Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Gbé Ìgbé Ayé Tó O Máa Gbé Nínú Ayé Tuntun Báyìí

Máa Gbé Ìgbé Ayé Tó O Máa Gbé Nínú Ayé Tuntun Báyìí

Kí wọ́n máa ṣe rere . . . kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.’ 1 TÍM. 6:18, 19.

ORIN: 125, 40

1, 2. (a) Àwọn ìbùkún wo ló wù ẹ́ jù lọ láti gbádùn nínú Párádísè? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Àwọn ìbùkún tẹ̀mí wo la máa gbádùn nínú ayé tuntun?

BÍBÉLÌ sọ̀rọ̀ nípa “ìyè tòótọ́.” Ohun tí gbólóhùn yìí máa gbé wá sọ́kàn ọ̀pọ̀ nínú wa ni ìrètí tá a ní láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè. Kódà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé “ìyè tòótọ́” ní “ìyè àìnípẹ̀kun.” (Ka 1 Tímótì 6:12, 19.) À ń fojú sọ́nà fún gbígbé títí láé nínú ayé tuntun níbi tí ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ pípẹ́ títí máa wá. Ó ṣòro láti fi ojú inú wo bí nǹkan á ṣe rí lára wa tá a bá ń jí lójoojúmọ́ pẹ̀lú ara dídá ṣáṣá, ọpọlọ tó ń ṣiṣẹ́ dáadáa àti ìbàlẹ̀ ọkàn. (Aísá. 35:5, 6) Wo bí inú wa ṣe máa dùn tó láti rí àwọn ará àti ọ̀rẹ́ wa, tó fi mọ́ àwọn tí Ọlọ́run jí dìde. (Jòh. 5:28, 29; Ìṣe 24:15) A tún máa láǹfààní láti fi kún òye wa nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, orin, yíya àwòrán ilé, tàbí ẹ̀ka ìmọ̀ míì.

2 Bá a ṣe ń fojú sọ́nà fún àwọn nǹkan wọ̀nyí tó, ohun tó máa mú ká láyọ̀ jù lọ nínú ayé tuntun ni àwọn ìbùkún tẹ̀mí. Ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó láti mọ̀ nípa ìyàsímímọ́ orúkọ Jèhófà àti ìdáláre ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ! (Mát. 6:9, 10) Inú wa máa dùn gan-an láti rí i pé ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún aráyé àti ilẹ̀ ayé ti ní ìmúṣẹ. Ẹ sì wo bó ṣe máa rọ̀ wá lọ́rùn tó láti sún mọ́ Jèhófà bá a ṣe ń sún mọ́ ìjẹ́pípé, àti nígbà tá a bá di ẹni pípé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.Sm. 73:28; Ják. 4:8.

3. Kí ló yẹ ká máa múra sílẹ̀ fún báyìí?

3 Àwa náà lè rí ìbùkún yìí gbà, torí Jésù mú kó dá wa lójú pé “lọ́dọ̀ Ọlọ́run ohun gbogbo ṣeé ṣe.” (Mát. 19:25, 26) Ṣùgbọ́n tá a bá fẹ́ gbé nínú ayé tuntun yẹn, ká sì tún wà láàyè lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, a gbọ́dọ̀ sapá nísinsìnyí láti “di” ìyè àìnípẹ̀kun “mú gírígírí.” Bá a ṣe ń gbé nínú ayé búburú yìí, a gbọ́dọ̀ máa fojú sọ́nà fún òpin rẹ̀ ká sì ṣe ohun tó yẹ nísinsìnyí láti múra sílẹ̀ de gbígbé nínú ayé tuntun. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé a ṣì ń gbé nínú ètò àwọn nǹkan búburú yìí, báwo la ṣe lè múra sílẹ̀?

BÁ A ṢE LÈ MÚRA SÍLẸ̀

4. Sọ bá a ṣe lè múra sílẹ̀ láti gbé nínú ayé tuntun?

4 Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ nísinsìnyí láti gbé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí? Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé à ń gbèrò láti kó lọ sí orílẹ̀-èdè míì. Báwo la ṣe máa múra sílẹ̀ fún ìṣípòpadà náà? A lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè àwọn tó ń gbé níbẹ̀. Ó máa ṣe wá láǹfààní tá a bá kọ́ èdè àwọn tó ń gbé níbẹ̀ àti àṣà ìbílẹ̀ wọn, ká sì tún fi oúnjẹ wọn kọ́ra. Dé ìwọ̀n àyè kan, á máa ṣe wá bíi pé a ti ń gbé ní orílẹ̀-èdè náà. Ó ṣe tán, ohun tá ó máa ṣe tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbébẹ̀ nìyẹn. Bákan náà, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í fi bá ó ṣe máa gbé nínú ayé tuntun kọ́ra báyìí bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Látàrí ìyẹn, gbé àwọn àpẹẹrẹ tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.

5, 6. Tá a bá ń ṣègbọràn sí ìtọ́ni tó ń wá látọ̀dọ̀ ètò Ọlọ́run, báwo nìyẹn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún gbígbé nínú ayé tuntun?

5 Nínú ayé tuntun, gbogbo èèyàn máa gbà pé Ọlọ́run ló ní ẹ̀tọ́ láti máa ṣàkóso. Ìyẹn á yàtọ̀ pátápátá sí bí àwọn èèyàn ṣe ń dá ṣàkóso ara wọn nínú ayé Sátánì yìí. Àwọn kan ò fẹ́ wà lábẹ́ ẹnikẹ́ni, tinú wọn ni wọ́n sì máa ń fẹ́ ṣe, àmọ́ kí ló ti jẹ́ àbájáde rẹ̀? Bí àwọn èèyàn ṣe kọ̀ láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run ti yọrí sí ìyà, òṣì àti ìbànújẹ́. (Jer. 10:23) À ń retí ìgbà tí gbogbo èèyàn máa gbà pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso àti pé ìfẹ́ ló fi ń ṣàkóso.

6 Ohun ayọ̀ ló máa jẹ́ láti wà nínú ayé tuntun lábẹ́ ìṣàkóso Jèhófà, a ó máa lọ́wọ́ nínú sísọ ilẹ̀ ayé di ibi ẹlẹ́wà, a ó máa kọ́ àwọn tó jíǹde lẹ́kọ̀ọ́, a ó sì máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Ká wá sọ pé wọ́n ní ká ṣe iṣẹ́ kan tí kò wù wá ńkọ́? Ṣé a máa fara mọ́ ìtọ́ni tí wọ́n fún wa, ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ náà, ká sì fi ayọ̀ ṣe é? Ó dájú pé bẹ́ẹ̀ ni ni ọ̀pọ̀ nínú wa máa dáhùn. Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ìgbà gbogbo là ń ṣègbọràn sí ìtọ́ni tó ń wá látọ̀dọ̀ ètò Ọlọ́run nísinsìnyí? Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn fi hàn pé à ń múra sílẹ̀ láti gbé títí láé lábẹ́ ìṣàkóso Jèhófà.

7, 8. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń múpò iwájú? (b) Ìyípadà wo ló ti dé bá àwọn ará wa kan? (d) Kí ló dá wa lójú nípa bí nǹkan á ṣe rí nínú ayé tuntun?

7 A lè múra sílẹ̀ fún gbígbé nínú ayé tuntun nípa fífara mọ́ ètò tí Jèhófà ṣe ní àkókò tá à ń gbé yìí, a sì tún lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa fífi ọwọ́ sowọ́ pọ̀ àti níní ìtẹ́lọ́rùn. Tá a bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń múpò iwájú lónìí, tá a sì ń rí ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn nínú àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tuntun tá a bá ní, irú ẹ̀mí yẹn náà la máa ní nínú ayé tuntun. (Ka Hébérù 13:17.) Ní Ilẹ̀ Ìlérí, ṣe ni wọ́n ṣẹ́ kèké láti pín ogún fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Núm. 26:52-56; Jóṣ. 14:1, 2) Àmọ́ ní báyìí, a ò tíì mọ ibi tí wọ́n á ní kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wá máa gbé nínú ayé tuntun. Ṣùgbọ́n, tá a bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ a máa ní ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ ńláǹlà bá a ti ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà níbikíbi tá a bá ń gbé lórí ilẹ̀ ayé nígbà yẹn.

8 Gbogbo ipá yòówù ká sà láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò Jèhófà ká sì máa bójú tó iṣẹ́ tí wọ́n bá yàn fún wa kò tó àǹfààní tá a máa ní láti gbé lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́ bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ipò wa lè yí pa dà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ní kí àwọn kan tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ máa sìn ní pápá, wọ́n sì ń gbádùn ìbùkún rẹpẹtẹ nínú àwọn apá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún mìíràn báyìí. Torí ara tó ti ń dara àgbà tàbí torí àwọn ìdí míì, wọ́n ti ní kí àwọn kan tó wà lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò lọ máa sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe báyìí. Tá a bá ní ìtẹ́lọ́rùn, tá à ń gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, a máa láyọ̀, a sì máa rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà kódà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn lílekoko yìí. (Ka Òwe 10:22.) Àwọn ohun tá à ń fojú sọ́nà fún lọ́jọ́ iwájú ńkọ́? Ó ṣeé ṣe ká ní apá ibi tá a fẹ́ gbé nínú ayé tuntun lọ́kàn, àmọ́ tí wọ́n bá sọ pé apá ibòmíì ni ká lọ ńkọ́? Ohun yòówù ká máa ṣe tàbí ibi yòówù ká máa gbé nínú ayé tuntun, ó dájú pé àá máa dúpẹ́, àá ní ìtẹ́lọ́rùn, inú wa á sì máa dùn.Neh. 8:10.

9, 10. (a) Àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ tó máa gba pé ká ní sùúrù nínú ayé tuntun? (b) Kí ló máa fi hàn pé a ní sùúrù?

9 Nínú ayé tuntun, àwọn nǹkan míì lè ṣẹlẹ̀ tó máa gba pé ká ní sùúrù. Bí àpẹẹrẹ, a lè gbọ́ pé àwọn kan ti jíǹde tí inú àwọn ìbátan àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn sì ń dùn, ṣùgbọ́n kí àwa má tíì rí àwọn èèyàn wa tó ti kú. Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé a máa bá wọn yọ̀ ká sì ní sùúrù? (Róòmù 12:15) Tó bá ti mọ́ wa lára láti máa ní sùúrù kí àwọn ìlérí Jèhófà tó ní ìmúṣẹ nísinsìnyí, àá lè máa ní sùúrù nígbà yẹn.Oníw. 7:8.

10 A tún lè múra sílẹ̀ de ayé tuntun nípa níní sùúrù bí ìyípadà bá dé bá òye tá a ti ní tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan. Ṣé a máa ń fi aápọn kẹ́kọ̀ọ́, ṣé a sì ń ní sùúrù bí òye tá a ní nípa Bíbélì ṣe ń ṣe kedere sí i ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kò ní ṣòro fún wa láti máa ní sùúrù nínú ayé tuntun bí Jèhófà bá ṣe ń sọ ohun tó fẹ́ ká ṣe di mímọ̀.Òwe 4:18; Jòh. 16:12.

11. Kí ni Jèhófà ń kọ́ wa nípa àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn míì nísinsìnyí, báwo lèyí sì ṣe máa ṣe wá láǹfààní nínú ayé tuntun?

11 Ohun mìíràn tó tún máa ṣe wá láǹfààní nínú ayé tuntun ni pé ká máa dárí jini. Nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Kristi, ó lè pẹ́ díẹ̀ kí àwọn olódodo àtàwọn aláìṣòdodo tó fi ìwà àìpé sílẹ̀. (Ìṣe 24:15) Ṣé a ó lè máa fìfẹ́ bára wa gbé nígbà yẹn? Tó bá ti mọ́ wa lára nísinsìnyí láti máa dárí jini ní fàlàlà tá a bá ní aáwọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan, ó máa rọrùn fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà yẹn.Ka Kólósè 3:12-14.

12. Ṣàlàyé bí àwọn nǹkan tá à ń fojú sọ́nà fún ṣe kan ìgbésí ayé tá à ń gbé báyìí.

12 Tá a bá dé inú ayé tuntun, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé gbogbo ìgbà ni ọwọ́ wa máa tẹ ohun tá a bá fẹ́ nígbà tá a bá fẹ́ ẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ní láti máa fi ìmọrírì hàn, ká ní ìtẹ́lọ́rùn ní ipòkípò tá a bá wà, ká sì máa jàǹfààní látinú mímọ̀ pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso àti pé ìfẹ́ ló fi ń ṣàkóso. Ìyẹn á túmọ̀ sí pé ká máa fi àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ń kọ́ wa nísinsìnyí ṣèwà hù. Tá a bá ń gbé irú ìgbé ayé tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbé nígbà yẹn báyìí, àá ní àwọn ànímọ́ tó yẹ ká máa fi ṣèwà hù títí láé. A ó máa sọ ìgbàgbọ́ wa dọ̀tun nínú “ayé tí n bọ̀” torí ó dá wa lójú pé ó máa dé. (Héb. 2:5, Bíbélì Mímọ́; 11:1) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a ó máa fi hàn pé ó wù wá gan-an pé kí òdodo gbilẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Paríparí rẹ̀ ni pé à ń múra sílẹ̀ fún ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí.

ÀWỌN NǸKAN TẸ̀MÍ NI KÓ O GBÁJÚ MỌ́ BÁYÌÍ

Máa kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù

13. Àwọn ìgbòkègbodò wo ló máa gbawájú nínú ayé tuntun?

13 Tún ronú nípa ọ̀nà míì tá a lè gbà múra sílẹ̀ fún gbígbé nínú ayé tuntun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ṣèlérí pé ọ̀pọ̀ oúnjẹ àti àwọn ohun kòseémáàní míì máa wà nínú ayé tuntun, àwọn ìpèsè tẹ̀mí tí Ọlọ́run á fún wa ló máa mú ká láyọ̀ jù lọ. (Mát. 5:3) Àwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ló máa gbawájú, àá sì máa fi hàn pé à ń ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà. (Sm. 37:4) Tá a bá ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tẹ̀mí gbawájú nínú ìgbésí ayé wa nísinsìnyí, à ń múra sílẹ̀ fún gbígbé nínú ayé tuntun nìyẹn.Ka Mátíù 6:19-21.

14. Àwọn àfojúsùn tẹ̀mí wo ló lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa fojú sọ́nà fún ìyè ayérayé?

14 Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ayọ̀ tá à ń rí nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run máa pọ̀ sí i? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká ní àwọn àfojúsùn tẹ̀mí. Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, tó o sì ń ronú jinlẹ̀ nípa bó o ṣe lè fi ìgbésí ayé rẹ ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, o ò ṣe ka àwọn ìtẹ̀jáde kan tó sọ̀rọ̀ nípa onírúurú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún kó o sì fi ọ̀kan lára wọn ṣe àfojúsùn rẹ? * O tún lè bá àwọn tó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún sọ̀rọ̀. Tó bá jẹ́ iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run lo pinnu láti fi ìgbésí ayé rẹ ṣe, ò ń múra sílẹ̀ láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run nìṣó nínú ayé tuntun nìyẹn. Àwọn ìrírí àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó o ti rí gbà á sì wúlò fún ẹ gan-an.

Máa lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò tẹ̀mí

15. Àwọn àfojúsùn tẹ̀mí wo ló lè rọrún fún àwa akéde Ìjọba Ọlọ́run láti lé bá?

15 Kí ni àwa akéde Ìjọba Ọlọ́run lè fi ṣe àfojúsùn tẹ̀mí wa? A lè mú kí apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa kan túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Tàbí ká sapá láti túbọ̀ lóye àwọn ìlànà Bíbélì dáadáa àti bá a ṣe lè máa fi wọ́n sílò. Ó sì lè jẹ́ pé ṣe la fẹ́ kí ọ̀nà tá a gbà ń kàwé fún àwùjọ, ọ̀nà tá a gbà ń sọ̀rọ̀ tàbí ìdáhùn wa ní ìpàdé sunwọ̀n sí i. Ó dájú pé o ṣì lè ronú kan ọ̀pọ̀ nǹkan míì. Ṣùgbọ́n kókó ibẹ̀ ni pé, tó o bá ní àfojúsùn tẹ̀mí, ìtara tó o ní fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run á pọ̀ sí i, èyí á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún gbígbé nínú ayé tuntun.

A TI Ń GBÁDÙN ÀWỌN ÌBÙKÚN TẸ̀MÍ BÁYÌÍ

Fi hàn pé o mọrírì oúnjẹ tẹ̀mí

16. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé sísin Jèhófà ni ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà lo ìgbésí ayé wa?

16 Tó bá jẹ́ pé ohun táá mú ká gbé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí là ń fi àkókò wa ṣe, ṣó wá túmọ̀ sí pé à ń pàdánù àǹfààní tá a ní láti fi ìgbésí ayé wa ṣe ohun tó ní láárí jùyẹn lọ ni? Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀! Kò sí ohun tó dáa tó kéèyàn fi ìgbésí ayé rẹ̀ sin Jèhófà. Kì í ṣe pé à ń fi tìpá tìkúùkù sin Jèhófà ká ṣáà lè la ìpọ́njú ńlá já o! Bí Ọlọ́run ṣe dá wa nìyẹn, ìyẹn sì loun tó lè fún wa láyọ̀ tó gadabú. Bí Jèhófà ṣe ń tọ́ wa sọ́nà tó sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa ṣe pàtàkì ju ohunkóhun mìíràn lọ. (Ka Sáàmù 63:1-3.) Àmọ́, kò dìgbà tá a bá dénú ayé tuntun ká tó gbádùn àwọn ìbùkún tẹ̀mí tó ń wá látinú fífi tọkàntọkàn sin Jèhófà, a ti ń gbádùn àwọn ìbùkún náà báyìí. Kódà, àwọn kan lára wa ti ń gbádùn ìbùkún náà fún ọ̀pọ̀ ọdún, a sì mọ̀ pé kò sí ọ̀nà ìgbésí ayé míì tó lè mú kéèyàn ní ìtẹ́lọ́rùn jùyẹn lọ.Sm. 1:1-3; Aísá. 58:13, 14.

Máa gba ìtọ́ni látinú Ìwé Mímọ́

17. Ṣé a lè gbádùn ara wa ká sì ṣe àwọn nǹkan tá a nífẹ̀ẹ́ sí nínú Párádísè?

17 A máa gbádùn ara wa, àá sì ṣe àwọn nǹkan tá a nífẹ̀ẹ́ sí nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Àbí, kí nìdí tí Jèhófà fi dá wa lọ́nà táá fi wù wá láti ṣe àwọn nǹkan ká sì tún gbádùn ara wa bí kò bá fẹ́ ká tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wa lọ́rùn ní kíkún? (Oníw. 2:24) Lọ́nà yìí àti láwọn ọ̀nà míì, Jèhófà máa “tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.” (Sm. 145:16) Ní báyìí, kò sí ohun tó burú nínú ká najú ká sì ṣeré ìtura. Ṣùgbọ́n wọ́n máa túbọ̀ gbádùn mọ́ni tó bá jẹ́ pé àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà la fi sípò àkọ́kọ́. Bó sì ṣe máa rí náà nìyẹn nínú Párádísè. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé ká fi àwọn ohun tó wù wá sí àyè tó yẹ wọ́n, ká máa wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́ ká sì gbájú mọ́ àwọn ìbùkún tẹ̀mí táwọn èèyàn Jèhófà ń gbádùn báyìí.Mát. 6:33.

18. Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń fojú sọ́nà fún ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè?

18 Nínú Párádísè tó ń bọ̀, a máa ní ayọ̀ tá ò tíì ní irú rẹ̀ rí. Ẹ jẹ́ ká fi hàn pé ó wù wá lóòótọ́ láti gbé nínú Párádísè nípa mímúra sílẹ̀ fún un nísinsìnyí. Ẹ jẹ́ ká ní àwọn ànímọ́ tó ń múnú Ọlọ́run dùn ká sì máa láyọ̀ bá a ṣe ń fìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tá a gbé lé wa lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kó máa wù wá láti gbájú mọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí. Bá a sì ṣe ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú àwọn ìlérí Jèhófà, ẹ jẹ́ ká máa fojú sọ́nà fún gbígbé nínú ayé tuntun.