Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Tá A Tún Ṣe Lọ́dún 2013

Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Tá A Tún Ṣe Lọ́dún 2013

A TI tún Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì ṣe nígbà mélòó kan látìgbà tá a ti mú un jáde, àmọ́ àtúnṣe ti ọdún 2013 yìí ló tíì pọ̀ jù lọ. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó wà nínú ìtumọ̀ tá a tún ṣe yìí kò pọ̀ tó ti tẹ́lẹ̀. A ti ṣàtúnṣe sí àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì kan nínú Bíbélì náà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹsẹ kan wọnú ara wọn tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n a ti tò wọ́n bí ẹní kọ ewì nínú ìtumọ̀ tá a tún ṣe náà, a sì tún fi àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé síbẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè ṣàlàyé gbogbo àtúnṣe tá a ṣe síbẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára wọn.

Àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì wo la ṣàtúnṣe sí? Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, a ti ṣàtúnṣe sí bá a ṣe túmọ̀ “Ṣìọ́ọ̀lù,” “Hédíìsì” àti ọ̀nà tá a gbà ń lo ọkàn. Yàtọ̀ sí èyí, àwọn ọ̀rọ̀ mélòó kan tún wà tá a ṣàtúnṣe sí.

Bí àpẹẹrẹ, a ti yí ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n lò láti fi ṣàlàyé bí wọ́n ṣe pa Jésù pa dà. Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì tá a lò tẹ́lẹ̀ lè mú káwọn èèyàn ní èrò tí kò tọ̀nà nípa bí wọ́n ṣe pa á. Àmọ́, èyí tá a lò báyìí ti jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere pé ńṣe ni wọ́n kàn án mọ́gi. (Mát. 20:19; 27:31) Dípò ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó túmọ̀ sí ìwà àìníjàánu a ti wá lo ọ̀rọ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú ìwà àìnítìjú tàbí ìwà ta-ní-máa-mú-mi, èyí tó bá a mu jù lọ nínú èdè Gíríìkì tí ọ̀rọ̀ náà ti wá. Bákan náà, táwọn èèyàn bá ka ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó túmọ̀ sí ìpamọ́ra, wọ́n lè máa rò pé ohun tó túmọ̀ sí ni pé kéèyàn jìyà fún àkókò gígùn. Àmọ́ ní báyìí a ti wá lo ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó túmọ̀ sí sùúrù torí pé ìyẹn ló gbé ìtumọ̀ náà yọ dáadáa. Ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó túmọ̀ sí àríyá aláriwo lè má tètè yé àwọn èèyàn, torí náà a ti yí i pa dà sí ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó máa tètè yé wọn. (Gál. 5:19-22) Dípò ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó túmọ̀ sí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́, a ti lo ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó túmọ̀ sí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, èyí tó máa jẹ́ káwọn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì tètè lóye ọ̀rọ̀ náà. Ohun tí ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sábà máa ń lò fún “ìṣòtítọ́” túmọ̀ sí náà nìyẹn.Sm. 36:5; 89:1.

Ní báyìí a ti túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ kan ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Bíbélì ń sọ níbi tí wọ́n bá ti fara hàn dípò ká kàn máa lo ọ̀rọ̀ kan ṣáà ní gbogbo ibi tí wọ́n ti fara hàn. Bí àpẹẹrẹ, a ti wá rí i pé ọ̀rọ̀ Hébérù náà, ʽoh·lamʹ tá a túmọ̀ sí “àkókò tí ó lọ kánrin” tẹ́lẹ̀, lè túmọ̀ sí ohun tó ti wà láti ayérayé tàbí ohun tó máa wà títí láé. Àpẹẹrẹ irú èyí wà nínú Sáàmù 90:2 àti Míkà 5:2.

Ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì tá a tú sí irú ọmọ fara hàn níbi tó pọ̀ díẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́. Wọ́n máa ń lò ó láwọn ibi tí Ìwé Mímọ́ bá ti ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀gbìn, wọ́n sì tún máa ń lò ó lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ láti tọ́ka sí ọmọ. Nínú àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì tá à ń lò tẹ́lẹ̀, ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó túmọ̀ sí irú ọmọ la lò ní gbogbo ibi tí ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì yìí ti fara hàn títí kan èyí tó fara hàn nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15. Àmọ́ kò wọ́pọ̀ mọ́ nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì káwọn èèyàn lo ọ̀rọ̀ yìí tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa ọmọ. Torí náà, nínú àtúnṣe yìí, ọmọ la lò ní Jẹ́nẹ́sísì 3:15 àtàwọn ẹsẹ míì tó sọ ohun tó fara jọ ọ́. (Jẹ́n. 22:17, 18; Ìṣí. 12:17) Àmọ́, ńṣe la túmọ̀ rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Bíbélì ń sọ láwọn ibòmíì tá a ti bá a pàdé.Jẹ́n. 1:11; Sm. 22:30; Aísá. 57:3.

Kí nìdí tá a fi ṣàtúnṣe sí ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú wọn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan? Àfikún A1 tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe lọ́dún 2013 sọ pé ìtumọ̀ Bíbélì tó dára “máa gbé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn kan yọ, níbi tí títúmọ̀ ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan bá ti máa mú kí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà yí pa dà tàbí kó ṣòroó lóye.” Bí àkànlò èdè tí wọ́n lò nínú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi kọ Bíbélì bá nítumọ̀ láwọn èdè míì, àwọn atúmọ̀ lè lò ó. Ìlànà yìí la tẹ̀ lé tá a fi túmọ̀ gbólóhùn kan tó wà nínú Ìṣípayá 2:23 sí “ń wá inú . . . ọkàn,” èyí sì nítumọ̀ ní ọ̀pọ̀ èdè. Àmọ́, àwọn èèyàn lè má tètè lóye gbólóhùn náà “ń wá inú kíndìnrín” tó fara hàn nínú ẹsẹ Bíbélì kan náà yẹn. Torí náà, a lo gbólóhùn Gẹ̀ẹ́sì tó túmọ̀ sí “èrò inú lọ́hùn-ún” dípò “kíndìnrín” ká lè gbé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò fún un ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ yọ. Nínú Diutarónómì 32:14, àkànlò èdè Hébérù náà “ọ̀rá kíndìnrín àlìkámà” la túmọ̀ sí “ọkà àlìkámà tó dára jù lọ.” Ìlànà yìí kan náà la tẹ̀ lé tá a fi yí gbólóhùn náà, “mo . . . jẹ́ aláìdádọ̀dọ́ ètè” tó wà nínú Ẹ́kísódù 6:12 pa dà sí “mo ní ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ.”

Kí nìdí tá a fi yí ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó túmọ̀ sí “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì” àti èyí tó túmọ̀ sí “àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba” pa dà sí “àwọn ọmọ Ísírẹ́lì” àti “àwọn ọmọ aláìníbaba”? Nínú èdè Hébérù, bí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan, wọ́n sábà máa ń sọ bóyá ọkùnrin ni onítọ̀hún tàbí obìnrin. Àmọ́, ọ̀rọ̀ míì tí wọ́n ń lò fún ọkùnrin tún lè dúró fún tọkùnrin tobìnrin. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ tó ṣáájú àti èyí tó tẹ̀ lé àwọn ẹsẹ kan nínú Bíbélì fi hàn pé tọkùnrin tobìnrin ni gbólóhùn náà “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì” ń tọ́ka sí. Torí náà, ohun tá a túmọ̀ gbólóhùn náà sí báyìí ni “àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”Ẹ́kís. 1:7; 35:29; 2 Ọba 8:12.

Bákan náà, nínú àwọn Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tẹ̀ jáde tẹ́lẹ̀, “àwọn ọmọ” la lò fún ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “àwọn ọmọkùnrin” nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:16. Ohun kan náà la wá ṣe báyìí nínú Ẹ́kísódù 22:24 tá a ti lo “àwọn ọmọkùnrin” tẹ́lẹ̀. Ohun tá a wá túmọ̀ rẹ̀ sí báyìí ni: “Àwọn ọmọ yín yóò sì di aláìníbaba.” A tún fi ìlànà yìí sílò nígbà tá à ń tú àwọn ẹsẹ Bíbélì míì, ìyẹn ló mú ká túmọ̀ “ọmọdékùnrin aláìníbaba” sí “ọmọ aláìníbaba” tàbí “ọmọ òrukàn.” (Diu. 10:18; Jóòbù 6:27) Bí Bíbélì Septuagint lédè Gíríìkì náà ṣe túmọ̀ rẹ̀ nìyẹn. Èyí ló mú ká lo gbólóhùn ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó túmọ̀ sí “àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́” dípò ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó túmọ̀ sí “àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin” tá a lò tẹ́lẹ̀ nínú Oníwàásù 12:1.

Kí nìdí tá a fi lo èdè Gẹ̀ẹ́sì tó rọrùn lóye láti túmọ̀ ọ̀pọ̀ lára ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù tó fara hàn nínú Bíbélì tá a tún ṣe? Ọ̀rọ̀ iṣé inú èdè Hébérù sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tá à ń ṣe lọ́wọ́ tàbí ohun tá a ti ṣe parí. Ní gbogbo ibi tí ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù tó ń sọ nípa ohun tẹ́nì kan ń ṣe lọ́wọ́ bá ti fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì tá a ti tẹ̀ jáde tẹ́lẹ̀, ńṣe la máa ń túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù náà tá ó sì wá fi ọ̀rọ̀ míì gbá a lẹ́gbẹ̀ẹ́. Bí àpẹẹrẹ, a lè lo èdè Gẹ̀ẹ́sì tó túmọ̀ sí “bẹ̀rẹ̀ sí” láti fi hàn pé ohun kan ti bẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n kò tíì parí tàbí ká lo “ń bá a lọ” ká lè fi hàn pé ohun kan ò tíì parí tàbí pé a tún irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe. * Àmọ́, nínú Bíbélì tá a tún ṣe yìí, a ti wá lo àwọn ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó túmọ̀ sí “dájúdájú,” “gbọ́dọ̀” àti “ní tòótọ́” láti fi hàn pé ohun kan ti parí.

Ṣùgbọ́n, kìkì ìgbà tó bá pọn dandan pé kí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ ṣe kedere nìkan la lo irú àwọn ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì bẹ́ẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe lọ́dún 2013. Bí àpẹẹrẹ, kò sídìí láti ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ pé, “Kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà” bíi pé ńṣe ni Ọlọ́run ń sọ bẹ́ẹ̀ léraléra. Torí náà, nínú Bíbélì tá a tún ṣe yìí, a ò fi ọ̀rọ̀ kankan gbá ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù náà, “sọ” lẹ́gbẹ̀ẹ́. (Jẹ́n. 1:3) Àmọ́ torí pé ṣe ni Jèhófà ń ké sí Ádámù léraléra nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:9, ọ̀rọ̀ tá a fi gba ọ̀rọ̀ ìṣe náà “pè” lẹ́gbẹ̀ẹ́ ṣì wà níbẹ̀ pé, Ọlọ́run “sì ń pe.” Lọ́rọ̀ kan ṣá, a túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù lọ́nà tó túbọ̀ rọrùn, ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an la fún láfiyèsí kì í ṣe bóyá ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù náà fi hàn pé nǹkan náà ti parí tàbí kò tíì parí. Àǹfààní míì tá a rí nínú èyí ni pé, níbi tó bá ti ṣeé ṣe, a lo ọ̀rọ̀ tí kò pọ̀ láti túmọ̀ ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù tó sábà máa ń kúrú.

Àwọn ẹsẹ tó pọ̀ sí i la ti tò bí ẹní kọ ewì, kí wọ́n lè dọ́gba pẹ̀lú bá a ṣe kọ wọ́n ní ìpilẹ̀ṣẹ̀

Kí nìdí táwọn ẹsẹ tá a tò bí ẹní kọ ewì fi wá pọ̀ sí i nínú Bíbélì tá a tún ṣe náà? Nígbà tí wọ́n kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀pọ̀ ẹsẹ tó wà níbẹ̀ ni wọ́n tò bí ẹní kọ ewì. Lóde òní, ohun táwọn èèyàn fi ń dá ewì mọ̀ ni pé ó máa ń dún lọ́nà tó bára jọ. Àmọ́ nínú èdè Hébérù, ńṣe ni ewì máa ń jẹ́ ká rí bí ọ̀rọ̀ kan ṣe jọ èkejì tàbí bí ọ̀rọ̀ ṣe yàtọ̀ síra. Nínú èdè Hébérù, ewì kì í dá lórí bí ọ̀rọ̀ ṣe dún lọ́nà tó bára jọ bí kò ṣe bí èrò tó wà nínú ọ̀rọ̀ ṣe tẹ̀ léra lọ́nà tó gún régé.

Nínú àwọn Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a ti tẹ̀ jáde tẹ́lẹ̀, a kọ ìwé Jóòbù àti Sáàmù bí ẹní kọ ewì láti fi hàn pé ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ńṣe ni wọ́n kọ wọ́n káwọn èèyàn lè máa kọ wọ́n lórin tàbí kí wọ́n máa há wọn sórí. Èyí máa ń jẹ́ kí wọ́n tètè lóye àwọn kókó tó wà níbẹ̀, kí wọ́n sì máa rántí ẹ̀. Nínú Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì tá a tún ṣe lọ́dún 2013, a ti tún àwọn ẹsẹ tó wà nínú ìwé Òwe, Orin Sólómọ́nì àtàwọn ìwé míì táwọn wòlíì kọ tò bí ẹni kọ ewì káwọn èèyàn lè mọ̀ pé ṣe ni wọ́n kọ wọn bí ewì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, kí wọ́n sì lè tètè rí àwọn ọ̀rọ̀ tó jọra níbẹ̀ àtàwọn tó yàtọ̀ síra. Àpẹẹrẹ irú ohun tá à ń sọ yìí wà nínú Aísáyà 24:2, níbi tá a ti lè rí ohun tó yàtọ̀ síra nínú gbólóhùn kọ̀ọ̀kan tó wà níbẹ̀ àti bí ẹsẹ kọ̀ọ̀kan ṣe ṣàlàyé síwájú sí i nípa ẹsẹ tó ṣáájú ẹ̀ láti mú kó ṣe kedere pé kò sẹ́ni tó máa bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. Bá a ṣe kọ àwọn ẹsẹ yìí bí ẹní kọ ewì máa jẹ́ kí òǹkàwé mọ̀ pé kì í ṣe àsọtúnsọ lásán ni òǹkọ̀wé Bíbélì náà ń sọ; kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló kọ ọ́ bí ẹní kọ ewì kó lè fi tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run ń sọ níbẹ̀.

Ó lè má rọrùn láti tètè rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọ̀rọ̀ Hébérù tó jẹ́ ewì àti èyí tí kì í ṣe ewì, torí náà ohùn àwọn tó túmọ̀ Bíbélì ò ṣọ̀kan lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ ewì. Torí náà, ọwọ́ ẹni tó ń ṣètumọ̀ ló kù sí láti pinnu àwọn ẹsẹ tó jẹ́ ewì. Àwọn ẹsẹ kan wà tí wọn ò kọ bí ẹní kọ ewì, àmọ́ tí wọ́n ní ọ̀rọ̀ tó jọ ewì nínú. Nínú irú àwọn ẹsẹ bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń fi ọ̀rọ̀ ṣàpèjúwe, wọ́n máa ń fọ̀rọ̀ dárà tàbí kí wọ́n lo àwọn ọ̀rọ̀ tó jọra láti ṣàlàyé kókó pàtàkì kan.

Ní báyìí, a ti wá fi Àwọn Kókó Pàtàkì Tó Wà Nínú Orí Kọ̀ọ̀kan sí ìbẹ̀rẹ̀ ìwé Bíbélì kọ̀ọ̀kan. Ohun tuntun yìí á ran òǹkàwé lọ́wọ́ láti mọ onírúurú ẹni tó ń sọ̀rọ̀ pàápàá jù lọ tó bá jẹ́ pé ewì àtijọ́ náà, ìyẹn Orin Sólómọ́nì, ló ń kà.

Báwo ni àwọn ìwé àfọwọ́kọ èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ tá a ṣèwádìí nínú ẹ̀ ṣe mú kó rọrùn láti ṣe àtúnṣe sí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun? Nígbà tá a fẹ́ túmọ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a kọ́kọ́ ṣe ìtumọ̀ rẹ̀, ìwé àwọn Másọ́rẹ́tì lédè Hébérù àti Bíbélì èdè Gíríìkì tí Westcott àti Hort tú la lò. Ìwádìí ṣì ń bá a nìṣó lórí àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́, àwárí wọn sì túbọ̀ ń mú ká lóye ohun táwọn ẹsẹ Bíbélì kan sọ ní ti gidi. Wọ́n tún ti ṣàwárí àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú. Àwọn ọ̀mọ̀wé tún ti ṣe ìwádìí tó jinlẹ̀ sí i nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ èdè Gíríìkì. Ọ̀pọ̀ àwọn ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n ṣàwárí ti wà lórí kọ̀ǹpútà báyìí, ìyẹn sì mú ko rọrùn fáwọn atúmọ̀ Bíbélì láti ṣe àyẹ̀wò wọn kínníkínní kí wọ́n lè mọ ìyàtọ̀ tó wà nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ náà. Èyí á wá mú kó rọrùn fún wọn láti mọ èyí tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ bá ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tàbí ti Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ mu jù lọ. Àwọn àwárí tuntun yìí mú kó ṣeé ṣe fún Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun láti túbọ̀ lóye àwọn ẹsẹ Bíbélì kan, ìyẹn sì mú kí wọ́n ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ.

Bí àpẹẹrẹ, ohun tó wà nínú 2 Sámúẹ́lì 13:21 nínú Bíbélì Septuagint lédè Gíríìkì ni: “Ṣùgbọ́n kò fẹ́ láti ṣe ohun tó máa bí Ámínónì ọmọ rẹ̀ nínú, torí pé òun ni àkọ́bí rẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” Àwọn Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a ti tẹ̀ jáde tẹ́lẹ̀ kò ní gbólóhùn yìí nínú torí pé wọn ò sí nínú ìwé àwọn Másọ́rẹ́tì. Àmọ́, gbólóhùn yìí wà nínú àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú, a sì ti fi kún Bíbélì tá a tún ṣe lọ́dún 2013. Ohun tó fà á náà nìyẹn tá a fi dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sáwọn ibi márùn-ún míì tó ti fara hàn nínú ìwé Sámúẹ́lì Kìíní. Ìwádìí tá a ṣe nínú àwọn Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì tún mú ká ṣe àtúntò ọ̀rọ̀ tó wà nínú Mátíù 21:29-31. Torí náà, ìwádìí tá a ṣe nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ ló mú ká ṣe díẹ̀ lára àwọn àtúnṣe tá a ṣe kì í wulẹ̀ ṣe Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì kan pàtó la tẹ̀ lé látòkè délẹ̀.

Àwọn ohun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ lára àwọn àtúnṣe tá a ṣe sí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kó lè túbọ̀ rọrùn kà, kó sì túbọ̀ rọrùn lóye fáwọn tó kà á sì ẹ̀bùn kan látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó máa ń bá àwa èèyàn sọ̀rọ̀.

^ ìpínrọ̀ 10 Wo Àfikún 3C tó ní àkòrí náà, “Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìṣe Hébérù Tó Sọ̀rọ̀ Nípa Ohun Tá À Ń Ṣe Lọ́wọ́” lójú ìwé 1572, nínú Bíbélì New World Translation of the Holy Scriptures—With References.

Òṣùwọ̀n

Kàlẹ́ńdà Àwọn Hébérù