Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

“Kí Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Erékùṣù Máa Yọ̀”

“Kí Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Erékùṣù Máa Yọ̀”

Mánigbàgbé ni ọjọ́ náà jẹ́. Mo wà lára àwọn arákùnrin tó wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lágbàáyé, inú yàrá àpérò tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti máa ń ṣe ìpàdé la wà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù ń bà wá, a mọ̀ pé Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé máa tó wọlé. Wọ́n ti yàn wá láti wá jíròrò àwọn nǹkan kan pẹ̀lú wọn. Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, a ti ṣe àkópọ̀ àwọn ìṣòro tí àwọn atúmọ̀ èdè máa ń ní, a sì fẹ́ dámọ̀ràn ojútùú sí wọn. Ọjọ́ kejìlélógún oṣù May ọdún 2000 lọjọ́ yẹn. Àmọ́, kí nìdí tí ìpàdé yìí fi ṣe pàtàkì? Kí n tó ṣàlàyé, ẹ jẹ́ kí n kọ́kọ́ sọ díẹ̀ fún yín nípa ìgbésí ayé mi àtẹ̀yìnwá.

Mo ṣèrìbọmi ní ìlú Queensland, mo gbádùn iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní erékùṣù Tasmania àti iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè Tuvalu, erékùṣù Samoa àti ìlú Fíjì

ÌPÍNLẸ̀ Queensland, lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà ni wọ́n bí mi sí ní ọdún 1955. Kété lẹ́yìn ìyẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ màmá mi, Estelle lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọdún tó tẹ̀ lé e ni màmá mi ṣèrìbọmi, ọdún mẹ́tàlá lẹ́yìn náà sì ni bàbá mi tó ń jẹ́ Ron di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó di ọdún 1968, mo ṣèrìbọmi ní àrọko kan ní ìlú Queensland.

Àtìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé ni mo ti fẹ́ràn láti máa kàwé, mo sì nífẹ̀ẹ́ èdè púpọ̀. Tí ìdílé wa bá ń rìnrìn-àjò lọ gbafẹ́, màá jókòó sẹ́yìn mọ́tò, kàkà kí n máa wo àwọn ilẹ̀, òkè, òdòdó àti àyíká tó rẹwà bá a ṣe ń lọ, ìwé ni mo máa ń kà ṣáá. Ó dájú pé inú àwọn òbí mi kì í dùn sí ohun tí mò ń ṣe yẹn. Àmọ́, ìfẹ́ tí mo ní fún ìwé kíkà ràn mí lọ́wọ́ gan-an ní ilé ìwé. Mo gba oríṣiríṣi àmì ẹ̀yẹ ní ilé ẹ̀kọ́ girama tí mo lọ ní erékùṣù Tasmania ní ìlú Glenorchy, nítorí àwọn àṣeyege tí mo ṣe nínú ẹ̀kọ́ mi.

Nígbà tó yá, mo ṣèpinnu kan tó máa yí ìgbésí ayé mi pa dà. Ṣé kí n gba ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ láti lọ sí yunifásítì àbí kí n má lọ? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo fẹ́ràn ìwé kíkà àti ẹ̀kọ́ kíkọ́, mo mọrírì ìsapá àti ìrànlọ́wọ́ tí màmá mi ṣe kí n lè ní ìfẹ́ tó lágbára jùyẹn lọ, ìyẹn ìfẹ́ fún Jèhófà. (1 Kọ́r. 3:18, 19) Ìgbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] ni mo parí ilé ẹ̀kọ́ girama ní January ọdún 1971, àwọn òbí mi sì gbà mí láyè láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.

Ọdún mẹ́jọ tó tẹ̀ lé e ni mo fi ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní erékùṣù Tasmania. Ní àkókò yẹn, mo fẹ́ Jenny Alcock, arẹwà obìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ erékùṣù Tasmania, ọdún mẹ́rin ni àwa méjèèjì fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní Smithton àti Queenstown tó jẹ́ ìpínlẹ̀ ìwàásù àdádó.

A LỌ SÍ ÀWỌN ERÉKÙṢÙ ÒKUN PÀSÍFÍÌKÌ

A lọ sí àpéjọ àgbáyé fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ìlú Port Moresby ní orílẹ̀-èdè Papua New Guinea lọ́dún 1978. Mo ṣì rántí àsọyé tí míṣọ́nnárì kan sọ lédè Hiri Motu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò lóye nǹkan kan nínú ohun tó sọ, àsọyé náà wú mi lórí gan-an débi pé ó wu èmi náà láti di míṣọ́nnárì, láti kọ́ èdè míì kí n sì máa fi sọ àsọyé bíi ti arákùnrin náà. Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín mo láǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó jẹ́ kí n lè fi ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà hàn láìpa ìfẹ́ tí mo ní fún èdè tì.

Ó yà wá lẹ́nu nígbà tí a pa dà sí ilẹ̀ Ọsirélíà pé wọ́n ní ká wá máa sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì ní erékùṣù Funafuti (tó ń jẹ́ Ellice tẹ́lẹ̀) ní orílẹ̀-èdè Tuvalu. Oṣù January ọdún 1979 la débẹ̀. Yàtọ̀ sí èmi àti ìyàwó mi, àwọn akéde mẹ́ta tó ti ṣèrìbọmi ló wà ní orílẹ̀-èdè Tuvalu nígbà yẹn.

Èmi àti Jenny rèé ní orílẹ̀-èdè Tuvalu

Kò rọrùn fún wa láti kọ́ èdè Tuvaluan. “Májẹ̀mú Tuntun” tó jẹ́ apá kan nínú Bíbélì ni ìwé kan ṣoṣo tó wà lédè yẹn. Kò sí ìwé atúmọ̀ èdè tàbí ètò láti kọ́ àwọn èèyàn lédè rárá nígbà yẹn, torí náà a pinnu pé àá máa kọ́ ọ̀rọ̀ tuntun mẹ́wàá sí ogún lójoojúmọ́. Àmọ́ a wá rí i pé a ò lóye ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tá à ń kọ́ yẹn dáadáa. Kàkà ká máa sọ fún wọn pé kò dáa kéèyàn máa woṣẹ́, ńṣe là ń sọ fún wọn pé kí wọ́n yé lo ọ̀pá ìdiwọ̀n àti ọ̀pá tí wọ́n fi ń rìn mọ́. Ó sì pọn dandan pé ká kọ́ èdè náà ká lè máa darí ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a ti bẹ̀rẹ̀, torí náà, a ò jẹ́ kó sú wa. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ọ̀kan lára àwọn tí a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tá a kọ́kọ́ débẹ̀ sọ fún wa pé: “Inú wa dùn pé ẹ ti wá ń sọ èdè wa dáadáa báyìí. Nígbà tẹ́ ẹ kọ́kọ́ dé, a ò tiẹ̀ lóye gbogbo ohun tẹ́ ẹ̀ ń sọ rárá.”

Síbẹ̀, ilé àwọn ará kan là ń gbé nínú abúlé torí pé kò sí ilé kankan tí a lè yá gbé, èyí fún wa láǹfààní láti kọ́ èdè náà dáadáa. Ìyẹn gan-an ló wá jẹ́ ká ki gbogbo ara bọ kíkọ́ èdè náà, tí ìgbésí ayé abúlé sì mọ́ wa lára. Fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, a ò sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì mọ́, èdè Tuvaluan wá di lájorí èdè tá à ń sọ.

Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í fìfẹ́ hàn sí òtítọ́. Àmọ́, ìwé wo la máa fi kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́? Níwọ̀n bí kò ti sí ìwé kankan ní èdè wọn, báwo ni wọ́n á ṣe máa dá kẹ́kọ̀ọ́? Tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wá sí ìpàdé, orin wo ni wọ́n á máa kọ, ìwé wo ni wọ́n á máa lò, báwo ni wọ́n á sì ṣe máa múra ìpàdé sílẹ̀? Báwo ni wọ́n á ṣe kẹ́kọ̀ọ́ débi tí wọ́n á fi ṣèrìbọmi? Àwọn ọlọ́kàn tútù yìí nílò oúnjẹ tẹ̀mí lédè wọn. (1 Kọ́r. 14:9) A wá ń ronú pé, ‘Ǹjẹ́ ìwé kankan tiẹ̀ máa wà ní èdè Tuvaluan, nígbà tó jẹ́ pé àwọn èèyàn tó ń sọ èdè náà ò ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000] lọ?’ Jèhófà dáhùn àwọn ìbéèrè náà, ìyẹn sì kọ́ wa ní ohun méjì. (1) Ó fẹ́ ká sọ Ọ̀rọ̀ òun “láàárín àwọn erékùṣù jíjìnnàréré,” àti pé (2) ó fẹ́ kí àwọn tí ayé mọ̀ sí “onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni rírẹlẹ̀” sá di orúkọ òun.Jer. 31:10; Sef. 3:12.

À Ń ṢE ÌTÚMỌ̀ OÚNJẸ TẸ̀MÍ NÍ ÈDÈ WỌN

Ní ọdún 1980, ẹ̀ka ọ́fíìsì sọ pé kí èmi àti ìyàwó mi máa tú àwọn ìwé wa láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Tuvaluan, ńṣe ló ń ṣe wá bíi pé a ò tóótun fún iṣẹ́ náà. (1 Kọ́r. 1:28, 29) A kọ́kọ́ ra ògbólógbòó ẹ̀rọ kan tí wọ́n fi ń ṣe ẹ̀dà ìwé lọ́dọ̀ ìjọba, òun là ń lò láti fi ṣe ẹ̀dà àwọn ìwé tá a fi ń ṣe ìpàdé ìjọ. A tú ìwé náà Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye sí èdè Tuvaluan, a sì fi ẹ̀rọ yìí tẹ̀ ẹ́ jáde. Mo ṣì rántí bí yíǹkì tá a lò ṣe ń rùn gan-an àti ìsapá tó gbà ká tó lè fi ẹ̀rọ yìí tẹ gbogbo ìwé náà bi ooru ṣe ń mú tó ní ilẹ̀ yẹn. Torí pé kò tíì sí iná mànàmáná nígbà yẹn.

Ó nira gan-an láti ṣe ìtúmọ̀ sí èdè Tuvaluan, torí pé ìwé tá a lè ṣèwádìí nínú ẹ̀ kí iṣẹ́ náà lè rọrùn ò tó nǹkan. Ṣùgbọ́n ìrànlọ́wọ́ máa ń wá látibi tá ò fọkàn sí nígbà míì. Láàárọ̀ ọjọ́ kan, mo bá ara mi ní ilé ọkùnrin kan tí kò nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́. Àgbàlagbà kan tó ti ṣiṣẹ́ tíṣà rí ni, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló sọ fún mi pé a ò gbọ́dọ̀ wá sílé òun mọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, ó wá sọ pé: “Mo ní ohun kan tí mo fẹ́ sọ o, bẹ́ ẹ ṣe ń túmọ̀ ìwé yín kò bá bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ lédè Tuvaluan mu.” Nígbà tí mo bi àwọn míì, ohun kan náà ni wọ́n sọ. Torí náà, a ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. Síbẹ̀, ó yà mí lẹ́nu pé Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ nípasẹ̀ ẹnì kan tó ta ko òtítọ́, àmọ́ tó ń ka àwọn ìwé wa.

Ìròyìn Ìjọba Ọlọ́run No. 30 ní èdè Tuvaluan

Ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi la kọ́kọ́ tẹ̀ jáde ní èdè Tuvaluan, tí a sì pín kiri fún àwọn èèyàn. Lẹ́yìn ìyẹn, a tẹ Ìròyìn Ìjọba Ọlọ́run No. 30 tó jáde nígbà kan náà pẹ̀lú ti èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ẹ wo bí inú wa ṣe dùn tó pé àwọn èèyàn yẹn láǹfààní láti ka ìwé tí a fi èdè wọn kọ! Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, a túmọ̀ àwọn ìwé pẹlẹbẹ àti àwọn ìwé ńlá kan pàápàá sí èdè Tuvaluan. Ní ọdún 1983, ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní ilẹ̀ Ọsirélíà bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ Ilé Ìṣọ́ olójú-ewé mẹ́rìnlélógún jáde lẹ́ẹ̀mẹrin lọ́dún, èyí ń mú ká kẹ́kọ̀ọ́ nǹkan bí ìpínrọ̀ méje lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Kí ni àwọn èèyàn ṣe nígbà tí wọ́n rí ìwé ìròyìn náà? Àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè Tuvalu fẹ́ràn ìwé kíkà púpọ̀, torí náà, ìwé ìròyìn wa di gbajúmọ̀. Tí ẹ̀dà tuntun bá ti jáde, wọ́n máa ń sọ ọ́ lórí rédíò tàbí kí wọ́n gbé e jáde nínú abala ìwé ìròyìn, kódà nígbà míì òun ni wọ́n máa fi ṣe kókó inú ìwé ìròyìn. *

Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè, orí ìwé la máa ń kọ ọ́ sí. Nígbà tó yá, a máa ń tẹ àwọn ìwé tí a fọwọ́ kọ ní àtẹ̀túntẹ̀ kí a tó fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń tẹ̀wé ní Ọsirélíà. Nígbà kan, ẹ̀ka ọ́fíìsì ní àwọn arábìnrin méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n máa ń tẹ ẹ̀dà tí a fi ọwọ́ kọ sí orí kọ̀ǹpútà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò gbọ́ èdè Tuvaluan. Bí àwọn méjèèjì bá tẹ̀ ẹ́ tán, àá fi ohun tí wọ́n tẹ̀ wéra lórí kọ̀ǹpútà, lọ́nà yìí, àá rí àṣìṣe èyíkéyìí tó bá wà níbẹ̀ àá sì tún un ṣe. Èyí máa ń dín àṣìṣe tó wà nínú ìwé wa kù gan-an. Kí wọ́n tó tẹ̀ ẹ́ jáde, wọ́n á kọ́kọ́ fi ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà tó máa ń tẹ èdè púpọ̀ to ọ̀rọ̀ tá a túmọ̀ náà sí ojú ìwé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n á kó àwọn ìwé náà pa pọ̀, wọ́n á sì fi ọkọ̀ òfúúrufú gbé e ránṣẹ́ sí wa ká lè yẹ̀ ẹ́ wò. Lẹ́yìn náà, àá wá fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó máa tẹ̀ ẹ́ jáde.

Àmọ́ nǹkan ti yí pa dà gan-an báyìí! Ńṣe ni àwọn atúmọ̀ èdè máa ń tẹ ọ̀rọ̀ wọn ní tààràtà sínú kọ̀ǹpútà. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ojú ìwé tí a ti kà lákàtúnkà, tí a gbé jáde láti orí kọ̀ǹpútà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè ni a máa fi ránṣẹ́ látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì sí ẹ̀ka tó máa tẹ̀ ẹ́ jáde. Kò tún sí pé à ń kánjú lọ sílé ìfìwéránṣẹ́ mọ́ torí àtilọ fi ẹ̀dà tí a fọwọ́ tẹ̀ ránṣẹ́ nípasẹ̀ ọkọ̀ òfúúrufú.

A NÍ ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌSÌN PÚPỌ̀ SÍ I

Bí ọdún ti ń gorí ọdún, èmi àti Jenny ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn púpọ̀ sí i jákèjádò erékùṣù Pàsífíìkì. Láti orílẹ̀-èdè Tuvalu, wọ́n rán wa lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní erékùṣù Samoa ní ọdún 1985. A wá ń ran àwọn atúmọ̀ èdè Samoan, Tongan àti Tokelauan lọ́wọ́ ní àfikún sí títúmọ̀ àwọn ìwé wa sí èdè Tuvaluan. * Nígbà tó di ọdún 1996, wọ́n tún ní ká lọ ṣe irú iṣẹ́ yẹn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní ìlú Fíjì, a tún ran àwọn tó ń túmọ̀ èdè Fijian, Kiribati, Nauruan, Rotuman àti Tuvaluan lọ́wọ́.

Mò ń fi ìwé tá a tú sí èdè Tuvaluan kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́

Gbogbo ìgbà ni ìtara tí àwọn tó ń túmọ̀ àwọn ìwé wa ń fi hàn máa ń yà mí lẹ́nu. Iṣẹ́ tó le tó sì máa ń tánni lókun ni. Síbẹ̀, àwọn olóòótọ́ yìí fẹ́ kí ìfẹ́ Jèhófà di ṣíṣe nípa wíwàásù ìhìn rere náà “fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n [tàbí, èdè] àti ènìyàn.” (Ìṣí. 14:6) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a kọ́kọ́ máa tú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ sí èdè Tongan, mo pàdé pọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn alàgbà tó wà ní erékùṣù Tonga, mo sì bi wọ́n bóyá a lè rí ẹnì kan nínú wọn tó lè ṣe iṣẹ́ atúmọ̀ èdè. Ọ̀kan nínú àwọn alàgbà náà ní iṣẹ́ tó dáa lọ́wọ́, iṣẹ́ mẹkáníìkì ló ń ṣe, ó ní òun máa fi iṣẹ́ òun sílẹ̀ lọ́jọ́ kejì òun á sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ atúmọ̀ èdè. Ohun tó ṣe yẹn yà mí lẹ́nu gan-an torí pé olórí ìdílé ni, kò sì ní iṣẹ́ míì tó máa fi gbọ́ bùkátà. Àmọ́ Jèhófà gbọ́ bùkátà òun àti ìdílé rẹ̀, ó sì ṣe iṣẹ́ atúmọ̀ èdè fún ọ̀pọ̀ ọdún.

Irú ẹ̀mí tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ní làwọn atúmọ̀ èdè náà ní, wọ́n fẹ́ kí àwọn tó ń sọ èdè tó jẹ́ pé ìwọ̀nba èèyàn kéréje ló ń sọ ọ́ máa gba oúnjẹ tẹ̀mí tí wọ́n nílò. Bí àpẹẹrẹ, nígbà kan a béèrè pé ṣó tiẹ̀ yẹ ká máa ṣe gbogbo wàhálà yẹn láti túmọ̀ ìwé sí èdè Tuvaluan? Ìṣírí ló jẹ́ fún mi nígbà tí mo ka lẹ́tà tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí kọ sí wa pé: “A ò rí ìdí kankan tó fi yẹ kẹ́ ẹ dá iṣẹ́ ìtúmọ̀ sí èdè Tuvaluan dúró. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ń sọ èdè náà ò tó nǹkan tá a bá fi wé èdè míì, síbẹ̀ wọ́n ṣì nílò ìhìn rere náà ní èdè wọn.”

Ìrìbọmi nínú omi ọ̀sà

Ní ọdún 2003, wọ́n ní kí èmi àti Jenny kúrò ní Ẹ̀ka Ìtúmọ̀ Èdè lórílẹ̀ èdè Fíjì ká wá lọ sí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Ìtúmọ̀ ní ìlú Patterson, ní ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ọwọ́ mi ti wá ba nǹkan tí mò ń wá báyìí! A wá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀ka tó ń rí sí i pé a tú àwọn ìwé wa sí èdè tó pọ̀. Ní nǹkan bí ọdún méjì lẹ́yìn náà, a láǹfààní láti máa ṣèbẹ̀wò sí onírúurú orílẹ̀-èdè ká lè ran àwọn atúmọ̀ èdè tó wà níbẹ̀ lọ́wọ́.

A ṢE ÀWỌN ÌPINNU PÀTÀKÌ

Ẹ jẹ́ kí n wá pa dà sí ìtàn tí mo fi bẹ̀rẹ̀. Ní ọdún 2000, Ìgbìmọ̀ Olùdarí rí i pé ó pọn dandan láti fún àwọn atúmọ̀ èdè ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ sí i kárí ayé. Nígbà yẹn, ìwọ̀nba nǹkan díẹ̀ ni èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn atúmọ̀ èdè mọ̀ nípa iṣẹ́ wọn. Lẹ́yìn tá a parí ìjíròrò wa pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé kí gbogbo àwọn atúmọ̀ èdè kárí ayé gba ìdálẹ́kọ̀ọ́. Lára àwọn ohun tí ẹ̀kọ́ náà dá lé lórí ni lílóye èdè Gẹ̀ẹ́sì, ọgbọ́n ìṣètumọ̀ àti bí àwùjọ àwọn atúmọ̀ èdè ṣe lè máa ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀.

Kí ló ti wá jẹ́ àbájáde gbogbo làálàá lórí ìtúmọ̀ èdè yìí? Ohun kan ni pé ọ̀nà tí a gbà ń tú àwọn ìwé wa ti túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Iye àwọn èdè tí à ń tú àwọn ìwé wa sí tún ti pọ̀ sí i ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Nígbà tá a kọ́kọ́ dé ibi tí wọ́n ti ní ká lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní ọdún 1979, èdè méjìlélọ́gọ́rin [82] péré là ń túmọ̀ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sí. Ọ̀pọ̀ wọn ló sì máa ń jáde lẹ́yìn oṣù díẹ̀ tí ẹ̀dà ti Gẹ̀ẹ́sì bá ti jáde. Àmọ́ ní báyìí, ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ ti wà ní èdè tó ju igba ó lé ogójì [240] lọ, èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ló sì máa ń jáde nígbà kan náà pẹ̀lú ẹ̀dà ti Gẹ̀ẹ́sì. Oúnjẹ tẹ̀mí ti wá wà báyìí ní èdè tó ju ọgọ́rùn-ún méje [700] lọ. Bí àlá lásán ni àṣeyọrí yìí rí lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn.

Ní ọdún 2004, Ìgbìmọ̀ Olùdarí tún ṣe ìpinnu pàtàkì mìíràn, ìyẹn ni mímú kí iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì túbọ̀ yára sí i. Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì náà di apá kan iṣẹ́ tí àwọn atúmọ̀ èdè ń bójú tó, èyí wá mú kó ṣeé ṣe láti tú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sí èdè tó pọ̀ sí i. Ní ọdún 2014, a ti tẹ Bíbélì yìí lódindi tàbí ní apá kan ní èdè méjìdínláàádóje [128], tó fi mọ́ díẹ̀ lára àwọn èdè tí wọ́n ń sọ ní Gúúsù Pàsífíìkì.

A mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde lédè Tuvaluan

Ní ọdún 2011, wọ́n rán mi lọ sí àpèjọ àgbègbè kan ní orílẹ̀-èdè Tuvalu. Ọ̀kan lára àǹfààní tí mó mọrírì jù lọ ní ìgbésí ayé mi nìyẹn. Ọ̀pọ̀ oṣù ṣáájú ìgbà yẹn ni ọ̀dá omi ti dá wọn lórílẹ̀-èdè náà, ó sì dà bíi pé wọ́n máa wọ́gi lé àpéjọ náà. Àmọ́ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí a débẹ̀, òjò rọ̀ gan-an, a sì ṣe àpéjọ náà. Mo láǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ láti mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde lédè Tuvaluan, àwọn tó ń sọ èdè yẹn ló kéré jù nínú gbogbo àwọn tó tíì ní Bíbélì yìí ní èdè wọn. Nígbà tá a parí àpéjọ náà, òjò míì tún rọ̀. Torí náà, gbogbo èèyàn rí omi nípa tẹ̀mí àti nípa tara gbà.

Mò ń fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn òbí mi, ìyẹn Ron àti Estelle ní àpéjọ àgbègbè kan ní ìlú Townsville, Ọsirélíà lọ́dún 2014

Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé Jenny, alábàákẹ́gbẹ́ mi ọ̀wọ́n fún ọdún márùndínlógójì [35] kú kó tó dìgbà yẹn, kò rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé náà. Ọdún mẹ́wàá ló fi fara da àrùn jẹjẹrẹ ọmú, kó tó wá kú lọ́dún 2009. Ó dájú pé nígbà àjíǹde, inú rẹ̀ máa dùn gan-an pé Bíbélì wà ní èdè Tuvaluan.

Látìgbà yẹn, Jèhófà ti fún mi ní ìyàwó míì tó rẹwà tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Loraini Sikivou. Loraini àti Jenny jọ ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Fíjì, àmọ́ Ẹ̀ka Ìtúmọ̀ Èdè Fijian ni Loraini ń bá ṣiṣẹ́ ní tiẹ̀. Mo tún wá ní ìyàwó olóòótọ́ míì báyìí, àwa méjèèjì jọ nífẹ̀ẹ́ èdè, a sì jọ ń sin Jèhófà.

Èmi àti Loraini ń wàásù ní ìlú Fíjì

Tí mo bá ń ronú nípa àwọn ọdún tí a ti lò nínú iṣẹ́ ìsìn, inú mi máa ń dùn láti rí bí Jèhófà, Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ṣe ń pèsè fún àwọn tó ń sọ onírúurú èdè, yálà wọ́n kéré tàbí wọ́n pọ̀. (Sm. 49:1-3) Mo ti rí bí ìfẹ́ tó ní sí wa ṣe máa ń hàn lójú àwọn èèyàn nígbà tí wọ́n bá kọ́kọ́ rí díẹ̀ lára àwọn ìwé wa ní èdè wọn tàbí tí wọ́n bá fi èdè tó gbádùn mọ́ wọn jù lọ kọ orin ìyìn sí Jèhófà. (Ìṣe 2:8, 11) Mo ṣì máa ń rántí ohun tí Arákùnrin Saulo Teasi, àgbàlagbà kan tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Tuvalu sọ nígbà tó kọ orin Ìjọba Ọlọ́run lédè rẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́, ó ní: “Mo ronú pé ó yẹ kí ẹ sọ fún Ìgbìmọ̀ Olùdarí pé àwọn orin yìí dùn-ún kọ ní èdè Tuvaluan ju èdè Gẹ̀ẹ́sì lọ.”

Láti September ọdún 2005, mo ti láǹfààní tí kò ṣeé ronú kàn láti di ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò lè ṣe iṣẹ́ atúmọ̀ èdè mọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń lò mí láti máa ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè tá à ń ṣe kárí ayé. Ohun àgbàyanu ló jẹ́ pé Jèhófà ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún gbogbo èèyàn, títí kan àwọn tó wà ní àwọn erékùṣù Òkun Pásífíìkì. Èyí ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ohun tí onísáàmù náà sọ pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ti di ọba! Kí ilẹ̀ ayé kún fún ìdùnnú. Kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù máa yọ̀.”Sm. 97:1.

^ ìpínrọ̀ 18 Wo àlàyé nípa bí àwọn èèyàn ṣe ń gba àwọn ìwé wa nínú Ilé Ìṣọ́, December 15, 2000, ojú ìwé 32; August 1, 1988, ojú ìwé 22; àti Jí! December 22, 2000, ojú ìwé 9.

^ ìpínrọ̀ 22 Tó o bá fẹ́ ka àlàyé púpọ̀ sí i nípa iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè ní erékùṣù Samoa, wo Ìwé Ọdọọdún 2009 [Gẹ̀ẹ́sì], ojú ìwé 120 sí 121 àti 123 sí 124.