Se Waa “Maa Ba A Niso Ni Sisona”?
“Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.”—MÁT. 25:13.
1, 2. (a) Kí ni Jésù jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?
OHUN mánigbàgbé ló máa jẹ́ ká sọ pé o wà níjòókòó lọ́dọ̀ Jésù lórí Òkè Ólífì, tó ń sọ ọ̀kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tó fa kíki jù lọ bó ṣe ń wo tẹ́ńpìlì tó wà nílùú Jerúsálẹ́mù lọ́ọ̀ọ́kán. Pétérù, Áńdérù, Jákọ́bù àti Jòhánù tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ bí Jésù ṣe ń sọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ó sọ ọ̀pọ̀ nǹkan fún wọn nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò nǹkan búburú yìí, ìyẹn àkókò tí òun yóò ṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run. Ó sọ fún wọn pé lákòókò òpin yẹn, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” yóò máa ṣojú fún òun lórí ilẹ̀ ayé, kó lè máa fún àwọn ìránṣẹ́ òun ní oúnjẹ tẹ̀mí tí wọ́n nílò lásìkò tó yẹ.—Mát. 24:45-47.
2 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù ń sọ bọ̀ yìí, ó sọ àkàwé kan nípa àwọn wúńdíá mẹ́wàá. (Ka Mátíù 25:1-13.) Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ìbéèrè yìí: (1) Kí ni kókó pàtàkì inú àkàwé náà? (2) Báwo ni àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ olóòótọ́ ṣe fi ìmọ̀ràn tó wà nínú àkàwé náà sílò, kí sì ni àbájáde rẹ̀? (3) Báwo lẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè jàǹfààní látinú àkàwé yìí lóde òní?
KÍ NI KÓKÓ PÀTÀKÌ INÚ ÀKÀWÉ NÁÀ?
3. Láwọn ìgbà tó ti kọjá, báwo làwọn ìtẹ̀jáde wa ṣe ṣàlàyé àkàwé wúńdíá mẹ́wàá, kí ló sì ṣeé ṣe kí èyí ti yọrí sí?
3 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, a mẹ́nu bà á pé láti ẹ̀wádún mélòó kan sẹ́yìn ló ti jẹ́ pé tí ẹrú olóòótọ́ náà bá ń ṣàlàyé Ìwé Mímọ́, kì í sábà ṣàlàyé rẹpẹtẹ lórí àwọn apá tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, kàkà bẹ́ẹ̀, bá a ṣe lè fi àwọn ẹ̀kọ́ náà sílò nínú ìgbésí ayé wa ló sábà máa ń sọ. Láwọn ìgbà kan sẹ́yìn, ìtẹ̀jáde wa máa ń sọ ìtúmọ̀ pàtó ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn nǹkan tí Jésù mẹ́nu bà nínú àkàwé tó ṣe nípa àwọn wúńdíá mẹ́wàá túmọ̀ sí, àní títí dórí fìtílà, òróró, àwọn kòlòbó tí wọ́n ń da òróró sí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àmọ́, ǹjẹ́ kò ṣeé ṣe kí gbogbo èyí ti mú ká máa yí àfiyèsí kúrò lórí ẹ̀kọ́ pàtàkì tó yẹ ká dì mú, ká sì tètè fi sílò nínú àkàwé yìí? Bí a ó ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, ìdáhùn ìbéèrè yìí ṣe pàtàkì gan-an.
4. Nínú àkàwé yìí, báwo la ṣe lè fòye mọ (a) ọkọ ìyàwó náà? (b) àwọn wúńdíá náà?
4 Ẹ jẹ́ ká wo kókó pàtàkì tí Jésù fẹ́ fà yọ nínú àkàwé yìí. Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ ká wo àwọn tí àkàwé náà dá lé. Ta ni ọkọ ìyàwó inú àkàwé yìí? Ohun tí Jésù sọ fi hàn kedere pé, ara rẹ̀ ló ń tọ́ka sí. Kódà nínú ọ̀rọ̀ míì tó sọ, ó pe ara rẹ̀ ní ọkọ ìyàwó! (Lúùkù 5:34, 35) Àwọn wúńdíá náà ńkọ́? Nínú àkàwé yìí, Jésù sọ pé àwọn wúńdíá náà gbọ́dọ̀ wà ní sẹpẹ́ kí fìtílà wọn sì wà ní títàn nígbà tí ọkọ ìyàwó bá dé. Ẹ kíyè sí ìtọ́sọ́nà tó jọra tí Jésù fún “agbo kékeré” rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn, ó ní: “Ẹ wọ aṣọ, kí àwọn fìtílà yín sì máa jó, kí ẹ̀yin fúnra yín sì dà bí àwọn ọkùnrin tí ń dúró de ọ̀gá wọn nígbà tí ó padà dé láti ibi ìgbéyàwó.” (Lúùkù 12:32, 35, 36) Bákan náà, Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti àpọ́sítélì Jòhánù láti fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn wé àwọn wúńdíá tó níwà mímọ́. (2 Kọ́r. 11:2; Ìṣí. 14:4) Torí náà, ó ṣe kedere pé ìmọ̀ràn àti ìkìlọ̀ ni Jésù fi àkàwé inú ìwé Mátíù 25:1-13 ṣe fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn.
5. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ ká mọ àkókò tí àkàwé yìí máa ṣẹ?
5 Ohun míì tó yẹ ká mọ̀ ni àkókò tí àkàwé náà máa ṣẹ. Ìgbà wo ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù máa fi ìmọ̀ràn tó fún wọn sílò? Jésù mẹ́nu ba àkókò kan pàtó lápá ìparí àkàwé náà nígbà tó ní: “Ọkọ ìyàwó dé.” (Mát. 25:10) Bá a ṣe jíròrò rẹ̀ nínú Ilé Ìṣọ́ July 15, 2013, ìgbà mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jésù sọ̀rọ̀ nípa ‘dídé’ rẹ̀ nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Mátíù orí 24 àti 25, irú ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan náà sì ni wọ́n lò nígbà mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ. Ìgbà ìpọ́njú ńlá tí Jésù máa wá ṣèdájọ́ àwọn èèyàn, tó sì máa pa ayé búburú yìí run ni ìgbà mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ ń tọ́ka sí. Nígbà náà, láìsí àní-àní, àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ni àkàwé yìí bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ, àmọ́ yóò ṣẹ tán pátápátá nígbà ìpọ́njú ńlá.
6. Tá a bá fojú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ kó tó ṣe àkàwé yìí wò ó, kí ni kókó pàtàkì inú àkàwé náà?
6 Kí ni kókó pàtàkì inú àkàwé náà? Jẹ́ ká wo ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ kó tó ṣe àkàwé yìí. Ọ̀rọ̀ nípa “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” rẹ̀ ló ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán. Ẹrú yìí jẹ́ àwùjọ kéréje àwọn ọkùnrin tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn, tí yóò máa múpò iwájú láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Jésù kìlọ̀ fáwọn ọkùnrin yìí pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti jẹ́ adúróṣinṣin. Lẹ́yìn náà, ó darí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ́dọ̀ gbogbo àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn, ìyẹn ló fi sọ àkàwé yìí láti gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n “máa báa nìṣó ní ṣíṣọ́nà,” àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ wọ́n lè pàdánù èrè wọn tó ṣeyebíye. (Mát. 25:13) Ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa àkàwé náà, ká sì rí báwọn ẹni àmì òróró ṣe fi ìmọ̀ràn inú rẹ̀ sílò.
BÁWO LÀWỌN ẸNI ÀMÌ ÒRÓRÓ ṢE FI ÌMỌ̀RÀN INÚ ÀKÀWÉ NÁÀ SÍLÒ?
7, 8. (a) Ohun méjì wo ló jẹ́ kí àwọn wúńdíá olóye náà lè wà ní ìmúrasílẹ̀? (b) Báwo làwọn ẹni àmì òróró ṣe fi hàn pé àwọn wà ní ìmúrasílẹ̀?
7 Àkàwé tí Jésù ṣe jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn wúńdíá tí wọ́n jẹ́ olóye ti múra sílẹ̀, wọ́n sì ń retí ọkọ ìyàwó, wọn ò dà bí àwọn wúńdíá òmùgọ̀ náà. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n ṣe ohun méjì yìí: wọ́n múra sílẹ̀, wọ́n sì wà lójúfò. Kí àwọn wúńdíá yìí tó lè ṣọ́nà ní gbogbo òru láti mọ ìgbà tí ọkọ ìyàwó máa dé, wọ́n gbọ́dọ̀ rí i pé iná fìtílà wọn ò kú, wọ́n sì gbọ́dọ̀ wà lójúfò fún ọ̀pọ̀ wákàtí títí ohun ayọ̀ tí wọ́n ń retí fi máa ṣẹlẹ̀. Àwọn wúńdíá márùn-ún ya òmùgọ̀, àmọ́ àwọn márùn-ún tó kù múra sílẹ̀ dáadáa, yàtọ̀ sí òróró tó wà nínú fìtílà wọn tó ń jó, wọ́n tún fi kòlòbó wọn gbé òróró díẹ̀ sí i dání. Ǹjẹ́ àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró náà fi hàn pé àwọn wà ní ìmúrasílẹ̀?
8 Wọ́n múra sílẹ̀ dáadáa! Jálẹ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe bíi tàwọn wúńdíá olóye, ní ti pé wọ́n múra sílẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wọn lọ́wọ́ títí dé òpin láìkù-síbì-kan. Wọ́n mọ̀ pé káwọn tó lè jẹ́ olóòótọ́, àwọn gbọ́dọ̀ yááfì èyí tó pọ̀ jù lára àwọn nǹkan tara inú ayé Sátánì, wọ́n sì gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ti Jèhófà ni wọ́n ń fi gbogbo ayé wọn gbọ́, kì í sì í ṣe torí ọjọ́ kan pàtó tí Ọlọ́run dá láti ṣèdájọ́ ni wọ́n fi ń sìn ín bí kò ṣe ìfẹ́ tí wọ́n ní sí i àti bó ṣe ń wù wọ́n láti jẹ́ olóòótọ́ sí òun àti Ọmọ rẹ̀. Wọn ò yẹsẹ̀ rárá, wọn ò sì jẹ́ kí ẹ̀mí ayé, ìfẹ́ ọrọ̀, ìṣekúṣe àti ìmọtara-ẹni-nìkan tó gbayé kan kó èèràn ràn wọ́n. Nípa bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n múra sílẹ̀, tí wọ́n ń tàn bí ìmọ́lẹ̀ nígbà gbogbo, wọn kò sì jẹ́ kí bó ṣe dà bíi pé ọkọ ìyàwó náà pẹ́ dé mú kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì lọ́nàkọnà.—Fílí. 2:15.
9. (a) Ìkìlọ̀ wo ni Jésù ṣe nípa bí ẹnì kan ṣe lè di ẹni tó ń tòògbé? (b) Kí làwọn ẹni àmì òróró ti ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ igbe to ta pé: “Ọkọ ìyàwó ti dé”? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
9 Ànímọ́ kejì tó mú káwọn wúńdíá náà lè múra sílẹ̀ dáadáa ni bí wọn ṣe wà lójúfò. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí oorun gbé ẹnikẹ́ni lọ lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró láàárín àkókò gígùn tá a retí pé kí wọ́n fi ṣọ́nà lóru? Bẹ́ẹ̀ ni. Kíyè sí ohun tí Jésù sọ nípa àwọn wúńdíá mẹ́wàá náà, ó ní: Nígbà tí ọkọ ìyàwó kò tètè dé “gbogbo wọn tòògbé, wọ́n sì sùn lọ.” Jésù mọ̀ pé bẹ́nì kan tiẹ̀ fẹ́ ṣe ohun tí ó tọ́ tó sì wù ú gan-an, àìpé ṣì lè ṣàkóbá fún un. Àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró ti fetí sí ìkìlọ̀ yìí, wọ́n sì ti ṣiṣẹ́ kára láti rí i dájú pé àwọn wà lójúfò, àwọn sì ń ṣọ́nà. Nínú àkàwé yìí, gbogbo àwọn wúńdíá náà ló ta jí, tí wọ́n sì dáhùn nígbà tí igbe ta lóru pé: “Ọkọ ìyàwó ti dé!” Àmọ́ ìwọ̀nba àwọn tó wà lójúfò ló fara dà á títí dé òpin. (Mát. 25:5, 6; 26:41) Àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró òde òní ńkọ́? Jálẹ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí àwọn ẹ̀rí tó dájú tí wọ́n rí tó dà bí igbe tó ta pé, “Ọkọ ìyàwó ti dé,” ìyẹn àwọn àmì tó ń fi hàn pé ó ti fẹ́rẹ̀ dé. Wọ́n tún lo ìfaradà ní ti pé gbogbo ìgbà ni wọ́n múra sílẹ̀ de Ọkọ ìyàwó tó ń bọ̀ náà. * Àmọ́ o, àárín àkókò míì tó ṣe pàtó ni lájorí ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé nínú àkàwé náà máa ní ìmúṣẹ. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
ÈRÈ ÀWỌN OLÓYE ÀTI ÌYÀ ÀWỌN ÒMÙGỌ̀
10. Ìbéèrè tó rúni lójú wo ló jẹ yọ nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó wáyé láàárín àwọn òmùgọ̀ wúńdíá àtàwọn wúńdíá olóye?
10 Apá ìparí àkàwé náà lè fẹ́ rúni lójú Mátíù 25:8, 9.) Ọ̀rọ̀ tí wọ́n jọ sọ mú kí ìbéèrè yìí wáyé: “Ìgbà wo nínú ìtàn àwọn èèyàn Ọlọ́run ni àwọn olóòótọ́ náà kọ̀ jálẹ̀ láti ṣèrànwọ́ fáwọn tó nílò rẹ̀?” A máa rí ojútùú sí ohun tó rúni lójú yìí tá a bá tún wo sáà àkókò tí àkàwé náà ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ẹ rántí òye tó ṣe kedere tá a ní báyìí pé apá ìparí ìpọ́njú ńlá náà ni Jésù tó jẹ́ Ọkọ ìyàwó dé láti ṣe ìdájọ́. Nígbà náà, ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tó máa ṣẹlẹ̀ gẹ́rẹ́ kí ìdájọ́ yẹn tó wáyé ni apá yìí nínú àkàwé náà ń tọ́ka sí? Ó ṣeé ṣe kó rí bẹ́ẹ̀ torí pé tó bá fi máa di àkókò yẹn, àwọn ẹni àmì òróró yóò ti gba èdìdì ìkẹyìn wọn.
díẹ̀, ìyẹn ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó wáyé láàárín àwọn òmùgọ̀ wúńdíá àtàwọn wúńdíá olóye. (Ka11. (a) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ gẹ́rẹ́ kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀? (b) Kí ni àwọn wúńdíá olóye náà ní lọ́kàn tí wọ́n fi sọ fún àwọn òmùgọ̀ wúńdíá pé kí wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń ta òróró?
11 Ṣáájú kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀, gbogbo àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró tó wà láyé yóò ti gba èdìdì ìkẹyìn. (Ìṣí. 7:1-4) Láti ìgbà yẹn ló ti dájú pé wọ́n ń lọ sọ́run. Àmọ́ àwọn ọdún tí wọ́n máa gbé ṣáájú kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀ ńkọ́? Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹni àmì òróró tó kùnà láti máa ṣọ́nà tàbí tí wọ́n di aláìṣòótọ́? Wọ́n máa pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti lọ sí ọ̀run. Ó ṣe kedere pé, wọn ò ní gba èdìdì ìkẹyìn kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀. Ní àkókò yẹn, Jèhófà máa fẹ̀mí yan àwọn míì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. Nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀, ó lè bá irú àwọn òmùgọ̀ bẹ́ẹ̀ lójijì nígbà tí wọ́n bá rí i tí Bábílónì Ńlá pa run. Ó lè jẹ́ pé àsìkò yẹn ni wọ́n á ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí i pé àwọn ò múra sílẹ̀ de ìgbà tí Ọkọ ìyàwó máa dé. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé àsìkò tí nǹkan ti bọ́ sórí yẹn ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá ìrànlọ́wọ́? A rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú àkàwé Jésù. Àwọn wúńdíá olóye náà kò fún àwọn òmùgọ̀ wúńdíá náà ni òróró, ńṣe ni wọ́n sọ fún wọn pé kí wọ́n lọ ra tiwọn lọ́dọ̀ àwọn tó ń ta òróró. Ẹ má sì gbàgbé pé “ọ̀gànjọ́ òru” ni àkókò náà. Ṣé wọ́n máa rí ẹni tó máa ta òróró fún wọn lọ́gànjọ́ òru? Rárá o. Ẹ̀pa kò ní bóró mọ́ fún wọn.
12. (a) Nígbà ìpọ́njú ńlá, ìṣẹ̀lẹ̀ tó burú jáì wo ló máa dé bá ẹnikẹ́ni tí Ọlọ́run ti fẹ̀mí yàn àmọ́ tó di aláìṣòótọ́ kó tó di ìgbà èdìdì ìkẹyìn? (b) Kí ló máa jẹ́ ìgbẹ̀yìn àwọn tí wọ́n fi hàn pé àwọn dà bí àwọn òmùgọ̀ wúńdíá náà?
12 Bíi táwọn wúńdíá olóye náà, àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró kò ní lè ran ẹnikẹ́ni tó di aláìṣòótọ́ lọ́wọ́ nígbà ìpọ́njú ńlá náà. Kò sí ẹnikẹ́ni tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọ̀ràn wọn ti kọjá àtúnṣe. Ibo wá ni ọ̀rọ̀ wọn máa jálẹ̀ sí? Jésù sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn òmùgọ̀ wúńdíá náà jáde lọ ra òróró, ó ní: “Ọkọ ìyàwó dé, àwọn wúńdíá tí wọ́n sì ti gbára dì wọlé pẹ̀lú rẹ̀ síbi àsè ìgbéyàwó náà; a sì ti ilẹ̀kùn.” Tí Kristi bá dé nínú ògo rẹ̀ ní apá ìparí ìpọ́njú ńlá náà, yóò kó àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró rẹ̀ lọ sí ọ̀run. (Mát. 24:31; 25:10; Jòh. 14:1-3; 1 Tẹs. 4:17) Ilẹ̀kùn máa tì mọ́ àwọn aláìṣòótọ́ tí wọ́n fi hàn pé àwọn dà bí àwọn òmùgọ̀ wúńdíá náà. Èyí lè jẹ́ kí wọ́n máa kígbe pé: “Ọ̀gá, Ọ̀gá, ṣílẹ̀kùn fún wa!” Àmọ́, ìdáhùn tí wọ́n máa gbà máa dà bí èyí táwọn ẹni bí ewúrẹ́ máa gbà nígbà ìdájọ́ pé: “Mo sọ òtítọ́ fún yín, èmi kò mọ̀ yín.” Ó má ṣe o!—Mát. 7:21-23; 25:11, 12.
13. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká parí èrò pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi máa di aláìṣòótọ́? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jésù fọkàn tán àwọn ẹni àmì òróró rẹ̀ látinú ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ tó sọ fún wọn? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
13 Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí, kí la lè parí èrò sí? Ǹjẹ́ ohun tí Jésù ń sọ ni pé èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ìránṣẹ́ òun tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn ló máa di aláìṣòótọ́, tó sì máa gba pé kí òun fi ẹlòmíì pààrọ̀ wọn? Rárá o. Ẹ rántí pé, ńṣe ló ṣẹ̀ṣẹ̀ kìlọ̀ fún “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pé kó má ṣe di ẹrú burúkú. Ìyẹn ò sọ pé Jésù retí pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀. Bákan náà, Hébérù 6:4-9; fi wé Diutarónómì 30:19.) Ẹ kíyè sí i pé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí sojú abẹ níkòó, àmọ́ ọ̀rọ̀ onífẹ̀ẹ́ tó sọ tẹ̀ lé e fi hàn pé ó fọkàn tán àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ̀ pé wọ́n máa gba “ohun dídárajù” tó wà níwájú fún wọn. Lọ́nà kan náà, ńṣe ni ìkìlọ̀ tí Jésù fi àkàwé àwọn wúńdíá mẹ́wàá náà ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù fọkàn tán àwọn ẹni àmì òróró. Ó mọ̀ pé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ òun lè máa bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́, kí wọ́n sì gba ère àgbàyanu náà!
Jésù fi àkàwé yìí ṣe ìkìlọ̀ kan tó gbàfiyèsí. Bó ṣe jẹ́ pé àwọn wúńdíá márùn-ún jẹ́ òmùgọ̀ táwọn márùn-ún míì sì jẹ́ olóye, àwọn ẹni àmì òróró ní òmìnira láti yàn bóyá wọ́n máa wà ní ìmúrasílẹ̀ tí wọ́n á sì wà lójúfò tàbí wọ́n máa hùwà òmùgọ̀ àti aláìṣòótọ́. Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ ohun kan náà nígbà tó ń kọ̀wé sáwọn Kristẹni táwọn náà jẹ́ ẹni àmì òróró. (KaBÁWO NI ÀWỌN “ÀGÙNTÀN MÌÍRÀN” TI KRISTI ṢE LÈ JÀǸFÀÀNÍ?
14. Kí nìdí tí àwọn “àgùntàn mìíràn” náà fi lè jàǹfààní látinú àkàwé àwọn wúńdíá mẹ́wàá náà?
14 Ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ kankan wà tí àwọn “àgùntàn mìíràn” lè kọ́ nínú àkàwé náà? (Jòh. 10:16) Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ má gbàgbé pé ẹ̀kọ́ pàtàkì inú àkàwé náà kò lọ́jú pọ̀ rárá: Ẹ “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” Ǹjẹ́ àwọn ẹni àmì òróró nìkan ni ọ̀rọ̀ yìí kàn? Jésù sọ nígbà kan pé: “Ohun tí mo sọ fún yín ni mo sọ fún gbogbo ènìyàn, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” (Máàkù 13:37) Jésù fẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ múra ọkàn wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè jẹ́ olóòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé ìlànà kan náà tó bá kan ọ̀rọ̀ wíwà lójúfò. Torí náà, bí àwọn ẹni àmì òróró ti ń mú ipò iwájú, gbogbo àwa Kristẹni ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àtàtà tí wọ́n fi lélẹ̀, a sì ń fi iṣẹ́ ìwàásù sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa tún lè fi sọ́kàn pé àwọn òmùgọ̀ wúńdíá náà sọ pé káwọn wúńdíá olóye náà fún àwọn lára òróró wọn, àmọ́ pàbó ni ẹ̀bẹ̀ wọn já sí. Èyí kọ́ wa pé ojúṣe wa ni pé ká jẹ́ olóòótọ́, ká dúró nínú òtítọ́, ká sì máa ṣọ́nà, kò sẹ́ni tó lè ṣe àwọn nǹkan yìí fún wa. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa jíhìn fún Onídàájọ́ tó jẹ́ olódodo èyí tí Jèhófà yàn. Torí náà, a gbọ́dọ̀ wà lójúfò. Ó sì ń bọ̀ láìpẹ́!
15. Kí nìdí tí ìgbéyàwó tó máa wáyé láàárín Kristi àti ìyàwó rẹ̀ fi múnú gbogbo Kristẹni tòótọ́ dùn?
15 Gbogbo àwa tá a jẹ́ Kristẹni tún lè jàǹfààní nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé nínú àkàwé tí Jésù sọ. Ó ṣe tán, ta ni nínú wa tí inú rẹ̀ kò dùn sí ìgbéyàwó tó ń bọ̀ lọ́nà yìí? Àwọn ẹni àmì òróró yóò ti wà ní ọ̀run lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì, wọ́n á sì di ìyàwó Kristi. (Ìṣí. 19:7-9) Gbogbo àwọn tó bá wà láyé nígbà yẹn yóò jàǹfààní nínú ìgbéyàwó tó máa wáyé lókè ọ̀run yẹn, torí pé ó fìdí ìjọba pípé kan múlẹ̀ fún gbogbo èèyàn. Yálà à ń retí láti gbé lókè ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé, ẹ jẹ́ ká kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú àkàwé àwọn wúńdíá mẹ́wàá náà. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa múra tán nípa mímúra ọkàn wa sílẹ̀, ká fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, ká sì túbọ̀ wà lójúfò ká bàa lè gbádùn ọjọ́ ọ̀la ológo tí Jèhófà ní nípamọ́ fún wa!
^ ìpínrọ̀ 9 Nínú àkàwé náà, àlàfo tó ṣe kedere wà láàárín ìgbà tí igbe ta pé, “Ọkọ ìyàwó ti dé!” (ẹsẹ 6) àti ìgbà tí ó tó wọlé dé gan-an tàbí tí ó tó fara hàn (ẹsẹ 10). Ní gbogbo ọjọ́ ìkẹyìn yìí, àwọn ẹni àmì òróró tó wà lójúfò ti róye àmì wíwà níhìn-ín Jésù. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n mọ̀ pé ó ti “dé,” Ìjọba rẹ̀ sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Ohun tó wá kù báyìí ni pé wọ́n gbọ́dọ̀ fara dà á títí tó fi máa wọlé dé tàbí tó fi máa fara hàn.
Bí àwọn òmùgọ̀ wúńdíá náà ṣe lọ ra òróró tiwọn kọ́ wa pé ojúṣe wa ni pé ká jẹ́ olóòótọ́, ká dúró nínú òtítọ́, ká sì máa ṣọ́nà, kò sẹ́ni tó lè ṣe àwọn nǹkan yìí fún wa