Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Òfin Ti Di Akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Wa”

“Òfin Ti Di Akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Wa”

“Òfin Ti Di Akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Wa”

ǸJẸ́ gbogbo ọmọdé ló mọyì ìbáwí àti ìlànà? Ó tì o, àwọn tó mọyì rẹ̀ kò pọ̀. Ńṣe ni inú máa ń bí wọn tí àyè ò bá gbà wọ́n láti ṣe ohun tó wù wọ́n. Ṣùgbọ́n àwọn tó lọ́mọdé lọ́dọ̀ mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì káwọn tọ́ wọn sọ́nà. Táwọn ọmọ náà bá wá dàgbà tán, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló máa ń mọyì ìtọ́ní tí wọ́n gbà ní kékeré. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo àpẹẹrẹ àwọn ọkùnrin kan tó máa ń tọ́jú ọmọdé láti fi ṣàpèjúwe ọ̀nà tí Jèhófà Ọlọ́run gbà tọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ́nà fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún.

Àwọn kan lára àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní ìpínlẹ̀ Gálátíà tó wà lábẹ́ ìjọba Róòmù ń fi ìdánilójú sọ pé kìkì àwọn tó bá pa Òfin Mósè tí Ọlọ́run fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́ nìkan ni Ọlọ́run máa ṣojú rere sí. Ṣùgbọ́n àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé kò sóòótọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ yìí, ìdí sì ni pé Ọlọ́run fún àwọn míì tí wọn ò tiẹ̀ mọ nǹkan kan nípa Òfin Mósè ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Ìṣe 15:12) Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù lo àpèjúwe kan láti fi tún èrò wọn ṣe. Nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Gálátíà, ó ní: “Òfin ti di akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi.” (Gálátíà 3:24) Ohun tí ọ̀mọ̀wé kan sọ ni pé “akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan ní ojúṣe pàtàkì tó máa ń ṣe láyé àtijọ́.” Mímọ̀ tá a bá mọ ojúṣe akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ láyé àtijọ́ máa jẹ́ ká lóye àpèjúwe àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.

Akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àti Ojúṣe Rẹ̀

Àwọn tí wọ́n rí já jẹ lára àwọn ará ilẹ̀ Gíríìsì, Róòmù àtàwọn Júù kan pàápàá máa ń ní akọ́nilẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn ẹnì kan tó dà bí alágbàtọ́, tó ń bá wọn bójú tó ọmọ wọn títí tọ́mọ náà á fi dàgbà. Akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tàbí ẹni tó dà bí alágbàtọ́ yìí sábà máa ń jẹ́ àgbàlagbà ẹrú kan tó ṣeé fọkàn tán. Ó máa ń dáàbò bo ọmọ, ó sì máa ń rí i dájú pé ohun tí bàbá ọmọ fẹ́ ni wọ́n ń ṣe fún ọmọ náà. Akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí máa ń tẹ̀ lé ọmọ náà lọ síbikíbi tó bá ń lọ, ó máa ń rí i pé ọmọ náà wà ní mímọ́ tónítóní, á mú un lọ sílé ìwé, á tún bá a kó ìwé àtàwọn ohun èlò rẹ̀ míì dání, yóò sì tún rí i pé ó fojú sí ẹ̀kọ́ rẹ̀.

Akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí kọ́ ló sábà máa ń kọ́ ọmọ náà lẹ́kọ̀ọ́ nílé ìwé. Kàkà bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ rẹ̀ ò ju pé kó kàn máa tọ́ ọmọ náà sọ́nà bí bàbá rẹ̀ ṣe fẹ́. Ó máa ń fún ọmọ náà ní ìtọ́ni, ó sì máa ń bá a wí. Irú bíi kó kọ́ ọ béèyàn ṣe ń hùwà tàbí kó tiẹ̀ fìyà jẹ ẹ́ tó bá hùwà àìtọ́. Lóòótọ́, ojúṣe bàbá àti ìyá ọmọ ló jẹ́ láti tọ́ ọmọ wọn, àmọ́ bí ọmọ náà ṣe ń dàgbà, akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ máa ń kọ́ ọ bó ṣe yẹ kó máa rìn, bó ṣe yẹ kó máa wọṣọ, bó ṣe yẹ kó máa jókòó, bó ṣe yẹ kó máa jẹun, bó ṣe yẹ kó máa bọ̀wọ̀ fún àgbàlagbà, bó ṣe yẹ kó nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí rẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kan tó jẹ́ onímọ̀ nípa ọgbọ́n orí, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Plato, tó gbé láyé lọ́dún 428 sí 348 ṣáájú Sànmánì Kristẹni gbà pé àwọn ọmọdé nílò ìbáwí gan-an. Ó ní: “Bí ò ṣe yẹ káwọn àgùntàn tàbí àwọn ẹran míì máa dá jẹ̀ káàkiri láìní olùṣọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni ọmọ ò ṣe lè wà láìní akọ́nilẹ́kọ̀ọ́, tàbí kí ẹrú wà láìní ọ̀gá.” Ohun tí Plato sọ yẹn lè dà bíi pé ó le jù, àmọ́ ojú tó fi wo ọ̀ràn náà nìyẹn.

Nítorí pé àwọn akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí sábà máa ń wà pẹ̀lú àwọn ọmọ nígbà gbogbo, àwọn ọmọ míì kà wọ́n sí ẹni tó máa ń fìyà jẹni, ìkà àti oníwàhálà ẹ̀dá tí kì í jẹ́ kéèyàn rímú mí, tó kàn máa ń ka ẹ̀sùn tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ séèyàn lọ́rùn. Lóòótọ́ làwọn akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan nírú ìwà bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ wọ́n máa ń dáàbò bo ọmọ ní gbogbo ọ̀nà. Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Appian, tó gbé láyé ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Kristẹni sọ ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan àti ọmọ tó wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀ lọ́jọ́ kan tó ń mú ọmọ náà lọ sí ilé ìwé. Akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí ràgà bo ọmọ náà kó lè dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn kan tí wọ́n fẹ́ pa á. Nígbà tí akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí kọ̀ tí kò fi ọmọ náà sílẹ̀, ni wọ́n bá pa òun àti ọmọ náà.

Ìṣekúṣe gbilẹ̀ gan-an ní ilẹ̀ Gíríìsì àtijọ́. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì láti dáàbò bo àwọn ọmọdé, pàápàá jù lọ àwọn ọmọkùnrin kúrò lọ́wọ́ àwọn abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe. Ìdí nìyí tí akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ fi máa ń jókòó ti ọmọ nílé ìwé, torí ọ̀pọ̀ olùkọ́ ni ò ṣeé fọkàn tán. Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Libanius tó gbé láyé ní ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Kristẹni tiẹ̀ sọ pé àwọn akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ máa ń ṣe bí “ẹ̀ṣọ́ fáwọn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà” kí “wọ́n lè lé àwọn tó bá fẹ́ fi ìṣekúṣe lọ àwọn ọmọ náà dà nù, kí wọ́n má sì gba irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ láyè láti bá àwọn ọmọkùnrin ṣe ọ̀rẹ́ àpàpàǹdodo.” Ọ̀pọ̀ akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ló sì di ẹni iyì lọ́wọ́ àwọn ọmọ tí wọ́n bójú tó. Àwọn òkúta ìrántí táwọn tó ti dàgbà máa ń gbé síbi sàréè ẹni tó jẹ́ akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wọn nígbà tí wọ́n wà ní kékeré jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé wọ́n mọyì akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wọn.

Bí Òfin Ṣe Jẹ́ Akọ́nilẹ́kọ̀ọ́

Kí nìdí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi fi Òfin Mósè wé akọ́nilẹ́kọ̀ọ́? Kí ló sì jẹ́ kí àpèjúwe yìí bá a mu gan-an?

Ìdí àkọ́kọ́ ni pé Òfin Mósè yìí dáàbò bò wọ́n. Pọ́ọ̀lù sọ pé “a ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí [àwọn Júù] lábẹ́ òfin.” Ńṣe ló dà bí ìgbà tí akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan ń dáàbò bò wọ́n. (Gálátíà 3:23) Òfin Mósè ló ń darí gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe nígbèésí ayé wọn. Ó ń ká wọn lọ́wọ́ kò tó bá dọ̀ràn ìṣekúṣe àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn. Òfin yìí ló ń jẹ́ kí wọ́n mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n hùwà, ó sọ ìyà tẹ́ni tó bá dẹ́ṣẹ̀ máa jẹ, ó sì ń jẹ́ kí ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan rántí pé aláìpé lòun.

Òfin náà tún jẹ́ ààbò fún wọn kúrò lọ́wọ́ àwọn ìwà tó lè ṣàkóbá fún wọn, irú bí ìwàkiwà àti ìbọ̀rìṣà àwọn orílẹ̀-èdè tó yí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ká. Bí àpẹẹrẹ, òfin tí Ọlọ́run fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ bá àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà dána jẹ́ kí gbogbo orílẹ̀-èdè yẹn lè ní àjọṣe tó dán mọ́ràn pẹ̀lú Ọlọ́run. (Diutarónómì 7:3, 4) Irú òfin báyìí jẹ́ kí ìjọsìn àwọn èèyàn Ọlọ́run jẹ́ mímọ́, ó sì mú kí wọ́n lè dá Mèsáyà mọ̀. Ẹ ò rí i pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ gan-an tó fi fún wọn lófin tó ṣàǹfààní bẹ́ẹ̀! Mósè rán àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì létí pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ti í tọ́ ọmọ rẹ̀ sọ́nà ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń tọ́ ọ sọ́nà.”—Diutarónómì 8:5.

Àmọ́, ohun kan tó ṣe pàtàkì nínú àpèjúwe tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ni pé akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kì í láṣẹ lórí ọmọ títí lọ. Bí ọmọ kan bá ti dẹni tó tójúúbọ́, kò ní sí lábẹ́ akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ mọ́. Òpìtàn kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sẹ́nófọ̀n tó gbé láyé ní ọdún 431 sí 352 ṣáájú Sànmánì Kristẹni sọ pé: “Bí ọmọ kan bá ti ń kúrò lọ́mọdé, tó ń dàgbà, àwọn èèyàn, pàápàá àwọn òbí rẹ̀, á gbà á kúrò lọ́wọ́ [akọ́nilẹ́kọ̀ọ́] rẹ̀ àti kúrò lọ́dọ̀ [olùkọ́] rẹ̀; wọ́n á sì jẹ́ kó dòmìnira.”

Bí agbára tí Òfin Mósè ní náà ṣe rí nìyẹn. Kò wà títí lọ. Ohun tó kàn wà fún ni láti ‘mú kí àwọn ìrélànàkọjá fara hàn kedere, títí irú-ọmọ náà, Jésù Kristi yóò fi dé.’ Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ‘akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi’ ni Òfin Mósè jẹ́ fáwọn Júù. Káwọn Júù tí wọ́n jẹ́ alájọgbáyé Pọ́ọ̀lù yìí tó lè rí ojú rere Ọlọ́run, wọ́n gbọ́dọ̀ gbà pé Jésù kó ipa pàtàkì nínú ohun tí Ọlọ́run pinnu láti ṣe. Táwọn Júù bá sì ti gbà bẹ́ẹ̀ àbùṣe bùṣe, iṣẹ́ akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ parí nìyẹn.—Gálátíà 3:19, 24, 25.

Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì jẹ́ pípé. Òfin yẹn ṣe ohun tí Ọlọ́run tìtorí rẹ̀ gbé e kalẹ̀, ìyẹn ni láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀, kó sì jẹ́ kí wọ́n mọ ìlànà rẹ̀. (Róòmù 7:7-14) Òfin náà ṣiṣẹ́ rẹ̀ bí iṣẹ́. Àmọ́, àwọn ohun tí òfin náà ń béèrè lè nira fàwọn kan. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé nígbà tí àsìkò tí Ọlọ́run yàn tó, “Kristi nípa rírà, tú wa sílẹ̀ kúrò lábẹ́ ègún Òfin.” Òfin jẹ́ “ègún” ní ti pé ó mú káwọn Júù wà lábẹ́ àwọn ìlànà tí wọn ò lè pa mọ́ délẹ̀délẹ̀. Ó mú kí wọ́n máa ṣe àwọn ààtò fínnífínní láìkù síbi kan. Àmọ́ tí Júù kan bá lè nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, èyí tó ta yọ ìwẹ̀nùmọ́ tí Òfin Mósè pèsè, kò tún sí lábẹ́ akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ mọ́, ìyẹn òfin tó ń mú kó máa ṣe àwọn ààtò fínnífínní.—Gálátíà 3:13; 4:9, 10.

Nígbà náà, ohun tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ fà yọ bó ṣe fi Òfin Mósè wé akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ni bí Òfin náà ṣe ń darí àwọn Júù àti pé kò ní wà títí lọ. Nítorí náà, kì í ṣe pípa Òfin yẹn mọ́ ló máa jẹ́ kéèyàn rí ojú rere Jèhófà, bí kò ṣe pé kéèyàn mọ Jésù kó sì gbà á gbọ́.—Gálátíà 2:16; 3:11.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

“ÀWỌN ỌKÙNRIN TÍ Ń ṢE ÀBÓJÚTÓ” ÀTI “ÀWỌN ÌRÍJÚ”

Yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ, ó tún sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ọkùnrin tí ń ṣe àbójútó” àti “àwọn ìríjú.” Gálátíà orí kẹrin ẹsẹ ìkíní àti ìkejì kà pé: “Níwọ̀n ìgbà tí ajogún náà bá ṣì jẹ́ ìkókó, kò yàtọ̀ rárá sí ẹrú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ olúwa ohun gbogbo, ṣùgbọ́n ó wà lábẹ́ àwọn ọkùnrin tí ń ṣe àbójútó àti lábẹ́ àwọn ìríjú títí di ọjọ́ tí baba rẹ̀ ti yàn tẹ́lẹ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ “àwọn ọkùnrin tí ń ṣe àbójútó” àti “àwọn ìríjú” yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn akọ́nilẹ́kọ̀ọ́, ohun kan náà ni Pọ́ọ̀lù ń fi wọ́n ṣàlàyé.

Lábẹ́ òfin àwọn ará Róòmù, wọ́n máa ń fi ọmọ òrukàn tí ò tíì tójúúbọ́ sábẹ́ ‘ọkùnrin tí ń ṣe àbójútó’ kó máa tọ́jú rẹ̀ kó sì máa bójú tó ogún ọmọ náà títí yóò fi dàgbà. Pọ́ọ̀lù wá sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ náà ni “olúwa” lórí ogún rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tó ṣì wà lọ́mọdé, kò láṣẹ lórí ogún náà bí ẹrú náà ò ṣe láṣẹ lórí ogún náà.

Àmọ́, ‘ìríjú’ jẹ́ ẹni tó ń bójú tó okòwò ìdílé. Òpìtàn ọmọ Júù kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Flavius Josephus sọ pé ọmọdékùnrin kan tó ń jẹ́ Hyrcanus sọ fún bàbá rẹ̀ pé kó fóun ní lẹ́tà tóun máa fún ìríjú ìdílé àwọn kó lè fún òun lówó tóun yóò máa fi ra àwọn nǹkan.

Nítorí náà, bí ọmọ tí kò ì tíì tójúúbọ́ kò ṣe ní òmìnira ara rẹ̀ lábẹ́ akọ́nilẹ́kọ̀ọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni kò ṣe ní òmìnira lábẹ́ ‘ọkùnrin tí ń ṣe àbójútó’ àti lábẹ́ ‘ìríjú.’ Tó fi hàn pé àwọn kan ni yóò máa darí ọmọ náà títí dọjọ́ tí bàbá rẹ̀ bá fẹ́ kó dòmìnira.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Àwòrán akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan tó mú ọ̀pá dání ló wà lára àwo òdòdó àwọn ará ilẹ̀ Gíríìsì ayé àtijọ́ yẹn

[Credit Line]

National Archaeological Museum, ní ìlú Áténì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Àwòrán akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ (tó mú ọ̀pá dání) tá a yà sára ife lọ́rùn-úndún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni, akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí jókòó ti ọmọ tó ń bójú tó bí ọmọ náà ṣe ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí ewì àti orin

[Credit Line]

Bildarchiv Preussischer Kulturbesitz/Art Resource, NY