Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Gbé Ìgbé Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Àdúrà Àwòṣe Náà—Apá Kejì

Máa Gbé Ìgbé Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Àdúrà Àwòṣe Náà—Apá Kejì

“Baba yín mọ àwọn ohun tí ẹ ṣe aláìní.”—MÁT. 6:8.

1-3. Kí nìdí tó fi dá arábìnrin kan lójú pé Jèhófà mọ ohun tí a nílò?

ARÁBÌNRIN Lana kò jẹ́ gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 2012 ní orílẹ̀-èdè Jámánì. Ó mọ̀ pé Jèhófà dáhùn àdúrà méjì kan tí òun gbà. Inú ọkọ̀ ojú irin tó ń lọ sí pápákọ̀ òfuurufú ló ti gbàdúrà àkọ́kọ́ pé kí Jèhófà jẹ́ kí àǹfààní ṣí sílẹ̀ fún òun láti wàásù. Nígbà tó dé pápákọ̀ òfuurufú, ó gbọ́ pé ọkọ̀ òfuurufú tó máa gbé òun kò ní lọ mọ́ lọ́jọ́ yẹn, ó di ọjọ́ kejì. Lana tún gbàdúrà sí Jèhófà, torí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ná owó tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ tán, kò sì sí ibi tó máa sùn sí di ọjọ́ kejì.

2 Kódà Lana ò tíì parí àdúrà tó ń gbà tó fi gbọ́ tẹ́nì kan sọ pé, “Lana, ìwọ nìyẹn, kí lò ń ṣe níbí?” Ọkùnrin kan tí òun àti Lana jọ lọ sí ilé ìwé nígbà kan rí ló ń bá a sọ̀rọ̀. Ọkùnrin náà ń lọ sí orílẹ̀-èdè South Africa, ìyá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ àgbà sìn ín wá wọ ọkọ̀ òfuurufú. Nígbà tí Lana sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wọn, ìyá ọkùnrin náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elke sọ fún Lana pé kó wá sùn sí ilé àwọn. Elke àti ìyá rẹ̀ ṣe Lana lálejò, wọ́n sì ń bi í ní ìbéèrè nípa ohun tó gbà gbọ́ àti iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tó ń ṣe.

3 Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, lẹ́yìn tí wọ́n jẹ oúnjẹ aládùn kan tán, Lana tún bẹ̀rẹ̀ sí í dáhùn àwọn ìbéèrè míì látinú Bíbélì, ó wá gba àdírẹ́sì àti nọ́ńbà fóònù wọn kí ó lè ṣètò bí wọ́n á ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lana dé ilé láyọ̀, ó sì ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà rẹ̀ nìṣó. Ó mọ̀ pé “Olùgbọ́ àdúrà” lọ́wọ́ sí bí gbogbo nǹkan ṣe yọrí sí rere.—Sm. 65:2.

4. Àwọn ohun tá a nílò wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Kì í ṣòro fún wa láti gbàdúrà sí Jèhófà tí a bá ṣàdédé bá ara wa nínú ìṣòro, inú Jèhófà sì máa ń dùn láti gbọ́ irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀ táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ gbà. (Sm. 34:15; Òwe 15:8) Àmọ́ tá a bá ronú lórí àdúrà àwòṣe náà, a lè rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó ṣe pàtàkì wà tá à ń gbójú fò. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí i pé apá mẹ́ta tó kẹ́yìn nínú àdúrà àwòṣe náà dá lórí àwọn ohun tá a nílò nípa tẹ̀mí. Ǹjẹ́ àwọn nǹkan kan ṣì wà tí a lè ṣe ká lè máa gbé ìgbé ayé wa ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí apá kẹrin àdúrà náà sọ pé ká bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹ òòjọ́ wa?—Ka Mátíù 6:11-13.

“FÚN WA LÓNÌÍ OÚNJẸ WA FÚN ỌJỌ́ ÒNÍ”

5, 6. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní, ká tiẹ̀ sọ pé a ní ohun tó pọ̀ tó nípa tara?

5 Ẹ kíyè sí i pé ìbéèrè ara ẹni yìí kì í wulẹ̀ ṣe pé fún “mi” ní oúnjẹ fún ọjọ́ òní, àmọ́ fún “wa” ní oúnjẹ fún ọjọ́ òní. Alábòójútó àyíká kan nílẹ̀ Áfíríkà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Victor sọ pé: “Mo sábà máa ń fi tọkàntọkàn dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé èmi àti ìyàwó mi kì í dààmú lórí ohun tá a máa jẹ tàbí bá a ṣe máa rí owó ilé san. Àwọn ará ló máa ń fìfẹ́ bójú tó wa lójoojúmọ́. Àmọ́, mo máa ń gbàdúrà pé kí àwọn tó ń ràn wá lọ́wọ́ lè rí ọ̀nà láti bójú tó ìṣúnná owó wọn.”

6 Tá a bá ní oúnjẹ tó pọ̀ tó láti jẹ fáwọn ìgbà kan, a lè ronú kan àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ṣaláìní tàbí àwọn tí ìjábá ti ba nǹkan ìní wọn jẹ́. Kì í ṣe pé ká kàn gbàdúrà fún wọn nìkan, àmọ́ ká tún ṣe ohun tó bá àdúrà náà mu. Bí àpẹẹrẹ, a lè fún àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni tí wọ́n ṣaláìní látinú ohun tá a ní. Bákan náà, a lè máa fi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé déédéé, bá a ṣe mọ̀ pé a máa ń lo irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó yẹ.—1 Jòh. 3:17.

7. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà ṣàpèjúwe ìmọ̀ràn tó fún wa pé ká “má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la”?

7 Nígbà tí Jésù mẹ́nu kan oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ohun tá a nílò lójú ẹsẹ̀ ló ní lọ́kàn. Torí náà, ó sọ̀rọ̀ lórí bí Ọlọ́run ṣe ń wọ àwọn òdòdó pápá láṣọ, ó wá sọ pé: “Òun kì yóò ha kúkú wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ẹ ní ìgbàgbọ́ kíkéré? Nítorí náà, ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, . . . ‘Kí ni a ó wọ̀?’” Ó fún wa ní ìmọ̀ràn kan tó ṣe pàtàkì láti fi kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la.” (Mát. 6:30-34) Èyí fi hàn pé, kàkà tá a fi máa to àwọn nǹkan ìní tara jọ, ńṣe ló yẹ ká ní ìtẹ́lọ́rùn tá a bá ti ní àwọn ohun kòṣeémáàní ojoojúmọ́. Lára rẹ̀ ní ilé tó bójú mu, iṣẹ́ táá jẹ́ ká lè máa pèsè fún àwọn ìdílé wa àti bá a ṣe lè máa fọgbọ́n lo ìlera wa. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan ìní tara yẹn nìkan lá ń sọ nínú àdúrà wa, á jẹ́ pé tara wa nìkan la mọ̀ nìyẹn. Àmọ́ o, àwọn nǹkan kan wà tá a nílò nípa tẹ̀mí tí wọ́n ṣe pàtàkì ju ohunkóhun mìíràn lọ.

8. Ohun pàtàkì tá a nílò wo ni Jésù rán wa létí rẹ̀ bó ṣe mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ oúnjẹ òòjọ́ wa? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

8 Bí Jésù ṣe mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ oúnjẹ òòjọ́ wa yẹ kó rán wa létí pé a nílò oúnjẹ tẹ̀mí. Jésù Ọ̀gá wa sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mát. 4:4) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo pé kí Jèhófà máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sákòókò fún wa.

“DÁRÍ ÀWỌN GBÈSÈ WA JÌ WÁ”

9. Ọ̀nà wo ni àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa gbà jẹ́ “gbèsè”?

9 Kí nìdí tí Jésù fi lo ọ̀rọ̀ náà “gbèsè,” nígbà tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀ṣẹ̀” ló lò nígbà míì tó ń sọ̀rọ̀? (Mát. 6:12; Lúùkù 11:4) Ní ohun tó lé ní ọgọ́ta [60] ọdún sẹ́yìn, ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ sí òfin Ọlọ́run mú ká jẹ Ọlọ́run ní gbèsè. . . . Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, Ọlọ́run lè gba ẹ̀mí wa. . . . Ó lè mú àlááfíà rẹ̀ kúrò lára wa, kó sì já gbogbo àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ kúrò. . . . A jẹ ẹ́ ní gbèsè ìfẹ́, ìgbọ́ràn wa ló sì máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀; tí a bá wá dá ẹ̀ṣẹ̀, a ti kùnà láti san gbèsè ìfẹ́ wa fún un nìyẹn, kò sì fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí a bá ń dá ẹ̀ṣẹ̀.”—1 Jòh. 5:3.

10. Kí ló lè mú kí Jèhófà dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, báwo ló sì ṣe yẹ kí èyí rí lára wa?

10 Nítorí pé a ní láti máa tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lójoojúmọ́, Ọlọ́run pèsè ẹbọ ìràpadà Jésù tó jẹ́ ìlànà kan ṣoṣo tó bá òfin mu tí Jèhófà lè fi pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún tí ìràpadà náà ti wáyé, ó yẹ ká mọrírì rẹ̀ bí ẹni pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ rí i gbà lónìí. “Iye owó ìtúnràpadà” tí Jésù san “ṣe iyebíye tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́” tó fi jẹ́ pé kò sí ohunkóhun tí ẹ̀dá èèyàn aláìpé èyíkéyìí lè ṣe fún wa tó lè sún mọ́ àtisan ìràpadà náà. (Ka Sáàmù 49:7-9; 1 Pétérù 1:18, 19.) Torí náà, ńṣe ló yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ẹ̀bùn bàǹtàbanta yìí nígbà gbogbo. Bákan náà, gbólóhùn náà “àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa,” dípò “àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi” yẹ kó máa rán wa létí pé gbogbo àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà ni ìpèsè onífẹ̀ẹ́ yìí wúlò fún. Ó ṣe kedere pé, Jèhófà kò fẹ́ kí ọ̀rọ̀ ipò tẹ̀mí tara wa nìkan jẹ wá lógún, ó fẹ́ ká ro ti àwọn ẹlòmíì náà, títí kan àwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n ti ṣẹ̀ wá. Lọ́pọ̀ ìgbà sì rèé, irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ kì í tó nǹkan. Torí náà, àǹfààní ló jẹ́ fún wa láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa àti pé a múra tán láti dárí jì wọ́n, bí Ọlọ́run náà ṣe ń fi àánú hàn sí wa tó sì ń dárí jì wá.—Kól. 3:13.

Tó o bá fẹ́ kí Ọlọ́run dárí jì ẹ́, ìwọ náà gbọ́dọ̀ máa dárí ji àwọn ẹlòmíì (Wo ìpínrọ̀ 11)

11. Kí nìdí tó fi yẹ ká ní ẹ̀mí ìdáríjini?

11 Torí a jẹ́ aláìpé, ó ṣeni láàánú pé nígbà míì a máa ń di àwọn èèyàn sínú. (Léf. 19:18) Tá a bá lọ ro ẹjọ́ fáwọn ẹlòmíì, wọ́n lè gbè sẹ́yìn wa, ìyẹn sì lè fa ìpínyà nínú ìjọ. Tí a bá fàyè gba irú ẹ̀mí yìí, ńṣe là ń fi hàn pé a kò mọrírì àánú Ọlọ́run àti ẹ̀bùn ìràpadà náà nìyẹn. Tí a kò bá ní ẹ̀mí ìdáríjini, Baba wa kò ní jẹ́ kí ìtóye ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀ ṣiṣẹ́ fún wa mọ́. (Mát. 18:35) Jésù túbọ̀ ṣàlàyé lórí kókó yìí ní gbàrà tó sọ àdúrà àwòṣe náà tán. (Ka Mátíù 6:14, 15.) Paríparí rẹ̀, tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run dárí jì wá, a gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa kí á má ṣe sọ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì dàṣà. Ní báyìí, tó ti wù wá láti máa sá fún ẹ̀ṣẹ̀, àdúrà ẹ̀bẹ̀ míì ló tún kàn.—1 Jòh. 3:4, 6.

“MÁ SÌ MÚ WA WÁ SÍNÚ ÌDẸWÒ”

12, 13. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Jésù kété tó ṣèrìbọmi tán? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ kí á máa di ẹ̀bi ru àwọn ẹlòmíì tó bá ṣẹlẹ̀ pé a kó sínú ìdẹwò? (d) Kí ni Jésù fi hàn bó ṣe jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú?

12 Tá a bá ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù kété tó ṣèrìbọmi tán, a óò lóye ìdí tó fi yẹ ká gbàdúrà pé: “Má . . . mú wa wá sínú ìdẹwò.” Ẹ̀mí Ọlọ́run ṣamọ̀nà Jésù lọ sínú aginjù. Kí nìdí? “Kí Èṣù lè dẹ ẹ́ wò.” (Mát. 4:1; 6:13) Ǹjẹ́ ó yẹ kí èyí yà wá lẹ́nu? Kò ní yà wá lẹ́nu tá a bá lóye ìdí tí Ọlọ́run fi rán Ọmọ rẹ̀ wá sí ayé. Ìdí rẹ̀ ni pé kó wá yanjú ọ̀ràn tó jẹ yọ nígbà tí Ádámù àti Éfà kọ Ọlọ́run ní Ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Àwọn ìbéèrè kan yọjú tó máa gba àkókò kó tó lè níyanjú. Bí àpẹẹrẹ, ṣé àṣìṣe kankan wà nínú ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá èèyàn ni? Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí ẹ̀dá èèyàn pípé fara mọ́ ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, kódà bí “ẹni burúkú náà” tiẹ̀ ń fínná mọ́ ọn? Àti pé, gẹ́gẹ́ bí Sátánì ṣe sọ, ṣé nǹkan máa sàn fáwọn ẹ̀dá èèyàn tí wọ́n ò bá sí lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run. (Jẹ́n. 3:4, 5) Ó máa gba àkókò ká tó lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, àmọ́ ìdáhùn wọn máa jẹ́ kí gbogbo èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì mọ̀ pé ọ̀nà tó tọ́ ni Jèhófà gbà ń lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba aláṣẹ.

13 Jèhófà jẹ́ mímọ́, torí náà, kò lè fi ibi dán ẹnikẹ́ni wò. Kàkà bẹ́ẹ̀, Èṣù ni “Adẹniwò náà.” (Mát. 4:3) Èṣù lè hùmọ̀ àwọn ipò tó lè fi dẹ wá wò. Síbẹ̀, ó kù sọ́wọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan, yálà a máa gbà kí Sátánì mú wa wá sínú ìdẹwò tàbí a ò ní gbà. (Ka Jákọ́bù 1:13-15.) Ní ti Jésù, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá a mu láti kọ ìdẹwò kọ̀ọ̀kan tí Sátánì gbé síwájú rẹ̀. Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun fara mọ́ ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Àmọ́ Sátánì ò jáwọ́ o. Ó dúró “títí di àkókò mìíràn tí ó wọ̀.” (Lúùkù 4:13) Síbẹ̀, Jésù ń bá a nìṣó láti máa dènà gbogbo ìsapá Sátánì láti mú kó di aláìṣòótọ́. Kristi fìdí ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ múlẹ̀, ó sì fi hàn pé ẹ̀dá èèyàn pípé lè jẹ́ olóòótọ́ kódà lójú àdánwò tó le koko jù lọ. Àmọ́ ṣá o, Sátánì ń dá gbogbo ọgbọ́n kó lè dẹkùn mú àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, kò sì yọ ìwọ náà sílẹ̀.

14. Kí ló yẹ ká ṣe tí a kò bá fẹ́ kó sínú ìdẹwò?

14 Torí àríyànjiyàn tó ń lọ lọ́wọ́ lórí ipò Ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, Jèhófà fàyè gba Adẹniwò náà pé kó lo ayé yìí láti fi dẹ wá wò. Ọlọ́run kọ́ ló ń mú wa wá sínú ìdẹwò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fọkàn tán wa, ó sì fẹ́ ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́ o, torí pé Jèhófà fún wa lómìnira láti yan òun tó wù wá, kì í dédé yọ wá ká máa bàa kó sínú ìdẹwò. A ní láti ṣe ohun méjì kan. Àkọ́kọ́ ni pé ká wà lójúfò nípa tẹ̀mí. Ìkejì sì ni pé ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo. Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà wa?

Máa fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà, má sì jẹ́ kí ìtara rẹ jó rẹ̀yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù (Wo ìpínrọ̀ 15)

15, 16. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìdẹwò tá a ní láti sá fún? (b) Ta ló yẹ ká dá lẹ́bi tí ẹnì kan bá kó sínú ìdẹwò?

15 Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tó lágbára, tó lè fún wa nígboyà kó sì mú ká yàgò fún ìdẹwò. Ọlọ́run tún ń lo Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ìjọ rẹ̀ láti kìlọ̀ fún wa ká lè mọ àwọn nǹkan tá a gbọ́dọ̀ yẹra fún, irú bíi ká máa lo okun wa, owó àti àkókò tó pọ̀ jù lórí àwọn nǹkan ìní tara tí kò pọn dandan. Espen àti ìyàwó rẹ̀ tó ń jẹ́ Janne ń gbé ní orílẹ̀-èdè kan tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù nílẹ̀ Yúróòpù. Ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé ní ibì kan lórílẹ̀-èdè náà tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Àmọ́ nígbà tí wọ́n bí àkọ́bí wọn, wọ́n fi iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀, wọ́n sì ti bí ọmọ kejì báyìí. Arákùnrin Espen sọ pé: “A máa ń gbàdúrà ní gbogbo ìgbà sí Jèhófà pé ká má ṣe kó sínú ìdẹwò ní báyìí tó jẹ́ pé a ò lè lo àkókò tó pọ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ bíi ti ìgbà kan. A máa ń bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀, kí ìtara wa má sì jó rẹ̀yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.”

16 Ìdẹwò míì tó tún gbòde kan lóde òní ni wíwo àwòrán, fídíò tàbí gbígbọ́ àwọn orin tó ń mú kí ọkàn ẹni fà sí ìṣekúṣe. Ǹjẹ́ a lè dá Sátánì lẹ́bi tá a bá kó sínú ìdẹwò yìí? Rárá o. Kí nìdí? Ìdí ni pé Sátánì àti ayé yìí ò lè fipá mú wa ṣe ohun tí kò wù wá. Àwọn kan ti jẹ́ kí ìdẹwò yìí dẹkùn mú wọn torí pé wọ́n fàyè gba èròkerò lọ́kàn wọn. Àmọ́, ó dájú pé a lè sá fún un. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló sì ti ṣe bẹ́ẹ̀.—1 Kọ́r. 10:12, 13.

“DÁ WA NÍDÈ KÚRÒ LỌ́WỌ́ ẸNI BURÚKÚ NÁÀ”

17. (a) Báwo la ṣe lè gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá àdúrà náà mu pé kí Ọlọ́run dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà? (b) Ìtura wo ló dé tán?

17 Tí a bá fẹ́ gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá àdúrà náà mu pé kí Ọlọ́run “dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà,” a gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti má ṣe jẹ́ “apá kan ayé [Sátánì].” A kò gbọ́dọ̀ “nífẹ̀ẹ́ yálà ayé [Sátánì] tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé.” (Jòh. 15:19; 1 Jòh. 2:15-17) Èyí kì í ṣe ohun tá à ń ṣe lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo o, a gbọ́dọ̀ máa ṣe é ní gbogbo ìgbà. Ìtura gbáà ló máa jẹ́ nígbà tí Jèhófà bá dáhùn àdúrà yìí tó sì mú Sátánì àti ayé rẹ̀ kúrò! Àmọ́, ẹ jẹ́ ká rántí pé nígbà tí wọ́n lé Sátánì kúrò lọ́run, ó mọ̀ pé àkókò tí òun ní kéré gan-an. Pẹ̀lú ìbínú ló fi ń jà fitafita kó lè ba ìṣòtítọ́ wa jẹ́. Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀.—Ìṣí. 12:12, 17.

18. Tá a bá fẹ́ la òpin ayé Sátánì yìí já, kí la gbọ́dọ̀ máa ṣe?

18 Ǹjẹ́ ó wù ọ́ kírú àsìkò aláyọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣojú rẹ? Tó bá wù ẹ́, máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́, kó sì mú kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé. Máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó pèsè àwọn ohun tó o nílò nípa tẹ̀mí àti nípa tara fún ọ. Torí náà, pinnu pé wàá máa gbé ìgbé ayé rẹ ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà àwòṣe náà.