Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣé o tí fara balẹ̀ ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

Ṣé Jésù Kristi ló yẹ káwọn Kristẹni máa gbàdúrà sí?

Rárá o. Jésù fúnra rẹ̀ kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì fi àpẹẹrẹ èyí lélẹ̀ nígbà tó gbàdúrà sí Baba rẹ̀. (Mát. 6:6-9; Jòh. 11:41; 16:23) Bákan náà, Ọlọ́run ni àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù gbàdúrà sí, kì í ṣe Jésù. (Ìṣe 4:24, 30; Kól. 1:3)—1/1, ojú ìwé 14.

Kí la lè máa ṣe lọ́dọọdún ká lè múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Jésù?

Ohun kan tá a lè ṣe ni pé ká tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà tó wà fún Ìrántí Ikú Kristi. A tún lè sapá láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa lákòókò yẹn. Ká sì fọ̀rọ̀ ìrètí tí Ọlọ́run fún wa sádùúrà.—1/15, ojú ìwé 14 sí 16.

Ibo lọ̀rọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọmọ ilẹ̀ Íjíbítì méjì tí wọ́n rọ́ àlá tó bà wọ́n lẹ́rù fún Jósẹ́fù yọrí sí?

Jósẹ́fù sọ fún agbọ́tí Fáráò pé ó máa pa dà sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀. Àmọ́ àlá olùṣe búrẹ́dì túmọ̀ sí pé Fáráò yóò pa á yóò sì gbé e kọ́ sórí òpó igi. Ohun tí Jósẹ́fù sọ gẹ́lẹ́ náà ló sì ṣẹlẹ̀ sí wọn. (Jẹ́n. 40:1-22)—2/1, ojú ìwé 12 sí 14.

Ẹ̀bùn pàtàkì wo ni àwọn ará ní Japan rí gbà?

Wọ́n gba ẹ̀dà ìwé Ìhìn rere Mátíù. Ó jẹ́ àtúntẹ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Àwọn akéde ń lo ìwé yìí lóde ẹ̀rí, ọ̀pọ̀ àwọn ará Japan tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ mọ púpọ̀ nípa Bíbélì ni wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí i.—2/15, ojú ìwé 3.

Àwọn nǹkan wo ló wáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tó jẹ́ kí ìhìn rere tàn kálẹ̀?

Àkókò tó ní ìsinmi tí wọ́n ń pè ní Pax Romana túmọ̀ sí ìgbà tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí ogun tàbí ọ̀tẹ̀. Ó ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ìgbàanì láti rìnrìn-àjò lórí àwọn ọ̀nà tó dáa. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ èdè Gíríìkì, èyí mú kí iṣẹ́ ìwàásù náà túbọ̀ gbilẹ̀, kódà gbogbo ilẹ̀ ọba àwọn Júù ló gbọ́ nípa rẹ̀. Bákan náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lo òfin ilẹ̀ Róòmù láti gbèjà ìhìn rere.—2/15, ojú ìwé 20 sí 23.

Kí nìdí táwọn Kristẹni tòótọ́ kì í fi í ṣe ọdún Àjíǹde?

Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ṣe Ìrántí Ikú òun, kò sọ pé àjíǹde òun. (Lúùkù 22:19, 20)—3/1, ojú ìwé 8.

Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, kí nìdí tí àwọn ìtẹ̀jáde wa kò fi sábà máa ń sọ pé ẹnì kan, ìṣẹ̀lẹ̀ kan tàbí ohun kan nínú Bíbélì ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan míì bíi tìgbà kan?

Ìwé Mímọ́ mẹ́nu ba àwọn kan nínú Bíbélì tí wọ́n ṣàpẹẹrẹ ohun míì tó ṣe pàtàkì jù wọ́n lọ. Àpẹẹrẹ kan wà nínú Gálátíà 4:21-31. Àmọ́, á dáa ká má parí èrò sí pé ẹnì kan, ìṣẹ̀lẹ̀ kan tàbí ohun kan nínú Bíbélì máa ṣàpẹẹrẹ nǹkan míì. Síbẹ̀, a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára àwọn kan tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wà nínú Bíbélì. (Róòmù 15:4)—3/15, ojú ìwé 17 sí 18.

Kí nìdí tí àjákù òrépèté kan tí wọ́n rí nínú pàǹtírí tó wà nílẹ̀ Íjíbítì fi ṣàrà ọ̀tọ̀?

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá, wọ́n rí àjákù ìwé kan tí Ìhìn Rere Jòhánù wà nínú rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀wádún díẹ̀ lẹ́yìn tí Jòhánù kọ ìwé rẹ̀ ni wọ́n kọ ọ́, àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sì fi ẹ̀rí ohun tó wà nínú Bíbélì múlẹ̀, èyí sì tún fi hàn pé Bíbélì ṣeé gbára lé.—4/1, ojú ìwé 10 sí 11.

Kí nìdí tá a fi lè sọ pé torí ìfẹ́ la ṣe ń yọ ẹni tó hùwà àìtọ́ tí kò sì ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́?

Bíbélì sọ àwọn ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí wọ́n fi lè yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́, èyí sì lè ṣeni láǹfààní. (1 Kọ́r. 5:11-13) Ó máa bọlá fún orúkọ Ọlọ́run, ó máa dáàbò bo ìjọ Kristẹni kó lè máa wà ní mímọ́, ìyọlẹ́gbẹ́ sì lè pe orí oníwà àìtọ́ wálé. —4/15, ojú ìwé 29 sí 30.