ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ September 2014

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti October 27 sí November 30, 2014 ló wà nínú ẹ̀dá yìí.

Ǹjẹ́ Ò Ń ‘Nàgà fún Iṣẹ́ Àtàtà’?

Báwo lo ṣe lè ṣe é lọ́nà tí ó tọ́?

Ǹjẹ́ Ó Dá Ẹ Lójú Pé O Wà Nínú Òtítọ́? Kí Nìdí?

Àpilẹ̀kọ yií máa jóròrò àwọn ìdí tí ọ̀pọ̀ fi gbà pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní òtítọ́.

Máa Sin Jèhófà Láìyẹsẹ̀ Láìka “Ọ̀pọ̀ Ìpọ́njú” Sí

Gbogbo wa ni ojú ń pọ́n torí pé à ń gbé nínú ayé Sátánì. Kí ni díẹ̀ lára ọ̀nà tí Sátánì ń lò láti gbéjà kò wá? Báwo la ṣe múra sílẹ̀ dè wọ́n?

Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín

Ojúṣe àwọn òbí ni láti tọ́ àwọn ọmọ wọn “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò ọ̀nà mẹ́ta táwọn òbí lè gbà kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ṣé ohun tí Bíbélì sọ nínú Sáàmù 37:25 àti Mátíù 6:33 túmọ̀ sí pé Jèhófà kò ní jẹ́ kí ebi pa Kristẹni kan?

Gẹ́gẹ́ Bí Ọ̀tá Ìkẹyìn, Ikú Di Ohun Asán

Ikú àti gbogbo ohun tó fà á tá a fi ń kú ló fa ìjìyà tó lékenkà fún aráyé. Kí nìdí téèyàn fi ń kú? Báwo ni ‘ọ̀tá ìkẹyìn, ikú ṣe máa di asán’? (1 Kọ́ríńtì 15:26) Wo bí àwọn ìdáhùn sí ìbéèrè yìí ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo, ọlọgbọ́n àti pé ó nífẹ̀ẹ́ wa.

Ẹ Máa Rántí Àwọn Tó Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún

Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sin Jèhófà ló ń ṣiṣẹ́ kára nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Kí la lè ṣe tá a fi máa rántí “iṣẹ́ ìṣòtítọ́” àti “òpò onífẹ̀ẹ́” wọn?—1 Tẹsalóníkà 1:3.