Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo ló ṣe máa ń rí lára Ọlọ́run tó o bá ń jìyà?

Báwo ló ṣe máa ń rí lára Ọlọ́run tó o bá ń jìyà?

Àwọn kan gbà pé Ọlọ́run ò rí i pé ìyà ń jẹ wá, bẹ́ẹ̀ ni kò bìkítà nípa wa.

GBỌ́ OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

  • Ọlọ́run ń rí ìyà tó ń jẹ wá, ó sì bìkítà nípa wa

    “Jèhófà rí i pé ìwà búburú ènìyàn pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ ayé . . . , ó sì dùn ún ní ọkàn-àyà rẹ̀.”​—Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 6.

  • Ọlọ́run máa mú gbogbo ìyà kúrò

    “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”​—Sáàmù 37:10, 11.

  • Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún ẹ

    “‘Èmi fúnra mi mọ àwọn èrò tí mo ń rò nípa yín ní àmọ̀dunjú,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àwọn èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti ìyọnu àjálù, láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan. Dájúdájú, ẹ ó sì pè mí, ẹ ó sì wá gbàdúrà sí mi, èmi yóò sì fetí sí yín.”​—Jeremáyà 29:11, 12.

    “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”​—Jákọ́bù 4:8.