Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Fi ‘Ọ̀rọ̀ Tó Dára’ Gbé Ìdílé Rẹ Ró

Máa Fi ‘Ọ̀rọ̀ Tó Dára’ Gbé Ìdílé Rẹ Ró

Máa Fi ‘Ọ̀rọ̀ Tó Dára’ Gbé Ìdílé Rẹ Ró

ỌKÙNRIN kan tó ń jẹ́ David ń dúró de ìyàwó rẹ̀ nínú ọkọ̀, inú sì ń bí i gan-an pé ìyàwó òun pẹ́. Ìṣẹ́jú-ìṣẹ̀jú ló ń wo aago ọwọ́ rẹ̀ léraléra. Nígbà tí Diane ìyàwó rẹ̀ fi máa jáde nínú ilé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọkùnrin náà kò lè pa ìbínú rẹ̀ mọ́ra mọ́.

Ó jágbe mọ́ ìyàwó rẹ̀ pé: “Wo bó o ṣe dá mi dúró látàárọ̀! Ìgbà gbogbo lo máa ń pẹ́ kó o tó ṣe tán ní tìẹ! Kó o má tiẹ̀ lè tètè múra tán láyé ẹ.”

Ọ̀rọ̀ yẹn dun ìyàwó rẹ̀ wọnú eegun, ló bá bú sẹ́kún, ó sì sá padà sínú ilé. Ìgbà yẹn gan-an ló tó wá yé David pé ọ̀rọ̀ tóun sọ yẹn ò dáa. Ìbínú tó ru bò ó lójú ti jẹ́ kó bọ̀rọ̀ jẹ́. Kí ló máa wá ṣe báyìí? Ó paná ọkọ̀, ó mí kanlẹ̀ ó sì rọra lọ bá ìyàwó rẹ̀ nínú ilé.

Ọ̀pọ̀ èèyàn nirú nǹkan báyìí ti ṣẹlẹ̀ sí rí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ṣé ìwọ náà ti sọ̀rọ̀ kan rí tó o wá rí i pé ì bá dáa kó o má tiẹ̀ sọ ọ́ rara? Tá ò bá máa ronú dáadáa ká tó máa sọ̀rọ̀, kò sígbà tá ò ní máa sọ ohun tá a ó máa kábàámọ̀ rẹ̀. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn.”—Òwe 15:28.

Àmọ́ nígbà míì, ó lè ṣòro gan-an láti ronú jinlẹ̀ kéèyàn tó sọ̀rọ̀, àgàgà tínú bá ń bí wa, tẹ́rù bá ń bà wá tàbí tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá. Tó bá wá jẹ́ pé ẹnì kan tá a jọ wà nínú ìdílé lọ̀rọ̀ jọ dà wá pọ̀, dípò ká sọ ohun tó wà lọ́kàn wa, ó lè di pé ká máa dá ẹni tá à ń bá sọ̀rọ̀ lẹ́bi tàbí ká máa ta kò ó. Ìyẹn sì lè fa gbún-gbùn-gbún tàbí àríyànjiyàn.

Kí la lè ṣe tírú ẹ̀ ò fi ní máa wáyé? Ọ̀nà wo la lè gbé e gbà tí ìbínú ò fi ní máa ru bò wá lójú débi tí a ó fi ṣohun tí kò yẹ ká ṣe? A lè rí àwọn ìmọ̀ràn àtàtà látọ̀dọ̀ Sólómọ́nì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì.

Ronú Nípa Ohun Tó O Fẹ́ Sọ àti Bó Ṣe Yẹ Kó O Sọ Ọ́

Ọ̀nà tí Sólómọ́nì tó kọ ìwé Oníwàásù inú Bíbélì gbà sọ ohun tó mọ̀ nípa jíjẹ́ tí ayé jẹ́ asán fi hàn pé ọ̀rọ̀ náà ká a lára. Ó sọ pé: “Mo . . . kórìíra ìwàláàyè.” Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó pè é ní “asán pátápátá gbáà.” (Oníwàásù 2:17; 12:8) Àmọ́ kì í ṣe kìkìdá àwọn ohun tó ń dun Sólómọ́nì nìkan ló kọ sínú ìwé Oníwàásù. Ó wò ó pé kò bójú mu kò jẹ́ pé ohun tí kò dáa nípa ìgbésí ayé nìkan lóun máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Lápá ìparí ìwé náà, Sólómọ́nì sọ pé òun “wá ọ̀nà àtirí àwọn ọ̀rọ̀ dídùn àti àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ títọ̀nà tí ó jẹ́ òtítọ́.” (Oníwàásù 12:10) Ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn sọ pé ó “gbìyànjú láti ṣàlàyé àwọn nǹkan yìí lọ́nà tó dáa jù lọ tó sì péye jù lọ.”—Ìtumọ̀ Contemporary English Version.

Ó hàn gbangba pé Sólómọ́nì mọ̀ pé kò yẹ kí ọ̀rọ̀ yẹn ká òun lára jù. Ohun tó ṣe yẹn túmọ̀ sí pé, ó ń bi ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ sọ yìí, ṣé kò ní àbùmọ́ kankan? Tí mo bá sọ ọ́ bí mo ṣe fẹ́ sọ ọ́ yìí, ṣáwọn èèyàn á kà á sí ọ̀rọ̀ tó dára tó máa bá wọn lára mu?’ Bó ṣe gbìyànjú láti wá ‘ọ̀rọ̀ tó dára’ tó sì jóòótọ́ ni kò jẹ́ kí kíká tí ọ̀rọ̀ náà ká a lára mú kó ṣi inú rò.

Ohun tí Sólómọ́nì ṣe yẹn mú kí ìwé Oníwàásù tó kọ lárinrin, ìyẹn nìkan kọ́, ó kún fún ọgbọ́n tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run lórí ọ̀ràn ìgbésí ayé. (2 Tímótì 3:16, 17) Ǹjẹ́ kò yẹ kí ọ̀nà tí Sólómọ́nì gbà ṣàlàyé ọ̀rọ̀ tó gbẹgẹ́ yẹn ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bó ṣe yẹ ká máa bá àwọn èèyàn wa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó túbọ̀ dára sí i? Wo àpẹẹrẹ kan.

Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Máa Ká Ẹ Lára Jù

Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká sọ pé ọmọkùnrin kan ti iléèwé dé tóun ti èsì ìdánwò rẹ̀ lọ́wọ́ àmọ́ tójú ẹ̀ rẹ̀wẹ̀sì. Bàbá rẹ̀ yẹ káàdì rẹ̀ wò, ó sì rí i pé ó féèlì iṣẹ́ kan. Bínú ṣe bí bàbá yẹn nìyẹn, ó rántí ọ̀pọ̀ ìgbà tí ọmọ yẹn kì í tètè ṣe iṣẹ́ ilé tí wọ́n bá fún un láti iléèwé. Ó ṣe bàbá yẹn bíi kó jágbe mọ́ ọmọ yẹn pé: “O ò rí i pé òkú ọ̀lẹ nìwọ yìí! Tó o bá ń bá a lọ báyìí, èrò ẹ̀yìn lo máa dà láyé ẹ!”

Kí bàbá yẹn tó fi ìbínú sọ̀rọ̀, ó yẹ kó kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ ara rẹ̀ pé, ‘Ṣóòótọ́ pọ́ńbélé lohun tí mo fẹ́ sọ yìí?’ Tó bá bi ara rẹ̀ nírú ìbéèrè yìí, á lè rí bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an dípò táá fi fìbínú sọ̀rọ̀. (Òwe 17:27) Ṣóòótọ́ ni pé ọmọ yẹn á dèrò ẹ̀yìn torí pé kò mọ iṣẹ́ kan dáadáa níléèwé? Ṣé òkú ọ̀lẹ ni lóòótọ́? Àbí ṣe torí pé iṣẹ́ yẹn ò yé e dáadáa ni kì í fi í tètè ṣe é? Léraléra ni Bíbélì máa ń tẹ̀ ẹ́ mọ́ wa lọ́kàn pé ká máa lo òye nígbà tá a bá ń bójú tó àwọn ọ̀ràn kan ká lè rí ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an. (Títù 3:2; Jákọ́bù 3:17) Láti lè mú kórí ọmọ kan yá, òbí rẹ̀ ní láti máa sọ “àwọn ọ̀rọ̀ títọ̀nà tí ó jẹ́ òtítọ́.”

Ronú Nípa Ọ̀rọ̀ Tó Yẹ Kó O Sọ

Bí bàbá yẹn bá ti mọ ohun tó fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí báyìí, ó lè wá bi ara rẹ̀ pé, ‘Báwo ni màá ṣe sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dára tí ọmọ mi á fi lè gba ìbáwí yìí?’ Lóòótọ́, ó lè má rọrùn láti mọ ohun tó yẹ kéèyàn sọ. Ṣùgbọ́n, ó yẹ káwọn òbí máa rántí pé àwọn ọ̀dọ́ máa ń rò pé táwọn ò bá ti ṣe nǹkan bó ṣe yẹ káwọn ṣe é gẹ́lẹ́, àwọn ò lè ṣàṣeyọrí nídìí ẹ̀ mọ́ nìyẹn. Tí wọ́n bá ṣàṣìṣe kékeré kan, wọ́n lè sọ ọ́ di bàbàrà táá wá di pé wọ́n á máa wo ara wọn bí ẹni tí kò lè mọ nǹkan kan ṣe láé. Tí òbí kan bá bínú jù lórí àṣìṣe kan tí ọmọ rẹ̀ ṣe, ó lè mú kí ọmọ náà gbà pé òun ò lè mọ nǹkan kan ṣe láé. Kólósè 3:21 sọ pé: “Ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má bàa soríkodò.”

Àbùmọ́ sábà máa ń wọ ọ̀rọ̀ ẹni tó bá ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ bí “ìgbà gbogbo” tàbí “láéláé.” Tí òbí kan bá sọ pé, “Ìwọ ò tiẹ̀ wúlò fún nǹkan kan,” ṣé irú ọmọ bẹ́ẹ̀ ò ní máa wo ara rẹ̀ bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan? Tí wọ́n bá ń sọ irú gbólóhùn yẹn sí ọmọ kan lemọ́lemọ́, ọmọ yẹn á bẹ̀rẹ̀ sí í wo ara rẹ̀ bí ẹni tí kò lè ṣàṣeyọrí. Ńṣe nirú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọmọ, àti pé wọn kì í ṣòótọ́.

Ohun tó sábà máa ń dáa ni pé kéèyàn tẹnu mọ́ apá ibi tó dára nínú ohun tẹ́nì kan ṣe. Ì bá dáa ká ní bàbá tá a fi ṣàpèjúwe lẹ́ẹ̀kan yẹn sọ nǹkan bíi: “Mo rí i pé inú ẹ ò dùn torí o féèlì iṣẹ́ kan. Àmọ́ ṣá o, mo mọ̀ pé o máa ń múra sí iṣẹ́ ilé tí wọ́n bá fún ẹ láti ilé ìwé. Torí náà, jẹ́ ká wo ohun tó fà á tó o fi féèlì iṣẹ́ yìí ká sì wo ohun tá a lè ṣe lórí ẹ̀.” Láti lè mọ ọ̀nà tó dáa jù lọ tí bàbá yìí lè gbà ran ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, ó lè béèrè àwọn ìbéèrè kan láti lè rí i bóyá nǹkan kan wà tó fara sin tó jẹ́ ìṣòro ọmọ náà.

Tí bàbá yẹn bá ronú dáadáa lọ́nà yìí tó sì bójú tó ọ̀rọ̀ yẹn pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, ó ṣeé ṣe kí ìyẹn ṣiṣẹ́ ju fífìbínú sọ̀rọ̀ lọ. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “àwọn àsọjáde dídùnmọ́ni . . . dùn mọ́ ọkàn, ó sì ń mú àwọn egungun lára dá.” (Òwe 16:24) Ká sòótọ́, àwọn ọmọ, àtàwọn òbí máa ń gbádùn ara wọn nínú agboolé tí àlàáfíà àti ìfẹ́ bá ti ń jọba.

‘Lára Ọ̀pọ̀ Ohun Tí Ń Bẹ Nínú Ọkàn’

Tún ronú nípa ọkọ tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Ṣó o rò pé kò ní sàn ká ní ó ti ronú dáadáa, kó wá ‘ọ̀rọ̀ tó dára’ tó sì jẹ́ òótọ́ dípò kó máa fìbínú sọ̀rọ̀ sí ìyàwó rẹ̀? Ó yẹ kí irú ọkọ bẹ́ẹ̀ bi ara rẹ̀ pé: ‘Ká tiẹ̀ ní ó yẹ kí ìyàwó mi wá nǹkan ṣe lórí bó ṣe máa ń pẹ́ kó tó múra tán, ṣóòótọ́ ni pé ìgbà gbogbo ló máa ń pẹ́ kó tó ṣe tán? Ṣé irú àsìkò yìí ló yẹ kí n dá ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀? Ṣé tí mo bá fìbínú sọ̀rọ̀ sí i báyìí, ṣó máa mú kó ṣàtúnṣe?’ Tá a bá ń bi ara wa nírú àwọn ìbéèrè yìí, a ò ní máa ṣèèṣì ṣe ohun táá máa dun àwọn èèyàn wa.—Òwe 29:11.

Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà tá a bá ń jíròrò ọ̀rọ̀ nínú ilé ló máa ń di àríyànjiyàn ńkọ́? Ó yẹ ká fojú ṣùnnùkùn wo ọ̀ràn náà, ká sì mọ àwọn ohun tó máa ń mú ká sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ tá à ń sọ. Ohun tó bá jáde lẹ́nu wa, pàápàá nígbà tí nǹkan bá ń dà wá láàmù tàbí tí ìṣòro kan bá wáyé máa ń fi irú ẹni tá a jẹ́ gan-an hàn. Jésù sọ pé: “Lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.” (Mátíù 12:34) Ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé ọ̀rọ̀ ẹnu wa máa ń fi ohun tá à ń rò nínú ọkàn wa, ohun tó wù wá àti iru èèyàn tá a jẹ́ gan-an hàn.

Ǹjẹ́ a kì í retí ohun tó pọ̀ jù látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn? Ǹjẹ́ a gbà pé ohun tó le ṣì ń bọ̀ wá dẹ̀rọ̀? Ǹjẹ́ a nírètí pé ọjọ́ ọlá ṣì ń bọ̀ wá dára? Ọ̀nà tá à ń gbà sọ̀rọ̀ àtirú ọ̀rọ̀ tá à ń sọ yóò fi hàn bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ṣé kò jọ pé a máa ń rin kinkin mọ nǹkan tá a kì í sì í gbà pé ẹni tó ṣàṣìṣe lónìí lè ṣe dáadáa lọ́la? Àbí ńṣe la kàn máa ń dá àwọn èèyàn lẹ́bi ṣáá? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ wa àti ọ̀nà tá à ń gbà sọ ọ́ yóò máa kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn èèyàn. A lè má mọ bí èrò wa àti ọ̀rọ̀ wa ṣe máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn èèyàn tó. Kódà a lè máa rò pé èrò wa ló tọ̀nà jù. Àmọ́, ó yẹ ká ṣọ́ra kó má lọ jẹ́ pé ńṣe là ń tan ara wa jẹ.—Òwe 14:12.

Aǹfààní ńlá ló jẹ́ pé a ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò èrò wa, ká mọ èyí tó dáa àtèyí tí kò dáa nínú èrò tó máa ń wá sí wa lọ́kàn, ká sì mọ eyí tó ń fẹ́ àtúnṣe. (Hébérù 4:12; Jákọ́bù 1:25) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè ti jogún àwọn ànímọ́ kan lára àwọn òbí wa tàbí kó jẹ́ pé bí wọ́n ṣe tọ́ wa dàgbà ló mú ká ní àwọn ànímọ́ ọ̀hún, gbogbo wa la lè yí ọ̀nà tá a gbà ń ronú àti ìwà tá à ń hù padà tá a bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀.—Éfésù 4:23, 24.

Láfikún sí ṣíṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa ìwà àti èrò wa, nǹkan míì wà tá a tún lè ṣe tó máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá ọ̀nà tá à ń gbà sọ̀rọ̀ dáa tàbí kò dáa. Ohun náà ni pé, kó o béèrè lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíì. Bí àpẹẹrẹ, ní kí ọkọ tàbí ìyàwó tàbí ọmọ rẹ sọ fún ẹ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ bí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe máa ń rí lára wọn. Fi ọ̀rọ̀ lọ ọ̀rẹ́ rẹ kan tó jẹ́ olóye tó sì mọ̀ ẹ́ dáadáa. Amọ́ ṣá o, ó gba pé kó o lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kó o fara mọ́ ohun tí wọ́n bá sọ kó o sì ṣàtúnṣe tó bá yẹ lórí rẹ̀.

Máa Ronú Kó O Tó Sọ̀rọ̀!

Paríparí gbogbo ẹ̀ ni pé, tá ò bá fẹ́ máa sọ ohun tí yòó máa ba àwọn èèyàn lọ́kàn jẹ́, a ní láti máa ṣe ohun tí Òwe 16:23 sọ. Ó ní: “Àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń ronú kí wọ́n tó sọ̀rọ̀; ohun tí wọ́n bá sọ sì máa ń yíni lérò padà.” (ìtumọ̀ Today’s English Version) Ó lè má rọrùn láwọn ìgbà míì láti kó ara wa níjàánu nígbà tí ọ̀rọ̀ kan bá ń dùn wá. Síbẹ̀, tá a bá ń gbìyànjú láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn máa yé wá dípò ká máa bínú sí wọn tàbí ká máa láálí wọn, kò ní fi bẹ́ẹ̀ ṣòro fún wa láti rí àwọn ọ̀rọ̀ tó tọ́ láti fi ṣàlàyé ohun tó bá wà lọ́kàn wa.

A mọ̀ pé alaìpé ni gbogbo wa. (Jákọ́bù 3:2) Láwọn ìgbà míì, a máa ń sọ̀rọ̀ láìronú. (Òwe 12:18) Àmọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a lè kọ́ béèyàn ṣe ń ronú kó tó sọ̀rọ̀, ká sì máa fi èrò àwọn ẹlòmíì àtohun tó wù wọ́n ṣáájú tiwa. (Fílípì 2:4) Ẹ jẹ́ ká pinnu láti máa wá ‘ọ̀rọ̀ tó dára’ tó sì jẹ́ òtítọ́, pàápàá nígbà tá a bá ń bá àwọn ìdílé wa sọ̀rọ̀. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní máa fi ọ̀rọ̀ ẹnu wa na àwọn èèyàn ní pàṣán, kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ wa á máa tu àwọn èèyàn lára yóò sì máa gbé wọn ró.—Róòmù 14:19.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Kí lo lè ṣe tó ò fi ní máa sọ̀rọ̀ tí wàá kábàámọ̀ rẹ̀?