Kò Sí Bàbá Tó Dà Bíi Rẹ̀
Sún Mọ́ Ọlọ́run
Kò Sí Bàbá Tó Dà Bíi Rẹ̀
“BÀBÁ.” Ipa tí bàbá ń kó láyé ọmọ kò kéré. Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀ máa ń tọ́ ọ dàgbà lọ́nà tó dára. Abájọ tí Bíbélì fi pe Jèhófà Ọlọ́run ní “Baba.” (Mátíù 6:9) Irú Bàbá wo ni Jèhófà? Láti rí ìdáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká gbé ohun tí Jèhófà sọ fún Jésù nígbà tí Jésù ń ṣe ìrìbọmi yẹ̀ wò. Ó ṣe tán, ọ̀nà tí bàbá kan gbà ń bá ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ máa ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́.
Ní nǹkan bí October ọdún 29 Sànmánì Kristẹni, Jésù lọ ṣèrìbọmi lódò Jọ́dánì. Bíbélì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀, ó ní: “Lẹ́yìn tí a batisí rẹ̀, Jésù jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti inú omi; sì wò ó! ọ̀run ṣí sílẹ̀, ó sì rí tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà bọ̀ wá sórí rẹ̀. Wò ó! Pẹ̀lúpẹ̀lù, ohùn kan wá láti ọ̀run tí ó wí pé: ‘Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.’” a (Mátíù 3:16, 17) Ọ̀rọ̀ onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ yìí jẹ́ ká túbọ̀ mọ irú Bàbá tó jẹ́. Kíyè sí nǹkan mẹ́ta tí Jèhófà sọ fún Ọmọ rẹ̀.
Àkọ́kọ́, nígbà tí Jèhófà sọ pé “èyí ni Ọmọ mi,” ohun tó ń sọ ni pé, ‘Ọmọ àmúyangàn ni ọ́.’ Bàbá tó lákìíyèsí máa ń fún àwọn ọmọ rẹ̀ láfiyèsí, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun kà wọ́n sí, ìyẹn sì lohun táwọn ọmọ ń fẹ́. Ó yẹ kó hàn sáwọn ọmọ nínú ìdílé pé bàbá àwọn kì í fojú pa àwọn rẹ́. Ẹ wo bó ṣe máa rí lára Jésù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti dàgbà nígbà yẹn, láti mọ̀ pé Bàbá òun ka òun sí!
Èkejì, nígbà tí Jèhófà pe Ọmọ rẹ̀ ní “olùfẹ́ ọ̀wọ́n,” ńṣe ni Jèhófà ń fi hàn ní gbangba pé òun nífẹ̀ẹ́ Jésù. Lọ́rọ̀ kan ṣá, ohun tí Jèhófà ń sọ ni pé, ‘Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ.’ Bàbá rere máa ń sọ fáwọn ọmọ rẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. Irú àwọn ọ̀rọ̀ báyìí àti ìfẹ́ àtọkànwá tí bàbá bá fi hàn sí ọmọ máa ń jẹ́ kọ́mọ láyọ̀. Ẹ wo bínú Jésù á ṣe dùn tó bó ṣe ń gbọ́ tí Bàbá rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀!
Ẹ̀kẹta, nígbà tí Jèhófà sọ pé “ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà,” ohun tó ń sọ ni pé òun tẹ́wọ́ gba Ọmọ òun. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà ń sọ fún Ọmọ rẹ̀ pé: ‘Ọmọ, ó káre láé. Inú mi dùn sóhun tó o ṣe.’ Bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ máa ń lo àǹfààní tó bá yọ láti fi sọ fáwọn ọmọ rẹ̀ pé inú òun dùn sáwọn ohun rere tí wọ́n ṣe tàbí tí wọ́n sọ. Ara àwọn ọmọ máa ń yá gágá nígbà tí wọ́n bá rójú rere àwọn òbí wọn. Dájúdájú, ara Jésù náà ti ní láti yá gágá nígbà tó gbọ́ tí Bàbá rẹ̀ sọ pé òun tẹ́wọ́ gbà á.
Ká sòótọ́, kò sí bàbá tó dà bíi Jèhófà. Ṣé ó wù ọ́ kí ìwọ náà nírú bàbá bẹ́ẹ̀? Tó bá wù ọ́, lọ fọkàn balẹ̀ torí pé ìwọ náà lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà. Tó o bá nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, tó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀, tó o sì ń fi tọkàntọkàn sapá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, yóò fà ọ́ mọ́ra. Bíbélì sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Kí lohun tó tún lè fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀ bíi pé kó o ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tí kò sí bàbá tó dà bíi rẹ̀?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé Ìhìn Rere Lúùkù tó ròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kan náà fi hàn pé Jèhófà lo ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ náà “ìwọ,” ó ní: “Ìwọ ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.”—Lúùkù 3:22.