Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ò Ń Rí Oúnjẹ Gbà “Ní Àkókò Tí Ó Bẹ́tọ̀ọ́ Mu”?

Ṣé Ò Ń Rí Oúnjẹ Gbà “Ní Àkókò Tí Ó Bẹ́tọ̀ọ́ Mu”?

ÀSÌKÒ tó le koko jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn là ń gbé yìí. (2 Tím. 3:1-5) Ojoojúmọ́ là ń dojú kọ àwọn ohun tó ń dán ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà wò àti bá a ṣe múra tán láti máa tẹ̀ lé ìlànà òdodo rẹ̀. Jésù ti rí i ṣáájú pé àkókò tó le koko yìí máà wà, ìdí nìyẹn tó fi fàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀ pé wọ́n máa rí ìṣírí gbà kí wọ́n lè fara dà á dé òpin. (Mát. 24:3, 13; 28:20) Abájọ tó fi yan ẹrú olóòótọ́ tí yóò máa pèsè ‘oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,’ kó lè fún wọn lókun.—Mát. 24:45, 46.

Látọdún 1919 tí Jésù ti yan ẹrú olóòótọ́, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ “àwọn ará ilé” tí wọ́n wá látinú onírúurú èdè ni a ti kó jọ sínú ètò Ọlọ́run, tí a sì ń bọ́ wọn nípa tẹ̀mí. (Mát. 24:14; Ìṣí. 22:17) Àmọ́, kì í ṣe gbogbo èdè ló ní gbogbo ìtẹ̀jáde wa, kì í sì í ṣe gbogbo ará ló láǹfààní láti ka àwọn ìtẹ̀jáde tó wà lórí ẹ̀rọ. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ kò láǹfààní láti ka àwọn àpilẹ̀kọ tó ń jáde lórí ìkànnì jw.org nìkan, títí kan àwọn fídíò tó wà níbẹ̀. Ǹjẹ́ ìyẹn wá túmọ̀ sí pé àwọn kan ń pàdánù oúnjẹ táá jẹ́ kí wọ́n lókun nípa tẹ̀mí? Kí ìdáhùn wa lè tọ̀nà, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ìbéèrè pàtàkì mẹ́rin.

 1. Kí ni ohun èlò tó ṣe pàtàkì jù lọ tó wà nínú oúnjẹ tí Jèhófà ń pèsè fún wa?

Nígbà tí Sátánì sọ fún Jésù pé kó sọ òkúta di búrẹ́dì, Jésù fèsì pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mát. 4:3, 4) Ọ̀rọ̀ Jèhófà ló wà nínú Bíbélì. (2 Pét. 1:20, 21) Torí náà, Bíbélì ni ohun èlò pàtàkì tó wà nínú oúnjẹ tẹ̀mí wa.—2 Tím. 3:16, 17.

Ètò Jèhófà ti ṣe Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní odindi tàbí lápá kan ní èdè tí ó ju ọgọ́fà [120] lọ, ọdọọdún sì ni àwọn èdè náà ń pọ̀ sí i. Yàtọ̀ sí ìtumọ̀ Bíbélì yìí, ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dà àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì ló wà ní odindi tàbí lápá kan ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún èdè. Jèhófà ló mú kí àṣeyọrí tó pabanbarì yìí ṣeé ṣe torí ìfẹ́ rẹ̀ ni pé kí a gba “gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:3, 4) Torí pé “kò . . . sí ìṣẹ̀dá tí kò hàn kedere sí ojú [Jèhófà],” ó dá wa lójú pé ó máa fa “àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn” sínú ètò rẹ̀, á sì máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún wọn.—Héb. 4:13; Mát. 5:3, 6; Jòh 6:44; 10:14.

2. Ipa wo ni àwọn ìtẹ̀jáde wa ń kó nínú pípèsè oúnjẹ tẹ̀mí?

Téèyàn bá fẹ́ ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, ó kọjá kó máa ka Bíbélì nìkan. Ó gbọ́dọ̀ lóye ohun tó ń kà, kó sì máa fi í sílò. (Ják. 1:22-25) Ìwẹ̀fà ará Etiópíà kan ní ọ̀rúndún kìíní gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló ń kà nígbà tí Fílípì ajíhìnrere bi í pé: “Ìwọ ha mọ ohun tí o ń kà bí?” Ìwẹ̀fà náà dá a lóhùn pé: “Ní ti tòótọ́, báwo ni mo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé ẹnì kan fi mí mọ̀nà?” (Ìṣe 8:26-31) Fílípì ran ìwẹ̀fà náà lọ́wọ́ kó lè ní ìmọ̀ tó péye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ohun tí ìwẹ̀fà náà kọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an débi pé ó ṣe ìrìbọmi. (Ìṣe 8:32-38) Lọ́nà kan náà, àwọn ìwé wa tó ń ṣàlàyé Bíbélì ti jẹ́ ká lè ní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́. Wọ́n ń wọ̀ wá lọ́kàn, wọ́n sì ń mú ká lè fi àwọn ohun tá a kọ́ sílò.—Kól. 1:9, 10.

Jèhófà ń tipasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní oúnjẹ tẹ̀mí tí ó pọ̀ yanturu, èyí tí á tó wọn jẹ táá sì tó wọn mu. (Aísá. 65:13) Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ wà ní èdè tó ju igba ó lé mẹ́wàá [210] lọ, ó ń ṣàlàyé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ó ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn òtítọ́ tẹ̀mí tó jinlẹ̀, ó sì ń mú ká lè tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. Ìwé ìròyìn Jí! tó wà ní èdè tí ó tó ọgọ́rùn-ún [100] ń mú kí ìmọ̀ wa gbòòrò sí i nípa àwọn ohun tí Jèhófà dá, ó sì tún ń jẹ́ ká mọ bí a ṣe lè fi àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì sílò. (Òwe 3:21-23; Róòmù 1:20) Ẹrú olóòótọ́ ń pèsè àwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì ní èdè tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín ogún [680] lọ! Ǹjẹ́ o máa ń wá àyè láti ka Bíbélì lójoojúmọ́? Ǹjẹ́ ò ń ka àwọn ìwé ìròyìn tuntun àti gbogbo ìtẹ̀jáde tó ń jáde ní èdè rẹ lọ́dọọdún?

Yàtọ̀ sáwọn ìwé tí ètò Ọlọ́run ń tẹ̀ jade, wọ́n tún ń pèsè àwọn ìwé àsọyé tó dá lórí Bíbélì èyí tí a máa ń sọ ní àwọn ìpàdé wa àti ní àwọn àpéjọ. Ǹjẹ́ o máa ń gbádùn àwọn àsọyé, àwòkẹ́kọ̀ọ́, àṣefihàn àti àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó máa ń wáyé ní àwọn àpéjọ yìí? Láìsí àní-àní, oúnjẹ tẹ̀mí ni Jèhófà ń pèsè fún wa!—Aísá. 25:6.

 3. Tí kò bá sí gbogbo ìtẹ̀jáde tí ètò Ọlọ́run ń tẹ̀ jáde ní èdè rẹ, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé o ò ní rí oúnjẹ gidi jẹ nípa tẹ̀mí?

Rárá o. Kò sì yẹ kó yà wá lẹ́nu pé nígbà míì àwọn kan nínú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà ju àwọn kan lọ. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Wo àpẹẹrẹ àwọn àpọ́sítélì. Wọ́n rí ìtọ́sọ́nà gbà ju àwọn ọmọlẹ́yìn yòókù lọ ní ọ̀rúndún kìíní. (Máàkù 4:10; 9:35-37) Síbẹ̀, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé àwọn ọmọlẹ́yìn tó kù ò rí oúnjẹ gidi jẹ nípa tẹ̀mí. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé wọ́n ń rí oúnjẹ tẹ̀mí tí wọ́n nílò jẹ.—Éfé. 4:20-24; 1 Pét. 1:8.

Ohun pàtàkì míì tó tún yẹ ká mọ̀ ni pé ọ̀pọ̀ ohun tí Jésù sọ àtàwọn ohun tó ṣe nígbà tó wà láyé kọ́ ló wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ní ti tòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn wà pẹ̀lú tí Jésù ṣe, tí ó jẹ́ pé, bí a bá ní láti kọ̀wé kúlẹ̀kúlẹ̀ wọn ní kíkún, mo rò pé, ayé tìkára rẹ̀ kò ní lè gba àwọn àkájọ ìwé tí a bá kọ.” (Jòh. 21:25) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní ọ̀rúndún kìíní mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jésù ju bí a ṣe mọ̀ ọ́n lọ, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé a fi ohun tó yẹ ká mọ̀ dù wá. Jèhófà rí sí i pé a mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jésù, táá jẹ́ ká lè jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀.—1 Pét. 2:21.

Tún ronú nípa àwọn lẹ́tà tí àwọn àpọ́sítélì fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ ní ọ̀rúndún kìíní. Ó kéré tán, ọ̀kan nínú àwọn lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ kò sí nínú Bíbélì. (Kól. 4:16) Ṣé oúnjẹ tẹ̀mí wa ò pọ̀ tó torí pé a ò ní lẹ́tà yẹn? Rárá o. Jèhófà mọ ohun tí a nílò, ó sì ti fún wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan táá jẹ́ ká lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀.—Mát. 6:8.

Jèhófà mọ ohun tí a nílò, ó sì ti fún wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan táá jẹ́ ká lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀

Lóde òní, àwọn kan nínú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní oúnjẹ tẹ̀mí tí ó pọ̀ ju àwọn yòókù lọ. Ṣé ìwọ̀nba ìtẹ̀jáde díẹ̀ ló wà ní èdè rẹ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, mọ̀ pé Jèhófà bìkítà fún ẹ. Máa ka àwọn ìtẹ̀jáde náà, kí o sì máa lọ sí ìpàdé tí wọ́n ti ń sọ èdè tí ó yé ẹ dáadáa. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà yóò mú kí o ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú òun.—Sm. 1:2; Héb. 10:24, 25.

4. Tí o kò bá láǹfààní láti máa ka àwọn ìsọfúnni tó wà lórí ìkànnì jw.org, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà máa jó rẹ̀yìn?

Àwọn ìwé ìròyìn wa àti àwọn ìwé míì tí a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wà lórí Ìkànnì wa. Àwọn ìsọfúnni tó lè ran tọkọtaya, àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn ọmọdé lọ́wọ́ tún wà lórí Ìkànnì náà. Àwọn ìdílé máa jàǹfààní gan-an tí wọ́n bá gbé àwọn ìsọfúnni yìí yẹ̀ wò nígbà Ìjọsìn Ìdílé wọn. Bákan náà, a tún máa ń gbé ìròyìn nípa àwọn ètò pàtàkì kan sórí Ìkànnì wa, irú bí ìròyìn nípa ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì àti ti ìpàdé ọdọọdún. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa ń fi ìsọfúnni nípa àwọn àjálù tó ṣẹlẹ̀ tó ẹgbẹ́ ará kárí ayé létí lórí Ìkànnì wa àti àwọn ọ̀ràn òfin tí ó kan àwọn èèyàn Jèhófà. (1 Pét. 5:8, 9) Ìkànnì yìí tún wúlò gan-an láti fi mú kí ìhìn rere tàn káàkiri, kódà títí dé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa.

Àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà kò ní yingin, yálà o láǹfààní láti lọ wo Ìkànnì wa tàbí o kò ní. Ẹrú náà ti ṣiṣẹ́ kára gan-an láti pèsè ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìtẹ̀jáde tó máa mú kí àwọn ará ilé jẹ àjẹyó nípa tẹ̀mí. Torí náà, kì í ṣe dandan kó o ra ẹ̀rọ ìgbàlóde torí kó o lè máa fi wọ ìkànnì jw.org. Àwọn kan máa ń ṣètò láyè ara wọn láti tẹ díẹ̀ lára àwọn ìsọfúnni tó máa ń wà lórí Ìkànnì wa jáde, wọ́n á sì fún àwọn tí kò láǹfààní láti lo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àmọ́ èyí kì í ṣe ojúṣe ìjọ o.

A mà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jésù o, pé ó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun máa bójú tó àìní wa nípa tẹ̀mí! Bí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí ṣe ń yára lọ sí òpin, a ní ìdánilójú pé Jèhófà á máa bá a nìṣó láti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún wa “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.”