ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ November 2015

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti December 28, 2015 sí January 31, 2016 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Kọ́ Ọmọ Rẹ Kó Lè Sin Jèhófà—Apá Kìíní

Àwọn ànímọ́ mẹ́ta tí Jésù lò nígbà tó ń kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.

Kọ́ Ọmọ Rẹ Kó Lè Sin Jèhófà—Apá Kejì

Báwo lo ṣe lè ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè sin Jèhófà nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́?

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí ló fi hàn pé kò pẹ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì dó ti ìlú Jẹ́ríkò àtijọ́ tí wọ́n fi ṣẹ́gun rẹ̀?

Mọrírì Ìwà Ọ̀làwọ́ Jèhófà

Bíbélì jẹ́ ká mọ ọ̀nà tó dáa àti ọ̀nà tí kò dáa téèyàn lè gbà lo àkókò rẹ, okun rẹ̀ àtàwọn ohun ìní rẹ̀.

Ọlọ́run Ìfẹ́ Ni Jèhófà

Báwo ni Jèhófà ṣe fìfẹ́ hàn sí aráyé?

Ǹjẹ́ O “Nífẹ̀ẹ́ Aládùúgbò Rẹ Gẹ́gẹ́ Bí Ara Rẹ”?

O lè pa àṣe Jésù mọ́ nínú ìgbéyàwó rẹ, nínú ìjọ àti lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

Ọgọ́rùn-ún Ọdún Tí Ìjọba Ọlọ́run Ti Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣàkóso!

Àwọn ohun mẹ́ta wo ni Jèhófà ti fún wa ká lè máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run?

LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

‘Ohunkóhun Ò Gbọ́dọ̀ Dí Yín Lọ́wọ́!’

Àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tó wà nílẹ̀ Faransé láwọn ọdún 1930 sí ọdún 1939 fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká ní ìtara àti ìfaradà.