Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà Máa Ń Ṣẹ

Àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà Máa Ń Ṣẹ

Àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà Máa Ń Ṣẹ

J ÈHÓFÀ, ẹni tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, tó sì ń rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ sọ pé: “Èmi ni Olú Ọ̀run, kò sì sí Ọlọ́run mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí ó dà bí èmi; Ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin, tí ó sì ń ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn sọ àwọn nǹkan tí a kò tíì ṣe.”—Aísáyà 46:9, 10.

Kò sẹ́ni tí kò mọ̀ pé ọmọ èèyàn kò lè sàsọtẹ́lẹ̀ bọ́jọ́ ọ̀la ṣe máa rí, kó sì rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Níwọ̀n bí Bíbélì ti jẹ́ ìwé àsọtẹ́lẹ̀, ó yẹ káwọn tó fẹ́ mọ òtítọ́ yẹ̀ ẹ́ wò láti mọ̀ bóyá lóòótọ́ ìwé Ọlọ́run ni. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ tó nímùúṣẹ yẹ̀ wò.

Àwọn Orílẹ̀-Èdè Alágbára Láyé Àtijọ́

Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé ilẹ̀ Bábílónì máa pa run yán-ányán àti pé orílẹ̀-èdè Édómù, Móábù àti Ámónì náà máa pa run títí láé. (Jeremáyà 48:42; 49:17, 18; 51:24-26; Ọbadáyà 8, 18; Sefanáyà 2:8, 9) Báwọn orílẹ̀-èdè yìí ṣe ń dàwátì níkọ̀ọ̀kan títí wọn ò fi sí mọ́ jẹ́ ẹ̀rí pé àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run bá sọ máa ń ṣẹ.

Àwọn kan lè sọ pé ẹnikẹ́ni ló lè sàsọtẹ́lẹ̀ pé orílẹ̀-èdè kan yóò pa run, ì báà tiẹ̀ jẹ́ orílẹ̀-èdè tó lágbára gan-an. Àmọ́ ńṣe làwọn tó bá sọ bẹ́ẹ̀ gbàgbé kókó pàtàkì kan, ìyẹn ni pé Bíbélì máa ń ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lórí àsọtẹ́lẹ̀ tó bá sọ. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lórí bí wọ́n ṣe máa ṣẹ́gun ìlú Bábílónì. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ará Mídíà ni yóò ṣẹ́gun ìlú Bábílónì, pé Kírúsì ló máa kó àwọn ọmọ ogun wá àti pé wọ́n máa rí sí i pé omi tí ìlú náà fi ṣe odi ààbò gbẹ.—Aísáyà 13:17-19; 44:27–45:1.

Kì í ṣe gbogbo ìgbà tí Bíbélì bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ṣẹ́gun orílẹ̀-èdè kan tàbí àwọn èèyàn kan ló máa ń sọ pé wọn ò ní gbérí mọ́ láéláé. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ará Bábílónì máa ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù, ó sọ pé ìlú Jerúsálẹ́mù tún máa padà bọ̀ sípò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Bábílónì kì í dá àwọn tí wọ́n bá kó lẹ́rú sílẹ̀. (Jeremáyà 24:4-7; 29:10; 30:18, 19) Bó ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn, nítorí pé orílẹ̀-èdè àwọn Júù ṣì wà dòní olónìí.

Bákan náà, Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé orílẹ̀-èdè kan máa ṣẹ́gun Íjíbítì, yóò sì di orílẹ̀-èdè tí ó lágbára jù lọ láyé dípò rẹ̀, àmọ́ “lẹ́yìn ìgbà náà, a óò [padà] máa gbé inú rẹ̀ bí ti ìgbà láéláé.” Nígbà tó bá yá, orílẹ̀-èdè tó lágbára jù lọ tẹ́lẹ̀ yìí yóò wá “di ìjọba rírẹlẹ̀.” (Jeremáyà 46:25, 26; Ìsíkíẹ́lì 29:14, 15) Bó sì ṣe ṣẹlẹ̀ náà nìyẹn. Bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ṣẹ́gun ilẹ̀ Gíríìsì, wọ́n á sì gbapò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tó lágbára jù lọ láyé, àmọ́ kò sọ pé orílẹ̀-èdè yìí kò ní sí mọ́. Kí la rí kọ́ látinú bí àwọn orílẹ̀-èdè tó lágbára jù lọ tí Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa pa run ṣe dàwátì táwọn míì tí Jèhófà kò sọ pé wọ́n máa pa run ṣì wà di báyìí? Ó kọ́ wa pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣeé gbà gbọ́, tí wọ́n sì ṣeé gbára lé ló wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Kúlẹ̀kúlẹ̀ Àlàyé Tó Yani Lẹ́nu

Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ, Jèhófà ṣe àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa bí ilẹ̀ Bábílónì ṣe máa pa run. Lọ́nà kan náà, nígbà tí Jèhófà ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìparun ìlú Tírè, ó sọ nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì pé àwọn òkúta rẹ̀, iṣẹ́ àfigiṣe àti ekuru rẹ̀ ni wọn yóò kó “sí àárín omi.” (Ìsíkíẹ́lì 26:4, 5, 12) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ lọ́dún 332 ṣáájú Sànmánì Kristẹni nígbà tí Alẹkisáńdà Ńlá ní káwọn ọmọ ogun òun kó àwókù ìlú Tírè tó wà létí òkun, kí wọ́n fi ṣe ọ̀nà lọ sí ìlú Tírè kejì tó jẹ́ erékùṣù, tó sì wá pa ìlú náà run.

Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 8:5-8, 21, 22 àti 11:3, 4 náà fún wa ní àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó wúni lórí nípa “ọba ilẹ̀ Gíríìsì” kan tó lágbára lọ́nà tó kàmàmà. Ó ní wọn yóò pa ọba yìí nígbà tó bá ti di alágbára ńlá, pé wọ́n máa pín ìjọba rẹ̀ sọ́nà mẹ́rin, àmọ́, kì í ṣe láàárín àwọn ọmọ rẹ̀. Lẹ́yìn ohun tó lé ní igba ọdún tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti wà lákọsílẹ̀, a rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Alẹkisáńdà Ńlá ni ọba alágbára yẹn. Ìtàn sọ pé ọba yìí kú ikú òjijì, dípò kó sì jẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ló gbapò rẹ̀, àwọn ọ̀gágun rẹ̀ mẹ́rin ló pín ìjọba náà mọ́wọ́.

Àwọn aṣelámèyítọ́ sọ pé ẹ̀yìn tí nǹkan wọ̀nyí ti ṣẹlẹ̀ tán ni wọ́n tó kọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí. Jọ̀wọ́ tún ìtàn náà kà nínú ìwé Dáníẹ́lì tá a kọ sókè yìí. Tá a bá fojú àsọtẹ́lẹ̀ wò ó, àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé tó ṣe yóò jọni lójú gan-an ni. Àmọ́, tá a bá fojú ìtàn tó fara jọ àsọtẹ́lẹ̀ wò ó, ǹjẹ́ kò ní hàn kedere pé àwọn àlàyé tó ṣe kò kún tó? Tó bá jẹ́ pé afàwọ̀rajà kan tó gbé ayé lẹ́yìn tí Alẹkisáńdà kú ló kàn sọ ayédèrú àsọtẹ́lẹ̀ láti fi gbayì lójú àwọn èèyàn, kí nìdí tí kò fi kún un pé gbàrà tí Alẹkisáńdà bá kú, àwọn ọmọ rẹ̀ méjì máa gbìyànjú láti gorí àlééfà, àmọ́ wọ́n á pa wọ́n? Kí ló dé tí kò mẹ́nu kàn án pé ọ̀pọ̀ ọdún máa kọjá káwọn ọ̀gágun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso apá ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ilẹ̀ ọba Alẹkisáńdà? Àní sẹ́, kí ló dé tí kò fi sọ orúkọ ọba ńlá náà àti tàwọn ọ̀gágun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin?

Ọjọ́ pẹ́ táwọn kan ti ń sọ pé ẹ̀yìn táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bá ti ṣẹlẹ̀ tán ni wọ́n máa ń kọ wọ́n sínú Bíbélì gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀. Àmọ́, àwọn tó ń sọ bẹ́ẹ̀ kò ní ẹ̀rí kankan láti fi ti ohun tí wọ́n ń sọ lẹ́yìn torí wọn ò ṣèwádìí rárá nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà kí wọ́n tó sọ bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n kàn gbà pé kò lè ṣeé ṣe láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Nítorí wọn kò gbà rárá pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òye ọmọ èèyàn ni wọ́n fi ń ṣe gbogbo àlàyé wọn. Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run ọlọ́gbọ́n ló mú kí wọ́n kọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mélòó kan sínú Bíbélì, kí ìyẹn lè fi hàn pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni Bíbélì ti wá. a

Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì máa fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun bó o bá wáyè láti ṣàṣàrò lórí àwọn kan nínú wọn àti bí wọ́n ṣe nímùúṣẹ. O ò ṣe kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì? O lè lo àtẹ ìsọfúnni tó wà lójú ìwé 200 nínú ìwé náà “Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?” fún ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí. b Bó o bá ṣe ohun tá a sọ yìí, ní in lọ́kàn pé ńṣe lo fẹ́ túbọ̀ fún ìgbàgbọ́ rẹ lágbára bó o ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Má kàn sáré kà á wuuruwu nítorí pé o fẹ́ ka ibi tó pọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ronú jinlẹ̀ lórí òótọ́ náà pé ohunkóhun tí Jèhófà bá sọ tẹ́lẹ̀ máa ṣẹ dandan.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ àfikún àlàyé tó fi hàn pé kì í ṣe ẹ̀yìn táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ ni wọ́n kọ wọ́n sínú Bíbélì gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀, wo ojú ìwé 106 sí 111 nínú ìwé náà Is There a Creator Who Cares About You? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

ÌLÀNÀ TÓ O LÈ MÁA TẸ̀ LÉ NÍGBÈÉSÍ AYÉ

Nǹkan míì rèé tó tún yẹ ká ronú lé lórí. Ọlọ́run tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ báwọn orílẹ̀-èdè tó lágbára láyé yóò ṣe máa dìde tá a ó sì máa ṣẹ́gun wọn, tó sì rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ náà ló sọ àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì tó yẹ ká máa tẹ̀ lé nígbèésí ayé. Díẹ̀ lára wọn rèé:

Ohun tó o bá fúnrúgbìn lo máa ká.Gálátíà 6:7.

Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.Ìṣe 20:35.

Tó o bá fẹ́ láyọ̀, wá bó o ṣe máa tẹ́ ohun tó o ṣaláìní nípa tẹ̀mí lọ́rùn.Mátíù 5:3.

Bó o bá lo àwọn ìlànà yìí nígbèésí ayé rẹ, mọ̀ dájú pé wàá láyọ̀, wàá sì ṣàṣeyọrí.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22, 23]

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí yóò pa run títí láé . . .

ILẸ̀ ÉDÓMÙ

ILẸ̀ BÁBÍLÓNÌ

. . . Àmọ́ kò sọ pé àwọn wọ̀nyí yóò pa run títí láé

ILẸ̀ GÍRÍÌSÌ

ILẸ̀ ÍJÍBÍTÌ

[Àwọn Credit Line]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

Fọ́tò WHO látọwọ́ Edouard Boubat

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Alẹkisáńdà Ńlá