‘Pa Dà Kí O sì Fún Àwọn Arákùnrin Rẹ Lókun’
PÉTÉRÙ sunkún kíkorò lẹ́yìn tó sẹ́ Jésù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àpọ́sítélì náà ṣì ní láti sapá kó lè pa dà bọ̀ sípò nípa tẹ̀mí, Jésù fẹ́ lò ó láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Torí náà, Jésù sọ fún un pé: “Ní gbàrà tí o bá ti padà, fún àwọn arákùnrin rẹ lókun.” (Lúùkù 22:32, 54-62) Pétérù di ọ̀kan lára àwọn tá a lè pè ní ọwọ̀n tó gbé ìjọ Kristẹni rò ní ọ̀rúndún kìíní. (Gál. 2:9) Lọ́nà kan náà, arákùnrin kan tó ti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nígbà kan rí ṣì lè pa dà sìn lẹ́ẹ̀kan sí i, kó sì láyọ̀ bó ṣe ń fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni lókun nípa tẹ̀mí.
Àwọn kan tó ti fìgbà kan rí sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ni wọ́n ti mú kúrò nípò yẹn, èyí sì lè mú kírú àwọn bẹ́ẹ̀ máa rò pé aláṣetì làwọn. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Julio, * tó ti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà fún ohun tó lé ní ogún ọdún ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù sọ pé: “Èyí tó pọ̀ jù nínú apá ìgbésí ayé mi ni mo fi ń múra àsọyé, tí mo fi ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ará, tí mo sì ń bójú tó àwọn ará ìjọ! Mo kàn rí i pé gbogbo ẹ̀ lọ lójijì, bó ṣe di pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí ohun tí mò ń ṣe mọ́ nìyẹn. Ayé sú mi pátápátá láàárín àkókò yẹn.” Julio ti pa dà ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà báyìí.
“Ẹ KA GBOGBO RẸ̀ SÍ ÌDÙNNÚ”
Ọmọ ẹ̀yìn náà, Jákọ́bù sọ pé: “Ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ìdùnnú, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá ń bá onírúurú àdánwò pàdé.” (Ják. 1:2) Àwọn àdánwò tí a máa ń ní nítorí inúnibíni àti àìpé ni Jákọ́bù ń tọ́ka sí nínú ẹsẹ yìí. Ó mẹ́nu kan ìfẹ́ ọkàn tiwa fúnra wa, kéèyàn máa ṣègbè àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (Ják. 1:14; 2:1; 4:1, 2, 11) Tí Jèhófà bá bá wa wí, ó lè dùn wa wọra gan-an. (Héb. 12:11) Àmọ́, kò yẹ kírú àdánwò bẹ́ẹ̀ mú ká pàdánù ayọ̀ wa.
Kódà tí wọ́n bá mú wa kúrò ní ipò kan tá a ti ń sìn nínú ìjọ, a ṣì lè lo àǹfààní yẹn láti fi bí ìgbàgbọ́ wa ṣe lágbára tó hàn, ká sì fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. A tún lè ronú lórí ìdí tá a fi ń sìn nípò yẹn. Ṣé kì í ṣe torí àǹfààní tara wa? Ṣé ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run àti ìdánilójú tá a ní pé òun ló ni ìjọ àti pé a gbọ́dọ̀ fọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú àwọn ará ló mú ká máa sìn nínú ìjọ? (Ìṣe 20:28-30) Àwọn tí wọn ò sìn nípò alàgbà mọ́, àmọ́ tí wọ́n ṣì ń fayọ̀ bá iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wọn nìṣó ń fi dá gbogbo èèyàn lójú títí kan Sátánì pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn.
Nígbà tí Jèhófà bá Dáfídì Ọba wí fún ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì tó dá, ó gba ìbáwí náà, Ọlọ́run sì dárí jì í. Dáfídì sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí a dárí ìdìtẹ̀ rẹ̀ jì, tí a bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀. Aláyọ̀ ni ènìyàn tí Jèhófà kò ka ìṣìnà sí lọ́rùn, ẹni tí ẹ̀tàn kò sì sí nínú ẹ̀mí rẹ̀.” (Sm. 32:1, 2) Ìbáwí náà yọ́ Dáfídì mọ́, ó sì dájú pé ó mú kó lè bójú tó àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́nà tó dára sí i, gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn rere.
Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn arákùnrin tí wọ́n bá tún pa dà sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà máa ń wá di olùṣọ́ àgùntàn àtàtà. Alàgbà kan tí irú nǹkan yìí ti ṣẹlẹ̀ sí rí sọ pé: “Mo ti wá mọ ọ̀nà tó dára jù lọ láti bójú tó àwọn tó bá ṣe àṣìṣe.” Alàgbà míì sọ pé: “Ní báyìí, mo fọwọ́ pàtàkì mú àǹfààní tí mo ní láti máa bójú tó àwọn ará.”
ṢÉ O LÈ PA DÀ SÌN?
Onísáàmù kan sọ pé: “[Jèhófà] kì yóò máa wá àléébù ṣáá nígbà gbogbo.” (Sm. 103:9) Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká rò pé Ọlọ́run ò tún lè pa dà fọkàn tán ẹnì kan tó ṣe àṣìṣe tó burú jáì. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Ricardo tó ti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà fún ọ̀pọ̀ ọdún, àmọ́ tó pàdánù àǹfààní yẹn sọ pé: “Ó dùn mí wọra gan-an pé mo ṣe àṣìṣe. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi ṣe mí bíi pé mi ò tóótun mọ́, ìyẹn ló sì fà á ti mi ò fi fẹ́ pa dà di alábòójútó. Mo sọ ìrètí nù pé kò sí ohun tí mo lè ṣe táwọn èèyàn á fi tún pa dà máa fọkàn tán mi. Àmọ́ torí pé ó máa ń wù mí láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, mo ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mò ń sọ̀rọ̀ ìṣírí fáwọn ará ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, mo sì ń bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Ìyẹn jẹ́ kí n rí i pé ohun tí mo ṣì lè ṣe wà. Ní báyìí mo ti ń sìn pa dà gẹ́gẹ́ bí alàgbà.”
Tí arákùnrin kan bá ń bínú sáwọn kan, ó lè mú kó máà fẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà. Àmọ́, àpẹẹrẹ gidi ni Dáfídì ìránṣẹ́ Jèhófà jẹ́ fún wa, ńṣe ló ní láti sá kúrò nílùú fún Sọ́ọ̀lù Ọba tó ń jowú rẹ̀! Kódà, nígbà tí Dáfídì rí àǹfààní tó fi lè pa Sọ́ọ̀lù, kò pa á. (1 Sám. 24:4-7; 26:8-12) Nígbà tí Sọ́ọ̀lù kú lójú ogun, Dáfídì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀. Ó ní, Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ọmọ rẹ̀ jẹ́ “ẹni fífẹ́ àti ẹni gbígbádùnmọni.” (2 Sám. 1:21-23) Dáfídì ò gbé ìbínú sọ́kàn.
Tó o bá ronú pé wọ́n ṣì ẹ́ lóye tàbí wọ́n dájọ́ lọ́nà tí kò tọ́, má ṣe jẹ́ kí ìbínú gbà ẹ́ lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, Arákùnrin William tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Britain ti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà fún ọgbọ̀n ọdún, àmọ́ wọ́n yọ ọ́ kúrò nípò alàgbà, èyí mú kó di àwọn alàgbà kan sínú. Kí ló mú kí Arákùnrin William lè pa dà ní èrò tó tọ́? Ó sọ pé: “Ìwé Jóòbù tí mo kà ràn mí lọ́wọ́. Tí Jèhófà bá ran Jóòbù lọ́wọ́ tó fi dárí ji àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, á ran èmi náà lọ́wọ́ kí n lè dárí ji àwọn alàgbà tí mò ń bínú sí yẹn.”—Jóòbù 42:7-9.
ỌLỌ́RUN MÁA BÙ KÚN ÀWỌN TÓ BÁ PA DÀ SÌN GẸ́GẸ́ BÍ ALÁBÒÓJÚTÓ
Tó o bá ti gbé iṣẹ́ àbójútó ìjọ Ọlọ́run sílẹ̀, ó máa dáa kó o ronú lórí ìdí tó o fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣé ìṣòro ìgbésí ayé ló fà á? Ṣé àwọn nǹkan míì ló ṣe pàtàkì sí ẹ? Ṣé àìpé àwọn ẹlòmíì ló mú kí nǹkan sú ẹ? Ohun yòówù kó fà á, rántí pé o wà nípò láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà tó pọ̀ gan-an nígbà tó ò ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà. Àsọyé rẹ ń gbé ìjọ ró, àpẹẹrẹ rẹ ń fún wọn níṣìírí, ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn tó o sì ń ṣe ń jẹ́ kí wọ́n lè fara da ìdánwò tó dé bá wọn. Inú Jèhófà ń dùn bó o ṣe ń fi ìṣòtítọ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nígbà yẹn, ó sì dájú pé inú ìwọ náà ń dùn.—Òwe 27:11.
Jèhófà ti ran àwọn ọkùnrin kan lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà máa láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń ní in tẹ́lẹ̀ kó sì tún wù wọ́n láti ṣe àbójútó ìjọ. Tó bá jẹ́ pé o fi ipò alàgbà sílẹ̀ fúnra rẹ tàbí ṣe ni wọ́n mú ẹ kúrò ní ipò yẹn, o ṣì lè pa dà “nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó.” (1 Tím. 3:1) Pọ́ọ̀lù kò “ṣíwọ́ gbígbàdúrà” pé kí àwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè lè ní ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, “kí [wọ́n] lè máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún.” (Kól. 1:9, 10) Tó o bá tún láǹfààní láti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní okun, sùúrù àti ayọ̀. Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, àwọn èèyàn Ọlọ́run nílò àbójútó nípa tẹ̀mí látọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí wọ́n jẹ́ onífẹ̀ẹ́. Ṣé wàá lè fún àwọn ará lókun? Ṣé o sì múra tán láti ṣe bẹ́ẹ̀?
^ ìpínrọ̀ 3 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.