Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

A Ri Ohun To San Ju Ta A Fi Igbesi Aye Wa Se

A Ri Ohun To San Ju Ta A Fi Igbesi Aye Wa Se

ỌMỌ ọdún márùn-ún ni èmi àti Gwen nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ijó. A ò sì tíì mọ ara wa nígbà yẹn. Àmọ́ bá a ṣe ń dàgbà ọ̀kọ̀ọ̀kan wa pinnu pé ijó alálọ̀ọ́yípo la fẹ́ fi ṣiṣẹ́ ṣe. Ìgbà tá a ti rọ́wọ́ mú gan-an nídìí iṣẹ́ yìí la wá jáwọ́ níbẹ̀. Kí nìdí tá a fi pinnu pé a ò ṣe iṣẹ́ yìí mọ́?

David: Àgbègbè Shropshire lórílẹ̀-èdè England ni wọ́n bí mi sí lọ́dún 1945. Bàbá mi ní oko sí abúlé kan tí ó tòrò dáadáa. Tí mo bá dé láti ilé ìwé, mo fẹ́ràn kí n máa fún àwọn adìyẹ lóúnjẹ, kí n máa kó ẹyin wọn, kí n sì máa tọ́jú àwọn màlúù àtàwọn àgùntàn wa. Tá a bá ti gba ìsinmi nílé ìwé, mo máa ń bá àwọn òbí mi kórè oko wọn, mo tún máa ń wa àwọn katakata wa.

Àmọ́ nígbà tó yá, nǹkan míì tún wá gbà mí lọ́kàn. Látìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé ni bàbá mi ti kíyè sí pé mo fẹ́ràn ijó gan-an, kí n máà tíì gbọ́ orin sétí ni, màá ti máa jó. Torí náà, nígbà tí mo pé ọmọ ọdún márùn-ún bàbá mi sọ pé kí màmá mi mú mi lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ ijó tí wọ́n ń pè ní tap dance. Olùkọ́ mi tún wò ó pé máa lè jó ijó alálọ̀ọ́yípo, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi ní ìyẹn náà. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, mo gba ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ kan tó gbayì gan-an nílùú London, ìyẹn Royal Ballet School tí wọ́n ti ń kọ́ ijó alálọ̀ọ́yípo. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé Gwen, wọ́n sì pín wa pọ̀ pé ká jọ máa jó.

Gwen: Ọdún 1944 ni wọ́n bí mi ní ìlú London, ìlú kan tí èrò pọ̀ sí gan-an. Láti kékeré ni mo ti ní ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ nínú Ọlọ́run. Mo máa ń gbìyànjú láti ka Bíbélì, àmọ́ kò yé mi. Ìgbà tí mo wà lọ́mọ ọdún márùn ún ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ijó. Ọdún mẹ́fà lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n ṣe ìdíje kan tí gbogbo àwọn oníjó tó wà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lè kópa níbẹ̀. Ẹni tó bá yege ìdíje yìí máa di ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ti ìpele àkọ́bẹ̀rẹ̀ ní Royal Ballet School, mo sì yege ìdíje náà. Ibi tí ilé ìwé yìí wà rẹwà gan-an, ilé aláruru ni ilé náà, wọ́n ń pè é ní White Lodge, inú ọgbà kan tí wọ́n ń pè ní Richmond Park ló wà, lẹ́yìn ìlú London. Mò ń lọ ilé ìwé níbẹ̀ mo sì tún ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ijó alálọ̀ọ́yípo lọ́dọ̀ àwọn olùkọ́ tí wọ́n mọṣẹ́ náà gan-an. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ni mí nígbà tí mo bọ́ sí ìpele gíga ní Royal Ballet School tó wà ní àárín ìlú London, ibẹ̀ sì ni mo ti pàdé David. Láàárín oṣù mélòó kan, a ti bẹ̀rẹ̀ sí í jó ijó alálọ̀ọ́yípo pa pọ̀ láàárín àwọn akọrin ní ilé kan tí wọ́n ń pè ní Royal Opera House tó wà nínú ọgbà kan tí wọ́n ń pè ní Covent Garden, nílùú London.

Ijó alálọ̀ọ́yípo tí à ń jó gbé wa dé ọ̀pọ̀ ibi láyé

David: Gẹ́gẹ́ bí Gwen ṣe sọ, iṣẹ́ ijó tí à ń ṣe gbé wa dé Royal Opera House tó lókìkí gan-an. A tún dara pọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ oníjó kan tí wọ́n ń pè ní London Festival Ballet (tí wọ́n ń pè ní English National Ballet báyìí). Ọ̀kan nínú àwọn tó ń kọ́ni ní ijó ní ilé ẹ̀kọ́ Royal Ballet dá ilé iṣẹ́ ńlá kan sílẹ̀ ní ìlú Wuppertal lórílẹ̀-èdè, Jámánì, ó sì gba èmi àti Gwen pé ká máa jó fún ilé iṣẹ́ náà. Nígbà tí a wà lẹ́nu iṣẹ́ yìí, a máa ń lọ jó ní àwọn gbọ̀ngàn ìṣeré kárí ayé, a tún jó pẹ̀lú àwọn oníjó tó gbajúmọ̀, bíi Dame Margot Fonteyn àti Rudolf Nureyev. Ìbára-ẹni-díje pọ̀ gan-an nídìí iṣẹ́ yìí, ó tún máa ń mú kéèyàn gbéra ga, èmi àti Gwen sì kara bọ iṣẹ́ yìí gan-an.

Gwen: Tọkàn-tara ni mo fi ń ṣe iṣẹ́ ijó jíjó yìí. Ó wu èmi àti David ká rọ́wọ́ mú gan-an nídìí iṣẹ́ náà. Inú mi máa ń dùn táwọn èèyàn bá ní kí n bá àwọn buwọ́ lu nǹkan kan káwọn lè máa fi rántí mi tàbí tí wọ́n bá fún mi ní òdòdó. Ńṣe ni orí mi máa ń wú táwọn èèyàn bá ń pàtẹ́wọ́ nígbà tá a bá ń jó. Ọ̀pọ̀ àwọn tá a jọ ń jó ló jẹ́ oníṣekúṣe, wọ́n ń mu sìgá, wọ́n sì ń mutí. Bíi tàwọn tó kù tá a jọ ń jó, oògùn oríire tí mò ń lò ni mo gbójú lé.

ÌGBÉSÍ AYÉ WA YÍ PA DÀ PÁTÁPÁTÁ

Ọjọ́ ìgbéyàwó wa

David: Lẹ́yìn tí mo ti lo ọ̀pọ̀ ọdún nídìí iṣẹ́ ijó jíjó, ìrìn àjò tí mò ń rìn ní gbogbo ìgbà wá sú mi pátápátá. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé abúlé ni mo dàgbà sí, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í wù mí kí n pa dà síbẹ̀ kí n sì jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun tara tẹ́ mi lọ́rùn. Nígbà tó di ọdún 1967, mo fi iṣẹ́ ijó jíjó sílẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ nínú oko ńlá kan tí kò jìnnà sílé àwọn òbí mi. Mo rẹ́ǹtì ilé kékeré kan lọ́wọ́ àgbẹ̀ tó ni oko náà. Mo wá sọ fún Gwen lórí fóònù pé mo fẹ́ fẹ́ ẹ. Kò rọrùn fún un rárá láti ṣèpinnu torí wọ́n ti gbé e ga sípò oníjó táá máa dá nìkan jó, ó sì ti rọ́wọ́ mú gan-an nídìí iṣẹ́ náà. Síbẹ̀, Gwen gbà láti fẹ́ mi, a sì jọ ń gbé abúlé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò gbé abúlé rí.

Gwen: Ká sòótọ́, kò rọrùn fún mi rárá láti gbé abúlé. Ká máa fún wàrà màlúù àti ká máa fún àwọn ẹlẹ́dẹ̀ àtàwọn adìyẹ lóúnjẹ tòjò-tẹ̀ẹ̀rùn ṣàjèjì sí mi gan-an. Nígbà tó yá David lọ kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ọ̀nà tuntun táwọn àgbẹ̀ gbà ń ṣiṣẹ́ wọn, oṣù mẹ́sàn-án ló fi lọ́ sílé ẹ̀kọ́ gíga kan tó wà fáwọn àgbẹ̀. Tó bá ti lọ láàárọ̀, èmi nìkan ló máa dá wà nílé títí tó fi máa dé lálẹ́. Nígbà yẹn a ti bí ọmọbìnrin wa àkọ́kọ́ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gilly. David wá dábàá pé kí n lọ kọ́ bí wọ́n ṣe ń wa mọ́tò, mo sì ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́jọ́ kan, mo lọ sí ìlú tó wà nítòsí ọ̀dọ̀ wa, ibẹ̀ ni mo ti pàdé Gael. Ṣọ́ọ̀bù kan tó wà lágbègbè wa ló ti ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀, ibẹ̀ ni mo sì ti mọ̀ ọ́n.

Ìgbà tá a wà lóko nígbà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìgbéyàwó

Gael sọ pé kí n wá kí òun nílé. Ó fi àwọn fọ́tò ìgbéyàwó rẹ̀ hàn mí, nínú ọ̀kan lára àwọn fọ́tò yẹn ni mo ti rí àwọn kan tí wọ́n dúró síwájú ibì kan tí wọ́n ń pè ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Mo bí i pé ṣọ́ọ̀ṣì wo ni wọ́n tún ń pè bẹ́ẹ̀. Ó wá sọ fún mi pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun àti ọkọ òun, inú mi dùn gan-an nígbà tí mo gbọ́ bẹ́ẹ̀. Torí mo rántí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àǹtí mi kan tó jẹ́ àbúrò bàbá mi. Àmọ́, mo tún rántí pé bàbá mi máa ń bínú sí àbúrò wọn yẹn gan-an, ńṣe ni wọ́n máa ń da àwọn ìwé ìròyìn rẹ̀ síbi tá à ń da ìdọ̀tí sí. Mo máa ń ṣe kàyéfì pé kí ló dé tí bàbá mi tó máa ń kó èèyàn mọ́ra wá ń kanra mọ́ àǹtí dáadáa yẹn.

Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, mo wá láǹfààní láti mọ ìdí tí àwọn ohun tí àǹtí mi gbà gbọ́ fi yàtọ̀ sáwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì. Gael ṣàlàyé ohun tí Bíbélì fi kọ́ni fún mi. Ó yà mí lẹ́nu gan-an nígbà tí mo gbọ́ pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ irú bí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan àti àìleèkú ọkàn tako ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ. (Oníw. 9:5, 10; Jòh. 14:28; 17:3) Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí mo rí orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà nínú Bíbélì.—Ẹ́kís. 6:3.

David: Gwen sọ ohun tó ń kọ́ fún mi. Mo rántí pé nígbà tí mo wà ní kékeré bàbá mi máa ń sọ fún mi pé kí n máa ka Bíbélì. Lọ́rọ̀ kan, èmi àti Gwen gbà kí Gael àti Derrick ọkọ rẹ̀ máa kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà a kó lọ sí ìlú Oswestry ní àgbègbè Shropshire, torí wọ́n jẹ́ ká rẹ́ǹtì oko kékeré kan níbẹ̀. Nígbà tá a débẹ̀, Arábìnrin Deirdre ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò yẹn ló wá ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Arábìnrin náà máa ń ṣe sùúrù tó bá ń kọ́ wa. Níbẹ̀rẹ̀, a ò tètè tẹ̀ síwájú. Ìdí sì ni pé, àwọn ohun ọ̀sìn tí à ń bójú tó máa ń gba àkókò wa gan-an. Síbẹ̀, ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí à ń kọ́ ń yí ìgbésí ayé wa pa dà díẹ̀díẹ̀.

Gwen: Ó ṣòro gan-an fún mi láti borí ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun asán. Aísáyà 65:11 jẹ́ kí n mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo “àwọn tí ń tẹ́ tábìlì fún ọlọ́run Oríire.” Ó pẹ́ kí n tó da àwọn oògùn oríire àti àwọn ère mi nù, àmọ́ àdúrà ràn mí lọ́wọ́. Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ pé “ẹnì yòówù tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó rẹ̀ sílẹ̀, ẹnì yòówù tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga” mo wá róye irú àwọn tí Jèhófà ń wá. (Mát. 23:12) Ó wù mí kí n sin Ọlọ́run tó bìkítà nípa wa débi pé ó fi Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n rà wá pa dà. Lákòókò yẹn, a ti bí ọmọbìnrin wa kejì, inú wa dùn gan-an nígbà tí a kẹ́kọ̀ọ́ pé ìdílé wa lè gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé nínú Párádísè.

David: Nígbà tí mo lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àgbàyanu tí Bíbélì sọ, irú èyí tó wà nínú ìwé Mátíù orí 24 àtèyí tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì, ó wá túbọ̀ dá mi lójú pé òtítọ́ ni ẹ̀kọ́ tí mò ń kọ́. Ó wá yé mi dáadáa pé kò sí nǹkan kan nínú ayé yìí tó dà bíi kéèyàn ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà. Torí náà, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, mi ò fi bẹ́ẹ̀ lépa ipò ńlá mọ́. Mo lóye pé kò yẹ kí n máa rò pé mo ṣe pàtàkì ju ìyàwó mi àtàwọn ọmọbìnrin mi lọ. Ìwé Fílípì 2:4 túbọ̀ jẹ́ kí n lóye pé mi ò gbọ́dọ̀ máa ro tara mi nìkan àti bí mo ṣe máa ní oko ńlá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìjọsìn Jèhófà ni mo gbọ́dọ̀ fi sípò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé mi. Nígbà tó yá mi ò mu sìgá mọ́. Nǹkan bí kìlómítà mẹ́wàá ni ibi tí a ti ń ṣe ìpàdé sí ilé wa. Àmọ́, kò rọrùn fún ìdílé mi láti máa lọ sí ìpàdé ní àwọn ìrọ̀lẹ́ Sátidé, torí pé àkókò yẹn ni a máa ń fún wàrà àwọn màlúù wa. Àmọ́, Gwen máa ń rí i dájú pé a ò pa ìpàdé jẹ, a sì tún ń kó àwọn ọmọ wa dání lọ sóde ẹ̀rí láàárọ̀ Sunday, lẹ́yìn tá a bá fún wàrà àwọn màlúù tán.

Inú àwọn mọ̀lẹ́bí wa ò dùn sí wa rárá bá a ṣe yí ẹ̀sìn tá à ń ṣe pa dà. Ọdún mẹ́fà gbáko ni bàbá ìyàwó mi fi bá ìyàwó mi yan odì. Àwọn òbí mi pàápàá ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe ká má bàa ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́.

Gwen: Jèhófà ló ràn wá lọ́wọ́ tá a fi lè fara da gbogbo ìṣòro yìí. Àwọn ará tó wà ní ìjọ Oswestry di ìdílé wa tuntun nígbà tó yá, wọ́n sì dúró tì wá tìfẹ́tìfẹ́ nígbà ìpọ́njú. (Lúùkù 18:29, 30) A ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1972. Ó wù mí kí n ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ káwọn náà wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ìdí nìyẹn tí mo fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.

A RÍ IṢẸ́ MÍÌ TÓ LÉRÈ JÙ

David: Iṣẹ́ àṣekára la máa ń ṣe láwọn ọdún tá a fi ń ṣiṣẹ́ lóko; síbẹ̀ ní ti ìjọsìn Jèhófà a sapá ká lè fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn ọmọbìnrin wa. Nígbà tó yá, a fi iṣẹ́ oko sílẹ̀, torí ìjọba dín ìrànwọ́ tí wọ́n ń ṣe fáwọn àgbẹ̀ kù. Bó ṣe di pé a ò ní ilé a ò sì ní iṣẹ́ mọ́ nìyẹn, ọmọbìnrin wa kẹta kò sì tíì ju ọmọ ọdún kan lọ. A wá gbàdúrà pé kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà. Ni a bá pinnu pé a máa lo ẹ̀bùn àbínibí wa. Torí náà, a ṣí ibì kan tá a ti ń kọ́ àwọn èèyàn ní ijó, ká lè fi gbọ́ bùkátà ìdílé wa. Bá a ṣe pinnu láti fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ so èso rere fún wa. Inú wa dùn gan-an nígbà táwọn ọmọbìnrin wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lẹ́yìn tí wọ́n jáde ilé ìwé. Nítorí aṣáájú-ọ̀nà ni ìyàwó mi náà, ojoojúmọ́ ló máa ń fún àwọn ọmọbìnrin wa níṣìírí.

Nígbà táwọn ọmọbìnrin wa àgbà méjèèjì ìyẹn Gilly àti Denise ṣègbéyàwó, a ti ibi tá a ti ń kọ́ àwọn èèyàn ní ijó. A wá kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì pé kí wọ́n jẹ́ ká mọ ibi tá a ti lè ṣèrànwọ́. Wọ́n ní ká lọ sáwọn ìlú tó wà ní gúúsù ìlà oòrùn nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ní báyìí tó jẹ́ pé Debbie nìkan ló kù nílé, èmi náà wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà, ẹ̀ka ọ́fíìsì sọ pé ká lọ ran àwọn ìjọ kan lọ́wọ́ ní àwọn ibì kan tó jìn lápá àríwá. Lẹ́yìn tí Debbie ṣègbéyàwó, a lo ọdún mẹ́wàá lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ kárí ayé. A ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Sìǹbábúwè, Moldova, Hungary àti Côte d’Ivoire. Lẹ́yìn ìyẹn, a pa dà sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ká lè lọ ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé tí wọ́n ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú London. Torí pé mo mọ̀ nípa iṣẹ́ àgbẹ̀ dáadáa, wọ́n ní kí n lọ ràn wọ́n lọ́wọ́ ní oko Bẹ́tẹ́lì nígbà yẹn. Ní bàyìí a ṣì ń bá iṣẹ́ àṣáájú-ọ̀nà lọ ní apá àríwá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Inú wa ń dùn gan-an bá a ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ kárí ayé

Gwen: Iṣẹ́ tá a kọ́kọ́ pinnu pé a máa fi ìgbésí ayé wa ṣe ni jíjó ijó alálọ̀ọ́yípo, a gbádùn rẹ̀ lóòótọ́, àmọ́ kò fún wa ní ojúlówó ayọ̀. Ìpinnu kejì tá a ṣe ló wá ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn bá a ṣe ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà. A wá ní ojúlówó ayọ̀ tí kò lópin. Èmi àti David ṣì jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀, kì í wá ṣe iṣẹ́ ijó jíjó mọ́, àmọ́ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà la jọ ń ṣe. Inú wa ń dùn gan-an bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣe iyebíye tó sì ń gba ẹ̀mí là. “Àwọn lẹ́tà ìdámọ̀ràn” yìí sì sàn ju òkìkí èyíkéyìí tí ayé lè fúnni lọ. (2 Kọ́r. 3:1, 2) Tí kì í bá ṣe pé a kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, gbogbo ohun tíì bá kù wá kù ì bá máà ju pé ká máa rántí àwọn àkókò tá a fi ń jó káàkiri, àwọn fọ́tò àtijọ́ àtàwọn eré tá a ṣe nínú gbọ̀ngàn ìwòran.

David: Iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ti mú kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀ gan-an ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ó ti mú kí n sunwọ̀n sí i nínú ojúṣe mi gẹ́gẹ́ bí ọkọ àti bàbá. Bíbélì sọ pé Míríámù, Dáfídì Ọba àtàwọn míì jó láti fi ìdùnnú wọn hàn. A ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí àwa àti ọ̀pọ̀ èèyàn máa jó ijó ayọ̀ nínú ayé tuntun tí Jèhófà máa mú wá.—Ẹ́kís. 15:20; 2 Sám. 6:14.