Ǹjẹ́ Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Bá Bíbélì Mu?
Ǹjẹ́ Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Bá Bíbélì Mu?
ǸJẸ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹranko ni Ọlọ́run mú kó dèèyàn bí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ṣe sọ? Ṣé ńṣe ni Ọlọ́run mú kí àwọn kòkòrò tín-tìn-tín yí padà di ẹja, tí ẹja wá di ẹ̀dá afàyàfà, tí ẹ̀dá afàyàfà wá di ẹranko afọ́mọlọ́mú bí ìnàkí, tí ìnàkí sì wá dèèyàn nígbẹ̀yìn? Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn aṣáájú ìsìn kan sọ pé àwọn gba Bíbélì gbọ́, àwọn sì tún gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́. Wọ́n ní àròkọ lọ̀rọ̀ inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì tó wà nínú Bíbélì. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti rò ó pé, ‘Ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tó sọ pé ẹranko ló yí padà dèèyàn bá ohun tí Bíbélì sọ nípa ìṣẹ̀dá mu?’
Ká tó lè mọ irú ẹni tá a jẹ́, ibi tá a ń lọ àti bó ṣe yẹ ká máa gbé ìgbésí ayé wa, a ní láti kọ́kọ́ mọ bá a ṣe dáyé. Ìgbà tá a bá mọ béèyàn ṣe dáyé la tó lè mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà àtohun tó máa ṣe fáráyé lọ́jọ́ iwájú. A ò lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run tí ò bá dá wa lójú pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa béèyàn ṣe dáyé, ipò táwa èèyàn wà nísinsìnyí àti bí nǹkan ṣe máa rí fún wa lọ́jọ́ iwájú. Ìyẹn á jẹ́ ká lè rí i bóyá ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n bá ẹ̀kọ́ Bíbélì mu tàbí kò bá a mu.
Ìgbà Tí Ọkùnrin Kan Ṣoṣo Wà
Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n ò gbà pé ìgbà kan wá tó jẹ́ pé ọkùnrin kan ṣoṣo ló wà láyé. Wọ́n ní àwọn ẹranko púpọ̀ ló ń yí padà díẹ̀díẹ̀ tí wọ́n wá di àwùjọ èèyàn. Àmọ́ kì í ṣe ohun tí Bíbélì sọ nìyẹn. Ohun tí Bíbélì sọ ni pé ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan, ìyẹn Ádámù, la ti ṣẹ̀ wá. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni gidi kan tó gbé ayé rí ni Ádámù. Ó sọ orúkọ ìyàwó rẹ̀ àti orúkọ díẹ̀ lára àwọn ọmọ rẹ̀. Bíbélì ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ohun tó ṣe, ohun tó sọ, ìgbà tó gbélé ayé àtìgbà tó kú. Jésù ò fojú wo àkọsílẹ̀ yìí bí ìtàn tó wà fáwọn púrúǹtù. Nígbà tó ń bá àwọn aṣáájú ìsìn tí wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀wé sọ̀rọ̀, ó ní: “Ẹ kò ha kà pé ẹni tí ó dá wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo?” (Mátíù 19:3-5) Lẹ́yìn náà, Jésù wá fa ọ̀rọ̀ nípa Ádámù àti Éfà tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:24 yọ.
Lúùkù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì, tó sì tún jẹ́ òpìtàn tó ń ṣèwádìí jinlẹ̀, fi hàn pé ẹni gidi kan bíi ti Jésù ni Ádámù jẹ́. Lúùkù tọpa ìlà ìdílé Jésù padà sọ́dọ̀ Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́. (Lúùkù 3:23-38) Bákan náà, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń bá àwùjọ èèyàn kan sọ̀rọ̀, táwọn kan nínú wọn jẹ́ ọ̀mọ̀ràn tó kàwé láwọn ilé ẹ̀kọ́ olókìkí tó wà nílẹ̀ Gíríìsì, ó sọ fún wọn pé: “Ọlọ́run tí ó dá ayé àti gbogbo nǹkan tí ó wà nínú rẹ̀. Òun ni ó dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti inú ẹni kan ṣoṣo láti máa gbé gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 17:24-26, Ìròhìn Ayọ̀) Dájúdájú, ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ni pé ọ̀dọ̀ “ẹni kan ṣoṣo” ni gbogbo wa ti ṣẹ̀ wá. Ǹjẹ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa ipò téèyàn wà nígbà tí Ọlọ́run dá èèyàn bá ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n mu?
Béèyàn Ṣe Di Aláìpé
Bíbélì sọ pé pípé ni Jèhófà dá ọkùnrin àkọ́kọ́. Ọlọ́run kò ní dá ohun tó jẹ́ aláìpé láéláé. Àkọsílẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 31) Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ ẹni pípé?
nípa ìṣẹ̀dá sọ pé: “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀ . . . Lẹ́yìn ìyẹn, Ọlọ́run rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an ni.” (Ẹni pípé lómìnira láti pinnu ohun tó bá fẹ́, ó sì lè fìwà jọ Ọlọ́run pátápátá. Bíbélì ní: “Ọlọ́run tòótọ́ ṣe aráyé ní adúróṣánṣán, ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn ti ṣàwárí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwéwèé.” (Oníwàásù 7:29) Ádámù mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Àìgbọràn rẹ̀ yìí ló sọ ọ́ di aláìpé, ó sì kó àìpé yìí ran àwọn àtọ̀mọdọ́mọ rẹ̀. Béèyàn ṣe di aláìpé yìí jẹ́ ká rídìí tá a fi máa ń ṣe àwọn nǹkan tó ń tì wá lójú nígbà míì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tó tọ́ là ń fẹ́ ṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ohun tí mo ń fẹ́, èyí ni èmi kò fi ṣe ìwà hù; ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìíra ni èmi ń ṣe.”—Róòmù 7:15.
Bíbélì sọ pé ńṣe ni Ọlọ́run dá èèyàn ní pípé, kó máa gbé lọ títí láé lórí ilẹ̀ ayé, kó sì ní ìlera pípé. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ fún Ádámù jẹ́ ká mọ̀ pé ì bá máà kú ká ní kò ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 3:22, 23) Ká sọ pé ẹni tó lè ṣàìsàn tàbí ẹni tó lè ṣọ̀tẹ̀ lèèyàn, Jèhófà ì bá má ti sọ pé “dáradára” lèèyàn nígbà tó dá a. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run dá ara wa lọ́nà ìyanu, aláìpé téèyàn dà ló fà á tá a fi ń lábùkù lára, tá a sì ń ṣàìsàn. Nítorí náà, ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n kò bá Bíbélì mu. Ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n sọ pé ẹranko tí ìdàgbàsókè ṣì ń bá lẹ̀dá èèyàn. Àmọ́, ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ni pé ńṣe layé ń bà jẹ́ fáwa èèyàn tó jẹ́ àtọ̀mọdọ́mọ ọkùnrin pípé tá a fi wà nípò tá a wà yìí.
Ọ̀rọ̀ táwọn kan sọ pé ìlànà ẹfolúṣọ̀n ni Ọlọ́run lò láti fi mú kèèyàn wà kò bá ohun tí Bíbélì sọ nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ mu. Tó bá jẹ́ pé ìlànà ẹfolúṣọ̀n ni Ọlọ́run lò láti fi mú kèèyàn wà, a jẹ́ pé òun ló sọ aráyé daláìsàn, òun ló sì kó wọn sínú wàhálà tí wọ́n wà báyìí. Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run ni pé: “Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; olódodo àti adúróṣánṣán ni. Wọ́n ti gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun níhà ọ̀dọ̀ àwọn fúnra wọn; wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀, àbùkù náà jẹ́ tiwọn.” (Diutarónómì 32:4, 5) Nítorí náà, ìyà tó ń jẹ aráyé báyìí kì í ṣe torí pé Ọlọ́run lo ìlànà ẹfolúṣọ́n láti fi mú kí wọ́n wà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ nítorí pé ọkùnrin kan ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run tó sì tipa bẹ́ẹ̀ di aláìpé, tó sì tún wá kó àìpé ran àwọn àtọ̀mọdọ́mọ rẹ̀. Ní báyìí tá a ti sọ̀rọ̀ lórí Ádámù, ẹ jẹ́ ká wá sọ ti Jésù. Ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n bá ohun tí Bíbélì sọ nípa Jésù mu?
Ṣé O lè Gba Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n àti Ẹ̀kọ́ Kristẹni Gbọ́ Lẹ́sẹ̀ Kan Náà?
Ó ṣeé ṣe kó o mọ̀ pé ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ẹ̀kọ́ tí ìsìn Kristẹni fi kọ́ni ni pé, “Kristi kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa.” (1 Kọ́ríńtì 15:3; 1 Pétérù 3:18) Ká tó lè mọ̀ pé ẹ̀kọ́ efolúṣọ̀n kò bá ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí mu, a ní láti kọ́kọ́ mọ ìdí tí Bíbélì fi sọ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá ká sì tún mọ àkóbá tí ẹ̀ṣẹ̀ ti ṣe fún wa.
Róòmù 3:23) Bíbélì kọ́ni pé ẹ̀ṣẹ̀ ló fa ikú. Kọ́ríńtì Kìíní orí kẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ẹsẹ kẹrìndínlọ́gọ́ta sọ pé: “Ìtani tí ń mú ikú jáde ni ẹ̀ṣẹ̀.” Ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti jogún yìí gan-an ló fà á tá a fi ń ṣàìsàn. Jésù náà sì fi hàn pé ẹ̀ṣẹ̀ ló fa àìsàn. Ó sọ fún alárùn ẹ̀gbà kan pé, “a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì,” ara ọkùnrin náà sì yá.—Mátíù 9:2-7.
Níwọ́n bí kò ti lè ṣeé ṣe fún wa láti láwọn ànímọ́ Ọlọ́run lọ́nà tó pé pérépéré, ìyẹn àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo, ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Ọ̀nà wo ni ikú Jésù gbà ṣàǹfààní fún wa? Bíbélì jẹ́ ká mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárìn Jésù Kristi àti Ádámù, ó ní: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí gbogbo ènìyàn ti ń kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni a ó sọ gbogbo ènìyàn di ààyè nínú Kristi.” (1 Kọ́ríńtì 15:22) Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ rà wá padà lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún lọ́dọ̀ Ádámù. Nítorí náà, gbogbo àwọn tó bá gba Jésù gbọ́ tí wọ́n sì ṣègbọràn sí i yóò jèrè ohun tí Ádámù pàdánù, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòhánù 3:16; Róòmù 6:23.
Ǹjẹ́ o wá rí i báyìí pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n kò bá ẹ̀kọ́ Kristẹni mu? Tá ò bá gbà pé “gbogbo ènìyàn . . . ń kú nínú Ádámù,” ǹjẹ́ a lè nírètí pé “a ó sọ gbogbo ènìyàn di ààyè nínú Kristi”?
Ìdí Táwọn Èèyàn Fi Nífẹ̀ẹ́ sí Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n
Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdí tí ẹ̀kọ́ efolúṣọ̀n fi gbilẹ̀. Ó ní: “Sáà àkókò kan yóò wà, tí wọn kò ní gba ẹ̀kọ́ afúnni-nílera, ṣùgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn, wọn yóò kó àwọn olùkọ́ jọ fún ara wọn láti máa rìn wọ́n ní etí; wọn yóò sì yí etí wọn kúrò nínú òtítọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé a óò mú wọn yà sínú ìtàn èké.” (2 Tímótì 4:3, 4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlànà sáyẹ́ǹsì ni wọ́n fi ń ṣàlàyé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, síbẹ̀ ẹ̀kọ́ ìsìn ni. Ìdí ni pé ó kọ́ni ní ojú tó yẹ kéèyàn máa fi wo ìgbésí ayé àti ìhà tó yẹ ká kọ sí Ọlọ́run. Ohun tó sì mú kí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n fa àwọn èèyàn mọ́ra ni pé, èèyàn lẹ́mìí ìmọtara-ẹni-nìkan, ó sì máa ń fẹ́ dá wà lómìnira. Ọ̀pọ̀ àwọn tó gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́ tún sọ pé àwọn nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Síbẹ̀, wọn ò ká Ọlọ́run sí Ẹlẹ́dàá, wọn ò gbà pé ohun tá a bá ṣe kàn án, wọn ò sì rò pé o máa ṣe ìdájọ́ àwa èèyàn. Irú ohun tọ́mọ aráyé sì máa ń fẹ́ gbọ́ gan-an nìyẹn.
Kì í ṣe torí pé àwọn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n ní ẹ̀rí láti fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn ni wọ́n ṣe fi ń kọ́ àwọn èèyàn, àmọ́ ó jẹ́ torí “ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn,” ìyẹn ìfẹ́ ọkàn pé kí wọ́n lè tẹ́wọ́ gbà wọ́n lágbo àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì níbi tí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ti jẹ́ ẹ̀kọ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn tẹ́wọ́ gbà. Ọ̀jọ̀gbọ́n Micheal Behe tó ní ìmọ̀ gan-an nípa ìṣesí èròjà inú ohun alààyè, tó sì ti lo èyí tó pọ̀ jù ní ìgbésí ayé rẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun tín-tìn-tín tó ń ṣiṣẹ́ nínú ara ṣàlàyé pé, àwọn tó ń fi ìlànà ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ṣàlàyé ìgbékalẹ̀ àwọn ohun tín-tìn-tín tó wà nínú ara kò ní ìpìlẹ̀ tó ṣe gúnmọ́ fún ohun tí wọ́n ń sọ. Ǹjẹ́ ìlànà ẹfolúṣọ̀n lè ṣiṣẹ́ nínú àwọn ohun alààyè tín-tìn-tín yìí? Behe ní: “Ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tó dá lórí àwọn ohun alààyè tín-tìn-tín yìí kò bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu. Kò sí ìwé kankan táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún, ìwé tí wọ́n dìídì ṣe lákànṣe tàbí ìwé èyíkéyìí tó jẹ́ ìwé sáyẹ́ńsì tó fi ìlànà ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ṣàlàyé báwọn ohun tín-tìn-tín tó wà nínú ohun alàyè ṣe wáyé tàbí bó ṣe yẹ kó wáyé. . . . Ńṣe ni Darwin kàn gbé èrò tara rẹ̀ kalẹ̀ nígbà tó fi ìlànà ẹfolúṣọ̀n ṣàlàyé báwọn ohun tín-tìn-tín tó wà nínú ohun alàyè ṣe wáyé.”
Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni wọn ò lè fi ẹ̀rí ti ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n lẹ́yìn, kí wá nìdí tí wọ́n fi ń pariwo rẹ̀? Behe ní: “Ìdí rẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn, títí kan àwọn gbajúmọ̀ àtàwọn tí wọ́n ń bọ̀wọ̀ fún lágbo àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, kò tiẹ̀ fẹ́ gbà rárá pé ẹni alágbára kan wà tó ṣẹ̀dá àwọn nǹkan.”
Ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n fa àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì náà mọ́ra nítorí wọ́n fẹ́ káwọn èèyàn máa wo àwọn bí ọ̀jọ̀gbọ́n. Wọ́n fìwà jọ àwọn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ohun tí a lè mọ̀ nípa Ọlọ́run fara hàn kedere láàárín wọn . . . Àwọn ànímọ́ Róòmù 1:19-22) Kí lo lè ṣe káwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ èké yìí má tàn ẹ́ jẹ?
rẹ̀ tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní àwíjàre; nítorí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ Ọlọ́run, wọn kò yìn ín lógo gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n di olórí òfìfo nínú èrò wọn, ọkàn-àyà wọn tí kò mòye sì di èyí tí ó ṣókùnkùn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń tẹnu mọ́ ọn pé àwọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n, wọ́n ya òmùgọ̀.” (Ẹ̀rí Tó Ti Ìgbàgbọ́ Nínú Ẹlẹ́dàá Lẹ́yìn
Bí Bíbélì ṣe ṣàlàyé ohun tí ìgbàgbọ́ jẹ́ fi hàn pé ó ṣe pàtàkì ká máa fi ẹ̀rí ti ọ̀rọ̀ lẹ́yìn. Ó sọ pé: “Ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” (Hébérù 11:1) Ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ní láti dá lórí ẹ̀rí tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wà. Bíbélì sì sọ ibi tá a ti lè rí ẹ̀rí náà.
Dáfídì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí Ọlọ́run mí sí láti kọ Bíbélì kọ̀wé pé: “Èmi yóò gbé ọ lárugẹ, nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu.” (Sáàmù 139:14) Tá a bá ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà ìyanu tí Ọlọ́run gbà dá ara àwa èèyàn àtàwọn ẹ̀dá alaàyè yòókù, a ó gbà pé àgbàyanu ni ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá wa. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ohun tó ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ ká lè wà láàyè ni Ọlọ́run fi ọgbọ́n ṣe. Bákan náà, ayé, òòrùn, òṣùpá, àtàwọn ìràwọ̀ wà lójú ibi tó yẹ kí wọ́n wà gẹ́lẹ́, wọ́n sì wà létòlétò. Ìyẹn ni Dáfídì fi kọ̀wé pé: “Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run; òfuurufú sì ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.”—Sáàmù 19:1.
Inú Bíbélì gan-an lèèyàn ti lè mọ ohun púpọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá. Tó o bá fara balẹ̀ wo báwọn ìwé inú Bíbélì tí gbogbo rẹ̀ jẹ́ mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] ṣe bára mu, báwọn ìlànà ìwà rere tó wà nínú rẹ̀ kò ṣe láfiwé, àti báwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ ṣe ń ní ìmúṣẹ, wàá rí ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó fi hàn pé ìwé Ẹlẹ́dàá ni. Tó o bá sì wá lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì, èyí á tún fún ẹ ní ìdánilójú pé Ọ̀rọ̀ Ẹlẹ́dàá ni Bíbélì jẹ́ lóòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá lóye ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa ohun tó fà á tá a fi ń jìyà, ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́, bí ọjọ́ ọ̀la ìran èèyàn ṣe máa rí àti bó o ṣe lè láyọ̀, wàá rí bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó. Ìwọ náà á lè ní irú èrò tí Pọ́ọ̀lù ní nígbà tó kọ̀wé pé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o! Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó, àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì ré kọjá àwákàn!”—Róòmù 11:33.
Bó o ti ń ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí wọ̀nyí tí ìgbàgbọ́ rẹ sì túbọ̀ ń lágbára sí i, á dá ọ lójú pé tó o bá ka Bíbélì, Ẹlẹ́dàá fúnra rẹ̀ ló ń bá ọ sọ̀rọ̀. Ọlọ́run sọ pé: “Èmi fúnra mi ni mo ṣe ilẹ̀ ayé tí mo sì dá ènìyàn pàápàá sórí rẹ̀. Èmi—ọwọ́ mi ni ó na ọ̀run, gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ni mo sì ti pàṣẹ fún.” (Aísáyà 45:12) Dájúdájú o ò ní kábàámọ̀ láé pé o sa gbogbo ipá rẹ láti dẹni tó mọ̀ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]
Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ọ̀mọ̀ràn nílẹ̀ Gíríìsì pé: “Ọlọ́run . . . dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti inú ẹni kan ṣoṣo láti máa gbé gbogbo ilẹ̀ ayé”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 15]
Ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n sọ pé ẹranko tí ìdàgbàsókè ṣì ń bá lèèyàn. Àmọ́ Bíbélì fi kọ́ni pé ńṣe layé ń bà jẹ́ fáwa èèyàn tó jẹ́ àtọ̀mọdọ́mọ ọkùnrin pípé tá a fi wà nípò tá a wà yìí
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 16]
“Ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tó dá lórí àwọn ohun alààyè tín-tìn-tín kò bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 17]
Ọ̀nà ìyanu tí Ọlọ́run gbà dá àwọn ẹ̀dá alààyè jẹ́ ká gbà pé àgbàyanu ni ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá wa