Se Igi Ti Won Ge Lule Tun Le Hu Pa Da?
IGI ólífì tára rẹ̀ rí ṣágiṣàgi, tó sì lọ́ mọ́ra bìrìpà lè má dùn ún wò tá a bá fi wé igi kédárì ti Lẹ́bánónì. Àmọ́ igi ólífì rọ́kú, kò sí ojú ọjọ́ tí kò bá a lára mu, àtìgbà òjò àtìgbà ẹ̀rùn. A gbọ́ pé àwọn míì ti lo ẹgbẹ̀rún ọdún kan. Gbòǹgbò igi ólífì máa ń ta gan-an, ó sì máa ń rinlẹ̀, ìyẹn máa ń jẹ́ kó tún lè sọjí bí wọ́n tiẹ̀ gé ìtì rẹ̀ lulẹ̀. Tí gbòǹgbò ẹ̀ ò bá ṣáà ti kú, ó máa hù pa dà.
Jóòbù baba ńlá ìgbàanì gbà gbọ́ dájú pé bí òun bá tiẹ̀ kú, òun ṣì máa pa dà wà láàyè. (Jóòbù 14:13-15) Ó fi ọ̀rọ̀ igi ṣàpèjúwe bó ṣe dá òun lójú tó pé Ọlọ́run máa jí òun dìde, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé igi ólífì ló ní lọ́kàn. Jóòbù sọ pé: “Ìrètí wà fún igi pàápàá. Bí a bá gé e lulẹ̀, àní yóò tún hù.” Nígbà tí òjò bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ lẹ́yìn tí ọ̀dá ti mú kí gbogbo nǹkan gbẹ táútáú, kùkùté igi ólífì tó ti gbẹ lè sọjí pa dà, á bẹ̀rẹ̀ sí í yọ “ẹ̀tun bí ọ̀gbìn tuntun.”—Jóòbù 14:7-9.
Bí àgbẹ̀ ṣe máa ń retí ìgbà tí gbòǹgbò igi ólífì tí wọ́n gé lulẹ̀ máa sọjí pa dà, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà Ọlọ́run ṣe ń retí ìgbà tó máa jí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn míì tó ti kú dìde kí wọ́n lè wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i. (Mát. 22:31, 32; Jòh. 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Ọjọ́ ayọ̀ lọjọ́ náà máa jẹ́ nígbà tá a bá tún rí àwọn tó ti kú, tí wọ́n sì ń gbádùn ayé wọn lẹ́ẹ̀kan sí i!