‘Ẹ Máa Ka Irú Àwọn Ènìyàn Bẹ́ẹ̀ Sí Ẹni Ọ̀wọ́n’
LÁTI ọdún 1992 ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti ń yan àwọn alàgbà tó ní ìrírí tí òtítọ́ sì jinlẹ̀ nínú wọn láti máa ṣèrànwọ́ fún àwọn ìgbìmọ̀ tí wọ́n ń lò láti bójú tó iṣẹ́. * Ara “àwọn àgùntàn mìíràn” ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti yan àwọn tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ yìí, iṣẹ́ ribiribi ni wọ́n sì ń ṣe. (Jòh. 10:16) Wọ́n máa ń ṣèpàdé pẹ̀lú ìgbìmọ̀ tí wọ́n yàn wọ́n sí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, wọ́n máa ń fún ìgbìmọ̀ náà ní àwọn ìsọfúnni àti àbá tí wọ́n rí pé ó máa wúlò. Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló máa ń ṣe ìpinnu, àmọ́ àwọn olùrànlọ́wọ́ yìí ló máa ń ṣiṣẹ́ lórí ìpinnu náà, wọ́n á sì ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí bá yàn fún wọn. Àwọn olùrànlọ́wọ́ yìí àtàwọn mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Olùdarí jọ máa ń lọ sí àpéjọ àkànṣe àti ti àgbáyé. Ìgbìmọ̀ Olùdarí tún máa ń rán wọn lọ bẹ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wò gẹ́gẹ́ bí aṣojú orílé-iṣẹ́.
Ọ̀kan nínú àwọn olùrànlọ́wọ́ náà tó ti ń sìn láti ìgbà tí ètò yìí ti bẹ̀rẹ̀ sọ pé: “Tí mo bá ń bójú tó iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún mi, á ṣeé ṣe fún Ìgbìmọ̀ Olùdarí láti túbọ̀ pọkàn pọ̀ sórí ojúṣe rẹ̀.” Arákùnrin míì lára àwọn olùrànlọ́wọ́ tó ti sìn fún ohun tó lé ní ogún ọdún sọ pé: “Àǹfààní tí mi ò lè ronú kàn ni mo kà á sí.”
Iṣẹ́ bàǹtàbanta ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí fi síkàáwọ́ àwọn arákùnrin olóòótọ́ tó jẹ́ òṣìṣẹ́ kára yìí, Ìgbìmọ̀ Olùdarí sì mọrírì iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ń ṣe. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa “máa ka irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sí ẹni ọ̀wọ́n.”—Fílí. 2:29.
^ ìpínrọ̀ 2 Tó o bá fẹ́ kà nípa iṣẹ́ ìgbìmọ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń lò, wo Àpótí náà “Bí Ìgbìmọ̀ Olùdarí Ṣe Ń Bójú Tó Àwọn Ohun Tó Jẹ Mọ́ Ìjọba Ọlọ́run” ní Orí 12 nínú ìwé Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!