Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Yóò Dé?
Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Yóò Dé?
“OLÚWA, ìwọ ha ń mú ìjọba padà bọ̀ sípò fún Ísírẹ́lì ní àkókò yìí bí?” (Ìṣe 1:6) Àwọn àpọ́sítélì ń hára gàgà láti mọ ìgbà tí Jésù máa bẹ̀rẹ̀ Ìjọba rẹ̀. Ó ti lé ní ẹgbàá ọdún sẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì ti béèrè ìbéèrè yìí, síbẹ̀ àwọn èèyàn lónìí ṣì ń fi ìhára gàgà béèrè pé: Ìgbà wo ni Ìjọba Ọlọ́run máa dé?
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ìjọba Ọlọ́run ni ìwàásù Jésù dá lé lórí, ó yẹ ká retí pé kó dáhùn ìbéèrè yìí. Ohun tó sì ṣe gan-an nìyẹn! Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sọ̀rọ̀ nípa àkókò kan tó máa sàmì sí ìgbà “wíwàníhìn-ín” rẹ̀. (Matthew 24:37) Ìgbà wíwàníhìn-ín yẹn so pọ̀ mọ́ ìgbà tí Ìjọba Mèsáyà máa bẹ̀rẹ̀. Kí ni ìgbà wíwàníhìn-ín yìí? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn kókó mẹ́rin yẹ̀ wò lórí ohun tí Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nípa wíwàníhìn-ín Kristi.
1. Ó máa pẹ́ gan-an lẹ́yìn ikú Jésù kí wíwàníhìn-ín rẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀. Jésù sọ àkàwé kan nínú èyí tó fi ara rẹ̀ wé Ọkùnrin kan tó “rin ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ jíjìnnàréré láti gba agbára ọba síkàáwọ́ ara rẹ̀.” (Lúùkù 19:12) Báwo ni àkàwé tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe nímùúṣẹ? Ọ̀nà tó gbà nímùúṣẹ ni pé, Jésù kú ó sì jíǹde; ó wá rin ìrìn àjò lọ sí “ilẹ̀ jíjìnnàréré,” ìyẹn ọ̀run. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ nínú àkàwé mìíràn tó jọ èyí, ó padà bọ̀ pẹ̀lú agbára ìjọba “lẹ́yìn àkókò gígùn.”—Mátíù 25:19.
Ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn tí Jésù padà sí ọ̀run, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí [Jésù] Hébérù 10:12, 13) Nítorí náà, lẹ́yìn tí Jésù dé ọ̀run, ó dúró fún àkókò gígùn. Àkókò gígùn yẹn dópin nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run sọ Mèsáyà Ọmọ rẹ̀ di Ọba Ìjọba tí Bíbélì ti ṣèlérí rẹ̀ tipẹ́tipẹ́. Ìgbà yẹn sì ni wíwàníhìn-ín Kristi bẹ̀rẹ̀. Ǹjẹ́ àwọn èèyàn á rí ìṣẹ̀lẹ̀ pípabanbarì yìí?
rú ẹbọ kan ṣoṣo fún ẹ̀ṣẹ̀ títí lọ fáàbàdà, ó sì jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, láti ìgbà náà lọ, ó ń dúró títí a ó fi fi àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ̀.” (2. Wíwàníhìn- ín Jésù jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ táwọn èèyàn kò lè fojú rí. Má gbàgbé pé Jésù sọ ohun tó máa jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀. (Mátíù 24:3) Tó bá jẹ́ pé ohun táwọn èèyàn lè fojú rí ni wíwàníhìn-ín Kristi jẹ́ kí ló dé tá a tún fi nílò àmì? Wo àpèjúwe yìí ná: Ká sọ pé ó fẹ́ rin ìrìn àjò afẹ́ lọ sí òkun. Ó ṣeé ṣe kó o rí àwọn àmì tó ń tọ́ni sọ́nà táá máa sọ ibi tó yẹ kó o gbà, àmọ́ tó o bá ti dé etíkun tó o sì ń wo alagbalúgbú omi tó lọ salalu, ǹjẹ́ wàá tún máa retí pé kí wọ́n gbé àmì ńlá kan sétí òkun tí wọn kọ ọ̀rọ̀ náà, “Òkun” sí lára? Rárá o! O ò tún nílò àmì kankan mọ́ nígbà tó jẹ́ pé o ti fojú ara rẹ rí òkun náà.
Nígbà tí Jésù ń ṣàlàyé ohun tó máa jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀, kì í ṣe pé ó sọ ohun kan táwọn èèyàn máa fojú rí, àmọ́ ó sọ ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n fòye mọ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́run. Ìyẹn ló mú kí Jésù sọ pé: “Ìjọba Ọlọ́run kì yóò wá pẹ̀lú ṣíṣeérí tí ń pàfiyèsí.” (Lúùkù 17:20) Báwo wá ni àmì yẹn á ṣe jẹ́ káwọn tó wà láyé mọ̀ pé wíwàníhìn-ín Kristi ti bẹ̀rẹ̀?
3. Wàhálà tó kọjá àfẹnusọ tí yóò máa ṣẹlẹ̀ láyé jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín Jésù. Jésù sọ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò máa ṣẹlẹ̀ láyé tó máa jẹ́ àmì pé òun ti bẹ̀rẹ̀ sí í jọba lọ́run ni, ogun, ìyàn, ìsẹ̀lẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn àti ìwà àìlófin. (Mátíù 24:7-12; Lúùkù 21:10, 11) Kí ló fà á táwọn nǹkan ìbànújẹ́ báyìí á fi máa ṣẹlẹ̀? Bíbélì sọ pé, inú ń bí Sátánì, “olùṣàkóso ayé yìí” burúkú-burúkú nítorí ó mọ̀ pé àkókò kúkúrú ló kù fún òun ní báyìí tí Kristi ti wà níhìn-ín gẹ́gẹ́ bí Ọba. (Jòhánù 12:31; Ìṣípayá 12:9, 12) Lóde òní, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹ̀rí tó ṣeé fojú rí ló wà tó fi hàn pé inú ń bí Sátánì burúkú-burúkú, bákan náà là ń rí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Kristi ti wà níhìn-ín. Ẹ̀rí èyí túbọ̀ ṣe kedere ní pàtàkì látọdún 1914, tí gbogbo nǹkan yí padà káàkiri ayé lọ́nà tí kò ṣẹlẹ̀ rí, kódà àwọn òpìtàn gbà pé ọdún tó ṣàrà-ọ̀tọ̀ lọdún náà.
Ó lè dà bíi pé ìròyìn búburú làwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ yìí, àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ o. Ohun táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kàn ń jẹ́ ká mọ̀ ni pé Ìjọba Mèsáyà ti bẹ̀rẹ̀ lọ́run báyìí. Láìpẹ́, Ìjọba Mèsáyà yìí máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gbogbo ayé. Báwo làwọn èèyàn ṣe máa mọ̀ nípa Ìjọba yìí kí wọ́n lè fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀ kí wọ́n sì wà lára àwọn tí ìjọba náà yóò máa ṣàkóso lé lórí?
4. Iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé jẹ́ àmì pé Jésù ti wà níhìn-ín. Jésù sọ pé bí “àwọn ọjọ́ Nóà” a ni wíwàníhìn- ín òun á ṣe rí. (Mátíù 24:37-39) Yàtọ̀ sí pé Nóà kan ọkọ̀, ó tún jẹ́ “oníwàásù òdodo.” (2 Pétérù 2:5) Nóà kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé ìdájọ́ Ọlọ́run ti sún mọ́lé. Jésù sọ pé nígbà wíwàníhìn-ín òun, àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun pẹ̀lú á máa kìlọ̀ fáwọn èèyàn. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:14.
Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Ìjọba Ọlọ́run máa pa gbogbo ìjọba ayé yìí run. Iṣẹ́ ìwàásù yìí ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lórí gbogbo ayé, èyí á sì fún gbogbo èèyàn ní àǹfààní láti la ìparun tó ń bọ̀ já, wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ di ara àwọn tí Ìjọba yẹn á máa ṣàkóso lé lórí. Ìbéèrè pàtàkì wá ni pé, Kí lo máa ṣe sí ìkìlọ̀ yìí?
Ṣé Ìwọ Náà Ń Fẹ́ Ìjọba Ọlọ́run?
Ìrètí tí kò láfiwé ni iṣẹ́ ìwàásù Jésù ń fúnni. Lẹ́yìn tí Ádámù ṣọ̀tẹ̀ ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, Jèhófà Ọlọ́run ní in lọ́kàn láti fìdí ìjọba kan múlẹ̀ tó máa tún gbogbo nǹkan tó ti bà jẹ́ ṣe, á sì mú káwọn ẹ̀dá èèyàn olóòótọ́ pàdà sí ipò tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n wà ní ìbẹ̀rẹ̀, ìyẹn ni pé kí wọ́n máa gbé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Ká sòótọ́, ohun tó ń mórí ẹni yá ni láti mọ̀ pé ìjọbá tí Ọlọ́run ti ṣelérí tipẹ́tipẹ́ yẹn ti ń ṣàkóso lọ́run báyìí. Ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe ohun kan tó ṣòroó ṣàlàyé tàbí tó ṣòro láti lóye, àmọ́ ìjọba gidi kan ni!
Ní báyìí, Ọba tí Ọlọ́run yàn ti ń ṣàkóso láàárín àwọn ọ̀tà rẹ̀. (Sáàmù 110:2) Nínú ayé oníwà ìbàjẹ́ táwọn èèyàn ti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run yìí, Mèsáyà ń mú ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ ṣẹ láti máa wá gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ gàn-an kí wọ́n sì máa sìn ín “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:24) Ìrètí àtiwà láàyè títí láé lábẹ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run wà fún gbogbo ẹ̀yà, ọjọ́ orí tó yàtọ̀ síra àtàwọn tó wa ní ipò tó yàtọ̀ síra. (Ìṣe 10:34, 35) A rọ̀ ẹ́ pé kó o jẹ àǹfààní àgbàyanu yìí. Kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run nísinsìnyí, kó bàa lè ṣeé ṣe fún ọ láti wà láàyè títí láé lábẹ́ ìṣàkóso òdodo Ọlọ́run!—1 Jòhánù 2:17.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé báwọn Bíbélì kan ṣe túmọ̀ “wíwàníhìn-ín” kò tọ̀nà rárá. Àwọn Bíbélì kan tú u sí, “wíwá,” “dídé” tàbí “ìpadàbọ̀,” tá a bá sì wo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dáadáa, ohun tó máa ṣẹlẹ̀ fún kìkì àkókò kúkúrú ló túmọ̀ sí. Kíyè sí i pé Jésù kò fi wíwàníhìn-ín rẹ̀ wé ìkún-omi ọjọ́ Nóà, tó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé tó sì tètè parí, àmọ́ ó fi wé “àwọn ọjọ́ Nóà” tó jẹ́ àkókò gígùn kan tí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan ṣẹlẹ̀. Bíi ti ayé ìgbà yẹn, àkókò tí ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ á gba àwọn èèyàn lọ́kàn ni wíwàníhìn-ín Kristi yóò jẹ́. Àwọn èèyàn ò sì ní fiyè sáwọn ìkìlọ̀ táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń ṣe.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Àwọn ìròyìn burúkú tá à ń gbọ́ lójoojúmọ́ fi hàn pé àwọn ohun rere ti sún mọ́lé
[Credit Line]
Ìbọn tí wọ́n fi ń já ọkọ̀ òfuurufú: U.S. Army photo