Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Nílò Ìfaradà”

“Ẹ Nílò Ìfaradà”

LẸ́YÌN tí Anita * ṣèrìbọmi, tó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọkọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni tó rorò sí i. Anita sọ pé: “Kò jẹ́ kí n lọ sípàdé, kódà ó lóun ò gbọ́dọ̀ gbọ́ orúkọ Ọlọ́run lẹ́nu mi. Tí ọkọ mi bá gbọ́ orúkọ Jèhófà sétí lásán, ńṣe ló máa gbaná jẹ.”

Bí Anita á ṣe kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ nípa Jèhófà tún jẹ́ ìṣòro ńlá míì fún un. Ó sọ pé: “Ọkọ̀ mi ò fàyè gbà ìjọsìn Jèhófà nínú ilé wa. Mi ò lè bá àwọn ọmọ mi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ bó ṣe wù mí, kódà mi ò lè kó wọn lọ sí ìpàdé.”

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Anita yìí fi hàn pé, inúnibíni látọ̀dọ̀ àwọn ìdílé lè dán ìṣòtítọ́ Kristẹni kan wò lọ́nà tó lágbára. Bákan náà, àìsàn lílekoko, ikú ọmọ, ọkọ tàbí aya ẹni kan, tàbí kí ẹnì kan nínú ìdílé fi Jèhófà sílẹ̀ lè dán ìgbàgbọ́ ẹni wò. Torí náà, kí ló lè mú kí Kristẹni kan jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà?

Tó o bá dojú kọ irú àdánwò bẹ́ẹ̀, kí lo máa ṣe? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ nílò ìfaradà.” (Héb. 10:36) Àmọ́, kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí wàá fi lè ní ìfaradà?

GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ KÓ O SÌ MÁA GBÀDÚRÀ SÍ I

Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà pàtàkì tó máa jẹ́ ká lókun láti lè fara da àdánwò ni pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run ká sì máa gbàdúrà sí i. Gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò. Àjálù kan dé bá Ana àti ìdílé rẹ̀ ní ọ̀sán ọjọ́ Monday kan. Ọkọ rẹ̀ tí kò tíì ju ọgbọ̀n [30] ọdún tí wọ́n ti fẹ́ra ṣàdédé gbẹ́mìí mì. Ana sọ pé: “Ibiṣẹ́ ló lọ, a ò sì rí i kó pa dà wálé mọ́. Kò sì tíì ju ẹni ọdún méjìléláàádọ́ta [52] lọ.”

Báwo ni Ana ṣe fara da àjálù tó dé bá a yìí? Ó di dandan pé kó pa dà sẹ́nu iṣẹ́, èyí sì ràn án lọ́wọ́ gan-an torí ó gba pé kó máa fi gbogbo ọkàn ṣe iṣẹ́ rẹ̀, àmọ́ èyí kò mú ẹ̀dùn ọkàn tó ní kúrò. Ó sọ pé: “Mo sọ gbogbo ẹ̀dùn ọkàn mi fún Jèhófà, mo sì bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kí n lè fara da àdánù ńlá tó dé bá mi yìí.” Ṣé Jèhófà dáhùn àdúrà rẹ̀? Ó dá Ana lójú pé Jèhófà dáhùn àdúrà rẹ̀. Ó sọ pé: “Àlàáfíà tó jẹ́ pé Ọlọ́run nìkan ló lè fúnni tù mí lára, ó sì gbà mí lọ́wọ́ àròkàn tó lè yíni lórí. Ó dá mi lójú pé Jèhófà máa jí ọkọ mi dìde nígbà àjíǹde.”—Fílí. 4:6, 7.

“Olùgbọ́ àdúrà” ti ṣèlérí fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé òun máa pèsè gbogbo nǹkan tó máa jẹ́ kí wọ́n lè máa jẹ́ olóòótọ́ nìṣó fún wọn. (Sm. 65:2) Ǹjẹ́ ìlérí yìí kò túbọ̀ fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun? Ṣé ó jẹ́ kó o rí ìdí tó fi yẹ kíwọ náà máa fara dà á nìṣó?

ÀWỌN ÌPÀDÉ ÌJỌ JẸ́ ORÍSUN ÌTÌLẸ́YÌN

Jèhófà máa ń lo ìpàdé ìjọ láti fi ti àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, lákòókò kan tí wọ́n ń ṣe inúnibíni líle koko sáwọn ará ìjọ Tẹsalóníkà, Pọ́ọ̀lù rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ‘máa tu ara wọn nínú lẹ́nì kìíní-kejì, kí wọ́n sì máa gbé ara wọn ró lẹ́nì kìíní-kejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń ṣe ní tòótọ́.’ (1 Tẹs. 2:14; 5:11) Torí pé àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà ṣe ara wọn lọ́kan nínú ìfẹ́ tí wọ́n sì ń ran ara wọn lọ́wọ́, ó ṣeé ṣe fún wọn láti fara da àdánwò ìgbàgbọ́ náà. Àkọsílẹ̀ tó wà nípa ìfaradà wọn jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún wa lónìí, wọ́n sì tún jẹ́ ká mọ ohun táwa náà lè ṣe ká lè ní ìfaradà.

Tá a bá sọ àwọn ará ìjọ di ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́, èyí á jẹ́ ká lè máa ṣe “àwọn ohun tí ń gbéni ró fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (Róòmù 14:19) Èyí ṣe pàtàkì gan-an pàápàá nígbà ìṣòro. Pọ́ọ̀lù pàápàá dojú kọ ọ̀pọ̀ inúnibíni, Jèhófà sì fún un lókun láti fara dà á. Láwọn ìgbà míì, Ọlọ́run máa ń lo àwọn ará láti fún Pọ́ọ̀lù ní ìṣírí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Pọ́ọ̀lù fi ìkíni ránṣẹ́ sáwọn ará tó wà ní ìjọ Kólósè, ó sọ nípa wọn pé: “Àwọn wọ̀nyí gan-an sì ti di àrànṣe afúnnilókun fún mi.” (Kól. 4:10, 11) Torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Pọ́ọ̀lù dénúdénú, èyí mú kí wọ́n fún un lókun kí wọ́n sì tù ú nínú nígbà tó nílò rẹ̀ gan-an. Ó ṣe é ṣe kí ìwọ náà ti gba irú ìṣírí àti ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn ará ìjọ rẹ.

ÌRÀNWỌ́ LÁTỌ̀DỌ̀ ÀWỌN ALÀGBÀ

Ọ̀nà míì wa tí Ọlọ́run ń gbà ràn wá lọ́wọ́ nínú ìjọ Kristẹni, ìyẹn ni nípasẹ̀ àwọn alàgbà. Àwọn ọkùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn yìí lè “dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi, bí òjìji àpáta gàǹgà ní ilẹ̀ gbígbẹ táútáú.” (Aísá. 32:2) Ìdánilójú tó tuni lára mà lèyí o! Ǹjẹ́ ò ń jàǹfààní ìpèsè onífẹ̀ẹ́ yìí? Ìṣírí àti ìtìlẹ́yìn táwọn alàgbà bá fún ọ lè jẹ́ kó o máa fara dà á nìṣó.

Lóòótọ́, àwọn alàgbà kì í ṣe oníṣẹ́ ìyanu. Aláìpé làwọn náà, wọ́n “ní àwọn àìlera kan náà tí [a] ní.” (Ìṣe 14:15) Síbẹ̀, àdúrà ẹ̀bẹ̀ tí wọ́n bá gbà nítorí tiwa lè ṣèrànwọ́ gan-an. (Ják. 5:14, 15) Arákùnrin kan tó wà ní orílẹ̀-èdè Ítálì ti fi ọ̀pọ̀ ọdún fara da àrùn kan tó ń ba iṣan ara jẹ́, ó sọ pé: “Ìfẹ́ àti aájò táwọn ará fi hàn sí mi pa pọ̀ pẹ̀lú bí wọ́n ṣe wá ń kí mi lóòrèkóòrè ti jẹ́ kí n lè fara dà á.” Ǹjẹ́ o lè túbọ̀ jàǹfààní ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ látinú ìpèsè onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà fi àwọn alàgbà ṣe yìí?

MÁA ṢE ÀWỌN OHUN TÓ JẸ MỌ́ ÌJỌSÌN ỌLỌ́RUN DÉÉDÉÉ

Àwọn nǹkan míì tún wà tá a lè ṣe táá jẹ́ ká lè ní ìfaradà. Ọ̀kan lára rẹ̀ ni pé ká máa ṣe àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run déédéé. Ronú nípa John ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì [39] kan tó ní àrùn jẹjẹrẹ, irú èyí tí kò wọ́pọ̀. Ó sọ pé: “Ó ṣe mí bíi pé kò yẹ kírú èyí ṣẹlẹ̀ sí mi, torí ọmọdé ṣì ni mí.” Nígbà yẹn, ọmọkùnrin tí John bí ṣì wà ní ọmọ ọdún mẹ́ta péré. John sọ pé: “Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé, ìyàwó mi á máa tọ́jú ọmọ wa kékeré, ó tún gbọ́dọ̀ máa tọ́jú èmi náà, kó sì máa gbé mi lọ sílé ìwòsàn.” Ìtọ́jú oníkẹ́míkà, tí wọ́n sábà máa ń fún àwọn tó ní àrùn jẹjẹrẹ tí John ń gbà jẹ́ kó máa rẹ̀ ẹ́ gan-an, ó sì máa ń gbé e ní èébì. Àmọ́ kò tán síbẹ̀ o, bàbá John tún bẹ̀rẹ̀ àìsàn gbẹ̀mí gbẹ̀mí kan, ó sì nílò ìtọ́jú látọ̀dọ̀ ìdílé rẹ̀.

Ọgbọ́n wo ni John àti ìdílé rẹ̀ máa dá sí ìṣòro ńlá yìí? John sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń rẹ̀ mí gan-an, mo rí i dájú pé ìdílé wa ń ṣe àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run déédéé. A máa ń lọ sí gbogbo ìpàdé, à ń jáde òde ẹ̀rí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, a sì máa ń ṣe ìjọsìn ìdílé déédéé, kódà láwọn ìgbà tí nǹkan ò rọrùn rárá.” Láìsí àní-àní, John rí i pé kéèyàn tó lè fara da ìṣòro èyíkéyìí, ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn má ṣe fọwọ́ kékeré mú ìjọsìn Ọlọ́run. John wá gba àwọn tó ń dojú kọ àwọn ipò tó le koko níyànjú pé: “Lẹ́yìn tí ìbẹ̀rù tó máa ń kọ́kọ́ mú èèyàn bá ti lọọlẹ̀, okun tí Jèhófà bá fún ẹ àti ìfẹ́ tó fi hàn sí ẹ máa borí àníyàn tó wà lọ́kàn rẹ. Jèhófà máa fún ẹ lágbára, bó ṣe fún èmi náà.”

Ohun tó dájú ni pé, nípasẹ̀ ìtìlẹ́yìn Ọlọ́run, a lè fara da àdánwò tàbí ìṣòro tó le koko tó bá dojú kọ wá nísinsìnyí tàbí lọ́jọ́ iwájú. Ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ká sì máa gbàdúrà sí i, ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ, ká gba ìrànwọ́ àwọn alàgbà ìjọ, ká sì máa ṣe àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run déédéé. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ là ń ṣe yẹn, ó sọ pé: “Ẹ nílò ìfaradà.”

^ ìpínrọ̀ 2 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.