Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Tó Rọrùn Láti Lóye

Bíbélì Tó Rọrùn Láti Lóye

“Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè.”HÉB. 4:12.

ORIN: 37, 116

1. (a) Kí ni Ọlọ́run ní kí Ádámù ṣe? (b) Báwo làwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe ń lo ẹ̀bùn èdè látìgbà yẹn?

JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN ló fún àwa èèyàn ní ẹ̀bùn èdè. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run fi Ádámù sínú ọgbà Édẹ́nì, ó fún un ní iṣẹ́ kan tó gba pé kó lo èdè, ó ní kó sọ àwọn ẹranko lórúkọ. Ádámù lo ọgbọ́n tí Ọlọ́run dá mọ́ ọn láti sọ ẹranko kọ̀ọ̀kan lórúkọ tirẹ̀. (Jẹ́n. 2:19, 20) Látìgbà yẹn, àwọn èèyàn Ọlọ́run ń fi ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ àti èdè yin Jèhófà, wọ́n sì ń sọ ohun tó fẹ́ ṣe fáráyé. Ní báyìí, iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì tún wá ni ọ̀nà tó pabanbarì táwọn èèyàn Ọlọ́run ń gbà ti ìjọsìn mímọ́ lẹ́yìn.

2. (a) Àwọn ìlànà wo ni Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun tẹ̀ lé nígbà tí wọ́n ń túmọ̀ Bíbélì? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì ló wà, àmọ́ wọ́n péye jura wọn lọ. Lọ́dún 1940 sí 1949, Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun gbé àwọn ìlànà kan kalẹ̀, èyí tí wọ́n á máa tẹ̀ lé tí wọ́n bá ń túmọ̀ Bíbélì. Ìlànà yìí kan náà sì ni àwọn èdè tó lé ní àádóje [130] tẹ̀ lé nígbà tí wọ́n ń túmọ̀ Bíbélì. Àwọn ìlànà yìí ni: (1) Láti dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sí gbogbo ibi tó ti fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ kí orúkọ náà lè di sísọ di mímọ́. (Ka Mátíù 6:9.) (2) Ká túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, àmọ́ níbi tí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ bá ti máa yí ohun tí ọ̀rọ̀ túmọ̀ sí pa dà, ká tú ohun tí òǹkọ̀wé ní lọ́kàn gan-an. (3) Láti lo àwọn ọ̀rọ̀ tó rọrùn lóye táá mú kí Bíbélì máa wu èèyàn kà. * (Ka Nehemáyà 8:8, 12.) Ẹ jẹ́ ká wá wo bá a ṣe lo àwọn ìlànà yìí nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe lọ́dún 2013, lédè Gẹ̀ẹ́sì àti láwọn èdè míì.

BÍBÉLÌ TÓ Ń JẸ́ KÁWỌN ÈÈYÀN MỌ ORÚKỌ ỌLỌ́RUN

3, 4. (a) Inú àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ wo ni lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run ti fara hàn? (b) Kí ni ọ̀pọ̀ àwọn tó túmọ̀ Bíbélì ṣe sí orúkọ Ọlọ́run?

3 Àwọn kan ka àwọn Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fọwọ́ kọ lédè Hébérù àtijọ́ irú bí Àkájọ Ìwé Òkun Òkú. Ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n rí bí àwọn ibi tí lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run ti fara hàn ṣe pọ̀ tó. Kì í ṣe inú àwọn Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fọwọ́ kọ lédè Hébérù àtijọ́ yìí nìkan ni orúkọ Ọlọ́run ti fara hàn, ó tún fara hàn nínú Bíbélì Septuagint lédè Gíríìkì tó wà láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni.

4 Láìka bí ẹ̀rí ṣe pọ̀ lọ jáǹtirẹrẹ pé orúkọ Ọlọ́run wà nínú Bíbélì, ńṣe lọ̀pọ̀ àwọn tó túmọ̀ Bíbélì yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò pátápátá nínú ìtumọ̀ Bíbélì wọn. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ Ọlọ́run wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun tá a tẹ̀ jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 1950, Bíbélì Revised Standard Version tí wọ́n tẹ̀ jáde ní ọdún méjì lẹ́yìn náà yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò. Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì American Standard Version ti ọdún 1901 lo orúkọ Ọlọ́run, àmọ́ àwọn tó túmọ̀ Bíbélì Revised Standard Version tó yẹ kó jẹ́ àtúnṣe Bíbélì American Standard Version yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò. Kí nìdí tí wọ́n fi yọ ọ́ kúrò? Nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ tó wà nínú Bíbélì Revised Standard Version, wọ́n sọ pé: “Kò bójú mu rárá . . . pé kí àwọn Kristẹni máa fi orúkọ èyíkéyìí pe Ọlọ́run.” Ohun táwọn atúmọ̀ míì sì ṣe nìyẹn nígbà tí wọ́n ń túmọ̀ Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì àtàwọn èdè míì.

5. Kí nìdí tí kò fi yẹ káwọn tó túmọ̀ Bíbélì yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú Bíbélì?

5 Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ yẹ káwọn tó túmọ̀ Bíbélì yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú Bíbélì? Atúmọ̀ èdè kan tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí òun kọ́kọ́ lóye ohun tí òǹkọ̀wé ní lọ́kàn, kó sì wá jẹ́ kí ìyẹn máa darí ìtumọ̀ tí òun máa ṣe. Ọ̀pọ̀ ẹsẹ Bíbélì jẹ́ ká rí i pé orúkọ Ọlọ́run ṣe pàtàkì àti pé ó yẹ káwọn èèyàn mọ orúkọ náà kí wọ́n sì máa lò ó. (Ẹ́kís. 3:15; Sm. 83:18; 148:13; Aísá. 42:8; 43:10; Jòh. 17:6, 26; Ìṣe 15:14) Jèhófà Ọlọ́run mí sí àwọn tó kọ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti lo orúkọ rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. (Ka Ìsíkíẹ́lì 38:23.) Bí àwọn atúmọ̀ èdè bá wá yọ orúkọ tó fara hàn lọ́pọ̀ ìgbà nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ yìí kúrò nínú ìtumọ̀ wọn, á jẹ́ pé wọn ò bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run nìyẹn, torí pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni Bíbélì.

6. Kí nìdí tí orúkọ Ọlọ́run fi fara hàn ní ìgbà mẹ́fà sí i nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti ọdún 2013?

6 Ńṣe ni àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé a ò gbọ́dọ̀ yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú Bíbélì túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ìgbà ẹgbẹ̀rún méje ó lé igba àti mẹ́rìndínlógún [7,216] ni orúkọ náà fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 2013, ìyẹn sì fi ìgbà mẹ́fà lé sí iye ìgbà tó fara hàn nínú ti ọdún 1984. Márùn-ún nínú àwọn ẹsẹ tó ti fara hàn ni 1 Sámúẹ́lì 2:25; 6:3; 10:26; 23:14, 16. Ìdí tá a sì fi dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sí àwọn ẹsẹ yìí ni pé wọ́n fara hàn nínú àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú tó ti wà ní èyí tó ju ẹgbẹ̀rún ọdún kan ṣáájú kí ìwé àwọn Másọ́rẹ́tì lédè Hébérù tó wà. Ibì kan tó kù tá a tún dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sí wà nínú Àwọn Onídàájọ́ 19:18, a sì dá a pa dà síbẹ̀ torí ìwádìí tá a ṣe síwájú sí i nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́.

7, 8. Kí ni ìtumọ̀ orúkọ náà, Jèhófà?

7 Àwọn Kristẹni tòótọ́ ka orúkọ Jèhófà sí pàtàkì gan-an ni. Àlàyé síwájú sí i lórí kókó yìí wà nínú àfikún tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 2013. Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun lóye pé inú ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù náà ha·wah,’ tó túmọ̀ sí “láti di” ni orúkọ Ọlọ́run ti wá, torí náà, ìgbìmọ̀ yìí gbà pé orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí “Ó Ń Mú Kí Ó Di.” * Àlàyé tá a ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ nínú àwọn ìwé wa nìyí, ó sì dá lórí ohun tó wà nínú Ẹ́kísódù 3:14 tó sọ pé: “Èmi Yóò Jẹ́ Ohun Tí Èmi Yóò Jẹ́.” Ìyẹn ló fà á tá a fi sọ nínú “Àsomọ́” tó wà lẹ́yìn Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti ọdún 1984 pé orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí Ẹni “tí ń mú kí ara rẹ̀ di Olùmú àwọn ìlérí ṣẹ.” * Àmọ́, Àfikún A4 tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 2013 sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtumọ̀ yìí wà lára orúkọ náà, Jèhófà, kò mọ sí dídi ohunkóhun tí òun fúnra rẹ̀ lè dà. Ó tún kan ohun tó ń mú kó ṣẹlẹ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ àti bó ṣe ń mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ.”

8 Jèhófà máa ń mú kí àwọn ohun tó dá di ohun tó bá fẹ́. Ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ yìí sì máa ń rò ó. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run mú kí Nóà di ẹni tó ń kan ọkọ̀ áàkì, ó mú kí Bẹ́sálẹ́lì di ọ̀gá àwọn oníṣẹ́-ọnà, ó sọ Gídíónì di ajagunṣẹ́gun, ó sì mú kí Pọ́ọ̀lù di àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè. Ó ṣe kedere pé orúkọ Ọlọ́run ṣe pàtàkì gan-an sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun ò sì jẹ́ kóyán irú orúkọ pàtàkì bẹ́ẹ̀ kéré láé débi táá fi yọ ọ́ kúrò nínú Bíbélì.

9. Kí nìdí tí ètò Ọlọ́run fi fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ títúmọ̀ Bíbélì sí àwọn èdè míì?

9 Gbogbo Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tó wà lédè tó lé ní àádóje [130], ló lo orúkọ Ọlọ́run ní gbogbo ibi tó ti fara hàn nínú Ìwé Mímọ́. (Ka Málákì 3:16.) Àmọ́ ohun tí àwọn tó ń túmọ̀ Bíbélì ń ṣe báyìí yàtọ̀ síyẹn, ńṣe ni wọ́n ń fi àwọn orúkọ oyè bí “Olúwa” tàbí orúkọ òrìṣà wọn rọ́pò orúkọ Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì kí gbogbo èèyàn lè rí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kà ní èdè wọn.

BÍBÉLÌ TÓ PÉYE TÓ SÌ RỌRÙN LÓYE

10, 11. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìṣòro táwọn atúmọ̀ èdè bá pàdé nígbà tí wọ́n ń túmọ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sí èdè wọn?

10 Kò rọrùn láti túmọ̀ Bíbélì sí onírúurú èdè. Àwọn atúmọ̀ èdè sì máa ń kan ìṣòro lọ́pọ̀ ìgbà. Bí àpẹẹrẹ, nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì tá a kọ́kọ́ ṣe jáde, ọ̀rọ̀ Hébérù náà tá a tú sí “Ṣìọ́ọ̀lù” [tàbí, “Hédíìsì” lédè Gíríìkì] la lò nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì bí Oníwàásù 9:10 bí àwọn Bíbélì míì tó wà lédè Gẹ̀ẹ́sì ṣe ṣe. Ẹsẹ Bíbélì yẹn wá kà pé: “Kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù, ibi tí ìwọ ń lọ.” Èyí dá ìṣòro sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ń túmọ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sí èdè míì. Lára àwọn ìṣòro náà sì ni pé: Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tó ń sọ èdè wọn kò mọ ohun tó ń jẹ́ “Ṣìọ́ọ̀lù,” kò sí nínú àwọn ìwé atúmọ̀ èdè wọn, ńṣe ló sì máa ń dà bí ìgbà téèyàn ń dárúkọ ibì kan létí wọn. Nítorí èyí, ètò Ọlọ́run fọwọ́ sí i pé kí wọ́n lo ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, “Grave,” ìyẹn sàréè, kó lè yé àwọn èèyàn dáadáa.

11 Ó ṣòro fáwọn èdè kan láti túmọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù náà neʹphesh àti ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà psy·kheʹ tí èdè Gẹ̀ẹ́sì pè ní “soul,” ìyẹn ọkàn. Tí wọ́n bá lo ọ̀rọ̀ kan náà láti túmọ̀ rẹ̀ ní gbogbo ibi tó bá ti fara hàn, ó máa mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣi ọ̀rọ̀ náà lóye. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n ní fún un lédè wọn lè túmọ̀ sí òkú. Èyí tó máa mú kó dà bíi pé ọkàn kò tọ́ka sí ẹni náà fúnra rẹ̀, bí kò ṣe òkú rẹ̀ tó ń rìn káàkiri. Torí náà, ètò Ọlọ́run fọwọ́ sí i pé kí wọ́n túmọ̀ ọkàn níbàámu pẹ̀lú ohun tí ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n ń túmọ̀ bá sọ, kó sì wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìtumọ̀ tí ètò Ọlọ́run fún un nínú àsomọ́ tó wà lójú ìwé 1834 nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Yorùbá. Ní báyìí, a ti fi àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé sínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì kó lè dùn-ún kà kó sì rọrùn lóye.

12. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àtúnṣe tá a ṣe sí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti ọdún 2013 lédè Gẹ̀ẹ́sì? (Tún wo àpilẹ̀kọ náà, “Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Tá A Tún Ṣe Lọ́dún 2013” nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.)

12 Àwọn ìbéèrè táwọn atúmọ̀ èdè kọ ránṣẹ́ jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ìṣòro míì bí irú èyí tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí tún lè wáyé. Torí náà, ní oṣù September ọdún 2007, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé ká tún Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì ṣe. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìbéèrè táwọn atúmọ̀ èdè kọ ránṣẹ́ la gbé yẹ̀ wò nígbà tí àtúnṣe yìí ń lọ lọ́wọ́. A tún fi èdè Gẹ̀ẹ́sì tó bóde mu rọ́pò èyí táwọn èèyàn ò lò mọ́, a sì sapá gan-an kí àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ lè ṣe kedere kó sì rọrùn lóye láì yí ìtumọ̀ rẹ̀ pa dà. Ohun táwọn tó túmọ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sí èdè wọn ti ṣe mú kí àwọn ọ̀rọ̀ tá a lò nínú àtúnṣe ti èdè Gẹ̀ẹ́sì yìí sunwọ̀n sí i.Òwe 27:17.

INÚ ÀWỌN ÈÈYÀN DÙN GAN-AN

13. Kí làwọn èèyàn ń sọ nípa Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe lọ́dún 2013?

13 Báwo ni inú àwọn èèyàn ṣe dùn tó nígbà tí wọ́n rí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti ọdún 2013 gbà? Ọ̀pọ̀ lẹ́tà ìdúpẹ́ la rí gbà ní oríléeṣẹ́ wa ní Brooklyn, New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ohun tí arábìnrin kan kọ sínú lẹ́tà rẹ̀ jẹ́ ká mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ọ̀pọ̀ èèyàn, ó ní: “Àpótí ìṣura ni Bíbélì, àwọn ohun iyebíye sì kún inú rẹ̀ ní àkúnwọ́sílẹ̀. Torí náà, téèyàn bá ń ka ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti ọdún 2013, ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn ń fara balẹ̀ yẹ àwọn ohun iyebíye tó wà nínú àpótí ìṣura náà wò tinú tẹ̀yìn. Báwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣe dùn-ún lóye ti mú kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Kódà, tí mo bá ń ka Bíbélì yìí, ńṣe ló máa ń dà bí ìgbà tí Jèhófà fúnra rẹ̀ fọwọ́ gbá mi mọ́ra tó sì ń ka àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ń tuni lára sí mi létí.”

14, 15. Kí làwọn tó ti rí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti ọdún 2013 gbà lédè wọn sọ?

14 Inú àwọn tó rí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti ọdún 2013 tá a tú sí èdè tiwọn náà gbà dùn gan-an. Ọkùnrin àgbàlagbà kan láti ìlú Sofia lórílẹ̀-èdè Bọ̀géríà sọ bínú rẹ̀ ṣe dùn tó nígbà tó rí Bíbélì náà gbà lédè Bulgarian, ó ní: “Àìmọye ìgbà ni mo ti ka Bíbélì, àmọ́ mi ò tíì ka ìtumọ̀ Bíbélì tó rọrùn lóye tó sì ń wọni lọ́kàn tó yìí rí.” Nígbà tí arábìnrin kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Alibéníà náà ń sọ bínú rẹ̀ ṣe dùn tó nígbà tó rí Bíbélì náà gbà lédè Albanian, ó ní: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mà dùn lédè Albanian o! Inú wa dùn gan-an pé Jèhófà ń bá wa sọ̀rọ̀ lédè wa!”

15 Bíbélì ò pọ̀ láwọn ilẹ̀ kan, ó sì tún wọ́n gan-an. Torí náà, pé àwọn kan tiẹ̀ rí Bíbélì yìí gbà tọ́pẹ́ ó ju ọpẹ́ lọ. Ìròyìn kan tá a gbọ́ láti orílẹ̀-èdè Rùwáńdà sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn táwọn ará ti ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì látọjọ́ yìí ni òye ò tíì fi bẹ́ẹ̀ yé torí wọn ò ní Bíbélì. Owó wọn ò ká èyí tí wọ́n ń tà ní àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó yí wọn ká. Àwọn ẹsẹ Bíbélì kan ò yé wọn dáadáa, ìyẹn ò sì jẹ́ kí wọ́n tètè lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́.” Àmọ́, nǹkan yí pa dà nígbà tí ètò Ọlọ́run mú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè wọn. Ìdílé ọlọ́mọ mẹ́rin kan lórílẹ̀-èdè Rùwáńdà sọ pé: “Ọpẹ́ ni fún Jèhófà pé a rí Bíbélì yìí gbà, a sì tún dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye. A ò rí já jẹ, torí náà, kò sówó tá a lè fi ra Bíbélì fún gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé wa. Àmọ́ kálukú wa ló ti ní Bíbélì tiẹ̀ báyìí. Ojoojúmọ́ là ń ka Bíbélì náà ká lè máa fìyẹn dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà.”

16, 17. (a) Kí ni Jèhófà fẹ́ fún àwọn èèyàn rẹ̀? (b) Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe?

16 Láìpẹ́ láìjìnnà, Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe lọ́dún 2013 máa wà ní èdè púpọ̀ sí i. A mọ̀ pé inú Sátánì ò lè dùn sí èyí, àmọ́, ó dá wa lójú pé Jèhófà fẹ́ kí gbogbo àwọn èèyàn òun máa gbóhùn òun bóun ṣe ń fi èdè tó máa tètè yé wọn bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ṣe kedere. (Ka Aísáyà 30:21.) Àkókò náà yóò dé nígbà tí “ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”Aísá. 11:9.

17 Ǹjẹ́ kí gbogbo wa pinnu láti máa lo gbogbo ẹ̀bùn tí Jèhófà ń fún wa títí kan Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tó ń gbé orúkọ rẹ̀ lárugẹ. Jẹ́ kí Ọlọ́run máa tipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá ẹ sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́, sì jẹ́ kó dá ẹ lójú pé tíwọ náà bá gbàdúrà sí i, yóò gbọ́ àdúrà rẹ. Èyí á jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà bí ìfẹ́ tó o ní fún un ṣe túbọ̀ ń lágbára sí i.Jòh. 17:3.

“Inú wa dùn gan-an pé Jèhófà ń bá wa sọ̀rọ̀ lédè wa!”

^ ìpínrọ̀ 2 Wo Àfikún A1 tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí ọdún 2013 lédè Gẹ̀ẹ́sì; tún wo àpilẹ̀kọ náà, “Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Bíbélì Tí Wọ́n Túmọ̀ Lọ́nà Tó Dára?” nínú Ilé Ìṣọ́ May 1, 2008.

^ ìpínrọ̀ 7 Ohun tí àwọn ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ náà sọ nìyẹn, àmọ́ àwọn ọ̀mọ̀wé kan ò gbà bẹ́ẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 7 Wo Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, Àsomọ́ 1 “Orúkọ Àtọ̀runwá náà Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì,” ojú ìwé 1832.