Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

KÍ NI ìwàásù Jésù dá lé lórí gan-an? Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé Ìjọba Ọlọ́run ni. (Lúùkù 4:43) Láìsí àní-àní, àwọn tó gbọ́rọ̀ Jésù máa ń gbọ́ tó ń sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run lemọ́lemọ́ nínú ìwàásù rẹ̀. Ṣóhun tó sọ fún wọn nípa Ìjọba Ọlọ́run yé wọn? Ǹjẹ́ wọ́n tiẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run túmọ̀ sí? Rárá o. A ò rírú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere. Ǹjẹ́ àwọn tó ń gbọ́rọ̀ Jésù nígbà yẹn mọ Ìjọba Ọlọ́run dáadáa?

Ohun tó dájú ni pé Ìwé táwọn Júù ayé ìgbà yẹn gbà pé ó jẹ́ mímọ́ ṣàlàyé Ìjọba náà, ó jẹ́ ká mọ ohun tó jẹ́ gan-an, ó sì tún jẹ́ ká mọ ohun tí Ìjọba náà máa ṣe fún aráyé. Bákan náà lónìí, a lè mọ púpọ̀ sí i nípa Ìjọba Ọlọ́run tá a bá ṣe bíi tàwọn Júù yẹn, ìyẹn ni pé ká gbé ohun tí Bíbélì sọ yẹ̀ wò. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ohun méje pàtàkì tí Bíbélì fi kọ́ wa nípa Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn Júù ìgbà ayé Jésù àtàwọn tó ti gbé láyé ṣáájú ìgbà yẹn mọ mẹ́ta lára ohun méje náà. Ní ọ̀rúndún kìíní, Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jẹ́ ká mọ ohun mẹ́ta mìíràn lára wọn. Àkókò wa yìí ni ohun keje tó wá ṣe kedere.

1. Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba gidi kan tó máa wà títí láé. Àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa rán olùgbàlà kan wá sáyé tó máa gba àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn là. Ìwé Mímọ́ pe ẹni náà ní “irú-ọmọ,” Òun ló máa yanjú gbogbo wàhálà tí Ádámù, Éfà àti Sátánì dá sílẹ̀ látàrí ìwà ọ̀tẹ̀ tí wọ́n hù. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, Ọlọ́run sọ ọ̀rọ̀ kan tó ń múni láyọ̀ fún Dáfídì Ọba nípa “irú-ọmọ” tó tún jẹ́ Mèsáyà yìí. Ó sọ pé “irú-ọmọ” yẹn máa di Ọba Ìjọba kan. Ìjọba yìí máa yàtọ̀ sí gbogbo ìjọba yòókù. Títí ayé ló máa wà.—2 Sámúẹ́lì 7:12-14.

2. Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ìjọba èèyàn. Wòlíì Dáníẹ́lì rí ìran kan nípa àwọn ìjọba ayé tí yóò máa ṣàkóso ayé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, títí tó fi máa dìgbà tiwa yìí. Kíyè sí ọ̀rọ̀ amóríyá tó fi parí ìran náà, ó ní: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn [ìyẹn ìjọba àwọn èèyàn tó máa ṣàkóso kẹ́yìn], Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Èyí fi hàn pé àwọn ìjọba ayé yìí, pẹ̀lú gbogbo ogun, ìwà ìkà àti ìwà ìbàjẹ́ wọn, yóò pa run títí láé. Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì yìí ṣe fi hàn, láìpẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lórí gbogbo ayé pátá. (Dáníẹ́lì 2:44, 45) Yàtọ̀ sí pé ìjọba gidi ni, òun tún ni ìjọba kan ṣoṣo tó máa wà ní gbogbo ayé. a

3. Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí ogun, àìsàn, ìyàn àti ikú pàápàá. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ amóríyá tó wà nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe lórí ilẹ̀ ayé. Ìjọba yẹn á ṣohun táwọn ètò tèèyàn gbé kalẹ̀ ò tíì ṣe rí, tí wọn ò sì lè ṣe láé. Tiẹ̀ wo bó ṣe máa rí ná, gbogbo ohun ìjà ogun yóò pa run títí láé! “Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 46:9) Kò ní sẹ́ni tí yóò máa ṣiṣẹ́ dókítà mọ́, kò ní sí ilé ìwòsàn, kò sì ní sí àìsàn kankan mọ́. Bíbélì sọ pé: “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Kò ní sí ìyàn mọ́, kò ní sí àìtó oúnjẹ, tàbí pé ẹnì kan ò jẹun kánú. Bíbélì sọ pé “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀.” (Sáàmù 72:16) Kò ní sí ayẹyẹ ìsìnkú, àìsùn òkú, itẹ́ òkú, mọ́ṣúárì, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ìjìyà tí ikú èèyàn ẹni máa ń fà mọ́. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Ọlọ́run máa ṣẹ́gun ikú tó jẹ́ ọ̀tá wa paraku. Bíbélì sọ fún wa pé: Ọlọ́run “yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.”—Aísáyà 25:8.

4. Ìjọba Ọlọ́run ní Alákòóso kan tí Ọlọ́run ti yàn. Mèsáyà tó máa ṣàkóso yẹn kọ́ ló yan ara rẹ̀, kì í sì í ṣe àwọn èèyàn aláìpé ló yàn án. Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló yàn án. Ìtumọ̀ orúkọ oyè rẹ̀, ìyẹn Mèsáyà, tó jẹ́ èdè Hébérù àti Kristi, tó jẹ́ èdè Gíríìkì fi hàn pé Ọlọ́run ló yàn án. Orúkọ méjèèjì yìí túmọ̀ sí “ẹni àmì òróró.” Ìyẹn fi hàn pé Jèhófà ló dìídì yan ọba yìí sí ipò pàtàkì tó wà yìí. Ọlọ́run sọ nípa ọba náà pé: “Wò ó! Ìránṣẹ́ mi, tí mo dì mú ṣinṣin! Àyànfẹ́ mi, ẹni tí ọkàn mi tẹ́wọ́ gbà! Èmi ti fi ẹ̀mí mi sára rẹ̀. Ìdájọ́ òdodo fún àwọn orílẹ̀-èdè ni ohun tí yóò mú wá.” (Aísáyà 42:1; Mátíù 12:17, 18) Ta ló mọ irú Alákòóso tó yẹ wá bí kò ṣe Ẹlẹ́dàá wa?

5. Alákòóso Ìjọba Ọlọ́run ti fi hàn lójú gbogbo aráyé pé òun yẹ ní alákòóso. Jésù ará Násárétì fi hàn pé òun ni Mèsáyà tí Ìwé Mímọ́ ti sọ tẹ́lẹ̀. Ìdílé tí Ọlọ́run ti yàn pé wọ́n á ti bí i náà ni wọ́n ti bí i. (Jẹ́nẹ́sísì 22:18; 1 Kíróníkà 17:11; Mátíù 1:1) Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó mú ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà ṣẹ. Ọ̀pọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ló sì ti wà lákọsílẹ̀ láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú àkókò yẹn. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ tún jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà náà. Ọ̀nà wo ló gbà ṣe é? Ọlọ́run sọ látọ̀run pé Ọmọ òun ni Jésù; àwọn áńgẹ́lì sọ pé Jésù ni Mèsáyà tí Ìwé Mímọ́ sàsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀; lọ́pọ̀ ìgbà tún ni Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu níṣojú ọgọ́rọ̀ọ̀rún tàbí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn, tó sì hàn gbangba gbàǹgbà pé agbára Ọlọ́run ló fi ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ọ̀hún. b Léraléra ni Jésù fi irú Alákòóso tóun máa jẹ́ hàn. Yàtọ̀ sí pé ó lágbára láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ó tún máa ń wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Mátíù 8:1-3) Jésù jẹ́ ẹni tí kò mọ tara rẹ̀ nìkan, ó jẹ́ aláàánú àti onígboyà, ó sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Àwọn ohun tó ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé wà lákọsílẹ̀ nínú Bíbélì fún gbogbo wa láti máa kà.

6. Ìjọba Ọlọ́run ní àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi. Jésù sọ pé àwọn míì, títí kan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ máa ṣàkóso lọ́run pẹ̀lú òun. Ó pe àwùjọ yìí ní “agbo kékeré.” (Lúùkù 12:32 ) Lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Jòhánù rí i nínú ìran kan pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ni iye táwọn agbo kékeré náà máa jẹ́. Iṣẹ́ tó ń fúnni láyọ̀ ni wọn yòó máa ṣe lọ́run, ìyẹn ni bíbá tí wọ́n máa bá Kristi ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà.—Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1, 3.

7. Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso lọ́run báyìí, ó sì máa tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lé gbogbo ilẹ̀ ayé lórí. Nínú àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tá a ti gbé yẹ̀ wò, kókó keje yìí ló ń mórí ẹnì yá jù lọ. Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé Ọlọ́run ti fi Jésù jẹ Ọba lọ́run. Ó ti ń jọba lọ́run báyìí, láìpẹ́, ó máa jọba lórí gbogbo ayé pátá, yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àgbàyanu tá a ti sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú àpilẹ̀kọ yìí ṣẹ. Àmọ́, báwo ló ṣe dá wa lójú pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso lọ́run nísinsìnyí? Ìgbà wo ló sì máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lé ayé lórí?

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ báyìí fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe ohun kan tó wà nínú ọkàn àwọn èèyàn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fi kọ́ àwọn kan. Wo abala “Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé,” tó wà ní ojú ìwé 13.