Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọlọ́run Ìfẹ́ Ni Jèhófà

Ọlọ́run Ìfẹ́ Ni Jèhófà

“Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”1 JÒH. 4:8, 16.

ORIN: 18, 91

1. Kí ni olórí ànímọ́ Ọlọ́run, báwo ni mímọ̀ tó o mọ èyí ṣe rí lára rẹ?

BÍBÉLÌ sọ fún wa pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” Kò wulẹ̀ sọ pé ìfẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ fífanimọ́ra tí Ọlọ́run ní, àmọ́ ó sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòh. 4:8) Olórí ànímọ́ rẹ̀ nìyẹn, òun ló sì ṣe pàtàkì jù nínú gbogbo ànímọ́ rẹ̀. Kì í ṣe pé Jèhófà kàn ní ìfẹ́ àmọ́ òun tó jẹ́ gan-an nìyẹn. Ẹ wo bó ṣe yẹ ká kún fún ọpẹ́ tó pé Ọlọ́run ìfẹ́ ló dá ayé àtọ̀run àti gbogbo ohun alààyè! Ìfẹ́ ló sì ń mú kó ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe.

2. Kí ni ìfẹ́ Ọlọ́run mú kó dá wa lójú? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

2 Torí pé Ọlọ́run jẹ́ aláàánú ó sì nífẹ̀ẹ́ gbogbo ohun tó dá, ìyẹn mú kó dá wa lójú pé gbogbo ìlérí tó ṣe fún aráyé máa ṣẹ, á sì ṣe gbogbo àwọn tó bá fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀ láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, torí ìfẹ́ tí Jèhófà ní, ó “ti dá ọjọ́ kan nínú èyí tí ó pète láti ṣèdájọ́ ilẹ̀ ayé tí a ń gbé ní òdodo nípasẹ̀ ọkùnrin kan tí ó ti yàn sípò,” ìyẹn Jésù Kristi. (Ìṣe 17:31) Ó dá wa lójú pé ìlérí yìí máa ṣẹ. Ọlọ́run máa fi ojú rere hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tí wọ́n sì ń ṣègbọràn, wọ́n á sì rí ìbùkún ayérayé gbà.

KÍ LÀWỌN OHUN TÓ Ń ṢẸLẸ̀ FI HÀN?

3. Báwo lo ṣe rò pé nǹkan máa rí ká ní Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ aráyé?

3 Tiẹ̀ rò ó wò ná, báwo lo ṣe rò pé nǹkan máa rí ká ní Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ aráyé? Kò sí nǹkan táà bá ṣe ju pé ká kàn máa wo àwọn láabi tó ń ṣẹlẹ̀ bí àwọn èèyàn ṣe ń jọba lórí ara wọn, tí Sátánì Èṣù tó jẹ́ òǹrorò sì ń darí wọn. (2 Kọ́r. 4:4; 1 Jòh. 5:19; ka Ìṣípayá 12:9, 12.) Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé bí Ọlọ́run bá yọwọ́ pátápátá lọ́rọ̀ àwa èèyàn, ayé yìí á bà jẹ́ bàlùmọ̀ ju bó ṣe wà yìí lọ.

4. Kí nìdí tí Jèhófà fi fàyè gba Sátánì láti ṣọ̀tẹ̀ sí ìṣàkóso rẹ̀?

4 Nígbà tí Èṣù ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, ó mú kí tọkọtaya àkọ́kọ́ náà ṣọ̀tẹ̀. Ó sọ pé Ọlọ́run ò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run àti pé ìṣàkóso rẹ̀ kò lè ṣe aráyé láǹfààní. Nípa báyìí, ohun tí Sátánì ń sọ ni pé ìṣàkóso òun máa dára ju ti Ẹlẹ́dàá lọ. (Jẹ́n. 3:1-5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà gba Sátánì láyè láti ṣe ohun tó rò pé ó tọ́ lójú ara rẹ̀, fúngbà díẹ̀ ni. Torí pé Jèhófà jẹ́ ọlọgbọ́n, ó ti mú sùúrù tó kó lè hàn gbangba pé kò sí ìṣàkóso kankan tó lè ṣàṣeyọrí yàtọ̀ sí ìṣàkóso òun. Gbogbo láabi tó ń ṣẹlẹ̀ láyé sì fi hàn pé, ẹ̀dá èèyàn kankan tàbí Sátánì pàápàá ò lè ṣàkóso àwọn èèyàn lọ́nà tó dára.

5. Kí ni àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn fi hàn?

5 Ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, àwọn èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù ló ti bógun lọ. Ó ṣe kedere pé ńṣe layé yìí ń bà jẹ́ sí i lójoojúmọ́. Ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé yóò máa ṣẹlẹ̀ ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan yìí nìyẹn. Kódà, ó fi kún un pé “àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.” (2 Tím. 3:1, 13) Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn fi hàn gbangba pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jer. 10:23) Ó ṣe kedere pé Jèhófà ò dá àwa èèyàn láti máa darí ara wa.

6. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi fúngbà díẹ̀?

6 Bí Ọlọ́run ṣe fàyè gba ìwà ibi fúngbà díẹ̀ jẹ́ ká rí i pé ìjọba èèyàn ò lè ṣàṣeyọrí láé. Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ o, ó tún jẹ́ kó ṣe kedere pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè ṣàṣeyọrí. Lẹ́yìn tí Jèhófà bá ti mú gbogbo ìwà ibi àtàwọn tó ń fà á kúrò, bí ẹnikẹ́ni bá tún yọwọ́kọ́wọ́ tó wá sọ pé ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣàkóso ò dáa, Jèhófà ò ní gba irú ọ̀tẹ̀ bẹ́ẹ̀ láyè mọ́ láé. Ọlọ́run máa lo àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí tó fi yẹ kó mú ìdájọ́ wá sórí irú àwọn ọlọ̀tẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ́gán, kò sì ní jẹ́ kí ìwà ibi tún gbérí mọ́ láé.

BÁWO NI JÈHÓFÀ ṢE FÌFẸ́ HÀN SÍ WA?

7, 8. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà fìfẹ́ hàn sí wa?

7 Onírúurú ọ̀nà ni Jèhófà gbà fìfẹ́ hàn sí wa. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa bí àgbáálá ayé wa yìí ti lẹ́wà tó, tó sì tún fẹ̀ lọ salalu. Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ló wà, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló sì ní ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ìràwọ̀ àti pílánẹ́ẹ̀tì nínú. Nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tí ayé yìí wà, ọ̀kan lára àwọn ìràwọ̀ tó wà níbẹ̀ ni oòrùn. Láìsí oòrùn, kò ní ṣeé ṣe fún ohun alààyè kankan láti wà lórí ilẹ̀ ayé. Gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run dá yìí fi hàn pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso, wọ́n sì tún jẹ́ ká rí àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní, irú bí agbára, ọgbọ́n àti ìfẹ́. Kódà, “àwọn ànímọ́ [Ọlọ́run] tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀.”Róòmù 1:20.

8 Ọlọ́run dá ayé lọ́nà táá mú kó ṣeé ṣe fún àwọn nǹkan tó dá sínú rẹ̀ láti máa wà láàyè nìṣó. Nígbà tí Ọlọ́run dá èèyàn, ó fi wọ́n sínú Párádísè ẹlẹ́wà kan, ó sì fún wọn ní ọpọlọ àti ara pípé tó máa mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti gbé títí láé. (Ka Ìṣípayá 4:11.) Síbẹ̀, ó “ń fi oúnjẹ fún gbogbo ẹlẹ́ran ara: Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”Sm. 136:25.

9. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, kí ló kórìíra, kí sì nìdí?

9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ìfẹ́ ni Jèhófà, ó kórìíra ohun búburú. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Sáàmù 5:4-6 sọ nípa Jèhófà pé: “Nítorí pé ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ń ní inú dídùn sí ìwà burúkú . . . Ìwọ kórìíra gbogbo àwọn aṣenilọ́ṣẹ́.” Ó tún sọ pé: “Ẹni ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ẹni ẹ̀tàn ni Jèhófà ń ṣe họ́ọ̀ sí.”

ÌWÀ IBI MÁA DÓPIN LÁÌPẸ́

10, 11. (a) Kí ni Jèhófà máa ṣe fún àwọn èèyàn búburú? (b) Kí ni Jèhófà máa ṣe fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́?

10 Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́ ó sì kórìíra ìwà ibi, torí náà ó ti pinnu láti mú gbogbo ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn lẹ́yìn tó bá ti pa gbogbo àwọn tí kò fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀ run. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Nítorí pé àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò, ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà ni yóò ni ilẹ̀ ayé. Àti pé ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́ . . . Àwọn ọ̀tá Jèhófà yóò sì dà bí ṣíṣeyebíye tí àwọn pápá ìjẹko ṣeyebíye; ṣe ni wọn yóò wá sí òpin wọn. Nínú èéfín ni wọn yóò wá sí òpin wọn.”Sm. 37:9, 10, 20.

11 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sm. 37:29) Irú àwọn olódodo bẹ́ẹ̀ yóò “rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sm. 37:11) Ó dájú pé èyí máa ṣẹ torí pé ohun tó máa ṣe àwọn ìránṣẹ́ olóòótọ́ láǹfààní ni Ọlọ́run máa ń ṣe. Bíbélì sọ pé: “Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣí. 21:4) Ẹ ò rí i pé ọjọ́ ọ̀la àgbàyanu ló ń dúró de gbogbo àwa tá a bá mọrírì ìfẹ́ tí Jèhófà ní, tá a sì ń ṣègbọràn sí i torí pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso wa!

12. Àwọn wo la lè pè ní “aláìlẹ́bi”?

12 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Máa ṣọ́ aláìlẹ́bi, kí o sì máa wo adúróṣánṣán, Nítorí pé ọjọ́ ọ̀la ẹni yẹn yóò kún fún àlàáfíà. Ṣùgbọ́n ó dájú pé a ó pa àwọn olùrélànàkọjá rẹ́ ráúráú lápapọ̀; ọjọ́ ọ̀la àwọn ènìyàn burúkú ni a óò ké kúrò ní tòótọ́.” (Sm. 37:37, 38) Àwọn “aláìlẹ́bi” làwọn tó mọ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Ka Jòhánù 17:3.) Irú ẹni bẹ́ẹ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ohun tó wà nínú 1 Jòhánù 2:17 tó sọ pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” Bí ayé yìí ṣe ń lọ sópin, ó ṣe pàtàkì ká “ní ìrètí nínú Jèhófà, [ká] sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́.”Sm. 37:34.

JÈHÓFÀ FI ÌFẸ́ ÀRÀ Ọ̀TỌ̀ HÀN SÍ WA

13. Báwo ni Jèhófà ṣe fìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sí wa?

13 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá, a lè ṣègbọràn sí Jèhófà. A tún lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà nítorí ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tó fi hàn sí wa. Ó pèsè ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, ó tipa bẹ́ẹ̀ ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn èèyàn onígbọràn láti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí wọ́n jogún láti ọ̀dọ̀ Ádámù. (Ka Róòmù 5:12; 6:23.) Jèhófà fọkàn tán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, torí ó ti wà pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run ó sì ti jẹ́ adúróṣinṣin fún àìmọye ọdún. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Jésù gan-an, ó sì dájú pé ó máa dùn ún gan-an nígbà tó rí bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Síbẹ̀, Jésù fi hàn pé òun fara mọ́ ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, ó sì tún jẹ́ kó ṣe kedere pé èèyàn pípé lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà kódà nígbà táwọn nǹkan bá nira gan-an.

Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa mú kó rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé (Wo ìpínrọ̀ 13)

14, 15. Báwo ni ikú Jésù ṣe ṣe aráyé láǹfààní?

14 Jésù pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́, ó sì fi hàn pé òun fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ kódà nígbà tó kojú àwọn àdánwò tó nira gan-an, ó sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Baba rẹ̀ títí tó fi kú. Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká kún fún ọpẹ́ pé nípasẹ̀ ikú rẹ̀ ó tún san ìràpadà tí aráyé nílò, ká lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí! Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ bí ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe yìí ṣe fi ìfẹ́ tí wọ́n ní sí wa hàn, ó ní: “Ní tòótọ́, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ aláìlera, Kristi kú fún àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ní àkókò tí a yàn kalẹ̀. Nítorí èkukáká ni ẹnikẹ́ni yóò fi kú fún olódodo; ní tòótọ́, bóyá ni ẹnì kan á gbójúgbóyà láti kú fún ènìyàn rere. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Róòmù 5:6-8) Àpọ́sítélì Jòhánù náà kọ̀wé pé: “Nípa èyí ni a fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn tiwa, nítorí Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀. Ìfẹ́ náà jẹ́ lọ́nà yìí, kì í ṣe pé àwa ti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, bí kò ṣe pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.”1 Jòh. 4:9, 10.

15 Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí aráyé, ó ní: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé [aráyé tó ṣeé rà pa dà] tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 3:16) Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní fún aráyé pọ̀ débi pé kì í fi ohun rere dù wọ́n, láìka ohun tó máa ná an sí. Ìfẹ́ rẹ̀ kì í kùnà láé. Gbogbo ìgbà la lè gbára lé e. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo gbà gbọ́ dájú pé kì í ṣe ikú tàbí ìyè tàbí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn ìjọba tàbí àwọn ohun tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tí ń bọ̀ tàbí àwọn agbára tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ni yóò lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.”Róòmù 8:38, 39.

ÌJỌBA ỌLỌ́RUN TI Ń ṢÀKÓSO

16. Kí ni Ìjọba Mèsáyà, ta ni Jèhófà sì yàn láti jẹ́ alákòóso Ìjọba náà?

16 Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn Ìjọba Mèsáyà tún fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa. Jèhófà ti fi ìjọba yìí sí ìkáwọ́ Ọmọ rẹ̀, Ọmọ rẹ̀ yìí nífẹ̀ẹ́ aráyé, òun ló sì kúnjú ìwọ̀n láti ṣàkóso. (Òwe 8:31) Nígbà tí àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tó máa bá Jésù jọba lókè ọ̀run yìí bá jíǹde, wọ́n á gbé gbogbo ìrírí tí wọ́n ti ni nígbà tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé lọ sọ́run. (Ìṣí. 14:1) Ìjọba Ọlọ́run ni lájorí ẹṣin ọ̀rọ̀ ìwàásù Jésù, ó sì kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mát. 6:9, 10) Ó dájú pé nígbà tí àdúrà yìí bá ṣẹ, ìbùkún àgbàyanu ló máa mú wá fún àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn.

17. Kí ló mú kí ìṣàkóso Jésù yàtọ̀ sí tàwọn èèyàn?

17 Ẹ ò rí i pé ìyàtọ̀ ńlá gbáà ló wà láàárín bí Jésù ṣe ń fìfẹ́ ṣàkóso àti bí ìṣàkóso àwọn èèyàn ṣe ń fa ikú ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn nígbà ogun! Ọ̀rọ̀ àwọn tí Jésù ń ṣàkóso lé lórí jẹ ẹ́ lógún gan-an, ó ní àwọn ànímọ́ àrà ọ̀tọ̀ tí Ọlọ́run ní, pàápàá jù lọ ìfẹ́. (Ìṣí. 7:10, 16, 17) Jésù sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Mát. 11:28-30) Ìlérí tó ṣeé gbára lé mà lèyí jẹ́ fún wa o!

18. (a) Kí ni Ìjọba Ọlọ́run ti ń gbé ṣe láti ìgbà tó ti bẹ̀rẹ̀? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

18 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì fi hàn pé ìgbà wíwàníhìn-ín Kristi lọ́dún 1914 ni Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀. Láti ìgbà yẹn ni ìkójọ àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn tó máa bá Jésù jọba lókè ọ̀run ti bẹ̀rẹ̀, bákan náà sì ni ìkójọ àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó máa la òpin ètò àwọn nǹkan yìí já, bọ́ sínú ayé tuntun. (Ìṣí. 7:9, 13, 14) Báwo làwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ti pọ̀ tó lónìí? Kí ni wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.