Eyi Ni “Ona Ti Iwo Tewo Gba”
“Ìwọ ti rọra fi ohun wọ̀nyí pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ìkókó.”—LÚÙKÙ 10:21.
1. Kí ló mú kí Jésù “ní ayọ̀ púpọ̀ nínú ẹ̀mí mímọ́”? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
FOJÚ inú wo bó ṣe máa rí ná nígbà tí Jésù “ní ayọ̀ púpọ̀ nínú ẹ̀mí mímọ́.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ló rẹ́rìn-ín músẹ́, tí ara rẹ̀ sì yá gágá. Kí ló dé tí inú rẹ̀ fi dùn tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rán àádọ́rin [70] lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni. Ó sì fẹ́ mọ bí wọ́n á ti ṣe iṣẹ́ tí òun gbé lé wọn lọ́wọ́. Torí pé àwọn ọ̀tá tó kórìíra ìhìn rere náà pọ̀, lára wọn ni àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí tí wọ́n já fáfá gan-an tí wọ́n sì kàwé dáadáa. Wọ́n mú kí ọ̀pọ̀ máa fi ojú káfíńtà lásán-làsàn wo Jésù, kí wọ́n sì ka àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sí “àwọn ènìyàn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù.” (Ìṣe 4:13; Máàkù 6:3) Àmọ́, nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà fi máa pa dà dé lẹ́nu iṣẹ́ tí Jésù rán wọn, ńṣe ni inú wọn ń dùn ṣìnkìn. Wọ́n wàásù láìka àtakò tí wọ́n kojú sí, kódà látọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá! Kí ló mú kí wọ́n máa láyọ̀ kí wọ́n sì nígboyà?—Ka Lúùkù 10:1, 17-21.
2. (a) Ọ̀nà wo ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbà dà bí àwọn ọmọdé? (b) Kí ló ran àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi lọ́wọ́ tí wọ́n fi lóye àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣe pàtàkì?
2 Jésù gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Mo yìn ọ́ ní gbangba, Baba, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, nítorí pé ìwọ ti fi nǹkan wọ̀nyí pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye, o sì ti ṣí wọn payá Mát. 11:25, 26) Ohun tí Jésù sọ yìí ò túmọ̀ sí pé ọmọdé làwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun dà bí ìkókó tá a bá fi wọ́n wé àwọn tí wọ́n jẹ́ amòye tí wọ́n kàwé débi gbì ní ilẹ̀ náà, tí wọ́n sì ti gbọ́n tán lójú ara wọn. Ìdí pàtàkì tí Jésù sì fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé ó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n dà bí ọmọdé, ní ti pé kí wọ́n ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kí wọ́n sì ṣeé kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. (Mát. 18:1-4) Báwo ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ní ṣe ṣe wọ́n láǹfààní? Jèhófà tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ mú kí wọ́n lóye àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣe pàtàkì. Àmọ́ Sátánì àti ẹ̀mí ìgbéraga ti fọ́ ojú àwọn ọlọgbọ́n àti amòye tó ń fi wọ́n ṣẹ̀sín.
fún àwọn ìkókó. Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ Baba, nítorí pé láti ṣe bẹ́ẹ̀ wá jẹ́ ọ̀nà tí ìwọ tẹ́wọ́ gbà.” (3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Abájọ tí inú Jésù fi dùn gan-an! Ayọ̀ rẹ̀ kún bó ṣe rí i tí Jèhófà ń ṣí àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí ó jinlẹ̀ payá fún àwọn onírẹ̀lẹ̀, láìka iye ìwé tí wọ́n kà tàbí ẹ̀bùn abínibí tí wọ́n ní sí. Inú Jésù dùn pé èyí jẹ́ ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí Baba rẹ̀ tẹ́wọ́ gba. Jèhófà ò sì tíì yí pa dà, báwo ló ṣe wá fi hàn pé òun ṣì tẹ́wọ́ gba irú ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí? Bá a ti ń wá ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, a máa rí i pé ìdáhùn náà máa mú inú wa dùn gan-an bó ṣe mú inú Jésù dùn.
À Ń JẸ́ KÍ GBOGBO ÈÈYÀN LÓYE Ẹ̀KỌ́ ÒTÍTỌ́ TÓ JINLẸ̀
4. Báwo ni ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tí a mú kó túbọ̀ rọrùn láti lóye ṣe jẹ́ ẹ̀bùn fáwọn èèyàn?
4 Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ó hàn gbangba pé ètò Jèhófà ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́nà tó túbọ̀ rọrùn lóye tó sì túbọ̀ ṣe kedere. Wo àpẹẹrẹ mẹ́ta. Àkọ́kọ́ ni pé a ti ń tẹ ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tí a mú kó túbọ̀ rọrùn láti lóye jáde. * Ẹ̀dà yìí dà bí ẹ̀bùn fún àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ lóye èdè náà dáadáa tàbí tí èdè náà kò rọrùn fún wọn láti kà. Àwọn olórí ìdílé ti kíyè sí i pé ẹ̀dà yìí ti jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fáwọn ọmọ wọn láti lóye ohun tá à ń kọ́ nínú Ilé Ìṣọ́, tó jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tí à ń gbà jẹ oúnjẹ tẹ̀mí. Ọ̀rọ̀ tó ń wúni lórí ni ọ̀pọ̀ kọ sínú lẹ́tà ìmọrírì tí wọ́n fi ránṣẹ́. Arábìnrin kan sọ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ẹ̀rù máa ń ba òun láti dáhùn nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Àmọ́ ní báyìí kò sí ìbẹ̀rù fún òun mọ́! Lẹ́yìn tó bẹ̀rẹ̀ sí í lo ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó túbọ̀ rọrùn láti lóye, ó kọ̀wé pé: “Mo máa ń dáhùn ju ẹ̀ẹ̀kan lọ nísinsìnyí, mi ò bẹ̀rù mọ́! Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà mo sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ yín.”
5. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí a tún ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì?
5 Àpẹẹrẹ kejì ni ti Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí a tún ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì, a mú un jáde níbi ìpàdé ọdọọdún tí a ṣe ní October 5, 2013. * Ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pọ̀ tẹ́lẹ̀ ló ti dín kù báyìí, síbẹ̀ ìtumọ̀ rẹ̀ kò yí pa dà, ńṣe ló túbọ̀ ṣe kedere. Bí àpẹẹrẹ, nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí a tún ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì ọ̀rọ̀ mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ló wà nínú ìwé Jóòbù 10:1 tẹ́lẹ̀, ní báyìí ó ti di ọ̀rọ̀ mọ́kàndínlógún; nínú ìwé Òwe 8:6 ogún ni ọ̀rọ̀ tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀, àmọ́ mẹ́tàlá ni báyìí. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ méjèèjì ti túbọ̀ ṣe kedere nínú ẹ̀dà tí a tún ṣe yìí. Kódà, arákùnrin kan tó jẹ́ ẹni àmì òróró tó ti ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ pé: “Nígbà tí mo ka ìwé Jóòbù nínú ẹ̀dà Bíbélì tí a tún ṣe yìí, ó ṣe mí bí i pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí màá lóye rẹ̀!” Ọ̀pọ̀ èèyàn náà ló sì ti sọ irú ọ̀rọ̀ yìí.
6. Báwo ni àtúnṣe tí a ṣe sí òye tí a ní nípa Mátíù 24:45-47 ṣe rí lára rẹ?
6 Ìkẹta, ronú nípa àwọn àtúnṣe tí a Mát. 24:45-47) Nínú Ilé Ìṣọ́ yìí a ṣàlàyé pé ẹrú olóòótọ́ náà ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àti pé àwọn “ará ilé” ni gbogbo àwọn tí ẹrú náà ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún, yálà àwọn ẹni àmì òróró tàbí àwọn “àgùntàn mìíràn.” (Jòh. 10:16) À ń láyọ̀ bí a ti ń kọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí, inú wa sì ń dùn láti kọ́ àwọn ẹni tuntun ní ẹ̀kọ́ náà! Àwọn ọ̀nà mìíràn wo ni Jèhófà ti fi hàn pé òun tẹ́wọ́ gba ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó rọrùn láti lóye tí ó sì ṣe kedere?
ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe sí òye tí a ní nípa àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan. Bí àpẹẹrẹ, inú wa dùn gan-an nígbà tí a ní òye tó túbọ̀ ṣe kedere nípa “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” nínú Ilé Ìṣọ́ July 15, 2013. (À Ń ṢÀLÀYÉ ÀWỌN ÌTÀN INÚ BÍBÉLÌ LỌ́NÀ TÓ TÚBỌ̀ RỌRÙN LÁTI LÓYE TÓ SÌ ṢE KEDERE
7, 8. Mẹ́nu kan díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nínú Bíbélì.
7 Tó o bá ti ń sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, o lè ti kíyè sí pé àyípadà ti wà nínú bá a ṣe ń ṣàlàyé àwọn ìtàn inú Bíbélì nínú àwọn ìwé wa. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Látẹ̀yìn wá, tá a bá ń ṣàlàyé àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì, a sábà máa ń sọ pé wọ́n ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan míì. Ǹjẹ́ ó ní ìdí tí a fi ń ṣàlàyé àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì lọ́nà yìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ̀rọ̀ nípa “àmì Jónà wòlíì.” (Ka Mátíù 12:39, 40.) Jésù ṣàlàyé pé àkókò tí Jónà lò nínú ikùn ẹja tó gbé e mì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìgbà tí òun máa lò nínú sàréè, ká ní Jèhófà ò sì dá sí ọ̀ràn náà ni, inú ikún ẹja yẹn ni ì bá di sàréè Jónà.
8 Yàtọ̀ sí ìṣẹ̀lẹ̀ tí Jésù tọ́ka sí yìí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ míì náà wà nínú Bíbélì tí Ọlọ́run lò láti sọ àsọtẹ́lẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ mélòó kan nínú wọn. Bí àpẹẹrẹ, àjọṣe tó wà láàárín Ábúráhámù, Hágárì àti Sárà jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tó ń ṣàpẹẹrẹ àjọṣe tí Jèhófà ní pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àti apá ti ọ̀run lára ètò Ọlọ́run. (Gál. 4:22-26) Bákan náà, àgọ́ ìjọsìn àti tẹ́ńpìlì, Ọjọ́ Ètùtù, àlùfáà àgbà àti àwọn apá mìíràn nínú Òfin Mósè jẹ́ “òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀.” (Héb. 9:23-25; 10:1) Bá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ńṣe ni ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ ń lókun sí i. Ǹjẹ́ a lè wá parí èrò sí pé gbogbo àwọn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì àti àwọn nǹkan míì tí Bíbélì ṣàpèjúwe rẹ̀ ló ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan kan tàbí ẹnì kan?
9. Báwo la ṣe ṣàlàyé ìtàn nípa Nábótì tẹ́lẹ̀?
9 Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ohun tá a rò nìyẹn. Wo àpẹẹrẹ ti Nábótì tí ayaba búburú náà Jésíbẹ́lì ṣètò pé kí wọ́n fi èrú yí ìdájọ́ po lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kí wọ́n sì pa á, torí ki Áhábù ọkọ rẹ̀ lè gba ọgbà àjàrà Nábótì. (1 Ọba 21:1-16) Lọ́dún 1932, a ṣàlàyé pé ìṣẹ̀lẹ̀ alásọtẹ́lẹ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn. A sọ pé Áhábù àti Jésíbẹ́lì ṣàpẹẹrẹ Sátánì àti ètò rẹ̀; Nábótì ṣàpẹẹrẹ Jésù; ikú Nábótì sì jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ bí wọ́n ṣe máa pa Jésù. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn, nínú ìwé “Let Your Name Be Sanctified,” tá a tẹ̀ lọ́dún 1961, a ṣàlàyé pé Nábótì ṣàpẹẹrẹ àwọn ẹni àmì òróró, Jésíbẹ́lì sì ṣàpẹẹrẹ Kirisẹ́ńdọ̀mù. Inúnibíni tí Jésíbẹ́lì ṣe sí Nábótì sì ṣàpẹẹrẹ inúnibíni tí wọ́n máa ṣe sáwọn ẹni àmì òróró láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Bá a ṣe ń ṣàlàyé Bíbélì lọ́nà yìí ti fún ìgbàgbọ́ àwọn olùjọ́sìn Ọlọ́run lókun fún ọ̀pọ̀ ọdún. Kí wá nìdí tá ò kì í sábà ṣàlàyé àwọn ìtàn Bíbélì lọ̀nà yìí mọ́?
10. (a) Bí òye tí ẹrú olóòótọ́ ní ṣe ń pọ̀ sí i, báwo nìyẹn ṣe mú kó túbọ̀ máa lo ìṣọ́ra tó bá ń ṣàlàyé àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì kan? (b) Kí ni à ń fún láfiyèsí jù nínú àwọn ìwé wa lónìí?
10 Kò ṣàjèjì pé láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ni Jèhófà ti ń ran “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” lọ́wọ́ kí òye rẹ̀ lè máa pọ̀ sí i. Òye tó ní yìí ti jẹ́ kó túbọ̀ máa ṣọ́ra tó bá fẹ́ sọ pé àkọsílẹ̀ Bíbélì kan jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀, àyàfi tó bá ṣe kedere pé ẹ̀rí tó fìdí èyí múlẹ̀ wà nínú *
Ìwé Mímọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó ti rí i pé ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ láti lóye àwọn àlàyé tí ètò Ọlọ́run ti ṣe nígbà kan nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń ṣàpẹẹrẹ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Tá a bá ń ṣàlàyé pé ẹnì kan nínú Bíbélì jẹ́ àpẹẹrẹ ẹlòmíì, tá a sì sọ ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀, irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ kì í sábà ṣe kedere, ó máa ń ṣòro rántí, kì í sì í rọrùn láti ṣàmúlò rẹ̀. Èyí tó tiẹ̀ ṣe pàtàkì jù ni pé tá a bá ń fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣàpẹẹrẹ ohun mìíràn lọ́jọ́ iwájú láfiyèsí jù, àlàyé tá a máa ṣe nípa rẹ̀ máa bó ẹ̀kọ́ gidi tó yẹ ká kọ́ nínú àwọn ìtàn Bíbélì náà mọ́lẹ̀ tàbí kó sọ ọ́ nù. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé, ohun tá à ń fún láfiyèsí nínú àwọn ìwé wa lónìí ni àwọn àlàyé tó túbọ̀ rọrùn láti lóye, tó sì máa jẹ́ ká rí ẹ̀kọ́ gidi kọ́ nípa ìgbàgbọ́, ìfaradà, ìfọkànsin Ọlọ́run àti àwọn ànímọ́ pàtàkì míì tí a lè rí nínú àwọn ìtàn Bíbélì.11. (a) Òye wo la ní báyìí nípa ìtàn Nábótì, kí sì nìdí tí àpẹẹrẹ rẹ̀ fi kọ́ gbogbo wa lẹ́kọ̀ọ́? (b) Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, kí nìdí tí àwọn ìwé wa kì í sábà sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń ṣàpẹẹrẹ ohun míì? (Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú ìtẹ̀jáde yìí.)
11 Òye wo la wá ní nípa ìtàn Nábótì báyìí? Òye tá a ní nípa rẹ̀ ti túbọ̀ ṣe kedere ó sì rọrùn láti lóye. Kì í ṣe torí pé ọkùnrin olódodo yẹn ń ṣàpẹẹrẹ Jésù tàbí àwọn ẹni àmì òróró ló ṣe kú, àmọ́ torí pé ó jẹ́ olùpàwàtítọ́mọ́. Ó pa Òfin Jèhófà mọ́ láìka bí àwọn ìkà tó ṣi agbára wọn lò ti fojú rẹ̀ gbolẹ̀ tó. (Núm. 36:7; 1 Ọba 21:3) Àpẹẹrẹ rẹ̀ ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ gan-an torí pé ẹnikẹ́ni nínú wa lè kojú irú inúnibíni tí Nábótì kojú. (Ka 2 Tímótì 3:12.) Gbogbo èèyàn láìka èdè, ẹ̀yà tàbí ipò wọn sí lè lóye ẹ̀kọ́ tó ń fún ìgbàgbọ́ ẹni lókun tí ìtàn náà kọ́ wa, wọ́n lè rántí rẹ̀, kí wọ́n sì fi í sílò.
12. (a) Kí ni kò yẹ ká parí èrò sí nípa àwọn ìtàn inú Bíbélì? (b) Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ṣe àlàyé tó ṣe kedere kódà nípa àwọn ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀ nínú Bíbélì? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
12 Ǹjẹ́ a wá lè parí èrò sí pé ẹ̀kọ́ nìkan la lè rí kọ́ lára àwọn ìtàn inú Bíbélì àti pé wọn ò ní ìtumọ̀ míì? Rárá o. Lónìí, àwọn ìtẹ̀jáde wa máa ń kọ́ wa pé ìṣẹ̀lẹ̀ Bíbélì kan ń rán wa létí nǹkan kan tàbí pé ó ń tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ míì nínú Bíbélì. A máa *
ń ṣàlàyé àwọn ìtàn inú Bíbélì lọ́nà tó rọrùn láti lóye, láìsí àlàyé tó lọ́jú pọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣàpẹẹrẹ ohun míì. Bí àpẹẹrẹ, a lè sọ pé bí Nábótì ṣe pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ láìka inúnibíni àti ikú sí ń rán wa létí bí Kristi àti àwọn ẹni àmì òróró rẹ̀ ṣe pa ìwà títọ́ mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún ń rán wa létí bí ọ̀pọ̀ “àwọn àgùntàn mìíràn” ti jẹ́ adúróṣinṣin. Irú àfiwéra tó ṣe kedere to sì rọrùn láti lóye bẹ́ẹ̀ ló mú kí ẹ̀kọ́ tí Ọlọ́run ń kọ́ wa dá yàtọ̀.À Ń ṢÀLÀYÉ ÀWỌN ÀPÈJÚWE JÉSÙ LỌ́NÀ TÓ TÚBỌ̀ RỌRÙN LÁTI LÓYE
13. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé ní báyìí à ń ṣàlàyé àwọn àpèjúwe Jésù lọ́nà tó túbọ̀ rọrùn láti lóye tó sì ṣe kedere?
13 Jésù Kristi ni Olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ jù lọ nínú gbogbo àwọn olùkọ́ tó ti gbé láyé yìí. Jésù fẹ́ràn kó máa fi àpèjúwe kọ́ àwọn èèyàn. (Mát. 13:34) Àpèjúwe máa ń jẹ́ kí àlàyé túbọ̀ ṣe kedere, ó máa ń mú kéèyàn ronú ó sì máa ń wọni lọ́kàn ṣinṣin. Látọdún yìí wá làwọn ìwé wa ti máa ń ṣàlàyé àwọn àpèjúwe Jésù lọ́nà tó túbọ̀ rọrùn láti lóye tó sì túbọ̀ ṣe kedere. Bí àpẹẹrẹ, Ilé Ìṣọ́ July 15, 2008 ṣe àlàyé tó kúnná lórí àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa ìwúkàrà, hóró músítádì àti àwọ̀n ńlá náà. Inú wa dùn gan-an bí a ti túbọ̀ ní òye tí ó kún sí i nípa àwọn àpèjúwe yìí. Ó ti wá yé wa kedere pé Ìjọba Ọlọ́run ni àwọn àpèjúwe yìí ń tọ́ka sí àti àṣeyọrí ribiribi tí Ìjọba náà ti ṣe láti mú kí àwọn èèyàn kọ ayé burúkú yìí sílẹ̀, kí wọ́n sì di olùṣòtítọ́ ọmọlẹ́yìn Kristi.
14. (a) Àlàyé wo la ti ṣe nípa àkàwé ọkùnrin ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere? (b) Òye wo la ní báyìí nípa àkàwé tí Jésù ṣe yìí?
14 Báwo ló wá ṣe yẹ ká lóye àwọn ìtàn tàbí àkàwé tó kún rẹ́rẹ́ tí Jésù sọ? Àpẹẹrẹ àti àsọtẹ́lẹ̀ ni àwọn kan, ẹ̀kọ́ gidi làwọn míì sì ń kọ́ wa. Àmọ́, báwo la ṣe máa mọ èyí tó jẹ́ ìṣàpẹẹrẹ àtèyí tí kì í ṣe ìṣàpẹẹrẹ? Bọ́dún ti ń gorí ọdún, ìdáhùn náà ti wá túbọ̀ ṣe kedere. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa bá a ṣe ti ṣàlàyé àkàwé tí Jésù ṣe nípa ọkùnrin ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere. (Lúùkù 10:30-37) Lọ́dún 1924, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì ṣàlàyé pé ọkùnrin ará Samáríà náà dúró fún Jésù; ojú ọ̀nà tó sọ̀ kalẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Jẹ́ríkò ṣàpẹẹrẹ bí ìwà aráyé ṣe túbọ̀ ń burú sí i látìgbà tí ìṣọ̀tẹ̀ ti wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì; àwọn olè náà ṣàpẹẹrẹ àwọn ilé iṣẹ́ ńlá àtàwọn oníṣòwò tí wọ́n jẹ́ oníwọra; àlùfáà náà àti ọmọ Léfì sì ṣàpẹẹrẹ Kirisẹ́ńdọ̀mù. Lónìí, a máa ń ṣàlàyé nínú àwọn ìwé wa pé àkàwé yìí ń rán gbogbo Kristẹni létí pé a kò gbọ́dọ̀ máa ṣe ojúsàájú tá a bá fẹ́ ran àwọn aláìní lọ́wọ́, pàápàá jù lọ tá a bá ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Ǹjẹ́ kò mú inú wa dùn pé Jèhófà ń mú kí àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ṣe kedere sí wa?
15. Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
15 Nínú àpilẹ̀kọ tí ó kàn, a máa ṣàyẹ̀wò àkàwé míì tí Jésù ṣe, ìyẹn àkàwé nípa àwọn wúńdíá mẹ́wàá. (Mát. 25:1-13) Báwo ni Jésù ṣe fẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn lóye àpèjúwe tó wọni lọ́kàn yìí? Ṣé ó kàn fẹ́ kí wọ́n wo àkàwé yìí bí ìtándòwe tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀, tí gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ inú rẹ̀, àwọn èèyàn tó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ àtàwọn nǹkan tó mẹ́nu kan ní ìtumọ̀ ìṣàpẹẹrẹ? Àbí, ńṣe ló fẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ rí ẹ̀kọ́ gidi kọ́ níbẹ̀, táá máa tọ́ wọn sọ́nà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn? Ẹ jẹ́ ká wò ó ná.
^ ìpínrọ̀ 4 Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni a ti kọ́kọ́ ṣe ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tí a túbọ̀ mú kó rọrùn láti lóye ní oṣù July ọdún 2011. Látìgbà yẹn, ẹ̀dà yìí ti wà láwọn èdè mélòó kan míì.
^ ìpínrọ̀ 5 A ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò bí a ṣe máa ṣe Bíbélì tí a tún ṣe yìí jáde ní àwọn èdè mìíràn.
^ ìpínrọ̀ 10 Bí àpẹẹrẹ, ìwé Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn ṣe àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa ìgbésí ayé àwọn ẹni mẹ́rìnlá kan tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn. Ìwé náà kò dá lórí ohun tí wọ́n ń ṣàpẹẹrẹ tàbí ìtumọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n ń mú ṣẹ, kàkà bẹ́ẹ̀, ó dá lórí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí a lè kọ́ lára wọn.
^ ìpínrọ̀ 12 Lóòótọ́, àwọn nǹkan míì wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó lè dà bí i pé “ó nira láti lóye,” títí kan àwọn kan nínú àwọn ìwé Bíbélì tí Pọ́ọ̀lù kọ. Àmọ́, gbogbo àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì ni ẹ̀mí mímọ́ mí sí. Ẹ̀mí mímọ́ yìí náà ló ń ran àwa Kristẹni tòótọ́ lọ́wọ́ lónìí tá a fi ń lóye òtítọ́ Bíbélì, kódà ó ń jẹ́ ká túbọ̀ mọ “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run,” ó sì ń mú kó túbọ̀ ṣe kedere sí wa, bí a tilẹ̀ jẹ́ aláìpé.—2 Pét. 3:16, 17; 1 Kọ́r. 2:10.