Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Gbọ́ Ohùn Jèhófà Níbikíbi Tó O Bá Wà

Máa Gbọ́ Ohùn Jèhófà Níbikíbi Tó O Bá Wà

“Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé: ‘Èyí ni ọ̀nà.’”—AÍSÁ. 30:21.

1, 2. Báwo ni Jèhófà ṣe ń bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀?

JÁLẸ̀ ìtàn Bíbélì, onírúurú ọ̀nà làwọn èèyàn fi ń gba ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ Jèhófà. Ọlọ́run lo àwọn áńgẹ́lì láti bá àwọn kan sọ̀rọ̀, ó lo ìran tàbí àlá fáwọn míì, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Jèhófà tún fún wọn láwọn iṣẹ́ kan pàtó tí wọ́n máa ṣe. (Núm. 7:89; Ìsík. 1:1; Dán. 2:19) Àwọn èèyàn tó jẹ́ aṣojú Jèhófà tí wọ́n ń sìn ní apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Ọlọ́run ló ń fún àwọn tó kù ní ìtọ́ni. Ọ̀nà yòówù kí ọ̀rọ̀ Jèhófà gbà dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀, nǹkan lọ dáadáa fáwọn tó tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀.

2 Lóde òní, Jèhófà ń lo Bíbélì, ẹ̀mí mímọ́ àti ìjọ rẹ̀ láti fi tọ́ àwa èèyàn rẹ̀ sọ́nà. (Ìṣe 9:31; 15:28; 2 Tím. 3:16, 17) Ìtọ́sọ́nà tá à ń gbà látọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣe kedere sí wa débi pé ṣe ló dà bíi pé ‘etí wa ń gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn wa tó ń sọ pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.”’ (Aísá. 30:21) Jésù tún ń jẹ́ ká gbọ́ ohùn Jèhófà bó ṣe ń lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti fún ìjọ ní ìtọ́ni. (Mát. 24:45) A gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ìtọ́ni àti ìtọ́sọ́nà yìí torí tá a bá fẹ́ ní ìyè àìnípẹ̀kun, àfi ká jẹ́ onígbọràn.—Héb. 5:9.

3. Kí ló lè fa ìdíwọ́ fún wa bá a ṣe ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà? (Wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

3 Gbogbo ọ̀nà ni Sátánì Èṣù ń wá kó lè mú ká má ṣe fọkàn sí ìtọ́ni tó ń gbẹ̀mí là tá à ń gbà lọ́dọ̀ Jèhófà. Bákan náà, ‘ọkàn’ wa ṣe ‘àdàkàdekè’ gan-an, ó sì lè mú kó ṣòro fún wa láti máa  tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà bó ṣe yẹ. (Jer. 17:9) Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò bá a ṣe lè borí àwọn ohun ìdènà tó lè mú kó ṣòro fún wa láti gbọ́ ohùn Ọlọ́run. A tún máa sọ̀rọ̀ lórí bí bíbá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ déédéé ò ṣe ní jẹ́ kí mìmì kan mi àjọṣe àwa àti Ọlọ́run láìka ipò èyíkéyìí tá a lè wà sí.

BÁ A ṢE LÈ BORÍ ÀWỌN ÈTEKÉTE SÁTÁNÌ

4. Báwo ni Sátánì ṣe ń sapá kó lè mú káwọn èèyàn máa ronú lọ́nà tí kò tọ́?

4 Sátánì ń sapá láti lo ìtàn èké àti ẹ̀tàn kó lè mú káwọn èèyàn máa ronú lọ́nà tí kò tọ́. (Ka 1 Jòhánù 5:19.) Ibi gbogbo láyé títí kan àwọn abúlé oko ni irọ́ Sátánì ń tàn dé, nípasẹ̀ ìwé, rédíò, tẹlifíṣọ̀n àti Íńtánẹ́ẹ̀tì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun tó gbádùn mọ́ni lè wà nínú ohun táwọn èèyàn ń gbọ́ tàbí tí wọ́n ń kà, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà ṣe ni wọ́n ń gbé ìlànà àti ìwà tó yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ìlànà Jèhófà lárugẹ. (Jer. 2:13) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ohun tí wọ́n ń gbé jáde nínú ìròyìn, tẹlifíṣọ̀n, eré orí ìtàgé, orin àtàwọn eré ìnàjú ń jẹ́ kó dà bíi pé kò sóhun tó burú nínú kí ọkùnrin àti ọkùnrin máa fẹ́ ara wọn tàbí kí obìnrin àti obìnrin máa fẹ́ ara wọn. Ọ̀pọ̀ ló sì rò pé ohun tí Bíbélì sọ pé ọkùnrin kò gbọ́dọ̀ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin tàbí kí obìnrin ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin ti lè ju.—1 Kọ́r. 6:9, 10.

5. Báwo la ṣe lè kíyè sára kí ẹ̀tàn Sátánì má bàa ṣàkóbá fún wa?

5 Báwo ni àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òdodo Ọlọ́run ṣe lè kíyè sára kí ẹ̀tàn tí Sátánì ń gbé kiri lónìí máa bàa ṣàkóbá fún wọn? Báwo ni wọ́n ṣe lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́? Bíbélì sọ pé: “Nípa ṣíṣọ́ra ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ [Ọlọ́run]”! (Sm. 119:9) Àwọn ìtọ́sọ́nà tó ṣe pàtàkì wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti fi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn ohun tó jẹ́ òótọ́ àti èké tí Sátánì ń tàn kálẹ̀. (Òwe 23:23) Ìgbà kan wà tí Jésù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́, ó sọ pé, “ènìyàn . . . yóò wà láàyè . . . nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mát. 4:4) A gbọ́dọ̀ kọ́ bá a ṣe ń fi ìlànà Bíbélì sílò nígbèésí ayé wa. Bí àpẹẹrẹ, tipẹ́tipẹ́ kí Mósè tó ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú òfin pé Jèhófà dẹ́bi fún àgbèrè ni Jósẹ́fù tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin nígbà yẹn ti lóye pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ sí Ọlọ́run. Nígbà tí ìyàwó Pọ́tífárì gbìyànjú láti mú kó ṣe ohun tí kò dára, kò gbà kí obìnrin yẹn mú kó rú òfin Jèhófà. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 39:7-9.) Láìka bí ìyàwó Pọ́tífárì ṣe dààmú Jósẹ́fù fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ sí, kò jẹ́ kí ohùn obìnrin náà borí rẹ̀ débi tí kò fi ní gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Ohun pàtàkì kan táá jẹ́ ká lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ ni pé ká máa tẹ́tí sí ohùn Jèhófà, ká sì máa di etí wa sí ariwo ẹ̀tàn tí Sátánì ń mú kó máa dún kíkankíkan àti léraléra.

6, 7. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe táá jẹ́ ká yẹra fún ìmọ̀ràn burúkú Sátánì?

6 Àwọn àṣà àti ẹ̀kọ́ èké tó ń ta kora ti pọ̀ láyé débi pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wò ó pé bí ẹni fàkókò ṣòfò ni téèyàn bá lóun ń wá ìsìn tòótọ́. Àmọ́ o, Jèhófà mú kí ìtọ́sọ́nà rẹ̀ tó ṣe kedere pọ̀ yanturu fún gbogbo ẹni tó  bá fẹ́ tẹ̀ lé e. A gbọ́dọ̀ pinnu ẹni tá a máa gbọ́ tirẹ̀. Níwọ̀n bí kò ti ṣeé ṣe láti máa gbọ́ ohùn méjì pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà, a ní láti “mọ ohùn” Jésù, ká sì tẹ́tí sí i. Jésù ni Jèhófà yàn pé kó máa bójú tó àwọn àgùntàn Òun.—Ka Jòhánù 10:3-5.

7 Jésù sọ pé: “Ẹ fiyè sí ohun tí ẹ ń gbọ́.” (Máàkù 4:24) Ìtọ́ni Jèhófà tọ́, ó sì ṣe kedere. Àmọ́ a gbọ́dọ̀ fọkàn sí i, ká sì tẹ́tí sí i nípa mímúra ọkàn wa sílẹ̀ láti gba àwọn ìtọ́ni rẹ̀. Tá ò bá kíyè sára, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́tí sí ìmọ̀ràn burúkú Sátánì dípò ká tẹ̀ lé ìtọ́ni onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run ń fún wa. Má ṣe gbà láé kí orin ayé, fídíò, tẹlifíṣọ̀n, àwọn ìwé, àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ayé tàbí àwọn tó pera wọn ní ògbógi máa darí ìgbésí ayé rẹ.—Kól. 2:8.

8. (a) Báwo ni ọkàn wa ṣe lè tàn wá débi tá a fi máa kó sọ́wọ́ àwọn ètekéte Sátánì? (b) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí wa tá ò bá kọbi ara sí ìkìlọ̀?

8 Sátánì náà mọ̀ pé àìpé lè mú ká ṣe ohun tí kò tọ́, ó sì máa ń fẹ́ mú ká máa fìyẹn kẹ́wọ́. Tí Sátánì bá fẹ́ ti ibi àìpé mú wa, ó máa ń nira gan-an fún wa láti pa ìwà títọ́ wa mọ́. (Jòh. 8:44-47) Àmọ́, báwo la ṣe lè borí ìṣòro náà? Ẹ wo àpẹẹrẹ ẹnì kan tí kò kíyè sára, tó lọ tara bọ adùn ayé yìí, ó lè ṣe ohun tí kò tọ́ tó ti rò tẹ́lẹ̀ pé òun kò lè ṣe láéláé. (Róòmù 7:15) Kí ló mú kí ó kó sínú wàhálà ńlá yìí? Ó ṣeé ṣe kí onítọ̀hún ti máa kọ etí dídi sí ohùn Jèhófà díẹ̀díẹ̀. Ó sì lè jẹ́ pé ṣe ni kò fiyè sí àwọn ìkìlọ̀ tó ń rí tó fi hàn pé nǹkan kan ti ń ṣẹlẹ̀ sí ọkàn rẹ̀ tàbí kó jẹ́ pé òun ló mọ̀ọ́mọ̀ má kọbi ara sáwọn ìkìlọ̀ yẹn. Bí àpẹẹrẹ, ó lè má gbàdúrà mọ́, kó má fọwọ́ pàtàkì mú iẹ́ ìwàásù mọ́ tàbí kó bẹ̀rẹ̀ sí í pa ìpàdé jẹ. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó gbà kí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ mú kó ṣe ohun tí òun fúnra rẹ̀ mọ̀ pé kò tọ́. A lè yẹra fún irú àṣìṣe tó burú jáì bẹ́ẹ̀ tá a bá ń wà lójúfò, tá à ń rí àwọn àmì tó ń kì wá nílọ̀, tá a sì ń gbé ìgbésẹ̀ ní kíámọ́sá láti wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ náà. Tá a bá sì ń tẹ́tí sí ohùn Jèhófà, ìyẹn ò ní jẹ́ ká fàyè gba èrò àwọn apẹ̀yìndà rárá.—Òwe 11:9.

9. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká tètè mọ àwọn ohun tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀?

9 Tí ẹnì kan bá tètè mọ̀ pé àìsàn kan ń ṣe òun, á tètè lọ tọ́jú ara rẹ̀, ìyẹn sì lè jẹ́ kó bọ́ lọ́wọ́ ohun tó lè ṣekú pà á. Lọ́nà kan náà, a lè dènà ohun tó lè kó wa sí wàhálà tá a bá tètè mọ àwọn ohun tó lè fà wá sínú ìdẹwò. Ojú ẹsẹ̀ ló bọ́gbọ́n mu ká gbé ìgbésẹ̀ ní gbàrà tá a bá ti rí àwọn ohun tó ń gbà wá lọ́kàn yẹn, kó tó di pé Sátánì ‘mú wa láàyè fún ìfẹ́ rẹ̀.’ (2 Tím. 2:26) Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá kíyè sí i pé a ti jẹ́ kí èrò àti ìfẹ́ ọkàn wa máa sú lọ kúrò nínú ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe? A ò ní fi àkókò falẹ̀ rárá, ṣe la gbọ́dọ̀ pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀, ká  la etí wá sí ìmọ̀ràn rẹ̀, ká sì fọkàn sí gbogbo ohun tó bá ń sọ́. (Aísá. 44:22) A gbọ́dọ̀ mọ̀ pé tá a bá ṣe ìpinnu tí kò tọ́, ó lè dá àpá tó lágbára sí ìgbésí ayé wa débi pé a lè jìyà àbájáde búburú ohun tí a ṣe yẹn nínú ayé ìsinsìnyí. Ẹ ò rí i pé ó kúkú sàn ká ṣe ohun tí kò ní jẹ́ ká sú lọ, ká gbé ìgbésẹ̀ ní kíámọ́sá ká lè dènà irú àṣìṣe ńlá yìí!

Báwo ni àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí tá à ń ṣe déédéé ṣe lè dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ètekéte Sátánì? (Wo ìpínrọ̀ 4 sí 9)

BÁ A ṢE LÈ BORÍ ÌGBÉRAGA ÀTI OJÚKÒKÒRÒ

10, 11. (a) Báwo ló ṣe máa ń hàn lára ẹnì kan pé ó ń gbéra ga? (b) Ẹ̀kọ́ wo ni ìwà ọ̀tẹ̀ tí Kórà, Dátánì àti Ábírámù hù kọ́ wa?

10 A gbọ́dọ̀ gbà pé ọkàn wa lè ṣì wá lọ́nà. Ẹ ò rí i pé ipa tí àìpé ń ní lórí wa kò kéré! Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí ìgbéraga àti ojúkòkòrò. Ẹ jẹ́ ká wo bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwà yìí ṣe lè mú ká má ṣe gbọ́ ohùn Jèhófà ketekete mọ́, tó sì lè mú ká ṣe ohun tí kò tọ́. Agbéraga èèyàn máa ń ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Ó lè máa wo ara rẹ̀ pé òun lè ṣe ohunkóhun tó bá wu òun àti pé ẹnikẹ́ni ò lè sọ ohun tóun máa ṣe fóun. Torí náà, ó lè máa wò ó pé òun ti kọjá ẹni tí àwọn alàgbà, àwọn táwọn jọ jẹ́ Kristẹni tàbí ẹni tí ètò Ọlọ́run pàápàá á máa fún ní ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà. Irú ẹni yìí ò ní fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ ohùn Jèhófà dáadáa mọ́.

11 Nígbà ìrìn-àjò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní aginjù, Kórà, Dátánì àti Ábírámù ṣọ̀tẹ̀ sí Mósè àti Áárónì. Torí ìgbéraga tó ti wọ àwọn ọlọ̀tẹ̀ yìí lẹ́wù, wọ́n ṣètò láyè ara wọn bí wọ́n á ṣe jọ́sìn Jèhófà. Kí ni Jèhófà wá ṣe? Ṣe ló pa wọ́n dànù. (Núm. 26:8-10) Ẹ̀kọ́ ńlá mà ni ìtàn yìí kọ́ wa o! Àjálù ló máa ń já sí fún ẹni tó bá ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká tún rántí pé, “ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá.”—Òwe 16:18; Aísá. 13:11.

12, 13. (a) Sọ àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká mọ bí ojúkòkòrò ṣe lè yọrí sí àjálù. (b) Ṣàlàyé bí ojúkòkòrò ṣe lè yára di nǹkan ńlá mọ́ èèyàn lọ́wọ́ téèyàn ò bá kápá rẹ̀.

12 Ẹ jẹ́ ká tún sọ̀rọ̀ lórí ojúkòkòrò. Olójúkòkòrò èèyàn sábà máa ń kù gìrì ṣe nǹkan tí kò yẹ kó ṣe, ó sì máa ń ṣe àṣejù. Lẹ́yìn tí wòlíì Èlíṣà wo Náámánì, olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Síríà sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀, ó kó ẹ̀bùn wá fún Èlíṣà, àmọ́ wòlíì yìí kò gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Àwọn ẹ̀bùn náà wọ Géhásì, ìránṣẹ́ Èlíṣà lójú. Géhásì sọ fún ara rẹ̀ pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ, . . . èmi yóò sáré tẹ̀ lé [Náámánì], èmi yóò sì gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀.” Géhásì ò jẹ́ kí Èlíṣà mọ̀ tó fi sáré tẹ̀ lé Náámánì, tó sì gbé irọ́ ńlá kalẹ̀ fún un kó lè gba “tálẹ́ńtì fàdákà kan àti ìpààrọ̀ ẹ̀wù méjì.” Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Géhásì torí ohun tó ṣe yìí tó sì parọ́ fún wòlíì Jèhófà? Ńṣe ni ẹ̀tẹ̀ tó wà lára Náámánì tẹ́lẹ̀ pa dà sára Géhásì torí pé ó ya olójúkòkòrò!—2 Ọba. 5:20-27.

13 Ojúkòkòrò lè bẹ̀rẹ̀ látorí nǹkan tí kò tó nǹkan, àmọ́ téèyàn ò bá kápá rẹ̀, ó lè yára di nǹkan ńlá tó lè ṣàkóbá fún onítọ̀hún. Ìtàn Ákánì nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ ọṣẹ́ tí ojúkòkòrò lè ṣe féèyàn. Ẹ kíyè sí i bí ojúkòkòrò ṣe yára wọ Ákánì lẹ́wù. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo ẹ̀wù oyè kan láti Ṣínárì láàárín àwọn ohun ìfiṣèjẹ, ọ̀kan tí ìrísí rẹ̀ dára, àti igba ṣékélì fàdákà àti wúrà gbọọrọ kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta ṣékélì, nígbà náà ni mo fẹ́ ní wọn, mo sì wọn.” Dípò tí Ákánì á fi gbé èròkerò yẹn kúrò lọ́kàn, ṣe ni ojúkòkòrò mú kó jí àwọn nǹkan iyebíye wọ̀nyẹn, ó sì fi wọ́n pa mọ́ sínú àgọ́ rẹ̀. Nígbà tí àṣírí Ákánì tú, Jóṣúà sọ fún un pé Jèhófà máa fa àjálù wá sórí rẹ̀. Ọjọ́ yẹn gan-an ni wọ́n sọ Ákánì àti ìdílé rẹ̀ lókùúta pa. (Jóṣ. 7:11, 21, 24, 25) Gbogbo ìgbà ni ojúkòkòrò jẹ́ ewu tó lè ṣàkóbá fún wa. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká “ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò.” (Lúùkù 12:15) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan èrò ìṣekúṣe tàbí èròkerò míì lè wá sí wa lọ́kàn, àmọ́ ó ṣe pàtàkì pé ká tètè wá nǹkan ṣe sí i, ká má sì jẹ́ kí èròkerò wọ̀nyẹn gbilẹ̀ lọ́kàn wa débi tí a fi máa dẹ́ṣẹ̀.—Ka Jákọ́bù 1:14, 15.

14. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá kíyè sí i pé ìgbéraga àti ojúkòkòrò ti ń hàn díẹ̀díẹ̀ nínú ìwà wa?

 14 Ìgbéraga àti ojúkòkòrò lè fa àjálù bá èèyàn. Tá a bá ń ronú lórí àbájáde ìwà ẹ̀ṣẹ̀, a ò ní jẹ́ kí ó kó bá wa débi tí a kò ní fi ọkàn sí ohùn Jèhófà mọ́. (Diu. 32:29) Yàtọ̀ sí pé Ọlọ́run sọ ohun tó yẹ ká máa ṣe fún wa nínú Bíbélì, ó tún ṣàlàyé fún wa àǹfààní tó wà níbẹ̀ àti ohun tó máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ téèyàn bá ṣe ohun tí kò tọ́. Ìgbéraga àti ojúkòkòrò lè mú kí ọkàn wa bẹ̀rẹ̀ sí í ro ohun kan tí kò tọ́, ó bọ́gbọ́n mu ká ro àbájáde rẹ̀ ká tó ṣe é. Ó yẹ ká ro ipa tí ìwà àìtọ́ lè ní lórí wa, àwọn èèyàn wa àti pàápàá jù lọ ipa tó máa ní lórí àjọṣe àwa àti Jèhófà.

MÁA BÁ JÈHÓFÀ SỌ̀RỌ̀ DÉÉDÉÉ

15. Kí la kọ́ lára Jésù nípa bá a ṣe lè máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀ déédéé?

15 Ohun tó dáa ni Jèhófà fẹ́ fún wa. (Sm. 1:1-3) Ó ń fún wa ní ìtọ́sọ́nà tó pọ̀ tó nígbà tá a nílò rẹ̀ gan-an. (Ka Hébérù 4:16.) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù, ó máa ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ déédéé, ó sì gbàdúrà láìdabọ̀. Ọ̀nà àrà ni Jèhófà gbà ti Jésù lẹ́yìn tó sì tọ́ ọ sọ́nà. Ó rán àwọn áńgẹ́lì sí i kí wọ́n lè máa ṣe ìránṣẹ́ fún un, ó fún un ní ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀ kó lè ran Jésù lọ́wọ́, ó sì tọ́ ọ sọ́nà nígbà tó fẹ́ yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjìlá. Jèhófà sọ̀rọ̀ látọ̀run láti fi hàn pé òun wà lẹ́yìn Jésù àti pé òun tẹ́wọ́ gbà á. (Mát. 3:17; 17:5; Máàkù 1:12, 13; Lúùkù 6:12, 13; Jòh. 12:28) Ó yẹ káwa náà ṣe bíi ti Jésù, ká sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa fún Ọlọ́run nígbà tá a bá ń gbàdúrà. (Sm. 62:7, 8; Héb. 5:7) Tá a bá ń gbàdúrà déédéé, àá máa tipa bẹ́ẹ̀ bá Jèhófà sọ̀rọ̀ déédéé, á sì ṣeé ṣe fún wa láti gbé ìgbé ayé tó máa mú ìyìn bá Jèhófà.

16. Báwo la ṣe lè rí ìrànlọ́wọ́ Jèhófà gbà tó máa jẹ́ ká lè máa gbọ́ ohùn rẹ̀ nìṣó?

16 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìtọ́ni Jèhófà wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo èèyàn lọ́fẹ̀ẹ́, kò fi tipátipá mú ẹnikẹ́ni pé kó tẹ̀ lé e. Ńṣe ló yẹ ká béèrè pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ó sì máa fún wa ní fàlàlà. (Ka Lúùkù 11:10-13.) Àmọ́, ó ṣe pàtàkì pé ká ‘fiyè sí bí a ṣe ń fetí sílẹ̀.’ (Lúùkù 8:18) Bí àpẹẹrẹ, ìwà àgàbàgebè ló máa jẹ́ tá a bá ń bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí èrò ìṣekúṣe tó ń wá sí wa lọ́kàn, àmọ́ a ṣì ń wo àwòrán tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe tàbí àwọn fídíò oníṣekúṣe. Nítorí náà, ká lè rí ìrànlọ́wọ́ Jèhófà gbà, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé à ń wà láwọn ibi tí ẹ̀mí Jèhófà máa ń wà tàbí ká máa wà nípò tí ẹ̀mí rẹ̀ á ti lè ṣiṣẹ́ lára wa. A mọ̀ pé ẹ̀mí rẹ̀ wà làwọn ìpàdé ìjọ. Ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà ti yọ ara wọn nínú àjálù torí pé wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà ní ìpàdé. Èyí ló jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé èrò búburú ti ń kóra jọ sínú ọkàn wọn, wọ́n sì tètè wá nǹkan ṣe sí i.—Sm. 73:12-17; 143:10.

MÁA TẸ́TÍ SÍ OHÙN JÈHÓFÀ NÍGBÀ GBOGBO

17. Kí nìdí tó fi léwu tá a bá gbára lé òye ara wa?

17 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Dáfídì, Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì. Ọmọdé ni nígbà tó pa Gòláyátì òmìrán ọmọ ilẹ̀ Filísínì. Dáfídì wá di ọmọ ogun. Nígbà tó yá, ó di ọba, olùdáàbòbò àti ẹni táá máa ṣèpinnu fún orílẹ̀-èdè kan. Àmọ́, ọkàn rẹ̀ tàn án jẹ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbára lé òye tara rẹ̀, ó sì dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì pẹ̀lú Bátí-ṣébà, kódà ó tún ṣètò pé kí wọ́n pa Ùráyà tó jẹ́ ọkọ obìnrin náà. Nígbà tí Jèhófà bá Dáfídì wí, ó gba àṣìṣe náà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀, ó sì mú kí àjọṣe àárín òun àti Jèhófà tún pa dà gún régé.—Sm. 51:4, 6, 10, 11.

18. Kí ló máa jẹ́ ká lè máa tẹ́tí sí ohùn Jèhófà nìṣó?

18 Ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 10:12, ká má sì ṣe dá ara wa lójú jù. Nítorí pé a ò lè “darí àwọn ìṣísẹ̀ ara” wa, ọwọ́ wa ló kù sí yálà láti tẹ́tí sí ohùn Jèhófà tàbí ká gbọ́ ti Elénìní rẹ̀. (Jer. 10:23) Ǹjẹ́ ká máa gbàdúrà déédéé, ká máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ́, ká sì máa tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ohùn Jèhófà.