Àdúrà Táwọn Èèyàn Ń Gbà Jákèjádò Ayé
Àdúrà Táwọn Èèyàn Ń Gbà Jákèjádò Ayé
RÒ Ó wò ná, kí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn máa béèrè ohun kan náà. Wọ́n ń bẹ aláṣẹ ayé àtọ̀run pé kó ṣe ohun kan fáwọn. Síbẹ̀, àwọn tó mọ ohun tí wọ́n ń tọrọ yìí kò pọ̀. Ǹjẹ́ o rò pé ọ̀pọ̀ èèyàn lè máa tọrọ nǹkan kí wọ́n má sì mọ nǹkan ọ̀hún? Bẹ́ẹ̀ ni, ojoojúmọ́ ni wọ́n ń béèrè nǹkan ọ̀hún. Kí ni wọ́n ń tọrọ gan-an? Wọ́n ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé!
Àwọn kan fojú bù ú pé ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógójì [37,000] ìsìn tó pe ara wọn ní Kristẹni, tí wọ́n sì gbà pé Jésù Kristi ni Aṣáájú àwọn. Àwọn tó sì ń ṣe ẹ̀sìn yìí lé ní bílíọ̀nù méjì. Ọ̀pọ̀ wọn ló máa ń ka Baba Wa Tí Ń Bẹ Lọ́run tí wọ́n tún ń pè ní Àdúrà Olúwa. Ṣé ìwọ náà mọ àdúrà yẹn? Bí Jésù ṣe kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní àdúrà náà nìyí, ó sọ pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:9, 10.
Ó ti pẹ́ gan-an táwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ti máa ń ka àdúrà yìí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ láwọn ilé ìjọsìn wọn. Ìdílé kọ̀ọ̀kan máa ń gba àdúrà yìí, ẹnì kọ̀ọ̀kan sì máa ń dá gbà á, bóyá lákòókò ayọ̀ ni o tàbí lákòókò ìbànújẹ́. Tọkàntọkàn ni wọ́n máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú àdúrà ọ̀hún. Ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn ti sọ ọ́ di àkọ́sórí tí wọ́n sì ń kà á láìtiẹ̀ ronú lórí ìtumọ̀ rẹ̀. Àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì nìkan kọ́ ló ń retí dídé Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n sì ń gbàdúrà pé kó dé.
Kì Í Ṣe Àwọn Tó Ń Lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Nìkan Ló Ń Fẹ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àdúrà kan wà táwọn onísìn Júù máa ń gbà tí wọ́n bá ń ṣọ̀fọ̀, wọ́n ń pe àdúrà ọ̀hún ní Kádíṣì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àdúrà náà kò sọ̀rọ̀ nípa ikú tàbí ìbànújẹ́, wọ́n sábà máa ń gbà á nígbà táwọn èèyàn bá ń ṣọ̀fọ̀. Bí àdúrà náà ṣe lọ rèé: “Kí Ọlọ́run gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ lójú ẹ̀mí rẹ . . . àní, ní kíákíá.” a Wọ́n tún máa ń gba àdúrà míì nínú sínágọ́gù láyé àtijọ́ tó sọ nípa ìrètí wọn pé Ìjọba Mèsáyà ń bọ̀ látinú ìdílé Dáfídì.
Àwọn míì tí wọn ò tiẹ̀ kì í ṣe onísìn Kristẹni pàápàá ń fẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Times of India, ṣe sọ, olókìkí ọkùnrin ará Íńdíà kan tó jẹ́ aṣáájú ìsìn fẹ́ kí ìṣọ̀kan wà láàárín ìsìn Híńdù, Mùsùlùmí àti ti Kristẹni. Ó sọ pé: “Ìjọba Ọlọ́run ò lè dé àfi táwọn ará ìlà oòrùn àtàwọn ará ìwọ̀ oòrùn ayé bá fìmọ̀ ṣọ̀kan.” Ọ̀gá àgbà iléèwé kan tó jẹ́ tàwọn Mùsùlùmí nílùú Strathfield, lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà kọ̀wé lẹ́nu àìpẹ́ yìí sí iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn kan, ó sọ pé: “Èmi náà nígbàgbọ́ nínú ohun kan tí gbogbo Mùsùlùmí gbà gbọ́, pé Jésù máa padà wá, ó sì máa fìdí Ìjọba Ọlọ́run múlẹ̀.”
Láìsí àní-àní, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń retí Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n sì ń gbàdúrà pé kó dé. Àmọ́ kíyè sí ohun pàtàkì kan.
Ó ṣeé ṣe kó o mọ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá à ń tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde máa ń lọ láti ilé dé ilé ládùúgbò rẹ ká lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ látinú Bíbélì. Ní báyìí, jákèjádò ayé là ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní igba ó lé mẹ́rìndínlógójì [236] ilẹ̀, tá a sì ń wàásù ní èdè tó lé ní irínwó [400]. Ìjọba Ọlọ́run ni ìwàásù wa dá lé lórí. Kódà, àpèjá orúkọ ìwé ìròyìn yìí ni Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà. A sábà máa ń béèrè lọ́wọ́ àwọn èèyàn bóyá wọ́n máa ń gbàdúrà pé kí Ìjọba yẹn dé. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sọ pé àwọn máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, tá a bá bi wọ́n léèrè pé kí ni Ìjọba Ọlọ́run, ìdáhùn ọ̀pọ̀ jù lọ wọn máa ń fi hàn pé, wọn ò mọ̀ ọ́n. Ìdáhùn àwọn míì ò sì lórí, kò nídìí.
Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń tọrọ ohun tí wọn ò lè ṣàlàyé rẹ̀? Ṣé torí pé Ìjọba Ọlọ́run ò yé èèyàn dáadáa tó sì ṣòroó ṣàlàyé ni? Rárá o. Bíbélì ṣàlàyé Ìjọba Ọlọ́run dáadáa ó sì jẹ́ kó ṣe kedere. Láfikún sí i, ohun tí Bíbélì sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run lè fún ọ nírètí tó dájú lákòókò oníwàhálà yìí. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a máa rí bí Bíbélì ṣe ṣàlàyé ìrètí yẹn. A ó sì tún rí ìgbà tí Ọlọ́run yóò dáhùn àdúrà Jésù, pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú àdúrà Kádíṣì táwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ máa ń gbà, wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ pé kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́, bí àdúrà tí Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ náà ṣe sọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ń jiyàn lórí bóyá àdúrà Kádíṣì ti wà láti àkókò Kristi tàbí pé ó ti wà ṣáájú ìgbà yẹn, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé àdúrà méjèèjì jọ ara wọn. Jésù ò fi àdúrà yẹn kọ́ àwọn èèyàn ní nǹkan tuntun tàbí nǹkan táwọn èèyàn ò gbọ́ rí. Gbogbo ohun tí Jésù tọrọ nínú àdúrà náà jẹ́ àwọn nǹkan tó wà nínú Ìwé Mímọ́ tó wà fún gbogbo àwọn Júù lákòókò yẹn. Ńṣe ni Jésù ń gba àwọn Júù bíi tiẹ̀ níyànjú nípa àwọn nǹkan tó ti yẹ kí wọ́n máa fi sínú àdúrà wọn, àní kí Jésù tó wá sáyé pàápàá.