Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Tọkọtaya Ṣe Lè Ṣera Wọn Lọ́kan Kí Wọ́n sì Láyọ̀

Bí Tọkọtaya Ṣe Lè Ṣera Wọn Lọ́kan Kí Wọ́n sì Láyọ̀

“Bí kò ṣe pé Jèhófà tìkára rẹ̀ bá kọ́ ilé náà, lásán ni àwọn tí ń kọ́ ọ ti ṣiṣẹ́ kárakára lórí rẹ̀.”SM. 127:1a.

1-3. Àwọn ìṣòro wo ló ń dojú kọ àwọn tọkọtaya? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

ỌKỌ kan tó ti ń gbádùn ìgbéyàwó rẹ̀ láti ọdún méjìdínlógójì [38] sẹ́yìn sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ló wù ẹ́ kí ìgbéyàwó rẹ yọrí sí rere, tó o sì sa gbogbo ipa rẹ, wàá rí ọwọ́ Jèhófà nínú ìgbéyàwó rẹ.” Ní ti gidi, tọkọtaya lè jọ gbádùn ara wọn, kí wọ́n sì tún dúró ti ara wọn nígbà ìṣòro.—Òwe 18:22.

2 Àmọ́, kò ṣàjèjì pé kí tọkọtaya ní “ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn.” (1 Kọ́r. 7:28) Kí nìdí? Àwọn ìṣòro ojoojúmọ́ lè máà jẹ́ kí nǹkan fara rọ láàárín tọkọtaya. Torí a jẹ́ aláìpé, ahọ́n wa lè dá ìjà sílẹ̀, ó lè dá èdèkòyédè sílẹ̀ tàbí kó mú ká ṣi ọ̀rọ̀ sọ, èyí sì lè fa ìṣòro kódà láàárín àwọn tọkọtaya tí wọ́n mọwọ́ ara wọn dáadáa. (Ják. 3:2, 5, 8) Ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló jẹ́ pé iṣẹ́ tó ń tánni lókun ni wọ́n ń ṣe, ìṣòro ọmọ títọ náà sì tún wà níbẹ̀. Kòókòó jàn-án jàn-án ojoojúmọ́ kì í jẹ́ káwọn tọkọtaya kan ráyè gbọ́ ti ara wọn kí wọ́n lè túbọ̀ ṣe ara wọn lọ́kan. Ìṣòro ìṣúnná owó, àìsàn tàbí àwọn ìṣòro míì lè mú kí ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ tí tọkọtaya ní fún ara wọn dín kù. Yàtọ̀ síyẹn, “àwọn iṣẹ́ ti ara” irú bí àgbèrè, ìwà àìníjàánu, ìṣọ̀tá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, owú, ìrufùfù ìbínú àti asọ̀ lè dá ìṣòro sílẹ̀ láàárín tọkọtaya tó dà bíi pé wọ́n ṣe ara wọn lọ́kan pàápàá.—Gál. 5:19-21.

3 Ohun míì tó tún dá kún ìṣòro yìí ni “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tí a wà yìí, ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan àtàwọn ìwà tí inú Ọlọ́run ò dùn sí ló kún inú ayé, àwọn ìwà yìí sì lè tú ìgbéyàwó ká. (2 Tím. 3:1-4) Paríparí rẹ̀ wá ni pé, ọ̀tá burúkú kan ti pinnu láti máa gbógun ti ìgbéyàwó. Àpọ́sítélì Pétérù kìlọ̀ fún wa pé: “Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.”—1 Pét. 5:8; Ìṣí. 12:12.

4. Kí ló máa ran tọkọtaya lọ́wọ́ tí wọ́n á fi máa láyọ̀ tí wọ́n á sì ṣe ara wọn lọ́kan?

4 Ọkọ kan tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Japan sọ pé: “Àtigbọ́ bùkátà nira fún mi gan-an. Èmi àti ìyàwó mi kì í sì fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ dáadáa, ìyẹn wá jẹ́ kí gbogbo nǹkan tojú sú òun náà. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àìsàn burúkú kan ṣe é. Ńṣe ni Gbogbo wàhálà yìí máa ń mú ká jágbe mọ́ra wa nígbà míì.” Lóòótọ́ a ò lè fẹ́ àwọn ìṣòro kan kù nínú ìgbéyàwó, àmọ́ àwọn ìṣòro yìí lójútùú. Jèhófà lè mú kí tọkọtaya ṣe ara wọn lọ́kan, kí wọ́n sì láyọ̀. (Ka Sáàmù 127:1.) Ẹ jẹ́ ká fi ìgbéyàwó wé ilé, pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn, a máa jíròrò márùn-ún lára ohun tá a lè pè ní búlọ́ọ̀kù tẹ̀mí tó máa mú kí tọkọtaya ṣe ara wọn lọ́kan kí ìgbéyàwó wọn lè wà pẹ́ títí. Àá tún jíròrò bí ìfẹ́ ṣe dà bí sìmẹ́ǹtì tó máa mú kí àárín tọkọtaya túbọ̀ gún régé.

Ẹ JẸ́ KÍ JÈHÓFÀ WÀ NÍNÚ ÌGBÉYÀWÓ YÍN

5, 6. Kí ni tọkọtaya lè máa ṣe táá fi hàn pé wọ́n jẹ́ kí Jèhófà wà nínú ìgbéyàwó wọn?

5 Tí tọkọtaya bá fẹ́ kí òpó ìgbéyàwó wọn dúró digbí, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin sí Ẹni tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rẹ̀. (Ka Oníwàásù 4:12.) Tọkọtaya tó bá gbà kí Jèhófà máa tọ́ àwọn sọ́nà ń fi hàn pé Jèhófà wà nínú ìgbéyàwó wọn. Bíbélì sọ nípa àwọn èèyàn Ọlọ́run láyé àtijọ́ pé: “Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé: ‘Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,’ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ́ sí apá ọ̀tún tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá òsì.” (Aísá. 30:20, 21) Lónìí, tọkọtaya lè “gbọ́” ọ̀rọ̀ Jèhófà tí wọ́n bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa pọ̀. (Sm. 1:1-3) Wọ́n á túbọ̀ wà níṣọ̀kan tí wọ́n bá ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé tó gbádùn mọ́ni tó sì ń gbéni ró déédéé. Ohun mìíràn tó tún ṣe pàtàkì ni pé, kí tọkọtaya jọ máa gbàdúrà lójoojúmọ́ kí ìdè ìgbéyàwó wọn lè lágbára láti dènà ogun tí ayé Sátánì ń gbé ko ìdílé.

Tí tọkọtaya bá ń ṣe àwọn nǹkan tẹ̀mí pa pọ̀, àárín wọn á tòrò, wọ́n á ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, àwọn méjèèjì á sì túbọ̀ fà mọ́ ara wọn (Wo ìpínrọ̀ 5, 6)

6 Gerhard tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé: “Ìgbàkigbà tí ìṣòro tàbí èdèkòyédè bá fẹ́ ba ayọ̀ wa jẹ́, ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti mú ká máa ṣe sùúrù ká sì máa dárí ji ara wa. Àwọn ànímọ́ yìí sì ṣe pàtàkì kí tọkọtaya lè láyọ̀.” Tí tọkọtaya bá jẹ́ kí Jèhófà wà nínú ìgbéyàwó wọn tí wọ́n sì jọ ń ṣe àwọn nǹkan tẹ̀mí pa pọ̀, àárín wọn á tòrò, wọ́n á ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, àwọn méjèèjì á túbọ̀ fà mọ́ ara wọn, ìgbéyàwó wọn á sì lóyin.

Ẹ̀YIN ỌKỌ Ẹ MÁA LO IPÒ ORÍ YÍN TÌFẸ́TÌFẸ́

7. Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn ọkọ máa lo ipò orí wọn?

7 Bí ọkọ bá ṣe ń lo ipò orí rẹ̀ lè pinnu bóyá òun àti ìyàwó rẹ̀ máa láyọ̀ tí wọ́n á sì ṣe ara wọn lọ́kan. Bíbélì sọ pé: “Orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi; ẹ̀wẹ̀, orí obìnrin ni ọkùnrin; ẹ̀wẹ̀, orí Kristi ni Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 11:3) Àwọn ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ débi gbólóhùn yìí fi hàn pé ó yẹ kí ọkọ máa lo ipò orí rẹ̀ bí Kristi ṣe ń lo ipò orí rẹ̀ lórí ọkùnrin. Jésù kì í ṣe òǹrorò, ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ó jẹ́ onínúure àti afòyebánilò, ó tún jẹ́ onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn.—Mát. 11:28-30.

8. Kí ló yẹ kí ọkọ ṣe tí ìyàwó rẹ̀ á fi nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ táá sì máa bọ̀wọ̀ fún un?

8 Àpẹẹrẹ Kristi ló yẹ kí ọkọ máa tẹ̀ lé, kò yẹ kí ọkọ máa sọ fún ìyàwó rẹ̀ léraléra pé ó yẹ kó máa bọ̀wọ̀ fún òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ ló yẹ kí ọkọ máa ṣe, Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní bíbá wọn gbé lọ́nà kan náà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀, kí ẹ máa fi ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí fún ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo.” (1 Pét. 3:7) Tí ọkọ bá ń lo èdè àpọ́nlé fún ìyàwó rẹ̀ tó sì ń fìfẹ́ bá a lò yálà nínú ilé tàbí níta, ńṣe ló ń fi hàn pé ìyàwó òun ṣeyebíye sóun. (Òwe. 31:28) Tí ọkọ bá ń lo ipò orí rẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́ lọ́nà yìí, ìyàwó rẹ̀ á nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, á máa bọ̀wọ̀ fún un, Jèhófà á sì bù kún ìgbéyàwó wọn.

Ẹ̀YIN AYA Ẹ MÁA TẸRÍ BA FÚN ỌKỌ YÍN

9. Báwo ni ìyàwó kan ṣe lè fi hàn pé òun tẹrí ba fún ọkọ òun?

9 Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn, tá a sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀, ó máa jẹ́ ká lè rẹ ara wa sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Jèhófà. (1 Pét. 5:6) Ọ̀nà pàtàkì kan tí aya tó tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀ lè fi hàn pé òun bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ Jèhófà ni pé kí ó máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, kí ó sì jẹ́ alátìlẹyìn fún un. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ nínú Olúwa.” (Kól. 3:18) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ó lè máà jẹ́ gbogbo ìpinnu tí ọkọ bá ṣe ni ìyàwó máa fara mọ́. Síbẹ̀, tí ìpinnu tí ọkọ ṣe kò bá ti tako òfin Jèhófà, aya tó ní ìtẹríba máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀.—1 Pét. 3:1.

10. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí aya fi tìfẹ́tìfẹ́ tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀?

10 Ipò iyì ni Jèhófà fi àwọn aya sí nínú ìdílé, òun ni “ẹnì kejì” ọkọ rẹ̀ tàbí alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀. (Mál. 2:14) Tí tọkọtaya bá fẹ́ ṣe ìpinnu, ìyàwó lè fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ èrò rẹ̀, síbẹ̀ kó ṣì fi hàn pé òun tẹrí ba fún ọkọ òun. Ńṣe ni ọkọ tó gbọ́n máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí ìyàwó rẹ̀. (Òwe 31:10-31) Tí aya bá ń fi tìfẹ́tìfẹ́ tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀, wọ́n á láyọ̀, àlàáfíà àti ìṣọ̀kan á wà nínú ìdílé wọn, ọkàn àwọn méjèèjì á sì balẹ̀ pé àwọn ń ṣe ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí.—Éfé. 5:22.

Ẹ MÁA DÁRÍ JI ARA YÍN FÀLÀLÀ

11. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí tọkọtaya máa dárí ji ara wọn?

11 Ọ̀kan lára búlọ́ọ̀kù tẹ̀mí tó ṣe pàtàkì kí ìgbéyàwó lè wà pẹ́ títí ni ìdáríjì. Ìdè ìgbéyàwó túbọ̀ máa lágbára tí tọkọtaya bá ń ‘fara dà á fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì, tí wọ́n sì ń dárí ji ara wọn fàlàlà.’ (Kól. 3:13) Tí ọkọ àti ìyàwó bá ń di ara wọn sínú, tí wọ́n wá ń ránró ohun tí ẹnì kejì ṣe fún wọn, ìdè ìgbéyàwó yẹn kò ní lágbára. Bó ṣe jẹ́ pé tí ògiri bá ti sán kò ní lágbára mọ́, bẹ́ẹ̀ ná ló ṣe jẹ́ pé tí tọkọtaya bá ń di ara wọn sínú, ó máa nira fún wọn láti máa dárí ji ara wọn. Àmọ́, tí tọkọtaya bá ń dárí ji ara wọn bí Jèhófà ṣe ń dárí jì wọ́n, ìdè ìgbéyàwó wọn máa lágbára gan-an.—Míkà 7:18, 19.

12. Báwo ni ìfẹ́ ṣe máa ń bo “ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀”?

12 Ìfẹ́ tòótọ́ “kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.” Kódà, “ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” (1 Kọ́r. 13:4, 5 ; ka 1 Pétérù 4:8.) Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé ìfẹ́ kì í ka ẹ̀ṣẹ̀ síni lọ́rùn. Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù bi Jésù pé ẹ̀ẹ̀melòó lò yẹ kóun dárí jini, Jésù sọ fún un pé: “Títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje.” (Mát. 18:21, 22) Ohun tí Jésù ń sọ ni pé Kristẹni kan ò gbọ́dọ̀ máa ka iye ìgbà tó lè dárí jini.—Òwe 10:12. *

13. Kí ló máa mú kó rọrùn fún tọkọtaya láti máa dárí ji ara wọn?

13 Annette sọ pé: “Tí tọkọtaya kì í bá dárí ji ara wọn, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í di ara wọn sínú wọn ò sì ní fọkàn tán ara wọn mọ́, èyí sì lè da ìgbéyàwó wọn rú. Àmọ́, tí tọkọtaya bá ń dárí ji ara wọn, wọ́n á túbọ̀ fà mọ́ ara wọn, ìgbéyàwó wọn á sì tọ́jọ́.” Torí náà, tí ẹ bá ń sapá láti ní ẹ̀mí ìmoore, tẹ́ ẹ sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹnì kejì yín fún ohun tó ṣe, á rọrùn fún yín láti máa dárí ji ara yín. Ẹ jẹ́ kó mọ́ ọn yín lára láti máa gbóríyìn fún ara yín látọkàn wá. (Kól. 3:15) Tẹ́ ẹ bá ń dárí ji ara yín, ẹ máa ní ìbàlẹ̀ ọkàn, ẹ máa wà níṣọ̀kan, kódà Jèhófà á bù kún yín torí ó máa ń bù kún àwọn tó lẹ́mìí ìdáríjì.—Róòmù 14:19.

Ẹ MÁA FI ÌLÀNÀ PÀTÀKÌ NÁÀ SÍLÒ

14, 15. Kí ni Ìlànà Pàtàkì náà, kí sì nìdí tó fi yẹ kí tọkọtaya máa fi ìlànà yìí sílò?

14 Gbogbo wa la máa ń fẹ́ káwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún wa kí wọ́n sì pọ́n wa lé. A máa ń fẹ́ káwọn èèyàn tẹ́tí sí wa kí wọ́n sì gba tiwa rò. Àmọ́, ǹjẹ́ o ti gbọ́ ọ rí kí ẹnì kan sọ pé, “Màá ṣe tèmi pa dà, màá jẹ́ kó mọ bó ṣe máa ń rí lára”? Kò sẹ́ni tí irú èrò yìí ò lè wá sọ́kàn ẹ̀ nígbà míì, àmọ́ Bíbélì ní: “Má sọ pé: ‘Gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí mi gan-an, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe sí i.’” (Òwe 24:29) Kódà, Jésù sọ ọ̀nà tó dáa jù tí a lè gbà yanjú àwọn ìṣòro tó bá jẹ yọ. Ó mẹ́nu kan Ìlànà Pàtàkì tí a lè fi sílò, àwọn kan sábà máa ń pè é ní Òfin Oníwúrà, Jésù sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.” (Lúùkù 6:31) Ohun tí Jésù ń sọ ni pé ohun tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí wa ni káwa náà ṣe sí wọn, a kò sì gbọ́dọ̀ foró yaró. Ìlànà yìí wúlò nínú ìgbéyàwó, ohun tó o bá ti fẹ́ kí ọkọ tàbí aya rẹ ṣe fún ẹ ni kí ìwọ náà máa ṣe sí i.

15 Ìdè ìgbéyàwó tọkọtaya máa túbọ̀ lágbára tí wọ́n bá ń fiyè sí bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹnì kejì wọn. Ọkọ kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè South Africa sọ pé: “A ti gbìyànjú láti máa fi Ìlànà Pàtàkì yìí sílò. Lóòótọ́, inú lè bí àwa méjèèjì nígbà míì, àmọ́ ohun tí mo fẹ́ kí ìyàwó mi ṣe fún mi lèmi náà máa gbìyànjú láti ṣe sí i, a máa ń bọ̀wọ̀ fún ara wa a sì máa ń ṣàpọ́nlé ara wa.”

16. Kí ni tọkọtaya kò gbọ́dọ̀ ṣe fún ara wọn?

16 Má ṣe máa sọ kùdìẹ̀-kudiẹ ọkọ tàbí aya rẹ fáwọn èèyàn, má sì máa ṣàròyé nípa àwọn ìwà rẹ̀ tó máa ń bí ẹ nínú, má tiẹ̀ fi ṣẹ̀fẹ̀ rárá. Rántí pé ìgbéyàwó kì í ṣe ìdíje kéèyàn lè mọ ẹni tó lágbára jù, tó lè pariwo jù tàbí ẹni tí ẹnu rẹ̀ mú jù. Ká sòótọ́, gbogbo wa la ní kùdìẹ̀-kudiẹ tiwa, a sì lè ṣe ohun tó máa bí àwọn míì nínú nígbà míì. Àmọ́, kò sí ìdí kankan tó fi yẹ kí tọkọtaya máa sọ̀rọ̀ burúkú sí ara wọn tàbí ọ̀rọ̀ tí ń buni kù, wọn ò gbọ́dọ̀ bínú débi tí wọ́n á fi ti ara wọn tàbí kí wọ́n gbá ara wọn.—Ka Òwe 17:27; 31:26.

17. Báwo ni ọkọ ṣe lè fi Ìlànà Pàtàkì náà sílò?

17 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé láwọn àṣà kan, tí ọkọ bá lu ìyàwó rẹ̀ wọ́n á ní ṣe ló fi hàn pé ọkùnrin lòun, àmọ́ Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú sàn ju alágbára ńlá, ẹni tí ó sì ń ṣàkóso ẹ̀mí rẹ̀ sàn ju ẹni tí ó kó ìlú ńlá.” (Òwe 16:32) Ó gba ìsapá gan-an kéèyàn tó lè fara wé Jésù Kristi, kéèyàn sì máa kápá ìbínú rẹ̀. Ọkùnrin tó bá ń sọ òkò ọ̀rọ̀ sí ìyàwó rẹ̀ tàbí tó ń lù ú kì í ṣe ọkùnrin gidi, àjọṣe tó ní pẹ̀lú Jèhófà sì máa bà jẹ́. Onísáàmù náà, Dáfídì tó jẹ́ akíkanjú ọkùnrin àti onígboyà sọ pé: “Kí inú yín ru, ṣùgbọ́n ẹ má ṣẹ̀. Ẹ sọ ohun tí ẹ ní í sọ ní ọkàn-àyà yín, lórí ibùsùn yín, kí ẹ sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.”—Sm. 4:4.

‘Ẹ FI ÌFẸ́ WỌ ARA YÍN LÁṢỌ’

18. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí tọkọtaya máa fi ìfẹ́ hàn síra wọn?

18 Ka 1 Kọ́ríńtì 13:4-7. Ìfẹ́ ló ṣe pàtàkì jù nínú ìgbéyàwó. Bíbélì sọ pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ. Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kól. 3:12, 14) Àwọn tọkọtaya gbọ́dọ̀ ní irú ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan tí Kristi ní, ìfẹ́ yìí ló dà bí sìmẹ́ǹtì tó máa jẹ́ kí àwọn búlọ́ọ̀kù tẹ̀mí náà lẹ̀ pọ̀ mọ́ra kí ìgbéyàwó wọn lè wà pẹ́ títí. Ìgbéyàwó wọn á dúró digbí kódà bí ọkọ tàbí aya bá ní àwọn ìwà tó ń bí ẹnì kejì rẹ̀ nínú, tí àìsàn ò jẹ́ kí wọ́n gbádùn ara wọn tàbí tí wọ́n ní ìṣòro ìṣúnná owó tàbí tí àárín àwọn àtàwọn àna wọn kò gún.

19, 20. (a) Báwo làwọn tọkọtaya ṣe lè ṣera wọn lọ́kan kí wọ́n sì máa láyọ̀ nínú ìgbéyàwó wọn? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?

19 Òótọ́ ni pé kí ìgbéyàwó kan tó lè ṣàṣeyọrí, ó gba kí tọkọtaya ní ìfẹ́ àtọkànwá síra wọn, kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ síra wọn, kí wọ́n sì máa ṣe gbogbo ohun ti wọ́n lè ṣe. Dípò kí tọkọtaya pa ara wọn tì nígbà tí wọ́n bá níṣòro, ńṣe ló yẹ kí wọ́n pinnu pé àwọn á mú kí àárín àwọn máa gún sí i lójoojúmọ́. Kì í ṣe pé kí wọ́n kàn jọ máa gbé ṣá, ó yẹ kí tọkọtaya Kristẹni pinnu láti túbọ̀ fà mọ́ ara wọn. Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà àti fún ara wọn máa mú kí wọ́n sapá láti yanjú ìṣòro èyíkéyìí tí wọ́n bá ní, torí “ìfẹ́ kì í kùnà láé.”—1 Kọ́r. 13:8; Mát. 19:5, 6; Héb. 13:4.

20 Ó ṣòro gan-an káwọn tọkọtaya tó lè ṣera wọn lọ́kan kí wọ́n sì máa láyọ̀ pàápàá ní “àwọn àkókò lílekoko” tí à ń gbé yìí. (2 Tím. 3:1) Àmọ́, Jèhófà lè mú kó ṣeé ṣe. Ìṣòro míì tí tọkọtaya tún ni láti kojú ni ìṣekúṣe tó kúnnú ayé yìí. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e máa jẹ́ ká mọ bí tọkọtaya ṣe lè dáàbò bo ìdílé wọn lọ́wọ́ ìṣekúṣe.

^ ìpínrọ̀ 12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí tọkọtaya máa dárí ji ara wọn kí wọ́n sì yanjú ìṣòro tí wọ́n bá ní, Bíbélì fàyè gbà á kí ẹnì kan pinnu yálà láti dárí ji ọkọ tàbí aya tó ṣe panṣágà tàbí kó kọ̀ ọ́ sílẹ̀. (Mát. 19:9) Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ojú-Ìwòye Bibeli: Panṣágà—Ṣé Kí N Dáríjì Í Tàbí Kí Ń Máṣe Dáríjì Í?” nínú Jí! August 8, 1995.