Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ó Dá Ẹ Lójú Pé O Wà Nínú Òtítọ́? Kí Nìdí?

Ǹjẹ́ Ó Dá Ẹ Lójú Pé O Wà Nínú Òtítọ́? Kí Nìdí?

“Ẹ . . . ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.”—RÓÒMÙ 12:2.

1. Kí ni àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì máa ń ṣe nígbà ogun?

ǸJẸ́ Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn Kristẹni tòótọ́ máa jagun, kí wọ́n sì máa pa àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè míì? Ní ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá, ọ̀pọ̀ àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni ló jagun, tí wọ́n sì pààyàn. Àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì máa ń ṣàdúrà fún àwọn ọmọ ogun àti ohun ìjà tí wọ́n ń kó lọ sógun kí wọ́n lè pa àwọn Kátólíìkì míì tó wà ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń bá jagun. Bí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì náà ti máa ń ṣe nìyẹn. Ìpakúpa tó wáyé nígbà ogun Àgbáyé Kejì jẹ́ àpẹẹrẹ táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa.

2, 3. Kí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe nígbà Ogun Àgbáyé Kejì àti lẹ́yìn ìgbà náà, kí sì nìdí?

2 Kí ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe nígbà ogun? Ìtàn fi hàn pé wọn kì í dá sí ogun tàbí ìjà láàárín orílẹ̀-èdè. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àti ẹ̀kọ́ Jésù. Jésù sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòh. 13:35) Bákan náà, wọ́n tún fi sọ́kàn pé ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì kan àwọn náà.—Ka 2 Kọ́ríńtì 10:3, 4.

3 Torí náà, àwọn Kristẹni tòótọ́ tó ti fi Bíbélì kọ́ ẹ̀rí ọkàn wọn kì í kọ́ṣẹ́ ogun tàbí kí wọ́n jagun. Torí pé wọ́n ń fi ohun  tí Bíbélì sọ sílò, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́mọdé lágbà, lọ́kùnrin àti lóbìnrin ni wọ́n ń ṣe inúnibíni sí. Wọ́n fìyà jẹ ọ̀pọ̀ wọn ní àwọn àgọ́ ìfipá-múni-ṣiṣẹ́ àti ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. Wọ́n tiẹ̀ pa àwọn míì nínú wọn nígbà ìjọba Násì lórílẹ̀-èdè Jámánì. Àmọ́, láìka àtakò líle koko tí wọ́n ṣe sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Yúróòpù sí, wọn ò gbàgbé ojúṣe wọn láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Jèhófà. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń wàásù ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, ní àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ àti ní ìgbèkùn. * Lẹ́yìn ìgbà náà, lọ́dún 1994 tí ogun tí wọ́n fẹ́ fi pa odindi ẹ̀yà kan run wáyé lórílẹ̀-èdè Rwanda, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò bá wọn dá sí i. Bákan náà, nígbà tí wọ́n pa àwọn èèyàn nípakúpa nínú ogun tó wáyé ní àgbègbè Balkans nígbà tí orílẹ̀-èdè Yugoslavia tẹ́lẹ̀ tú ká, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò bá wọn lọ́wọ́ sí i.

4. Ipá wo ni bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò ṣe dá sí ogun tàbí ìjà láàárín orílẹ̀-èdè ti ní lórí àwọn tó ń kíyè sí wọn?

4 Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò ṣe dá sí ogun tàbí ìjà láàárín orílẹ̀-èdè mú kó dá ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó ń kíyè sí wọn kárí ayé lójú pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ojúlówó ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti fún àwọn ọmọnìkejì wọn. Nítorí náà, àwọn gan-an ló ń ṣe ìsìn tòótọ́. Síbẹ̀, àwọn apá míì ṣì wà nínú ìjọsìn wa tí ọ̀pọ̀ kíyè sí tó mú kó dá wọn lójú pé, Kristẹni tòótọ́ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

IṢẸ́ ÌKỌ́NILẸ́KỌ̀Ọ́ TÓ TA YỌ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN

5. Àyípadà wo ni àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ní láti fara mọ́?

5 Jésù jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ pé pípolongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé. Ó yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjìlá tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó máa kárí ayé yìí, lẹ́yìn náà ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n jẹ́ àádọ́rin [70] bí wọ́n á ṣe máa wàásù. (Lúùkù 6:13; 10:1) Wọ́n múra tán láti lọ wàásù ìhìn rere náà fáwọn Júù, kí wọ́n tó wá lọ sọ́dọ̀ gbogbo èèyàn. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ nígbà tó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n wàásù dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tí wọn kò dádọ̀dọ́. Àyípadà tó kàmàmà ni èyí jẹ́ fún àwọn ọmọlẹ́yìn tó jẹ́ Júù tó ń fìtara wàásù!—Ìṣe 1:8.

6. Kí ló jẹ́ kí Pétérù wá gbà pé Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú?

6 Jèhófà rán àpọ́sítélì Pétérù lọ sọ́dọ̀ Kọ̀nílíù tó jẹ́ Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́. Pétérù wá gbà pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú. Kọ̀nílíù àti agbo ilé rẹ̀ sì ṣèrìbọmi. Ẹ̀sìn Kristẹni bẹ̀rẹ̀ sí í gbòòrò, àwọn èèyàn ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wá láǹfààní láti gbọ́ òtítọ́ kí wọ́n sì tẹ́wọ́ gbà á. (Ìṣe 10:9-48) Ní báyìí, gbogbo ayé ló lè gbọ́ ìhìn rere.

7, 8. Kí ni ètò Jèhófà ti ṣe káwọn èèyàn lè gbọ́ ìhìn rere? (Wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

7 Ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní fi hàn pé àwọn tó ń mú ipò iwájú ń fi ìtara ṣe iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni ní ìhìn rere kárí ayé. Lónìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́jọ ló ń fi ìtara kéde ìhìn rere tí Jésù gbé lé wa lọ́wọ́ ní èdè tó lé ní ẹgbẹ̀ta [600], púpọ̀ sí i ṣì ń bọ̀ lọ́nà! Àwọn èèyàn dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé a máa ń wàásù láti ilé dé ilé àti ní òpópónà, a tún máa ń kó àwọn ìwé wa sórí àwọn tábìlì tàbí káńtà tó ṣeé tì kiri.

8 Àwọn atúmọ̀ èdè tó ju ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [2,900] lọ ni wọ́n gba àkànṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè túmọ̀ Bíbélì àti àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì. Kì í ṣe àwọn èdè táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa nìkan ni wọ́n ń túmọ̀. Kódà, wọ́n ń túmọ̀ ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè táwọn èèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀, àmọ́ tó jẹ́ pé àràádọ́ta  ọ̀kẹ́ èèyàn ló ń sọ ọ́. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Sípéènì kò sí ojúmọ́ kan káwọn ará Catalan má sọ èdè abínibí wọn. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo èdè Catalan àtàwọn èdè ìbílẹ̀ rẹ̀ míì láwọn àgbègbè bíi Valencia àti Alicante, àwọn Erékùṣù Balearic àti lórílẹ̀-èdè Andorra. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde lédè Catalan, a ń ṣe àwọn ìpàdé Kristẹni ní èdè yìí, èyí sì ń múnú àwọn ará Catalan dùn gan-an.

9, 10. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé ètò Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo èèyàn kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?

9 Kárí ayé ni a ti ń ṣe ìtumọ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a sì ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní èdè wọn. Bí àpẹẹrẹ, èdè Sípáníìṣì ni wọ́n ń sọ ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, àmọ́ wọ́n tún ní ọ̀kan-kò-jọ̀kan àwùjọ tí wọ́n ní èdè ìbílẹ̀ tí wọ́n ń sọ, èdè Maya sì jẹ́ ọ̀kan nínú èdè náà. Torí náà, ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò sọ pé kí àwùjọ àwọn atúmọ̀ èdè tó ń ṣètúmọ̀ sí èdè Maya máa lọ gbé ní apá ibi táwọn èèyàn ti ń sọ èdè náà lójoojúmọ́. Àpẹẹrẹ míì ni èdè Nepali tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èdè tí wọ́n ń sọ ní orílẹ̀-èdè Nepal. Àwọn èèyàn tó wà lórílẹ̀-èdè yẹn tó mílíọ̀nù mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, èdè tí wọ́n sì ń sọ níbẹ̀ tó ọgọ́fà [120]. Àmọ́, àwọn tí ó tó mílíọ̀nù mẹ́wàá ló ń sọ èdè Nepali, ọ̀pọ̀ àwọn míì sì ń sọ ọ́ ní àfikún sí èdè ìbílẹ̀ wọn gangan. À ń tẹ àwọn ìwé ìròyìn wa jáde lédè Nepali.

10 Ọwọ́ pàtàkì ni ètò Jèhófà fi mú iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé, èyí hàn nínú ìtìlẹyìn tó ń ṣe fún àwùjọ àwọn atúmọ̀ èdè kárí ayé. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ìwé àṣàrò kúkúrú, ìwé pẹlẹbẹ àti àwọn ìwé ìròyìn ni a ti pín kiri kárí ayé fáwọn èèyàn. A kì í ta àwọn ìwé yìí, kàkà bẹ́ẹ̀ ọrẹ àtinúwá táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe la fi ń bojú tó iṣẹ́ ìwàásù náà. Ìtọ́ni Jésù là ń tẹ̀ lé, Jésù sọ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.”—Mát. 10:8.

Àwùjọ àwọn atúmọ̀ èdè tó ń tú àwọn ìtẹ̀jáde sí èdè ìbílẹ̀ Jámánì kan tí wọ́n ń pè ní Low German (Wo ìpínrọ̀ 10)

Àwọn ará Paraguay máa ń lo àwọn ìtẹ̀jáde ti èdè Low German (Tún wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí)

11, 12. Ipa rere wo ni iṣẹ́ ìwàásù táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé ní lórí àwọn èèyàn?

11 Tọkàntọkàn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wàásù tí wọ́n sì ń kọ́ni, ó dá wọn lójú hán-ún pé wọ́n ti rí òtítọ́, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kí wọ́n lè kéde ìhìn rere fún àwọn èèyàn onírúurú orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà. Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti mú kí ìwọ̀nba nǹkan ìní tara tẹ́ wọn lọ́rùn, wọ́n kọ́ èdè àti àṣà ìbílẹ̀ míì kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ pàtàkì tó yẹ kí gbogbo Kristẹni máa  ṣe. Ohun míì tó mú kó dá ọ̀pọ̀ èèyàn lójú pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gan-an ni ojúlówó ọmọlẹ́yìn Kristi Jésù ni iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni tí à ń ṣe kárí ayé.

12 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe torí pé ó dá wa lójú pé a ti rí òtítọ́. Àmọ́, kí ni nǹkan míì tó tún mú kó dá ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lójú pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní òtítọ́?—Ka Róòmù 14:17, 18.

ÌDÍ TÓ FI DÁ WỌN LÓJÚ

13. Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń mú kí ètò wọn wà ní mímọ́?

13 A máa jàǹfààní gan-an nínú ohun tí àwọn Kristẹni tó jẹ́ olùfọkànsìn sọ pé ó mú kó dá àwọn lójú pé àwọn wà nínú òtítọ́. Arákùnrin kan tó ti ń sin Jèhófà tipẹ́ sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀, ó ní: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ètò Jèhófà ń ṣe láti wà ní mímọ́ àti aláìlẹ́gbin, kò sì sẹ́ni tó kọjá ìtọ́ni tàbí ìbáwí nínú ètò Jèhófà.” Kí ló mú kí wọ́n lè wà ní mímọ́ lọ́nà yìí? Ìdí ni pé wọ́n ń tẹ̀ lé ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àpẹẹrẹ tí Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fi lélẹ̀. Abájọ tó fi jẹ́ pé nínú ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí, a ti yọ àwọn díẹ̀ kan lẹ́gbẹ́ torí pé wọn kò tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń sapá láti wà ní mímọ́ lójú Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣe ohun tí inú Ọlọ́run kò dùn sí tẹ́lẹ̀ ti yí pa dà, wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run báyìí.—Ka 1 Kọ́ríńtì 6:9-11.

14. Kí ni ọ̀pọ̀ ti ṣe lẹ́yìn tí wọ́n yọ wọ́n lẹ́gbẹ́, kí sì ni àbájáde rẹ̀?

14 Ìtọ́ni Bíbélì ni pé ká yọ àwọn tó kọ̀ láti tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run kúrò nínú ìjọ. Ó mú inú wa dùn pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún tó ti ronú pìwà dà, tí wọ́n sì ti yí pa dà ti pa dà sínú ìjọ. (Ka 2 Kọ́ríńtì 2:6-8.) Bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì ń mú kí ìjọ Ọlọ́run wà ní mímọ́, èyí sì ń mú ká lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run ló ń darí ìjọ rẹ̀, a sì fọkàn tán an. Ọwọ́ pàtàkì táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi mú ìlànà Ọlọ́run yàtọ̀ pátápátá sí ìwàkiwà tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, èyí sì mú kó túbọ̀ dá ọ̀pọ̀ èèyàn lójú pé Kristẹni tòótọ́ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

15. Kí ló mú kó dá arákùnrin kan lójú pé ẹ̀sìn tòótọ́ ló ń ṣe?

15 Kí nìdí tó fi dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti pẹ́ nínú ètò Ọlọ́run lójú pé wọ́n wà nínú òtítọ́? Arákùnrin kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta [54] sọ pé: “Ìgbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́ ni mo ti gbà pé ohun mẹ́ta kan ni ìgbàgbọ́ mi rọ̀ mọ́. Àwọn ohun mẹ́ta náà ni: (1) Ọlọ́run wà; (2) Ọlọ́run ló fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ mí sí àwọn tó kọ Bíbélì; àti pé (3) ètò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Ọlọ́run ń lò lónìí, ó sì ń bù kún ètò náà. Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún tí mò ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i, mo máa ń dán àwọn ohun tí ìgbàgbọ́ mi rọ̀ mọ́ wò bóyá orí ilẹ̀ tó dúró sán-ún ló wà lóòótọ́. Ohun tójú mi ti rí láti àwọn ọdún yìí wá ti fi hàn pé òtítọ́ làwọn ohun tí mo gbà gbọ́, èyí ń mú kí ìgbàgbọ́ mi jinlẹ̀ sí i, ó  sì túbọ̀ ń dá mi lójú pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà là ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́.”

16. Kí ló wú arábìnrin kan lórí nípa ẹ̀kọ́ òtítọ́?

16 Arábìnrin kan tó ń sìn ní orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní New York sọ ohun tó jẹ́ kó dá a lójú pé ó wà nínú òtítọ́. Ó sọ pé ètò Ọlọ́run nìkan ló ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Jèhófà, èyí tó fara hàn nínú Bíbélì ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà. Ọ̀rọ̀ inú 2 Kíróníkà 16:9 tún máa ń fún un níṣìírí gan-an, ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé: “Ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” Arábìnrin náà sọ pé: “Ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí mo kọ́ ti jẹ́ kí n mọ bí mo ṣe lè ní ọkàn tó pé pérépéré kí Jèhófà lè lo okun rẹ̀ nítorí mi. Àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú Jèhófà ló ṣe pàtàkì jù sí mi. Mo mọrírì ipa tí Jésù kó ká lè mọ Jèhófà dunjú, èyí sì máa ń gbé mi ró.”

17. Kí ló dá ọkùnrin kan tí kò gbà tẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run wà lójú, kí sì nìdí?

17 Ọkùnrin kan tí kò gbà tẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run wà sọ pé: “Tí mo bá wo àwọn ohun tí Ọlọ́run dá, ó máa ń túbọ̀ dá mi lójú pé Ọlọ́run fẹ́ kí àwa èèyàn máa gbádùn ayé wa àti pé kò ní jẹ́ kí ìyà máa jẹ àwa èèyàn títí lọ. Bákan náà, bí àwọn oníwà ìbàjẹ́ tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run ṣe ń pọ̀ sí i nínú ayé yìí, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́, ìtara àti ìfẹ́ àwọn èèyàn Jèhófà túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ẹ̀mí Jèhófà nìkan ló lè mú kí irú iṣẹ́ ìyanu yìí wáyé lóde òní.”—Ka 1 Pétérù 4:1-4.

18. Báwo ni ohun tí àwọn arákùnrin méjì kan sọ ṣe rí lára rẹ?

18 Arákùnrin míì tóun náà ti ń sin Jèhófà láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn sọ ìdí tóun fi gba òtítọ́ tá à ń wàásù rẹ̀ gbọ́, ó sọ pé: “Ohun tí mò ti kọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ti jẹ́ kó dá mi lójú pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà là ń sapá láti ṣe bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Mo ti rìnrìn àjò yíká ayé, mo sì ti rí i fúnra mi pé kárí ayé ni ìṣọ̀kan wà láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Òtítọ́ tí mo kọ́ látinú Bíbélì ti fọkàn mi balẹ̀, mo sì ń láyọ̀.” Arákùnrin kan tó ti lé ní ẹni ọgọ́ta [60] ọdún sọ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ nínú Jésù Kristi, ìyẹn sì jẹ́ kó túbọ̀ dá a lójú pé a ní òtítọ́, ó sọ pé: “A ti kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa nípa ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, a sì mọrírì àwọn àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀. A ti ṣe àwọn àyípadà kan ní ìgbésí ayé wa ká lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi Jésù. A gbà pé a lè rí ìgbàlà lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi. A sì gbà pé Ọlọ́run jí i dìde nígbà tó kú. Ohun táwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn sọ jẹ́ kó dá wa lójú pé ó jíǹde lóòótọ́.”—Ka 1 Kọ́ríńtì 15:3-8.

KÍ LA GBỌ́DỌ̀ FI ÒTÍTỌ́ YÌÍ ṢE?

19, 20. (a) Ojúṣe wo ni Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará ìjọ tó wà ní Róòmù pé wọ́n ní? (b) Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, àǹfààní wo la ní?

19 Àwa Kristẹni tòótọ nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ìdí nìyẹn tí a fi gbọ́dọ̀ sọ òtítọ́ tó ṣeyebíye tí a mọ̀ yìí fún wọn. Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará ìjọ tó wà nílùú Róòmù pé: “Bí ìwọ bá polongo ‘ọ̀rọ̀ yẹn tí ń bẹ ni ẹnu ìwọ alára’ ní gbangba, pé Jésù ni Olúwa, tí o sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ pé Ọlọ́run gbé e dìde kúrò nínú òkú, a ó gbà ọ́ là. Nítorí ọkàn-àyà ni a fi ń lo ìgbàgbọ́ fún òdodo, ṣùgbọ́n ẹnu ni a fi ń ṣe ìpolongo ní gbangba fún ìgbàlà.”—Róòmù 10:9, 10.

20 Torí pé Ẹlẹ́rìí tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà ni wá, ó dá wa lójú pé a wà nínú òtítọ́, a sì mọ̀ pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti kọ́ àwọn èèyàn nípa ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Torí náà, bí a ti ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́, ẹ jẹ́ kí ó hàn nínú ohun tí à ń kọ́ àwọn èèyàn látinú Bíbélì, pàápàá jù lọ kó hàn nínú bí a ṣe ń gbé ayé wa pé ó dá wa lójú lóòótọ́ pé a wà nínú òtítọ́.

^ ìpínrọ̀ 3 Wo ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, ojú ìwé 191 sí 198 àti 448 sí 454.