Bá A Ṣe Lè Yanjú Èdèkòyédè
Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀
Bá A Ṣe Lè Yanjú Èdèkòyédè
Ọkọ sọ pé: “Lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó, ilé àwọn òbí mi lèmi àtìyàwó mi ń gbé. Lọ́jọ́ kan ọmọbìnrin tí àbúrò mi ń fẹ́ sọ pé kí n fi mọ́tò wa gbé òun délé. Mo gbé e lọ, mo sì mú ọmọ mi ọkùnrin dání. Àmọ́ nígbà tí mo padà délé, ńṣe ni ìyàwó mi gbaná jẹ. A bẹ̀rẹ̀ sí í jiyàn, ojú àwọn èèyàn mi níbẹ̀ ló sì ti pè mí ní balógun lẹ́yìn obìnrin. Orí mi gbóná, lèmi náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ gbá a lórí.”
Ìyàwó sọ pé: “Àìsàn kan ń da ọmọ wa láàmú, kò sì fi bẹ́ẹ̀ sówó lọ́wọ́ wa lásìkò yẹn. Bí mo ṣe wá rí i tí ọkọ mi àti àfẹ́sọ́nà àbúrò rẹ̀ wọnú ọkọ̀ tó sì mú ọmọ wa dání báyìí, inú bí mi nítorí àwọn ìdí kan. Nígbà tí ọkọ mi padà dé, mo sọ ohun tó wà lọ́kàn mi fún un. Bá a ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í fa ọ̀rọ̀ náà nìyẹn tá a sì ń pe ara wa ní oríṣiríṣi orúkọ. Lẹ́yìn tá a ti fa ọ̀rọ̀ náà tán, inú mi bà jẹ́ gidigidi.”
TÍ ÀRÍYÀNJIYÀN bá wáyé láàárín ọkọ àti aya, ṣó fi hàn pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ ara wọn ni? Rárá o! Tọkọtaya tá a sọ̀rọ̀ wọn lókè yìí nífẹ̀ẹ́ ara wọn gan-an ni. Síbẹ̀, kò sí bí àárín tọkọtaya kan ṣe lè dùn tó tí kò ní máa sí èdèkòyédè lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.
Kí nìdí tí èdèkòyédè fi máa ń wáyé láàárín tọkọtaya, kí lo sì lè ṣe tí kò fi ní tú ìgbéyàwó rẹ ká? Níwọ̀n bó ti jẹ pé Ọlọ́rún ló dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀, ohun tó mọ́gbọ́n dání ni pé ká ṣàyẹ̀wò nǹkan tí Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí.—Jẹ́nẹ́sísì 2:21, 22; 2 Tímótì 3:16, 17.
Àwọn Ohun Tó Ń Fa Ìṣòro
Ṣàṣà ni tọkọtaya tí kò wù pé kí wọ́n máa fi ìfẹ́ bá ara wọn lò kí wọ́n sì máa ṣe dáadáa sí ara wọn. Àmọ́ Bíbélì sọ ohun kan tó jóòótọ́ pé “gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Nítorí náà, tí èdèkòyédè bá ṣẹlẹ̀, ó lè ṣòro fún èèyàn láti ṣàkóso ara rẹ̀. Tó bá sì ṣẹlẹ̀ pé àríyànjiyàn wáyé láàárín tọkọtaya, ó lè ṣòro fún wọn láti kó ara wọn níjàánu, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣohun tí kò yẹ kí wọ́n ṣe, bíi kí wọ́n máa pariwo lé ara wọn lórí tàbí kí wọ́n máa rọ̀jò èébú lé ara wọn lórí. (Róòmù 7:21; Éfésù 4:31) Kí làwọn nǹkan míì tó tún lè dá họ́wùhọ́wù sílẹ̀?
Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé ọ̀nà tí ọkọ ataya ń gbà sọ̀rọ̀ máa ń yàtọ̀ síra. Michiko* sọ pé: “Mo kíyè sí i pé ọ̀nà táwa méjèèjì máa ń fẹ́ gbà jíròrò ọ̀rọ̀ yàtọ̀ síra. Èmi máa ń fẹ́ ká jíròrò ohun tó ṣẹlẹ̀, ìdí tó fi ṣẹlẹ̀ àti ọ̀nà tó gbà ṣẹlẹ̀. Àmọ́, ó dà bíi pé ibi tọ́rọ̀ yẹn parí sí ló ṣe pàtàkì lójú ọkọ mi ní tiẹ̀.”
Ìṣòro Michiko yẹn kì í ṣohun tuntun. Irú ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ láàárín ọ̀pọ̀ tọkọtaya, tó jẹ́ pé ẹnì kan lè fẹ́ kí wọ́n jíròrò kúlẹ̀kúlẹ̀ èdèkòyédè tó wáyé, tẹ́nì kejì sì lè fẹ́ káwọn gbàgbé ọ̀rọ̀ yẹn káwọn má bàa tún jiyàn mọ́. Nígbà míì, ó máa ń ṣẹlẹ̀ pé bí ẹnì kan bá ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ yẹn ńṣe ni ẹnì kejì á máa wá bí wọ́n á ṣe fọ̀rọ̀ bò ó mọ́lẹ̀. Ṣéwọ náà ti kíyè sí i pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti fẹ́ máa ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó yín? Ṣé ó máa ń ṣẹlẹ̀ pé kí ọ̀kan nínú yín fẹ́ kẹ́ ẹ jíròrò kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ kan àmọ́ tẹ́nì kejì kì í fẹ́ kẹ́ ẹ fa ọ̀rọ̀ náà gùn?
Ohun míì tó tún yẹ ká gbé yẹ̀wò ni pé bí wọ́n ṣe ń ṣe nínú ìdílé tí wọ́n ti tọ́ olúkúlùkù wa lè ti nípa lórí bá a ṣe rò pé ó yẹ kí tọkọtaya máa bá ara wọn sọ̀rọ̀. Justin tó ti gbéyàwó láti ọdún márùn-ún sẹ́yìn sọ pé: “Nílé tiwa kálukú máa ń lọ nílọ tiẹ̀ ni, èyí ló sì mú kó ṣòro fún mi láti máa sọ ohun tó wà lọ́kàn mi jáde. Ó máa ń dun ìyàwó mi gan-an torí pé nínú ilé tiwọn, bí wọ́n ṣe kọ́ wọn ni pé kí wọ́n máa sọ ohun tó bá wà lọ́kàn wọn. Kì í sì í ṣòro fún un láti jẹ́ kí n mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀.”
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kẹ́ Ẹ Pawọ́ Pọ̀ Yanjú Ìṣòro?
Àwọn tó ti ṣèwádìí nípa ìgbéyàwó ti rí i pé téèyàn bá fẹ́ mọ bí tọkọtayọ kan ṣe láyọ̀ tó, kéèyàn má wo bí tọkọtaya yẹn ṣe máa ń sọ lemọ́lemọ́ tó pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Kéèyàn má sì wo báwọn méjèèjì á ṣe lè tẹ́ ara wọn lọ́rùn tó lórí ọ̀ràn ìbálòpọ̀ tàbí bí wọ́n ṣe lówó tó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun téèyàn lè fi mọ bí ìgbéyàwó ṣe láyọ̀ tó ni bí tọkọtaya kan ṣe máa ń yanjú èdèkòyédè tó bá wáyé.
Láfikún sí i, Jésù sọ pé táwọn méjì bá ti ṣègbéyàwó, kì í ṣe èèyàn ló so wọ́n pọ̀ bí kò ṣe Ọlọ́run. (Mátíù 19:4-6) Torí náà tí àárín tọkọtaya bá gún régé, Ọlọ́run ni ìgbéyàwó wọn ń fìyìn fún. Àmọ́, tí ọkọ kan kò bá fi ìfẹ́ àti ìgbatẹnirò bá aya rẹ̀ lò, ìyẹn lè dènà àdúrà rẹ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run. (1 Pétérù 3:7) Bí ìyàwó náà kò bá bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀, Jèhófà tó fi ọkọ yẹn ṣe olórí ìdílé ni kò bọ̀wọ̀ fún.—1 Kọ́ríńtì 11:3.
Tẹ́ Ẹ Bá Fẹ́ Láyọ̀, Ẹ Má Máa Sọ Kòbákùngbé Ọ̀rọ̀ Síra Yín
Láìfi bó o ṣe mọ ọ̀rọ̀ gbé kalẹ̀ pè tàbí inú ìdílé tí wọ́n ti tọ́ ẹ dàgbà, àwọn ọ̀rọ̀ kan wà tí kò yẹ kó máa jáde lẹ́nu rẹ. Ìyẹn ló máa fi hàn pé ò ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, o sì fẹ́ kí èdèkòyédè máa yanjú ní ìtùnbí-ìnùbí. Bi ara rẹ láwọn ìbéèrè yìí:
▪ ‘Ṣé mo máa ń kó ara mi níjàánu nígbà tó bá ṣe mí bíi pé kí n fìbìnú dá a lóhùn padà?’ Òwé ọlọ́gbọ́n kan sọ pé: “Fífún imú pọ̀ sì ni ohun tí ń mú ẹ̀jẹ̀ jáde, fífún ìbínú jáde sì ni ohun tí ń mú aáwọ̀ jáde.” (Òwe 30:33) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Wo àpẹẹrẹ kan. Ó lè jẹ́ pé ńṣe lẹ kàn ní èrò tó yàtọ̀ síra nígbà tẹ́ ẹ̀ ń jíròrò bó ṣe yẹ kẹ́ ẹ máa bójú tó ọ̀ràn ìnáwó inú ilé. Kẹ́ ẹ tó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ẹ lè ti bẹ̀rẹ̀ sí í bú ara yín. Ó lè jẹ́ pé bẹ́ ẹ ṣe bẹ̀rẹ̀ ni pé “ó mà yẹ ká máa kíyè sí owó tá à ń ná lórí fóònù alágbèéká,” lẹnì kan nínú yín bá sọ fún ẹnì kejì pé “o tí máa ń náwó ní ìná àpà jù.” Lóòótọ́, tí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ bá ‘fún ẹ nímú’ nípa sísọ ọ̀rọ̀ tí kò bá ẹ lára mu sí ọ, ó lè ṣe ìwọ náà bíi kó o ‘fún un nímú’ padà lójú ẹsẹ̀. Àmọ́ aforóyaró kì í jẹ́ kí oró tán ńlẹ̀, ṣe ni èdèkòyédè yẹn á di ńlá.
Jákọ́bù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Wò ó! Bí iná tí a fi ń dáná ran igbó igi tí ó tóbi gan-an ti kéré tó! Tóò, ahọ́n jẹ́ iná.” (Jákọ́bù 3:5, 6) Tí tọkọtaya ò bá ṣọ́ ahọ́n wọn, àríyànjiyàn kékeré lè di èdèkòyédè ńlá táwọn méjèèjì á sì gbaná jẹ. Tí tọkọ́taya kan bá ń gbé e gbóná fún ara wọn lemọ́lemọ́ báyìí, kò sí bí iná ìfẹ́ tó wà láàárín wọn ò ṣe ní jó rẹ̀yìn.
Dípò tí wàá fi dá a padà bó ṣe gbé e wá fún ẹ, ṣé kò ní dáa tó o bá fara wé Jésù tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n ń kẹ́gàn rẹ̀, “kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà”? (1 Pétérù 2:23) Ọ̀nà tó o lè tètè gbà paná èdèkòyédè ni pé kó o gbà pé ọ̀rọ̀ gidi ni ọkọ tàbí ìyàwó rẹ ń sọ, kó o sì ní kó dárí jì ẹ́ torí ohun tó o ṣe tí ọ̀rọ̀ náà fi di ńlá.
OHUN TÓ O LÈ ṢE: Tí àìgbọ́ra-ẹni-yé bá tún ti ṣẹlẹ̀, bi ara rẹ pé: ‘Ìpalára wo ló máa ṣe fún mi tí mo bá gbà pé ọkọ mi tàbí ìyàwó mi lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ohun tó ṣe yẹn? Ǹjẹ́ nǹkan wà témi náà ṣe tó dá kún wàhálà yìí? Kí ló dé tí mi ò lè tọrọ àforíjì fún àṣìṣe tí mo ṣe?’
▪ ‘Ṣé mo máa ń fojú kéré ọ̀rọ̀ tó ń dun ìyàwó mi tàbí ọkọ mi?’ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pàṣẹ pé: “Gbogbo yín ẹ jẹ́ onínú kan náà, kí ẹ máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn.” (1 Pétérù 3:8) Ṣàgbéyẹ̀wò ìdí méjì tó lè mú kó ṣòro fún ọ láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí. Àkọ́kọ́, ó lè jẹ́ pé o ò lè fòye mọ ohun tó wà lọ́kàn ọkọ tàbí ìyàwó rẹ. Bí àpẹẹrẹ, ká ní ọ̀ràn kan ká ìyàwó rẹ lára ju ìwọ lọ, ó lè ṣe ọ́ bíi kó o sọ pé, “O ti gbé ọ̀rọ̀ yìí karí ju bó ṣe yẹ lọ.” Bóyá ohun tíwọ fẹ́ ṣe ni pé kó o ràn án lọ́wọ́ láti má ṣe jẹ́ kó gbé ìṣòro yẹn karí ju bó ṣe yẹ. Àmọ́ ṣàṣà lẹni téèyàn á sọ irú gbólóhùn yẹn sí táá tù ú lára. Àtọkọ àtaya ló yẹ kó máa ṣohun tí ẹnì kejì rẹ̀ á fi mọ̀ pé olólùfẹ́ òun lóye ọ̀rọ̀ òun, ó sì máa ń bá òun kẹ́dùn.
Èkejì, tẹ́nì kan bá ní ìgbéraga, ó lè mú kó máa fojú téńbẹ́lú ohun tó wà lọ́kàn ọkọ tàbí ìyàwó rẹ̀. Agbéraga máa ń fẹ́ ṣe bí ẹni pé òun lòun ṣe pàtàkì jù, á wá máa ṣe ohun tó máa mú kẹ́nì kejì dà bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan. Ó lè máa pè é ní orúkọ tí kò dáa tàbí kó máa fi wé ohun tí kò dáa. Wo àpẹẹrẹ àwọn Farisí àtàwọn akọ̀wé ìgbà ayé Jésù. Tẹ́nì kan bá ti sọ ohun tó yàtọ̀ sí èrò wọn báyìí, kódà kí onítọ̀hùn jẹ́ Farisi bíi tiwọn, ńṣe làwọn agbéraga ẹ̀dá yìí máa ń pe irú ẹni bẹ́ẹ̀ lórúkọ burúkú, wọ́n á sì máa sọ ohun tí kò dáa nípa rẹ̀. (Jòhánù 7:45-52) Àmọ́ ti Jésù yàtọ̀. Ó máa ń bá àwọn èèyàn kẹ́dùn nígbà tí wọ́n bá sọ ohun tó ń dùn wọ́n fún un.—Mátíù 20:29-34; Máàkù 5:25-34.
Ronú nípa ohun tó o ṣe nígbà tí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ sọ ohun tó ń dùn ún fún ọ. Ṣé ọ̀rọ̀ tó o sọ, ohùn tó o fi sọ ọ́ àti bí ojú rẹ ṣe rí nígbà tó ò ń sọ ọ́ fi hàn pé o bá a kẹ́dùn? Àbí ṣe lo kàn máa ń ṣe bíi pé ohun tó wà lọ́kàn ọkọ tàbí ìyàwó rẹ yẹn kò tóó pọ́n?
OHUN TÓ O LÈ ṢE: Fi ọ̀sẹ̀ mélòó kan kíyè sí ọ̀nà tó ò ń gbà bá ọkọ rẹ tàbí ìyàwó rẹ sọ̀rọ̀. Tó o bá ṣèèṣì ṣohun tó dà bíi pé o ò ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí tàbí tó o sọ̀rọ̀ kan tó kàn án lábùkù, tètè tọrọ àforíjì.
▪ ‘Ṣé mo sábà máa ń rò pé ọkọ tàbí ìyàwó mi kò lè dédé hùwà tó dáa tí kò bá sí nǹkan míì nídìí ẹ̀?’ Sátánì sọ ọ̀rọ̀ kan láti fi hàn pé ó fura sí ìdí tí Jóòbù fi jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Lásán ha ni Jóòbù ń bẹ̀rù Ọlọ́run bí? Ìwọ fúnra rẹ kò ha ti ṣe ọgbà ààbò yí i ká, àti yí ilé rẹ̀ ká, àti yí ohun gbogbo tí ó ní ká?”—Jóòbù 1:9, 10.
Tí tọkọtaya kan ò bá kíyè sára, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í fura òdì sí ara wọn. Bí àpẹẹrẹ tí ọkọ rẹ tàbí ìyàwó rẹ bá ṣe ohun rere kan fún ọ, ṣó o máa ń rò ó pé ó ní nǹkan kan tó ń wá tàbí pé ó ti ṣe nǹkan kan tí kò fẹ́ kó o mọ̀ ló ṣe ń ṣe dáadáa sí ọ? Tí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ bá ṣàṣìṣe kan, ṣó o máa ń kà á sí ẹ̀rí pé tara ẹ̀ nìkan ló mọ̀ àti pé kò bìkítà nípa rẹ? Ṣé kíá ni wàá ti rántí àwọn àṣìṣe tó ti ṣe tẹ́lẹ̀ tí wàá sì fi èyí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe yìí kún un?
OHUN TÓ O LÈ ṢE: Kọ àwọn nǹkan dáadáa tí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ ti ṣe fún ẹ sílẹ̀ kó o sì tún kọ àwọn ohun rere tó o rò pé ó mú kó ṣe é.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìfẹ́ . . . kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.” (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Ìfẹ́ tòótọ́ kò fọ́jú o. Àmọ́ kì í ṣàkọsílẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́nì kan ṣẹ̀ ẹ́. Pọ́ọ̀lù tún sọ pé ìfẹ́ “a máa gba ohun gbogbo gbọ́.” (1 Kọ́ríńtì 13:7) Kì í ṣe pé irú ìfẹ́ yìí dùn-ún tàn jẹ là ń sọ o, àmọ́ ó máa ń fọkàn tán àwọn ẹlòmíì. Kì í fura sáwọn èèyàn. Irú ìfẹ́ tí Bíbélì sọ pé ó yẹ ká ní yìí máa ń múra tán láti dárí ji àwọn ẹlòmíì, ó sì máa ń gbà pé ohun rere ló wà lọ́kàn wọn. (Sáàmù 86:5; Éfésù 4:32) Tí tọkọtaya bá ní irú ìfẹ́ yìí sí ara wọn, ìgbéyàwó wọn á mà dùn bí oyin o.
BI ARA RẸ PÉ . . .
▪ Àṣìṣe wo ni tọkọtaya tá a kọ ọ̀rọ̀ wọn síbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ṣe?
▪ Báwo lèmi ò ṣe ní ṣerú àwọn àṣìṣe bẹ́ẹ̀ nínú ìgbéyàwó mi?
▪ Èwo nínú àwọn kókó tí àpilẹ̀kọ yìí mẹ́nu kan ló yẹ kí n ṣiṣẹ́ lé lorí jù lọ?