Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jẹ́ Kí Jèhófà Dáàbò Bo Ìgbéyàwó Rẹ Kó sì Fún Un Lókun

Jẹ́ Kí Jèhófà Dáàbò Bo Ìgbéyàwó Rẹ Kó sì Fún Un Lókun

“Bí kò ṣe pé Jèhófà tìkára rẹ̀ bá ṣọ́ ìlú ńlá náà, lásán ni ẹ̀ṣọ́ wà lójúfò.”SM. 127:1b.

1, 2. (a) Kí nìdí tí ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́rìnlélógún [24,000] nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi pàdánù àwọn ìbùkún àgbàyanu tí Ọlọ́run fún wọn? (b) Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà àtijọ́ yẹn kọ́ wa?

NÍGBÀ tó ku díẹ̀ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ní “ìbálòpọ̀ oníṣekúṣe pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin Móábù.” Torí ohun tí wọ́n ṣe yìí, Jèhófà pa ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́rìnlélógún [24,000] nínú wọn. Ó mà ṣe o, ohun tó kù kọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ ogún tí wọ́n ti ń dúró dè tipẹ́tipẹ́ kò tó nǹkan mọ́, àmọ́ wọ́n pàdánù ìbùkún àgbàyanu yẹn torí pé wọ́n jẹ́ kí ìdẹwò borí wọn.—Núm. 25:1-5, 9.

2 Àpẹẹrẹ tó bani nínú jẹ́ yìí wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì, kí ó lè “jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwa tí òpin àwọn ètò àwọn nǹkan dé bá.” (1 Kọ́r. 10:6-11) Ní báyìí, tá a wà ní apá ìgbẹ̀yìn “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti wà ní bèbè ayé tuntun òdodo. (2 Tím. 3:1; 2 Pét. 3:13) Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé àwọn olùjọ́sìn Jèhófà kan ti gba ìgbàkugbà láyè. Wọ́n jẹ́ kí ìṣekúṣe dẹkùn mú wọn, wọ́n sì ti rí aburú tó tẹ̀yìn rẹ̀ yọ. Tírú àwọn bẹ́ẹ̀ ò bá ṣọ́ra, wọ́n lè pàdánù àwọn ìbùkún ayérayé tí Ọlọ́run máa fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

3. Kí nìdí tí àwọn tọkọtaya fi nílò ìtọ́sọ́nà àti ààbò Jèhófà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

3 Torí bí ìwà ìṣekúṣe ṣe gbòde kan lóde òní, àwọn tọkọtaya nílò ìtọ́sọ́nà àti ààbò Jèhófà kí làálàá wọn láti dáàbò bo ìgbéyàwó wọn má bàa já sásán. (Ka Sáàmù 127:1.) A máa jíròrò bí tọkọtaya ṣe lè mú kí ìdè ìgbéyàwó wọn lókun tí wọ́n bá ń ṣọ́ ọkàn wọn, tí wọ́n sún mọ́ Ọlọ́run, tí wọ́n gbé ìwà tuntun wọ̀, tí wọ́n jọ ń sọ̀rọ̀ dáadáa, tí wọ́n sì ń fi ẹ̀tọ́ ìgbéyàwó fún ara wọn.

FI ÌṢỌ́ ṢỌ́ ỌKÀN RẸ

4. Kí ló sún àwọn Kristẹni kan sínú ìwà ìbàjẹ́?

4 Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè lọ́wọ́ nínú ìwà ìṣekúṣe? Ibi tí ìwà ìṣekúṣe tó lè bani láyé jẹ́ ti máa ń bẹ̀rẹ̀ ni ohun tí ojú wa ń rí. Jésù sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀. (Mát. 5:27, 28; 2 Pét. 2:14) Ọ̀pọ̀ Kristẹni tó lọ́wọ́ nínú ìwà ìbàjẹ́ ló jẹ́ torí pé wọ́n ṣe àwọn ohun tí kò jẹ́ kí wọ́n ní okun nípa tẹ̀mí, lára rẹ̀ ni pé wọ́n ń wo àwọn àwòrán oníhòòhò, wọ́n ń ka àwọn ìwé tó ń mú ọkàn ẹni fà sí ìṣekúṣe tàbí kí wọ́n máa wo àwọn fíìmù oníṣekúṣe àti oníwà ipa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àwọn míì ń wo àwọn fídíò tàbí sinimá tàbí àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n tó ń mú kí ọkàn ẹni fà sí ìṣekúṣe. Àwọn kan ń lọ sí àwọn ilé fàájì alaalẹ́ àtàwọn ibi táwọn obìnrin ti máa ń bọ́ ara wọn síhòòhò tàbí kí wọ́n lọ sáwọn ilé tí wọ́n ti máa ń wọ́ ara fáwọn èèyàn kí wọ́n lè fọwọ́ pa wọ́n lára.

5. Kí nìdí tó fi yẹ ká fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn wa?

5 Àwọn míì kó sínú ìdẹwò torí pé ẹni tí kò yẹ ni wọ́n fi ṣe alábàárò wọn. Inú ayé táwọn èèyàn ti ń dán oríṣiríṣi ìwà ìṣekúṣe wò là ń gbé, àwọn èèyàn ò sì ní ìkóra-ẹni-níjàánu, torí náà ó rọrùn kí ọkàn tó ń tanni jẹ tó sì ń gbékútà bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ẹlòmíì yàtọ̀ sí ọkọ tàbí aya wa. (Ka Jeremáyà 17:9, 10.) Jésù sọ pé: “Láti inú ọkàn-àyà ni àwọn èrò burúkú ti ń wá, ìṣìkàpànìyàn, panṣágà, àgbèrè.”—Mát. 15:19.

6, 7. (a) Inú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni ọkàn tó ń ṣe àdàkàdekè lè kó èèyàn sí? (b) Kí la lè ṣe ká má bàa pa òfin Jèhófà lórí ìwà rere tì?

6 Bíbélì sọ pé ọkàn ń ṣe àdàkàdekè. Torí náà, tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀ láàárín ẹni méjì tí ọkàn wọn ń fà sí ara wọn, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ́ pé àárín ọkọ tàbí aya wọn nìkan ló yẹ kó mọ. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n á máa wá bí ààyè ṣe máa ṣí sílẹ̀ kí wọ́n lè jọ wà pa pọ̀, wọ́n sì lè dọ́gbọ́n máa mú kí nǹkan pa wọ́n pọ̀ bíi pé ó kàn ṣe kòńgẹ́ ni, á sì máa rí bẹ́ẹ̀ léraléra. Bí ìmọ̀lára tí wọ́n ní fún ara wọn ṣe ń gbóná sí i, bẹ́ẹ̀ ni á ṣe túbọ̀ máa nira fún wọn láti ṣe ohun tó tọ́. Bí wọ́n bá ṣe ń ri ara wọn bọnú ẹ̀ṣẹ̀ lá ṣe túbọ̀ máa ṣòro fún wọn láti jáwọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ̀ pé ohun táwọn ń ṣe burú.—Òwe 7:21, 22.

7 Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, òfin Jèhófà lórí ìwà rere tó yẹ kó dáàbò bò wọ́n á di èyí tí wọ́n pa tì. Ìsọkúsọ àti èròkérò á wá mọ́ wọn lára débi pé wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í di ọwọ́ ara wọn mú, wọ́n á máa fẹnu ko ẹnu, wọ́n á máa dì mọ́ra, wọ́n á máa fọwọ́ pa ara wọn lára àtàwọn ọ̀nà ìfìfẹ́hàn míì. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àárín tọkọtaya nìkan ló yẹ kí gbogbo ìyẹn mọ. Ní paríparí rẹ̀, ìfẹ́ ọkàn wọn á fà wọ́n jáde, á sì ré wọn lọ, bí ìgbà tí ìjẹ ẹnu pàkúté tan ẹranko kan tó fi kó sínú pàkúté. Tí apá ò bá ká ìfẹ́ ọkàn náà mọ́, “a bí ẹ̀ṣẹ̀,” ìyẹn sì ni ìbálòpọ̀ tó máa wáyé láàárín wọn. (Ják. 1:14, 15) Èyí mà bani nínú jẹ́ gan-an o! Àmọ́, wọn ì bá má hùwà ìbàjẹ́ yìí ká ní àwọn méjèèjì fi ìlànà Jèhófà sílò pé kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún ìgbéyàwó. Báwo la ṣe lè máa bọ̀wọ̀ fún ìgbéyàwó?

MÁA TÚBỌ̀ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

8. Báwo ni àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà ṣe máa dáàbò bò wá ká má bàa kó sínú ìwà ìṣekúṣe?

8 Ka Sáàmù 97:10. Tí a ò bá fẹ́ kó sínú ìwà ìṣekúṣe, ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Bá a ṣe ń mọ àwọn ànímọ́ àtàtà tí Ọlọ́run ní, tí à ń sapá láti ‘di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n, tí a sì ń bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́,’ a máa ní okun tẹ̀mí láti kọ “àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo.” (Éfé. 5:1-4) Torí pé àwọn tọkọtaya mọ̀ pé “Ọlọ́run yóò dá àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà lẹ́jọ́,” wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn kí ìgbéyàwó wọn lè ní ọlá, kí ohunkóhun má sì kó ẹ̀gbin bá a.—Héb. 13:4.

9. (a) Kí ni Jósẹ́fù ṣe nígbà tó dojú kọ ìdẹwò láti ṣe ìṣekúṣe? (b) Ẹ̀kọ́ wo ni àpẹẹrẹ Jósẹ́fù kọ́ wa?

9 Àwọn kan tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti fàyè gba ìwà ìṣekúṣe torí pé alábàáṣiṣẹ́ wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n jọ máa ń wà pa pọ̀ lẹ́yìn iṣẹ́. Kódà lẹ́nu iṣẹ́, ohun tó lè kóni sínú ìdẹwò lè wáyé. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Jósẹ́fù rẹwà lọ́mọkùnrin, ó kíyè sí i pé ìyàwó ọ̀gá òun fẹ́ máa fa ojú òun mọ́ra. Ojoojúmọ́ ni ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ ń fojú sọ, tó ń fara sọ. Lọ́jọ́ kan, “ó dì í ní ẹ̀wù mú pé: ‘Sùn tì mí!’” Àmọ́, Jósẹ́fù jára ẹ̀ gbà, ó sì sá lọ. Kí ló mú kí Jósẹ́fù lè dúró digbí lábẹ́ irú ìdẹwò yìí? Ìpinnu tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó ti ṣe pé òun ò ní jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe òun àti Ọlọ́run jẹ́ ló mú kó lè pa ara rẹ̀ mọ́, kó sì di ìṣòtítọ́ rẹ̀ mú. Torí ohun tó ṣe yìí, iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fẹ̀wọ̀n gbára lórí ẹ̀ṣẹ̀ tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀, àmọ́ Jèhófà ò gbàgbé rẹ̀. (Jẹ́n. 39:1-12; 41:38-43) Torí pé a jẹ́ Kristẹni, yálà a wà níbi iṣẹ́ tàbí níbi tí ojú àwọn èèyàn kò ti tó wa, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún àwọn ipò tó lè sún wa sínú ìdẹwò débi tí a fi máa ṣe ìṣekúṣe.

GBÉ ÌWÀ TUNTUN WỌ̀

10. Báwo ni ìwà tuntun ṣe ń dáàbò bò wá ká má bàa kó sínú ìṣekúṣe?

10 Ó ṣe pàtàkì kí tọkọtaya ní “ìwà tuntun,” èyí tí ‘a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin,’ ìdí sì ni pé á jẹ́ kí wọ́n lókun nípa tẹ̀mí. (Éfé. 4:24) Àwọn tí wọ́n gbé ìwà tuntun yìí wọ̀ sọ ẹ̀yà ara wọn di “òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò.” (Ka Kólósè 3:5, 6.) Ohun tó túmọ̀ sí láti sọ ẹ̀yà ara wa di “òkú” ni pé, a gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ tó lágbára ká lè gbéjà ko ìfẹ́ ọkàn tó lè mú kéèyàn ṣe ìṣekúṣe. A gbọ́dọ̀ yẹra fún ohunkóhun tó lè mú kó máa wù wá láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni yàtọ̀ sí ọkọ tàbí aya wa. (Jóòbù 31:1) Bá a ṣe ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nígbèésí ayé wa, a ó mọ béèyàn ṣe lè “fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú,” a ò sì “rọ̀ mọ́ ohun rere.”—Róòmù 12:2, 9.

11. Báwo ni ìwà tuntun ṣe lè fún ìgbéyàwó lókun?

11 Ìwà tuntun máa ń jẹ́ ká mọ “àwòrán Ẹni tí ó dá a,” ìyẹn Jèhófà. (Kól. 3:10) Ìbùkún rẹpẹtẹ ló máa ń yọrí sí tí àwọn tọkọtaya bá di ìṣòtítọ́ wọn mú, tí wọ́n sì fi “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra” wọ ara wọn láṣọ. (Kól. 3:12) Àwọn tọkọtaya tún máa mọwọ́ ara wọn gan-an tí wọ́n bá ń ‘jẹ́ kí àlàáfíà Kristi máa darí ọkàn wọn.’ (Kól. 3:15) Ẹ ò rí i pé ó ṣàǹfààní gan-an tí tọkọtaya bá “ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara [wọn] lẹ́nì kìíní-kejì”! Ó máa fún wọn láyọ̀ tí wọ́n bá ń lo ìdánúṣe láti “bu ọlá fún ara [wọn] lẹ́nì kìíní-kejì.”—Róòmù 12:10.

12. Àwọn ìwà wo lo rò pé ó ṣe pàtàkì tí ìgbéyàwó bá máa láyọ̀?

12 Arákùnrin Sid sọ àwọn ìwà tí wọ́n ń hù nínú ìdílé wọn tó jẹ́ kí òun àti ìyàwó rẹ̀ máa láyọ̀, ó sọ pé: “Ìfẹ́ ló gbawájú jù lọ nínú àwọn ìwà tá à ń sọ dọ̀tun ní gbogbo ìgbà. A tún ti rí i pé ìwà tútù náà ṣe pàtàkì gan-an.” Ìyàwó rẹ̀ tó ń jẹ́ Sonja sọ pé bẹ́ẹ̀ lọ́rọ̀ rí, ó sì fi kún un pé: “Inú rere ṣe pàtàkì. A sì tún sapá láti máa lo ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í fi gbogbo ìgbà rọrùn.”

Ẹ JỌ MÁA SỌ̀RỌ̀ DÁADÁA

13. Kí lohun tó ṣe pàtàkì gan-an tí tọkọtaya bá fẹ́ kí àárín wọn gún, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

13 Tí tọkọtaya bá fẹ́ kí àárín wọn tòrò, ó ṣe pàtàkì pé kí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn máa tuni lára. Ẹ ò rí i pé ó máa burú jáì tí tọkọtaya kan bá ń sọ ọ̀rọ̀ àrífín sí ara wọn, tó sì jẹ́ pé wọn ò jẹ́ sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ sí àjèjì pàápàá! Tí tọkọtaya bá ń sọ ọ̀rọ̀ “kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú” sí ara wọn, ààbò tẹ̀mí tó wà lórí ìgbéyàwó wọn kò ní lágbára mọ́. (Éfé. 4:31) Dípò kí tọkọtaya fi ìgbéyàwó wọn sínú ewu nípa sísọ òkò ọ̀rọ̀ síra wọn tàbí kí wọ́n máa tẹ́ńbẹ́lú ara wọn, ńṣe ló yẹ kí wọ́n jẹ́ onínúure, kí wọ́n yọ́nú síra wọn, kí wọ́n sì máa sọ ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́.—Éfé. 4:32.

14. Àwọn ohun wo ni kò yẹ kí tọkọtaya ṣe?

14 Bíbélì sọ pé “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́” wà. (Oníw. 3:7) Àmọ́ èyí ò túmọ̀ sí pé ká wá dákẹ́ lọ gbári débi pé a ò ní bá ọkọ tàbí aya wa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó pọn dandan. Aya kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé: “Nírú àkókò yìí, téèyàn bá dákẹ́, ó lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá ọkọ tàbí aya rẹ̀.” Ó tún wa sọ síwájú sí i pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn kéèyàn dákẹ́ nígbà tínú ń bí i, kò dáa kéèyàn kàn máa da ọ̀rọ̀ sílẹ̀ torí kínú tó ń bí i lè wálẹ̀. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, o lè ṣèèṣì sọ ohun tó máa ba ọkọ tàbí aya rẹ̀ nínú jẹ́, ńṣe nìyẹn sì tún máa dá kún ìṣòro.” Ní kúkúrú, ohun tá à ń sọ ni pé, tọkọtaya kan ò lè yanjú ìṣòro wọn tí wọ́n bá ń jágbe mọ́ ara wọn tàbí tí wọ́n yan ara wọn lódì. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa túbọ̀ mọwọ́ ara wọn tí wọn ò bá jẹ́ kí èdèkòyédè máa wáyé ní gbogbo ìgbà tàbí kí èdèkòyédè náà wá di iṣu-ata-yán-anyàn-an mọ́ wọn lọ́wọ́.

15. Báwo ni àwọn tọkọtaya ṣe máa ṣe ara wọn lọ́kan tí wọ́n bá jọ ń sọ̀rọ̀ dáadáa?

15 Àwọn tọkọtaya máa túbọ̀ ṣe ara wọn lọ́kan tí wọ́n bá ń sọ èrò wọn àti bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Ohun tá a sọ àti bí a ṣe gbé e kalẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an. Torí náà, sa gbogbo ipá rẹ kí ọ̀rọ̀ tó kún fún oore ọ̀fẹ́ máa jáde lẹ́nu rẹ, yálà nínú ohùn tó o fi sọ̀rọ̀ àtàwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ tó o lò, kódà tínú bá tiẹ̀ ń bí ẹ gan-an. Èyí máa jẹ́ kó rọrùn fún ọkọ tàbí aya rẹ láti tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ. (Ka Kólósè 4:6.) Ọkọ àti aya kan lè fún ìdè ìgbéyàwó wọn lókun tí wọ́n bá jọ ń sọ̀rọ̀ dáadáa. Tí wọ́n sì ń sọ “àsọjáde . . . tí ó dára fún gbígbéniró bí àìní bá ṣe wà, kí [wọ́n] lè fi ohun tí ó ṣeni lóore” fún ara wọn.—Éfé. 4:29.

Tọkọtaya lè fún ìdè ìgbéyàwó wọn lókun tí wọ́n bá jọ ń sọ̀rọ̀ dáadáa (Wo ìpínrọ̀ 15)

Ẹ MÁ ṢE FI Ẹ̀TỌ́ ÌGBÉYÀWÓ DU ARA YÍN

16, 17. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí tọkọtaya máa fiyè sí bí nǹkan ṣe ń rí lára ọkọ tàbí aya wọn, kí wọ́n sì máa fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀?

16 Àwọn tọkọtaya tún lè ṣe ìdè ìgbéyàwó wọn ní alọ́májàá tí wọ́n bá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ọkọ tàbí aya wọn jẹ wọ́n lógún, tí wọ́n sì ń fi ire ọkọ tàbí aya wọn ṣáájú tara wọn. (Fílí. 2:3, 4) Àwọn tọkọtaya ò gbọ́dọ̀ fi bí nǹkan ṣe ń rí lára ọkọ tàbí aya wọn ṣeré, wọ́n sì gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀.—Ka 1 Kọ́ríńtì 7:3, 4.

17 Ó ṣeni láàánú pé àwọn tọkọtaya kan kì í fìfẹ́ hàn síra wọn, wọ́n sì máa ń fi ìbálòpọ̀ du ara wọn. Àwọn ọkùnrin kan tiẹ̀ máa ń sọ pé ọ̀dẹ̀ ọkùnrin ló máa ń gbé obìnrin gẹ̀gẹ̀. Àmọ́, Bíbélì sọ pé: ‘Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá àwọn aya yín gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀.’ (1 Pét. 3:7) Ọkọ kan gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ojúṣe rẹ̀ sí aya rẹ̀ kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ nìkan. Aya máa túbọ̀ fà mọ́ ọkọ rẹ̀ gan-an tó bá rí i pé kì í ṣe ìgbà tí ọkọ òun bá fẹ́ ní ìbálòpọ̀ nìkan ló tó máa ń fi ìfẹ́ hàn sóun tàbí ṣe òun jẹ́jẹ́. Táwọn méjèèjì bá ń gba tara wọn rò, wọ́n á mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wọn, wọ́n á sì gbádùn ìfararora pẹ̀lú ara wọn.

18. Báwo ni tọkọtaya ṣe lè fún ìdè ìgbéyàwó wọn lókun?

18 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí àwíjàre fún ọkọ tàbí aya tó hùwà àìṣòótọ́, tí kò bá sí ìfararora bó ṣe yẹ, ó lè wà lára ohun tó máa mú kí ọkọ tàbí aya wá alábàárò àti ẹni táá fìfẹ́ hàn sí i lọ síta. (Òwe 5:18; Oníw. 9:9) Abájọ tí Bíbélì fi rọ àwọn tọkọtaya pé: “Ẹ má ṣe máa fi [ẹ̀tọ́ ìgbéyàwó] du ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, àyàfi nípasẹ̀ àjọgbà fún àkókò tí a yàn kalẹ̀.” Kí nìdí? “Kí Sátánì má bàa máa dẹ yín wò nítorí àìlèmáradúró yín.” (1 Kọ́r. 7:5) Àjálù ńlá gbáà ló máa jẹ́ tí tọkọtaya bá jẹ́ kí Sátánì wọlé sí wọn lára torí “àìlèmáradúró” wọn, tí ọkọ tàbí aya á fi kó sínú ìdẹwò, táá sì ṣe panṣágà. Àmọ́ tí tọkọtaya bá ń fi ẹ̀tọ́ ẹnì kejì fún un, àwọn méjèèjì kò ní “máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.” Wọ́n á máa fi ẹ̀tọ́ ìgbéyàwó fún ara wọn tìfẹ́tìfẹ́, kò ní jẹ́ torí pé ó di dandan, èyí á sì mú kí wọ́n túbọ̀ ṣe ara wọn lọ́kan.—1 Kọ́r. 10:24.

MÁA DÁÀBÒ BO ÌGBÉYÀWÓ RẸ

19. Kí la gbọ́dọ̀ pinnu láti ṣe, kí sì nìdí?

19 Bèbè ayé tuntun òdodo la wà báyìí. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé tá a bá gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara láyè, àbájáde rẹ̀ lè burú jáì bó ṣe rí fáwọn ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́rìnlélógún [24,000] ọmọ Ísírẹ́lì ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù. Lẹ́yìn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń tini lójú tó sì bani lọ́kàn jẹ́ yẹn, ó wá kìlọ̀ pé: “Kí ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kíyè sára kí ó má bàa ṣubú.” (1 Kọ́r. 10:12) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì nígbà náà pé ká jẹ́ olóòótọ́ sí Baba wa ọ̀run àti sí ọkọ tàbí aya wa, ìyẹn sì máa fún ìdè ìgbéyàwó wa lókun. (Mát. 19:5, 6) Ìsinsìnyí gan-an la ní láti “sa gbogbo ipá [wa] kí òun lè bá [wa] nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà.”—2 Pét. 3:13, 14.