Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Sí Ẹ̀yin Òǹkàwé Wa

Sí Ẹ̀yin Òǹkàwé Wa

Sí Ẹ̀yin Òǹkàwé Wa

INÚ wa dùn láti sọ fún yín pé a óò ṣe àwọn àyípadà kan sí ọ̀nà tá à ń gbà tẹ Ilé Ìṣọ́. Inú ìtẹ̀jáde yìí la sì ti máa bẹ̀rẹ̀. Ká tó ṣàlàyé àwọn ohun tó máa yí padà, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ àwọn ohun tí kò ní yí padà.

Orúkọ ìwé ìròyìn yìí ò ní yí padà, Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà ni yóò ṣì máa jẹ́. Fún ìdí yìí, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yóò ṣì máa bọlá fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tòótọ́, yóò sì tún máa fi ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tu àwọn èèyàn nínú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 5 sí 9 nínú ìtẹ̀jáde yìí sọ ohun tí Ìjọba náà jẹ́ àti ìgbà tí yóò dé. Ilé Ìṣọ́ yóò tún máa bá a lọ láti mú kí ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn lágbára sí i nínú Jésù Kristi. Yóò máa gbé ohun tí Bíbélì fi kọ́ni jáde, yóò sì máa ṣàlàyé báwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ṣe ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ, ó sì ti ju ọgọ́rùn-ún ọdún lọ báyìí tó ti ń ṣe gbogbo ohun tá a sọ yìí.

Àwọn àyípadà wo ló máa wáyé? Ẹ jẹ́ ká sọ nípa díẹ̀ lára àwọn ohun tuntun alárinrin tí yóò máa jáde nínú ẹ̀dà àkọ́kọ́ nínú oṣù kọ̀ọ̀kan. a

Oṣooṣù la óò máa gbé àwọn àpilẹ̀kọ tó ń múni ronú jinlẹ̀ jáde. Abala tá a pè ní “Ǹjẹ́ O Mọ̀?” yóò máa sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ìtàn inú Bíbélì tó máa mú ká túbọ̀ lóye àwọn ìtàn náà dáadáa. Abala tó ń jẹ́ “Sún Mọ́ Ọlọ́run” yóò máa gbé àwọn ohun tá a lè kọ́ nípa Jèhófà yọ látinú àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a bá yàn. Abala “Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé” yóò máa dáhùn àwọn ìbéèrè táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè látinú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ èèyàn ti béèrè pé, “Ṣé inú ọkàn èèyàn ni Ìjọba Ọlọ́run wà?” Wàá rí ìdáhùn rẹ̀ ní ojú ìwé 13.

Ìwé ìròyìn yìí yóò máa gbé àwọn abala kan jáde tí yóò ṣe àwọn ìdílé láǹfààní. Abala tó sọ pé “Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀” yóò máa jáde lẹ́ẹ̀mẹrin lọ́dún. Yóò máa sọ àwọn ìṣòro tó máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé yóò sì máa ṣàlàyé bí ìlànà Bíbélì á ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú wọn. Abala kan wà tó dáa káwọn òbí máa kà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, a pè é ní “Kọ́ Ọmọ Rẹ,” yóò sì máa jáde lẹ́ẹ̀kan lóṣù méjì. Òmíràn tí yóò tún máa jáde lẹ́ẹ̀kan lóṣù méjì, láwọn oṣù tí “Kọ́ Ọmọ Rẹ” kò bá jáde, ni “Abala Àwọn Ọ̀dọ́,” tó ṣàlàyé àwọn ọ̀nà táwọn ọ̀dọ́ lè gbà máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Àwọn abala kan tún wà tí yóò máa jáde lẹ́ẹ̀mẹrin lọ́dún. Èyí tá a pè ní “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn” yóò máa sọ bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹnì kan tí ìtàn rẹ̀ wà nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, lójú ìwé 18 sí 21 nínú ìtẹ̀jáde yìí, wàá ka ìtàn amóríyá kan nípa wòlíì Èlíjà, wàá sì mọ bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ rẹ̀. Abala tá a pè ní “Lẹ́tà Kan Látọ̀dọ̀ . . . “ yóò máa gbé ìròyìn jáde látẹnu àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn mìíràn láti ibi gbogbo lágbàáyé. Abala tá a pè ní “Ohun Tá A Kọ́ Lára Jésù” yóò máa gbé àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì jáde lọ́nà tó máa rọrùn láti yéni.

A ní ìgbọ́kànlé pé ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ á ṣì máa fa ẹ̀yin òǹkàwé wa mọ́ra, ìyẹn ẹ̀yin tẹ́ ẹ fọwọ́ pàtàkì mú Bíbélì tẹ́ ẹ sì ń fẹ́ láti mọ ohun tó fi kọ́ni gan-an. A nírètí pé ìwé ìròyìn yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì dáadáa.

ÀWA ÒǸṢÈWÉ

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Oríṣi ẹ̀dà méjì ni Ilé Ìṣọ́ tí yóò máa jáde báyìí. Èyí tí déètì rẹ̀ á máa jẹ́ ọjọ́ kìíní oṣù ló máa wà fún kíkà gbogbo èèyàn. Èyí tí déètì rẹ̀ á máa jẹ́ ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù sì ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò máa lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ìpàdé ìjọ wa, èyí tá a pe gbogbo èèyàn sí.