹ̀rọ ìtẹ̀wé alátẹ̀yípo kékeré tẹ̀ ẹ́ jáde ní èdè mẹ́fà. A tún máa ń fi àwọn ìwé ìròyìn tí wọ́n san àsansílẹ̀ owó fún ránṣẹ́ sí onírúurú orílẹ̀-èdè tó bá béèrè fún un. Arákùnrin Otto Kuglitsch ló bójú tó àwọn iṣẹ́ yẹn, àmọ́ báyìí òun àti ìyàwó rẹ̀ Ingrid ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Jámánì.

Ní orílẹ̀-èdè Austria, mo gbádùn onírúurú ọ̀nà tá à ń gbà wàásù, títí kan ìwàásù ní òpópónà

Àwọn arákùnrin tó wà ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù tún máa ń tẹ ìwé nípa lílo ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń ṣe àdàkọ ìwé tàbí kí wọ́n tẹ̀ ẹ́ látinú èyí tí wọ́n ti gbé sorí àwo CD. Síbẹ̀ wọ́n ṣì nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn míì tí kì í ṣe ọmọ orílẹ̀-èdè wọn. Jèhófà jẹ́ kí iṣẹ́ yìí kẹ́sẹ járí. Àwa tá a wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì sì mọyì àwọn ará wa wọ̀nyí tó jẹ́ pé fún ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n fi sìn lábẹ́ ipò tí kò bára dé àti lábẹ́ ìfòfindè.

A ṢE ÀKÀNṢE ÌBẸ̀WÒ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ ROMANIA

Ní ọdún 1989, mo láǹfààní láti tẹ̀ lé Arákùnrin Theodore Jaracz tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí  lọ sí orílẹ̀-èdè Romania. Ìdí tó fi lọ ni pé kó lè ṣèràwọ́ fún ọ̀pọ̀ àwùjọ àwọn ará tí kò bá ètò Ọlọ́run ṣe mọ́ kí wọ́n lè pa dà wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ètò Ọlọ́run. Láti ọdún 1949 ni àwùjọ àwọn ará yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í yan ètò Ọlọ́run lódì. Onírúurú nǹkan ni wọ́n gbà pó fà á tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀, kálukú wọn sì dá ìjọ tara ẹ̀ sílẹ̀. Síbẹ̀, wọ́n ń wàásù, wọ́n sì ń ṣèrìbọmi fáwọn èèyàn. Bí wọ́n ṣe ń fi àwọn ará tó fara mọ́ ètò Ọlọ́run sẹ́wọ̀n náà ni wọ́n ń fi àwùjọ tí kò bá ètò Ọlọ́run ṣe mọ́ yìí náà sẹ́wọ̀n nítorí àìdá sí ọ̀ràn ìṣèlú. Torí pé wọ́n ṣì fòfin de iṣẹ́ wa ní Romania nígbà tá a lọ yẹn, ilé Arákùnrin Pamfil Albu ni a ti ṣèpàdé kan ní bòńkẹ́lẹ́ pẹ̀lú àwọn alàgbà mẹ́rin tí wọ́n jẹ́ abẹnugan àti aṣojú àwọn Ìgbìmọ̀ Orílẹ̀-èdè Romania tí ètò Ọlọ́run yàn sípò. A sì mú Arákùnrin Rolf Kellner dání pẹ̀lú wa láti Austria, òun ló ṣe ògbufọ̀.

Ní alẹ́ ọjọ́ kejì tá a ti wà lẹ́nu ìjíròrò náà, Arákùnrin Albu rọ àwọn alàgbà mẹ́rin yòókù bíi tiẹ̀ pé kí wọ́n pa dà wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wa, ó ní, “Tí a ò bá ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí, a lè má láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ láé.” Látàrí èyí, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún-un márùn-ún [5,000] àwọn arákùnrin wa ni wọ́n pa dà dara pọ̀ mọ́ ètò Ọlọ́run. Ọpẹ́ ńlá ni pé Jèhófà mókè, Sátánì sì pòfo!

Nígbà tí ọdún 1989 ń parí lọ, kó tó di pé ìjọba Kọ́múníìsì kógbá sílé ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù, Ìgbìmọ̀ Olùdarí pe èmi àti ìyàwó mi pé ká wá máa ṣiṣẹ́ ní oríléeṣẹ́ wa ní New York. Èyí yà wá lẹ́nu gan-an ni! A sì bẹ̀rẹ̀ sí í sìn ní Bẹ́tẹ́lì ti Brooklyn ní July 1990. Nígbà tó wá di ọdún 1992, wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Àmọ́ láti oṣù July ọdún 1994 ni mo ti ní àǹfààní láti máa sìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí.

MO RONÚ SÍWÁ-SẸ́YÌN

Èmi àti ìyàwó mi ní Brooklyn, New York

Ọjọ́ pẹ́ tí mo ti fi iṣẹ́ ká máa gbé oúnjẹ fúnni ní òtẹ́ẹ̀lì sílẹ̀. Ní báyìí mò ń gbádùn àǹfààní tí mo ní láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó sì ń pín in fún ẹgbẹ́ ará kárí ayé. (Mát. 24:45-47) Tí mo bá ro ohun tó lé ní àádọ́ta ọdún tí mo ti lò lẹ́nu àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, ńṣe ni ọkàn mi máa ń kún fún ìmọrírì àti ayọ̀ tó jinlẹ̀ bí Jèhófà ṣe bù kún ẹgbẹ́ ará wa tó kárí ayé. Mo máa ń fẹ́ láti lọ sí àwọn àpéjọ àgbáyé torí pé wọ́n máa ń tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa Baba wa ọ̀run Jèhófà àtàwọn òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì.

Àdúrà mi ni pé kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn wá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n wá sínú òtítọ́, kí wọ́n sì máa sin Jèhófà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn ará wa kárí ayé. (1 Pét. 2:17) Mo sì ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí màá wà lọ́run tí màá máa wo àwọn tí wọ́n jíǹde sórí ilẹ̀ ayé, tí màá sì láǹfààní láti rí bàbá tó bi mi lọ́mọ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Mo nírètí pé bàbá mi àti ìyá mi àtàwọn ìbátan mi ọ̀wọ́n yòókù á fẹ́ sin Jèhófà ní Párádísè.

Mò ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí màá wà lọ́run tí màá máa wo àwọn tí wọ́n jíǹde sórí ilẹ̀ ayé, tí màá sì láǹfààní láti rí bàbá tó bi mi lọ́mọ nígbẹ̀yìngbẹ́yín

^ ìpínrọ̀ 15 Ka ìtàn ìgbésí ayé wọn nínú Ile-Iṣọ Naa May 1, 1980 ojú ìwé 8.

^ ìpínrọ̀ 27 Ní báyìí, dípò ìránṣẹ́ ìjọ àti olùrànlọ́wọ́ ìránṣẹ́ ìjọ, ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà kọ̀ọ̀kan máa ń ní olùṣekòkárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà àti akọ̀wé.