Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ó Ń ṣamọ̀nà Mi Ní Àwọn Òpó Ọ̀nà Òdodo”

“Ó Ń ṣamọ̀nà Mi Ní Àwọn Òpó Ọ̀nà Òdodo”

“Ó Ń ṣamọ̀nà Mi Ní Àwọn Òpó Ọ̀nà Òdodo”

Gẹ́gẹ́ bí Olga Campbell ṣe sọ ọ́

Emily àbúrò mi obìnrin sọ pé: “Àpẹẹrẹ rere dà bí ìró aago iléèwé tó máa ń pe àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jọ. Àpẹẹrẹ yín sì dà bí ìró aago yìí létí mi, ni mo bá tẹ̀ lé e.” Inú lẹ́tà kan tó kọ sí mi láti fi bá mi yọ̀ pé mo ti lo ọgọ́ta ọdún nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ló ti sọ ọ̀rọ̀ yìí. Ẹ jẹ́ kí n sọ ìtàn ìgbà ọmọdé mi fún yín àti bí mo ṣe dẹni tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ tó gba gbogbo ìgbésí ayé mi.

WỌ́N bí mi ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù January, ọdún 1927. Abà kan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìlú Wakaw, lágbègbè Saskatchewan ní ìwọ̀ oòrùn Kánádà ni ìdílé wa tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ukraine ń gbé nígbà tí wọ́n bí mi. Àwa mẹ́jọ làwọn òbí wa bí. Ìbejì ni mí. Èmi àti Bill, ìkejì mi la ṣe ìkẹfà àti ìkeje. Òṣìṣẹ́ gidi ni bàbá wa, àwa ọmọ sì máa ń bá a ṣiṣẹ́ oko. Inú ilé kékeré kan là ń gbé, màmá wa sì máa ń tọ́jú wa gan-an láìka ìrora àrùn aromọléegun tó ní sí, àrùn náà ló sì padà pa á. Màmá wa ò ju ẹni ọdún mẹ́tàdínlógójì lọ tó fi kú; ọmọ ọdún mẹ́rin péré lèmi nígbà yẹn.

Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tí màmá wa kú, bàbá wa fẹ́ ìyàwó míì. Ìyàwó tuntun yìí bí ọmọbìnrin márùn-ún, kò sì pẹ́ rárá tí awuyewuye fi gbilẹ̀ nílé wa. Èmi gbìyànjú láti bọ̀wọ̀ fún ìyàwó bàbá wa yìí, àmọ́ òun àti ẹ̀gbọ́n mi tó ń jẹ́ John kì í fẹ́ rímí ara wọn láàtàn.

Láàárín ọdún 1937 sí 1939, èmi àti Bill, ìkejì mi ń lọ sílé ìwé girama, ìyẹn tún jẹ́ ká bọ́ lọ́wọ́ awuyewuye inú ilé wa fúngbà díẹ̀. Bí Ogun Àgbáyé Kejì ṣe rọ̀ dẹ̀dẹ̀, ẹ̀mí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni gba ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn. Olùkọ́ wa wá ní ká máa kí àsíá orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n ọmọbìnrin kan kọ̀ kò kí i. Làwọn ọmọ ilé ìwé bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ṣẹlẹ́yà. Àmọ́, ìgboyà tó ní jọ mí lójú gan-an, mo wá lọ bi í léèrè ìdí tí kò fi kí àsíá náà. Ó sọ pé Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lòun, ìyẹn orúkọ tí wọ́n ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn, àti pé Ọlọ́run nìkan lòun lè júbà lọ́nà bẹ́ẹ̀.—Ẹ́kísódù 20:2, 3; Ìṣe 5:29.

Mo Wá Iṣẹ́ Ajé Lọ

Lọ́dún 1943, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kan nílùú Prince Albert, mo máa ń bá ọkọ̀ tó ń ta ọtí ẹlẹ́rìndòdò lọ káàkiri. Nítorí pé mo ń fẹ́ kí Ọlọ́run máa tọ́ mi sọ́nà, mo lọ ra Bíbélì, àmọ́ nǹkan tí mò ń kà níbẹ̀ ò yé mi rárá, ó sì dùn mí dé bi pé mo bú sẹ́kún. Àdúrà Olúwa nìkan ṣoṣo ni mo lè sọ pé mo mọ̀ nínú gbogbo nǹkan tó wà nínú Bíbélì.—Mátíù 6:9-13.

Ìyá onílé wa tó jẹ́ oníṣọ́ọ̀ṣì ń sọ lọ́jọ́ Sunday kan báyìí pé òun taari obìnrin kan tó fẹ́ wàásù Bíbélì fún òun kúrò lẹ́nu ọ̀nà òun. Mo sọ ọ́ lọ́kàn mi pé, ‘Ìyá yìí máa burú lẹ́dàá o!’ Lọ́jọ́ Sunday kan lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mélòó kan sígbà yẹn, ó rẹ̀ mí, mi ò lè lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Lobìnrin oníwàásù yẹn bá dé.

Ó wá bi mí pé, “Ṣé o máa ń gbàdúrà?”

Mo dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni mo máa ń gba Àdúrà Olúwa.”

Mo tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ bó ṣe ń ṣàlàyé àwọn ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú àdúrà yẹn. Ó wá lóun máa padà wá lọ́jọ́ Wednesday ọ̀sẹ̀ yẹn.

Bí ìyá onílé mi ṣe dé, tayọ̀tayọ̀ ni mo fi sọ ọ̀rọ̀ obìnrin oníwàásù yẹn, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, fún un. Ó yà mí lẹ́nu gan-an bí ìyá onílé mi ṣe jágbe mọ́ mi, tó ní: “Bí n bá rí ẹsẹ̀ obìnrin yẹn nílé mi lọ́jọ́ Wednesday, ẹ̀yin méjèèjì ni màá lé jáde!”

Mo wá gbogbo àdúgbò bóyá màá tiẹ̀ rí obìnrin Ẹlẹ́rìí yẹn tí wọ́n ń pè ní ìyáàfin Rampel. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn mo rí i, mo bá kó mo rò fún un, mo wá ní kó sọ gbogbo ohun tó bá lè sọ nípa Bíbélì fún mi. Bíi pé a parí Bíbélì láti Jẹ́nẹ́sísì dé Ìṣípayá lọ̀rọ̀ rí lọ́jọ́ náà! Obìnrin yìí sọ pé ayé òde òní dà bí ìgbà ayé Nóà, nígbà tí Ọlọ́run pa àwọn aláìṣòdodo run tó sì dá ẹ̀mí Nóà àti ìdílé rẹ̀ sí.—Mátíù 24:37-39; 2 Pétérù 2:5; 3:5-7, 12.

Lẹ́yìn tá a ti fi ọ̀pọ̀ wákàtí sọ̀rọ̀, ìyáàfin Rampel sọ pé: “Mo rí i pé o ti gbà pé òótọ́ làwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí. Ní ọ̀sẹ̀ méjì sí i, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ṣe àpéjọ kan, o sì máa ṣèrìbọmi níbẹ̀.” Mi ò sùn lóru ọjọ́ yẹn, ńṣe ni mò ń ronú lórí gbogbo ohun tí mo ti kọ́. Mò ń wo ìrìbọmi bí ohun pàtàkì kan téèyàn ò kàn lè kù gìrì ṣe. Síbẹ̀, mo fẹ́ sin Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ Bíbélì tí mo ní ò tíì tó nǹkan, mo ṣèrìbọmi lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù October ọdún 1943, lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún.

Mo Ṣí Láti Ìwọ̀ Oòrùn Lọ sí Ìlà Oòrùn Ilẹ̀ Kánádà

Nígbà tó di oṣù November ọdún 1943, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tó ń jẹ́ Fred ní kí n wá ṣe olùtọ́jú ilé alájà mẹ́ta tó ń gbé ní ìlú Toronto lápá ìlà oòrùn ilẹ̀ Kánádà. Mo gbà, torí mo ronú pé iṣẹ́ yẹn máa fún mi láyè dáadáa láti máa sin Jèhófà. Kí n tó lọ, mo lọ kí ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ń jẹ́ Ann, tó ṣì ń gbé ní Saskatchewan nítòsí ibi tí mo wà. Ẹ̀gbọ́n mi yìí ní òun fẹ́ sọ nǹkan kan tí mi ò tíì mọ̀ fún mi, ó ní òun àtẹ̀gbọ́n wa àgbà, ìyẹn Doris ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì rọ̀ mí pé kí èmi náà lọ máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ wọn. Lèmi náà bá sọ ohun kan tí kò mọ̀ fún un pé, mo ti di Ẹlẹ́rìí, kódà mo ti ṣèrìbọmi!

Èmi àti àbúrò mi Emily wọ ọkọ̀ ojú irin lọ sí ìyànníyàn Toronto. Ìkejì mi ti ń dúró dè wá ní ibùdó ọkọ̀ ojú irin, ó sì mú wa lọ sí ibi tó ń gbé, lọ́dọ̀ Fred àti John. Mo bi Fred bóyá ẹlòmíì tún ń gbé ní ilé yẹn. Fred ní, “Bí àlá ló máa rí lójú ẹ tí n bá sọ fún ẹ. Ṣó o ṣì rántí Alex Reed lábúlé wa? Òun ló ń gbé lókè wa, èyí tó wá burú ńbẹ̀ ni pé òpònú ara ẹ̀ lọ ń gba àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láyè!” Bí mo ṣe gbọ́ ohun tó sọ yìí, inú mi dùn gan-an!

Mo rọra yọ́ lọ sí yàrá Alex lókè, mo sì ṣètò bí mo ṣe máa bá a lọ sípàdé lálẹ́ ọjọ́ yẹn gan-an. Mo kúkú fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé lọ́jọ́ yẹn gan-an, kó tó di pé àwọn ẹ̀gbọ́n mi á kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni mo jáde lọ wàásù fúngbà àkọ́kọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò dìídì ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí n tó ṣèrìbọmi. Inú mi máa ń dùn pé mo ń rí ọ̀pọ̀ ọmọ ilẹ̀ Ukraine wàásù fún, torí àti kékeré mi ni mo tí gbọ́ èdè wọn.

Bill, ìkejì mi máa ń ka Ilé Ìṣọ́ tí mo máa ń fi sínú yàrá rẹ̀ dáadáa. Mo bá a san àsansílẹ̀ owó Ilé Ìṣọ́ kó lè máa rí i gbà déédéé lẹ́yìn tó kó lọ sí àgbègbè kan tó ń jẹ́ British Columbia ní ìwọ̀ oòrùn Kánádà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò lágbaja ọ̀rọ̀ sísọ, ó kọ lẹ́tà ojú ewé mẹ́wàá láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ mi. Nígbà tó sì yá, ó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó sì di alábòójútó tó ń fìtara bójú tó iṣẹ́ rẹ̀ nínú ìjọ. Àwọn márùn-ún nínú ọmọ ìyá mi ló ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà tí wọ́n sì di ìránṣẹ́ rẹ̀. Àwọn ni: Bill, Ann, Fred, Doris àti Emily. Èyí sì máyọ̀ mi kún gan-an ni!

Lọ́jọ́ kejìlélógún, oṣù May, ọdún 1945, ìjọba ilẹ̀ Kánádà fagi lé òfin tí wọ́n fi de iṣẹ́ ìwàásù àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. a Ṣùgbọ́n, ẹ jẹ́ mọ̀ pé mi ò mọ̀ pé wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa àyàfi ìgbà tí mo gbọ́ ìkéde yẹn. Èmi àti ọ̀rẹ́ mi tó ń jẹ́ Judy Lukus pinnu láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn àwọn tó ń lo ọ̀pọ̀ àkókò lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run, ní ìlú Quebec, lápá ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè Faransé ní ìlà oòrùn Kánádà. Nígbà táwọn ọmọ ìyá mi obìnrin méjì, ìyẹn Doris àti Emily gbọ́ ohun tá a pinnu láti ṣe, àwọn náà pinnu láti lọ ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní ìlú Vancouver, lágbègbè British Columbia tó wà ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn Kánádà.

Àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì Ń Ṣe Inúnibíni sí Àwa Ẹlẹ́rìí ní Ìlú Quebec

Kì í ṣe pé mo kàn ṣípò padà nìkan nígbà tí mo kó lọ sí Quebec, ó nídìí pàtàkì tí mo fi ṣí lọ síbẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ ń fojú winá inúnibíni lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wọn. b Tayọ̀tayọ̀ la fi pín ìwé àṣàrò kúkúrú tó táṣìírí báwọn àlùfáà, àwọn ọlọ́pàá àtàwọn èèyànkéèyàn ṣe gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Quebec. Àkọlé rẹ̀ ni, Quebec’s Burning Hate for God and Christ and Freedom Is the Shame of All Canada. Ìkéde tó mú bí iná yẹn táṣìírí itú táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń pa nìdí inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí.

Aago méjì òru lójoojúmọ́ là ń jì, tá a ó yọ́ kẹ́lẹ́ lọ máa fi ìwé àṣàrò kúkúrú yìí sábẹ́ ilẹ̀kùn àwọn èèyàn, a sì ṣe èyí fún ọjọ́ mẹ́rìndínlógún gbáko. Lọ́jọ́ kan, bá a ṣe wà lẹ́nu ọ̀nà ilé kan, a gbọ́ pé àwọn ọlọ́pàá ń bọ̀ wá mú wa. La bá sá pa mọ́ sí kọ̀rọ̀ kan, wọn ò sì rí wa mú. Lọ́jọ́ kejì, a tún ti wà lójú pópó tá à ń pín ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Àìmọye ìgbà làwọn ọlọ́pàá mú wa lẹ́yìn ìgbà náà. Torí pé ìgbàkigbà ni wọ́n lè mú wa kí wọ́n sì tì wá mọ́lé, mo máa ń rí i dájú pé mo mú búrọ́ọ̀ṣì ìfọyín àti lẹ́ẹ̀dì tí mo fi ń tọ́jú dání nígbà gbogbo.

Lóṣù November, ọdún 1946, Arákùnrin Nathan Knorr tó ń múpò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé nígbà náà, wá ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wa láti Brooklyn, ní ìpínlẹ̀ New York. Ó ní kí àwa mẹ́rìnlélọ́gọ́ta tá a jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nílùú Quebec wá sí kíláàsì kẹsàn-án ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì tí wọ́n máa ṣe nílùú South Lansing ní ìpínlẹ̀ New York. Nílé ẹ̀kọ́ yìí, a gba ẹ̀kọ́ Bíbélì tó pọ̀ gan-an fún oṣù márùn-ún gbáko. Lẹ́yìn tá a kẹ́kọ̀ọ́ yege lóṣù August, ọdún 1947, wọ́n rán wa lọ sáwọn ìlú tó wà ní ìpínlẹ̀ Quebec pé ká lọ dá ìjọ tuntun sílẹ̀ níbẹ̀.

Iṣẹ́ Ìsìn Tó Mérè Wá

Àwa obìnrin mẹ́rin tá ò tíì lọ́kọ ni wọ́n rán lọ sí ìlú Sherbrooke. Bá a ṣe débẹ̀, a bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Faransé wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́. Bá a ti ń rìn lọ rìn bọ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa là ń fi èdè tá a ti kọ́ dánra wò. Nígbà míì a kì í lówó tá a máa fi ra oúnjẹ ọ̀sán, tó bá ti tó àsìkò oúnjẹ, àá padà lọ máa ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ nílé. Kay Lindhorst tá a jọ máa ń wàásù gbọ́ èdè Faransé àti Gẹ̀ẹ́sì dáadáa. Ó kọ́ mi ní gírámà èdè Gẹ̀ẹ́sì, kó bàa lè rọrùn fún mi láti kọ́ èdè Faransé.

Apá tí mo gbádùn jù lọ nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà mi ni èyí tí mo lò nílùú Victoriaville, nígbà yẹn, èèyàn tó wà níbẹ̀ ò ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ. Ìwọ̀nba èèyàn ló ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ìlú yìí, ìyẹn sì jẹ́ ká túbọ̀ gbọ́ èdè Faransé dáadáa. A gbádùn ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ tá a débẹ̀ gan-an. Kò síbi tá a dè, táwọn èèyàn ò ti gba ìwé wa. Àmọ́, nígbà tá a máa fi padà lọ ilé wọn, a rí i pé wọ́n ti gbogbo ilẹ̀kùn, wọ́n sì fa kọ́tìnì dí ojú fèrèsé ilé wọn. Kí ló dé?

Àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì wọn ló ti kìlọ̀ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ fetí sí wa mọ́. Nítorí náà, bá a ṣe ń lọ láti ilé dé ilé làwọn ọmọdé ń tẹ̀ lé wa, tí wọ́n ń ju òkò lù wá. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ṣì fẹ́ gbọ́ ìwàásù wa. Irú àwọn bẹ́ẹ̀ kọ́kọ́ gbà pé ká máa wá tílẹ̀ bá ṣú. Àmọ́, bí ẹ̀kọ́ òtítọ́ ṣe túbọ̀ ń gbádùn mọ́ wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn láìfi bò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú àwọn aládùúgbò wọn ò dùn sí i.

Ní àwọn ọdún 1950, èmi, àbúrò mi obìnrin àtẹ̀gbọ́n mi obìnrin jọ padà lọ kí wọn ní ìlú Wakaw. A sọ àwọn ìrírí tá a ti ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní ìpàdé ìjọ kan tá a bá wọn ṣe. Lẹ́yìn ìpàdé, alàgbà kan nínú ìjọ yẹn sọ fún wa pé: “Inú ìyá yín á dùn gan-an nígbà tó bá jíǹde tó sì gbọ́ pé àwọn ọmọ òun di Ẹlẹ́rìí Jèhófà!” Ó ní ìyá wa ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ Ẹlẹ́rìí kan kó tó kú. Omijé bọ́ lójú wa nígbà tá a gbọ́ pé ìyá wa ti ń kọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jẹ́ pé ì bá kọ́ àwa ọmọ rẹ̀ ká ní ikú kò dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò.

Mo Ṣègbéyàwó, Èmi Àtọkọ Mi sì Ń Bá Iṣẹ́ Ìsìn Lọ

Lọ́dún 1956, mo pàdé Merton Campbell, tó lo ọdún méjì àti oṣù mẹ́ta lẹ́wọ̀n nígbà Ogun Àgbáyé Kejì torí pé kò lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ológun. Àmọ́ nígbà tá a fi pàdé, ó ti tó nǹkan bí ọdún mẹ́wàá tó ti ń sìn ní orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Brooklyn. Mo rí i pé Merton máa jẹ́ ọkọ rere torí àwọn ànímọ́ dáadáa tí ẹ̀kọ́ Bíbélì ti jẹ́ kó ní. Lẹ́yìn tá a kọ lẹ́tà síra wa fún oṣù bíi mélòó kan, a bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra.

Èmi àti Merton ṣègbéyàwó ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù September, ọdún 1960. Inú mi sì dùn gan-an pé ọkùnrin tó ń fi ìlànà Bíbélì ṣèwà hù yìí ni ọkọ mi tá a ti jọ ń gbé fọ́dún mẹ́tàdínláàádọ́ta báyìí! Merton ti ṣiṣẹ́ fọ́dún méjìdínlọ́gọ́ta ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn, ìyẹn ẹ̀ka tó ń pèsè ìrànlọ́wọ́ àti ìtọ́ni fún ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Iṣẹ́ tí mo ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn fún ohun tó lé lọ́gbọ̀n ọdún ni ṣíṣe àwọn yàrá ìgbàlejò lọ́ṣọ̀ọ́, nígbà tó sì yá mò ń báwọn ṣe àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ ńláńlá tó wà lágbègbè ìlú New York lọ́ṣọ̀ọ́. Àmọ́ nígbà tó di ọdún 1995, wọ́n gbé wa lọ sí Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower tó wà ní Patterson níhà àríwá ìlú New York, èyí tó tó ìrìn nǹkan bí àádọ́fà [110] kìlómítà síbi tá a wà.

Mi ò lálàá rẹ̀ rárá nígbà tí mo kúrò nílé ní ọmọ ọdún méjìlá pé lọ́jọ́ kan màá ní ọ̀pọ̀ ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó ń sin Jèhófà títí kan àwọn ọmọ ìyá tèmi. Mò ń retí ọjọ́ náà tí ètò tuntun Ọlọ́run máa dé, tí àá rọ̀gbà yí màmá wa ká, tí àá máa sọ àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tó sùn nínú ikú fún un. Bí àpẹẹrẹ, a óò sọ bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe jẹ́ kí àwa ọmọ rẹ̀ dẹni tó mọ òun. A mà ṣọpẹ́ o, pé Jèhófà ti ‘ṣamọ̀nà wa ní àwọn òpó ọ̀nà òdodo’!—Sáàmù 23:3.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò dá sí ọ̀ràn ìṣèlú, ìjọba fòfin de iṣẹ́ wọn ní July 4, ọdún 1940.

b Àlàyé síwájú sí i lórí báwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe ṣenúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí nílùú Quebec wà nínú Jí! May 8, 2000, ojú ìwé 20 sí 23.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Àwọn òbí mi àti ilé táwa ọmọ mẹ́jọ ń gbé pẹ̀lú wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Èmi àtàwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ìwàásù nílùú Ottawa, lọ́dún 1952

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Èmi àtàwọn ọmọ ìyá mi (láti apá òsì lọ sí ọ̀tún) Ann, Mary, Fred, Doris, John, èmi, Bill, àti Emily

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Èmi àti Merton lónìí