Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Ife Ti Mo Ni fun Olorun Latibere Mu Ki N Le Fara Da A

Ife Ti Mo Ni fun Olorun Latibere Mu Ki N Le Fara Da A

OHUN kan ṣẹlẹ̀ sí mi nígbà ẹ̀ẹ̀rùn lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1970. Mo wà lórí ibùsùn níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú mi nílé ìwòsàn Valley Forge General Hospital, tó wà nílùú Phoenixville, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ọkùnrin kan tó jẹ́ nọ́ọ̀sì ń yẹ ìfúnpá mi wò láàárín ọgbọ̀n ìṣẹ́jú síra. Nígbà ti mò ń sọ yìí, sójà ni mí, mo jẹ́ ọmọ ogún ọdún nígbà yẹn, àìsàn burúkú tó ràn mí ló gbé mi dé ilé ìwòsàn. Díẹ̀ ni nọ́ọ̀sì tó ń tọ́jú mi fi jù mí lọ, àmọ́ ọkàn rẹ̀ dàrú bó ṣe ń wò mí. Bí ìfúnpá mi ṣe ń lọ sílẹ̀, mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé èèyàn ti kú lójú ẹ rí?” Ńṣe ló bojú jẹ́, ó sì dáhùn pé, “Rárá, èèyàn ò kú lójú mi rí.”

Lásìkò yẹn, ṣe ló dà bíi pé mi ò ní pẹ́ kú. Àmọ́, kí ló gbé mi dé ilé ìwòsàn? Tóò, ẹ jẹ́ kí n sọ díẹ̀ nínú ìtàn ara mi fún yín.

BÍ MO ṢE DÓJÚ OGUN

Mo wà lára àwọn tó ń ran dókítà lọ́wọ́ nínú yàrá tí wọ́n ti máa ń ṣiṣẹ́ abẹ lásìkò ogun nílẹ̀ Vietnam, ibẹ̀ ni àìsàn tó ń ṣe mí náà ti bẹ̀rẹ̀. Mo gbádùn kí n máa tọ́jú àwọn aláìsàn àtàwọn tó gbọgbẹ́, mo sì ní i lọ́kàn pé lọ́jọ́ kan èmi náà á di dókítà oníṣẹ́ abẹ. Oṣù July ní ọdún 1969 ni mo dójú ogun ní Vietnam. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe fáwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dójú ogun, wọ́n fún mí láyè ọ̀sẹ̀ kan láti mojú ilẹ̀ kí ara mi lè mọlé, kí ooru àsìkò náà sì lè bá mi lára mu.

Ẹ̀yìn ìyẹn ni mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ilé ìwòsàn kan tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ abẹ tó wà ní àgbègbè kan tó ń jẹ́ Mekong Delta, nílùú Dong Tam. Kò pẹ́ sígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ni àwọn hẹlikọ́pítà bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn tó fara gbọgbẹ́ dé. Mo nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè mi gan-an mi ò sì kì í fiṣẹ́ ṣeré rárá, nítorí náà àáyá mi bẹ́ sílẹ̀, ó bẹ́ sáré. Wọ́n ṣètò àwọn tó fara gbọgbẹ́ náà, wọ́n sì kó wọn wọnú ibi tá a ti máa ṣe iṣẹ́ abẹ fún wọn. Irin ni wọ́n fi ṣe àwọn yàrá kéékèèké tá à ń lò náà, wọ́n sì ní ẹ̀rọ amúlétutù. Àwọn tó wà níbi àyè kékeré tá a ti ń ṣiṣẹ́ abẹ náà ni dókítà oníṣẹ́ abẹ kan, oníṣègùn kan tó ń fúnni lábẹ́rẹ́ apàrora àtàwọn nọ́ọ̀sì méjì, wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n lè gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là. Mo ṣàkíyèsí pé wọn ò já àwọn ẹrù kan nínú àwọn báàgì dúdú ńlá kúrò nínú àwọn hẹlikọ́pítà. Wọ́n sọ fún mi pé ẹ̀yà ara àwọn sójà tí wọ́n ti já jálajàla lójú ogun ló wà nínú àwọn báàgì náà. Bí mo ṣe dójú ogun nìyẹn.

MO BẸ̀RẸ̀ SÍ Í WÁ ỌLỌ́RUN

Nígbà tí mo wà ní kékeré, mo mọ díẹ̀ lára ẹ̀kọ́ òtítọ́

Nígbà tí mo wà ní kékeré, mo mọ díẹ̀ lára ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ni. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ ìyá mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ kò tẹ̀ síwájú torí náà kò ṣèrìbọmi. Mo máa ń wà níbi tí wọ́n ti ń kọ́ ìyá mi lẹ́kọ̀ọ́, mo sì máa ń gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gan-an. Láwọn ìgbà yẹn, èmi àti ọkọ ìyá mi kọjá níbi tí Gbọ̀ngàn Ìjọba kan wà. Mo bi í pé, “Kí ni wọ́n ń ṣe níbi yìí?” Ó sọ pé, “O ò gbọ́dọ̀ sún mọ́ àwọn èèyàn yẹn láé!” Nítorí pé mo nífẹ̀ẹ́ ọkọ ìyá mi, mo sì fọkàn tán an, mo tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, mi ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́.

Lẹ́yìn tí mo dé láti Vietnam, ó ń wù mí kí n fi ayé mi fún Ọlọ́run. Àmọ́, àwọn nǹkan burúkú tójú mi ti rí mú kí n ya ọ̀dájú. Ó jọ pé kò sẹ́ni tó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ rárá ní Vietnam. Mi ò jẹ́ gbàgbé ìgbà kan tí àwọn alátakò ṣe ìwọ́de, tí wọ́n ń pe àwọn sójà Amẹ́ríkà ní ìkà, apanilọ́mọ nítorí wọ́n gbọ́ pé wọ́n ń pa àwọn ọmọ tí kò mọwọ́mẹsẹ̀ lójú ogun.

Nítorí ebi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń pa mí, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí oríṣiríṣi ṣọ́ọ̀ṣì. Kò sígbà tí ìfẹ́ Ọlọ́run kò sí lọ́kàn mi, àmọ́ ohun tí mò ń rí nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kò wú mi lórí. Níkẹyìn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Delray Beach, ní ìpínlẹ̀ Florida lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ọjọ́ yẹn bọ́ sí Sunday kan ní oṣù February 1971.

Nígbà tí mo wọnú Gbọ̀ngàn Ìjọba, àsọyé fún gbogbo èèyàn ti fẹ́ parí, torí náà, mo dúró de ìpàdé tó máa tẹ̀ le, ìyẹn ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Mi ò rántí ẹ̀kọ́ tí wọ́n jíròrò lọ́jọ́ yẹn, àmọ́ mo ṣì rántí àwọn ọmọ kékeré tí wọ́n ń ṣí Bíbélì wọn láti wá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́. Ìyẹn wú mi lórí gan-an! Mo fetí sílẹ̀ mo sì ń kíyè sí nǹkan tó ń lọ. Bí mo ṣe fẹ́ kúrò ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, arákùnrin kan tó jẹ́ ẹni ọgọ́rin [80] ọdún wá bá mi. Orúkọ rẹ̀ ń  jẹ́ Jim Gardner. Ó na ìwé kan sí mi, orúkọ rẹ̀ ni, Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye, ó sì sọ fún mi pé, “Jọ̀ọ́ gba ìwé yìí.” A ṣàdéhùn pé àárọ̀ ọjọ́ Thursday ni ìgbà àkọ́kọ́ tá a máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Mo ní láti lọ síbi iṣẹ́ lálẹ́ ọjọ́ Sunday yẹn. Ilé ìwòsàn àdáni kan ní Boca Raton, nílùú Florida ni mo ti ń ṣiṣẹ́, yàrá tí wọ́n ti ń bójú tó ọ̀ràn pàjáwìrì ni mo wà. Aago mọ́kànlá alẹ́ sí méje àárọ̀ niṣẹ́ mi bọ́ sí. Torí pé kò sí ariwo ni òru yẹn, mo fara balẹ̀ ka ìwé tí wọ́n fún mi náà. Bí mo ṣe ń ka ìwé yẹn, àgbà nọ́ọ̀sì kan wá sọ́dọ̀ mi, ó já ìwé náà gbà, ó wo orúkọ ìwé náà, ó sì jágbe mọ́ mi pé, “Ṣé kì í ṣe pé o fẹ́ di ọ̀kan lára àwọn èèyàn yìí?” Mo já ìwé mi gbà pa dà lọ́wọ́ rẹ̀, mo sì sọ fún un pé, “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ka ìwé náà dé ìdajì ni, àmọ́ ó jọ pé màá dara pọ̀ mọ́ wọn!” Bó ṣe fi mí sílẹ̀ nìyẹn, mo sì ń ka ìwé náà lọ lóru yẹn títí mo fi kà á tán.

Jim Gardner ló kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹni àmì òróró ni, ó sì mọ Charles Taze Russell

Nígbà àkọ́kọ́ tí Arákùnrin Gardner máa bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Tóò, kí la máa kẹ́kọ̀ọ́ ná?” Ó dáhùn pé, “Ìwé ti mo fún ẹ la máa kẹ́kọ̀ọ́.” Mo sọ fún un pé, “Aà, mo ti kà á tán.” Arákùnrin Gardner dá mi lóhùn tìfẹ́tìfẹ́ pé, “Ó dáa, jẹ́ ká jọ jíròrò orí àkọ́kọ́.” Ó yà mí lẹ́nu gan-an pé ọ̀pọ̀ nǹkan tí mo rò pé mo mọ̀ ni mi ò mọ̀. Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé yẹn, ó ní kí n ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nínú Bíbélì mi, ìyẹn Bíbélì King James tí wọ́n fi lẹ́tà pupa kọ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù. Ìsinsìnyí ni mo mọ̀ pé mò ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́. Arákùnrin Gardner, tí mo gbádùn àtimáa pè ní Jim kọ́ mi ní orí mẹ́tà nínú ìwé Òtítọ́ láàárọ̀ ọjọ́ yẹn. Látọjọ́ yẹn, ní gbogbo ọjọ́ Thursday, orí mẹ́ta mẹ́ta la máa ń kẹ́kọ̀ọ́. Mo máa ń gbádùn àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gan-an. Ẹ wo àǹfààní ńlá tí mo ní pé ẹni àmì òróró ló kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́, ó sì mọ arákùnrin Charles T. Russell dáadáa!

Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mélòó kan, wọ́n fọwọ́ sí i pé kí n di akéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí kò tíì ṣèrìbọmi. Jim ràn mí lọ́wọ́ kí n lè borí àwọn àníyàn mi, títí kan ìṣòro tí mo ní nípa iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. (Ìṣe 20:20) Torí pé mo máa ń bá Jim ṣiṣẹ́, mo wá ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù. Títí dòní olónìí, mo ka iṣẹ́ ìwàásù sí àǹfààní ńlá tí mo ní. Ẹ wo bí inú mi ṣe dùn tó pé mo jẹ́ alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run!—1 Kọ́r. 3:9.

ÌFẸ́ TÍ MO NÍ FÚN JÈHÓFÀ LÁTÌBẸ̀RẸ̀

Ẹ jẹ́ kí n wá sọ ọ̀rọ̀ tó kàn mi gan-an fún yín, ìyẹn ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà látìbẹ̀rẹ̀. (Ìṣí. 2:4) Ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà yìí ti ràn mí lọ́wọ́ láti borí ìdààmú ọkàn tí mo máa ń ní nígbà tí mo bá rántí ohun tójú mi rí lójú ogun àtàwọn àdánwò míì.—Aísá. 65:17.

Ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ láti borí ìdààmú ọkàn tí mo máa ń ní nígbà tí mo bá rántí ohun tójú mi rí lójú ogun àtàwọn ìdánwò míì

Mo ṣèrìbọmi ní July 1971 ní Àpéjọ Àgbègbè “Orukọ Atọrunwa” tá a ṣe ní pápá ìṣeré Yankee Stadium

Mo rántí ọjọ́ kan ní ìgbà ìrúwé ọdún 1971, ọjọ́ ńlá lọjọ́ náà. Ọkọ ìyá mi ṣẹ̀ṣẹ̀ lé mi jáde nínú yàrá tí àwọn méjèèjì ní kí n máa gbé ni. Ó sọ pé òun ò lè gbà láé kí Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa bá òun gbélé! Ó wá ṣẹlẹ̀ pé mi ò lówó lọ́wọ́ lásìkò yẹn. Ọ̀sẹ̀ méjì-méjì ni wọ́n máa ń sanwó fún mi nílé ìwòsàn tí mo ti ń ṣiṣẹ́, mo sì ṣẹ̀ṣẹ̀ fi owó ọwọ́ mi ra àwọn aṣọ tuntun ni kí n lè máa gbé ògo Jèhófà yọ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù mi. Mo ṣì ní owó nípamọ́, àmọ́ Báńkì tó wà ní ìpínlẹ̀ Michigan, níbi tí mo gbé dàgbà ni owó náà wà. Nítorí náà, mo ní láti máa sùn nínú mọ́tò mi fún àwọn ọjọ́ mélòó kan. Àwọn ilé ìwẹ̀ tó wà láwọn ilé epo ni mo ti máa ń wẹ̀ tí mo sì ti máa ń fá irùgbọ̀n mi.

Ní ọ̀kan lára àwọn ọjọ́ ti mò fi sùn inú mọ́tò mi, mo lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba bí mo ṣe ń bọ̀ láti ilé ìwòsàn tí mo ti ń ṣiṣẹ́, mo dé Gbọ̀ngàn Ìjọba ni nǹkan bíi wákàtí méjì kí àwọn ará tó fẹ́ lọ sóde ẹ̀rí tó dé. Bí mo ṣe jókòó sẹ́yìn Gbọ̀ngàn Ìjọba níbi tí ẹnikẹ́ni kò ti lè rí mi, bẹ́ẹ̀ ni èrò àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lójú ogun Vietnam tún pa dà sọ́kàn mi. Ó dà bíi pé mò ń gbóòórùn àwọn èèyàn tí wọ́n finá sun, tí àgbàrá ẹ̀jẹ̀ sì ń ṣàn. Nínú ọpọlọ mi lọ́hùn-ún, mò ń rí àwọn ọ̀dọ́kùnrin kan, mo sì ń gbọ́ tí wọ́n ń bẹ̀ mí pé, “Ṣé mi ò ní kú báyìí? Jọ̀ọ́, má jẹ́ n kú.” Mo mọ̀ pé wọ́n máa kú, àmọ́ mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti tù wọ́n nínú pé wọn ò ní kú, láìjẹ́ kó hàn lójú mi pé wọn máa tó kú. Bí mo ṣe jókòó sẹ́yìn Gbọ̀ngàn Ìjọba yẹn, ńṣe ni ìbànújẹ́ dorí mi kodò.

Mo máa ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe, kí ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà látìbẹ̀rẹ̀ má bàa yingin pàápàá nígbà tí mo bá dojú kọ àdánwò àti ìṣòro

Bí mo ṣe ń gbàdúrà, bẹ́ẹ̀ ni omi ń dà lójú mi pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀. (Sm. 56:8) Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú gan-an nípa ìgbà táwọn òkú máa jíǹde. Ohun kan wá sọ sí mi lọ́kàn: Nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run bá jí àwọn òkú dìde, a ò ní máa rántí ìpakúpa tó wáyé mọ́, ẹ̀dùn ọkàn tó sì máa ń báni kò ní sí mọ́. Ọlọ́run máa jí àwọn ọ̀dọ́kùnrin yẹn dìde, wọ́n á sì lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. (Ìṣe 24:15) Bí mo ṣe ń ronú nípa àjíǹde yìí, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ mi fún Jèhófà túbọ̀ ń jinlẹ̀ gidigidi lọ́kàn mi. Mi ò jẹ́ gbàgbé ọjọ́ yẹn láé. Látìgbà yẹn, mo máa ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe kí ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà látìbẹ̀rẹ̀ má bàa yingin, pàápàá nígbà tí mo bá dojú kọ àdánwò àti ìṣòro.

JÈHÓFÀ TI ṢE MÍ LÓORE GAN-AN

Nígbà ogun, àwọn èèyàn máa ń hùwàkiwà, kò sì yọ èmi náà sílẹ̀. Àmọ́, méjì lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí mo fẹ́ràn gan-an, tí mo sì máa ń ronú lé lórí ti ràn mí lọ́wọ́. Àkọ́kọ́ ni Ìṣípayá 12:10, 11, tó sọ pé a ṣẹ́gun Èṣù, kì í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ ìjẹ́rìí tá à ń ṣe nìkan, àmọ́ ó tún jẹ́ nítorí ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kejì ni Gálátíà 2:20. Torí ohun tí ẹsẹ yẹn sọ, mo mọ̀ pé Kristi Jésù kú “fún mi.” Jèhófà ń wo ti ẹ̀jẹ̀ Jésù mọ́ mi lára, ó sì ti dárí àwọn ohun tí mo ti ṣe jì mí. Òtítọ́ tí mo mọ̀ yìí ti mú kí n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ó sì ti mú kí n máa ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ káwọn náà lè mọ òtítọ́ nípa Jèhófà, Ọlọ́run wa aláàánú!—Héb. 9:14.

Bí mo bá ń rántí bí mo ṣe gbé ìgbé ayé mi, mo mọrírì ẹ̀ gan-an pé Jèhófà ń bójú tó mi, kò sì pa mí tì rárá. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ tí Jim mọ̀ pé inú mọ́tò ni mò ń gbé, ọjọ́ yẹn gan-an ló fi mí mọ arábìnrin kan tó ní ilé táwọn ọmọléèwé máa ń gbé. Ó dá mi lójú pé Jèhófà ló lo Jim àti arábìnrin ọ̀wọ́n yẹn láti mú kí n ní ibi tó tura tí màá máa gbé. Ká sòótọ́, aláàánú ni Jèhófà! Ó máa ń bójú tó àwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sìn ín.

MO KỌ́ BÉÈYÀN Ò ṢE NÍ MÁA LO ÌTARA LỌ́NÀ ÒDÌ

Ní May 1971, ó di dandan pé kí n lọ sí ìlú wa, ìyẹn Michigan kí n lè bójú tó àwọn nǹkan kan. Kí n tó fi ìjọ Delray Beach tó wà nílùú Florida sílẹ̀, mo di àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kún ẹ̀yìn mọ́tò mi, mo bá forí lé àríwá, níbi tá à ń pè ní Interstate 75. Nígbà tí mo fi máa dé ìpínlẹ̀ Georgia, gbogbo ẹrú ìwé tí mo dì ti tán. Mo fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ibi tí mo dé. Mo dúró láwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n láti wàásù, kódà mo fún àwọn ọkùnrin tó wà nílé ìgbọ̀nsẹ̀ ní àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú. Títí dòní olónìí, mo máa ń bi ara mi pé ṣé àwọn irúgbìn yẹn tiẹ̀ yè.—1 Kọ́r. 3:6, 7.

Kí n sòótọ́, nígbà tí mo kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ béèyàn ṣe ń fọgbọ́n wàásù fúnni, pàápàá tí mo bá ń bá àwọn ará ilé mi sọ̀rọ̀. Torí pé ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà níbẹ̀rẹ̀ ń jó bí iná, mo máa ń fi ìgboyà wàásù, àmọ́ ọ̀rọ̀ mi máa ń le jù. Mo nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹ̀gbọ́n mi gan-an, ìyẹn, John àti Ron, mo sì máa ń wàásù fún wọn tipátipá. Mo pa dà wá tọrọ àforíjì lọ́wọ́ wọn torí ìwà àìgbatẹnirò tí mo hù. Àmọ́, mi ò yé gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí wọ́n rí òtítọ́. Látìgbà yẹn, Jèhófà ti kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́, mo sì ti mọ béèyàn ṣe ń fọgbọ́n wàásù fáwọn èèyàn àti béèyàn ṣe ń kọ́ni.—Kól. 4:6.

MO TÚN NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN MÍÌ

Kò sígbà tí mi ò ní máa rántí ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà, síbẹ̀ mi ò lè gbàgbé ìfẹ́ tí mo ní fún àwọn míì. Lẹ́yìn Jèhófà, ẹni tí mo tún nífẹ̀ẹ́ ni ìyàwó mi ọ̀wọ́n tó ń jẹ́ Susan. Mo mọ̀ pé mo nílò ẹnì kejì táá máa ràn mí lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Akíkanjú obìnrin ni Susan, ó sì jẹ́ ẹni tẹ̀mí. Mo rántí ọjọ́ kan tí mo lọ bẹ̀ ẹ́ wò lásìkò tá à ń fẹ́ra sọ́nà. Iwájú ilé wọn tó wà nílùú Cranston, ní ìpínlẹ̀ Rhode Island ni Susan jókòó sí. Ó ń ka Ilé Ìṣọ́ (èdè Gẹ̀ẹ́sì) tòun ti Bíbélì rẹ̀ lọ́wọ́. Ohun tó wú mi lórí ni pé ọ̀kan lára àwọn àpilẹ̀kọ tí kì í ṣe ti ìkẹ́kọ̀ọ́ ló ń kà, tó sì tún ń yẹ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ inú rẹ̀ wò. Mo sọ lọ́kàn mi pé, ‘Ẹni tẹ̀mí ni obìnrin yìí!’ A ṣègbéyàwó ní December 1971, mo sì máa ń dúpẹ́ pé látìgbà yẹn wá, ó dúró tì mí gbágbáágbá, ó sì ń ràn mí lọ́wọ́. Ohun kan wà tí mo mọrírì nípa rẹ̀, ìyẹn ni pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó nífẹ̀ẹ́ mi, ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ju bó ṣe nífẹ̀ẹ́ mi lọ.

Èmi àti Susan àtàwọn ọmọkùnrin wa, Paul àti Jesse

Ọlọ́run fi ọmọkùnrin méjì kẹ́ èmi àti Susan, àwọn ọmọ náà ni Jesse àti Paul. Bí wọ́n ṣe ń dàgbà, Jèhófà wà pẹ̀lú wọn. (1 Sám. 3:19) Torí pé wọn sọ òtítọ́ di tiwọn, wọ́n máa ń mú inú èmi àti ìyá wọn dùn. Wọ́n ṣì wà nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà títí dòní, torí pé wọn ò gbàgbé ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà látìbẹ̀rẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ti lo ohun tó lé lógún ọdún nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Bákan náà, mo máa ń fi àwọn ìyàwó àwọn ọmọ mi yangàn, ìyẹn, Stephanie àti Racquel, mo sì kà wọ́n sí ọmọ mi. Àwọn obìnrin tó jẹ́ ẹni tẹ̀mí làwọn ọmọkùnrin mi fẹ́ torí pé gbogbo ọkàn wọn làwọn obìnrin náà fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.—Éfé. 6:6.

Mò ń darí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá nígbà tí mo wà lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn àjò

Lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi, mo fi ọdún mẹ́rìndínlógún [16] sìn ní ìpínlẹ̀ Rhode Island ní Amẹ́ríkà, mo sì ní àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà. Inú mi máa ń dùn bí mo bá ń rántí àwọn alàgbà tó nírìírí tí mo bá ṣiṣẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn alábòójútó arìnrìn àjò tí mi ò lè ka iye wọn, tí wọ́n ràn mí lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Ẹ wo àǹfààní ńlá tí mo ní láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí kò gbàgbé ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà látìbẹ̀rẹ̀! Lọ́dún 1987, a ṣí lọ sí ìpínlẹ̀ North Carolina ní Amẹ́ríkà, a lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù ìjọba Ọlọ́run, a sì tún ní àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà míì níbẹ̀. *

Ìdílé wa gbádùn ká máa lọ ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tí a kì í ṣe déédéé

Ní August 2002, wọ́n pe èmi àti Susan pé ká wá di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Patterson lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Mo ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn, Susan sì ń ṣiṣẹ́ ní ibi tí wọ́n ti ń fọṣọ. Ó gbádùn iṣẹ́ tó ń ṣe níbẹ̀ gan-an! Nígbà tó di August 2005, wọ́n fún mí láǹfààní pé kí n di ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Mi ò rò ó rí pé irú àǹfààní yìí tọ́ sí mi. Ọ̀rọ̀ náà máa ń ka ìyàwó mi láyà nígbà tó bá ń ronú nípa ojúṣe, iṣẹ́ àti ìrìn àjò tó ń bá àǹfààní náà rìn. Ẹ̀rù máa ń ba Susan láti wọkọ̀ òfúrufú, síbẹ̀ a ò yé fò lójú ọ̀run! Susan sọ pé ọ̀rọ̀ tí àwọn ìyàwó àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń bá òun sọ tìfẹ́tìfẹ́ ti ran òun lọ́wọ́ gan-an, ìyẹn sì ti mú kóun máa tì mí lẹ́yìn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Kò sí àní-àní, ó ń tì mí lẹ́yìn gan-an, mo sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ torí pé ó ń ṣe bẹ́ẹ̀.

Ọ̀pọ̀ fọ́tò ló wà ní ọ́fíìsì mi, ojú pàtàkì sì ni mo fi ń wò wọ́n! Wọ́n máa ń jẹ́ kí ń rántí ìgbésí ayé alárinrin tí mò ń gbádùn títí dòní. Èrè tó pọ̀ ni mo ti rí gbà torí pé mò ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti máa rántí ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà látìbẹ̀rẹ̀!

Inú mi máa ń dùn gan-an nígbà tí mo bá wà pẹ̀lú ìdílé mi

^ ìpínrọ̀ 31 Kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí Arákùnrin Morris ṣe ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún wà ní ojú ìwé 26 nínú Ilé Ìṣọ́ March 15, 2006.