Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Ikú Jésù Ṣe Lè Gbà Ọ́

Bí Ikú Jésù Ṣe Lè Gbà Ọ́

Bí Ikú Jésù Ṣe Lè Gbà Ọ́

Ó TI fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá [2,000] ọdún báyìí tí ọkùnrin kan kú láìṣẹ̀ láìrò torí káwọn ẹlòmíì lè yè. Ọjọ́ àjọ̀dún Ìrékọjá àwọn Júù, èyí tí wọ́n ṣe lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni ni ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn wáyé. Ta ni ọkùnrin náà tó kú irú ikú yìí? Jésù ará Násárétì ni. Fún àǹfààní àwọn wo ló sì ṣe kú? Gbogbo aráyé pátá ni. Ẹsẹ Bíbélì kan táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó ṣàkópọ̀ ọ̀rọ̀ nípa ẹbọ tó máa gbẹ̀mí aráyé là yẹn, ó sọ pé: “Ọlọrun fẹ araiye tobẹ̃ gẹ, ti o fi Ọmọ bíbi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun.”—Jòhánù 3:16, Bibeli Mimọ.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, àmọ́ àwọn díẹ̀ ló yé dáadáa. Wọ́n máa ń dà á rò pé: ‘Kí nìdí tá a fi nílò ẹbọ Kristi? Báwo ni ikú ẹnì kan ṣoṣo ṣe lè gba gbogbo aráyé lọ́wọ́ àgbákò ikú àkúrun yìí?’ Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí lọ́nà tó ṣe kedere, ìdáhùn tó mú wá sì ń tẹ́ni lọ́rùn.

Bí Ikú Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Jọba Lórí Ìran Èèyàn

Èrò àwọn kan ni pé ìgbà díẹ̀ ni Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn lò lórí ilẹ̀ ayé, pé ó fẹ́ kí wọ́n jìyà díẹ̀ kí wọ́n sì gbádùn díẹ̀, kí wọ́n wá kú nígbẹ̀yìngbẹ́yín kí wọ́n lè lọ sí ibì kan tó dára ju ayé lọ. Tó bá jẹ́ pé bí wọ́n ṣe rò ó yìí lọ̀rọ̀ rí, a jẹ́ pé ara ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fáwọn ọmọ aráyé ni pé kí wọ́n máa kú. Àmọ́ Bíbélì fi hàn pé ọ̀tọ̀ ni nǹkan tó fà á tí ikú fi ń pa èèyàn. Ó sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí fi hàn pé ẹ̀ṣẹ̀ ló fà á táwa èèyàn fi ń kú. Àmọ́ ta ni “ènìyàn kan” tí ẹ̀ṣẹ̀ tó ń fa ikú yìí tipasẹ̀ rẹ̀ dé ọ̀dọ̀ ìran èèyàn?

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló gbà pé orísun kan náà ni gbogbo èèyàn ti wá. Bíbélì sì wá sọ kedere pé “ènìyàn kan” yẹn ni orísun ọ̀hún. Nínú Jẹ́nẹ́sísì 1:27, a kà pé: “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; akọ àti abo ni ó dá wọn.” Ohun tí Bíbélì sọ yìí fi hàn pé nínú gbogbo ohun tí Ọlọ́run Olódùmarè dá sórí ilẹ̀ ayé, ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ ló gbé ògo Ọlọ́run yọ jù lọ.

Àkọsílẹ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì yẹn sọ àwọn nǹkan míì nípa ìgbésí ayé ẹ̀dá èèyàn lẹ́yìn tí Jèhófà Ọlọ́run ti dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́. Tá a bá sì kíyè sí ìtàn yẹn látòkèdélẹ̀, a ó rí i pé Ọlọ́run ò sọ pé wọ́n máa kú, kìkì ohun tó lè mú kí wọ́n kú ni àìgbọràn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Ó fẹ́ káwọn èèyàn máa gbé nínú Párádísè ẹlẹ́wà lórí ilẹ̀ ayé, kí inú wọn máa dùn, kára wọn sì máa le títí láé. Kò fẹ́ kí ọjọ́ ogbó máa dà wọ́n láàmú, kí wọ́n sì wá kú nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Báwo ni ikú ṣe wá jẹ gàba lórí gbogbo aráyé?

Jẹ́nẹ́sísì orí kẹta ṣàlàyé bí tọkọtaya àkọ́kọ́ ṣe mọ̀ọ́mọ̀ pinnu láti ṣàìgbọràn sí Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá wọn. Látàrí èyí, Ọlọ́run ṣe ìdájọ́ táwọn fúnra wọn ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ fún wọn. Ó sọ fún ọkùnrin yẹn pé: “Ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀, àwọn aláìgbọràn méjèèjì yìí kú nígbẹ̀gbẹ̀yìngbẹ́yín.

Tọkọtaya àkọ́kọ́ yìí nìkan kọ́ lohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣàkóbá fún. Ìdí ni pé ẹni pípé ni àwọn àtàwọn àtọmọdọ́mọ wọn ì bá máa jẹ́ lọ tí kì í bá ṣe àìgbọràn wọn tó ba nǹkan jẹ́. Àwọn àtìrandíran èèyàn tí wọn ò tíì bí wà lára àwọn tí Jèhófà ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún Ádámù àti Éfà pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn ni pé tó bá yá, ìran àwọn èèyàn á kún orí ilẹ̀ ayé wọ́n á sì máa gbádùn lọ fàlàlà láìní kú. Àmọ́ Ádámù baba ńlá wọn, tó jẹ́ “ènìyàn kan” yẹn, tà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀, èyí ló sì ń mú kí ikú máa rẹ́yìn wọn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tóun náà jẹ́ àtọmọdọ́mọ ènìyàn akọ́kọ́ yẹn sọ pé: “Èmi jẹ́ ẹlẹ́ran ara, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.”—Róòmù 7:14.

Ńṣe ló dà bí ìgbà táwọn bàṣèjẹ́ lọ ba iṣẹ́ ọ̀nà tó ṣeyebíye jẹ́. Ádámù tipasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tó dá yẹn ba iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run jẹ́, ìyẹn ìran èèyàn. Àwọn ọmọ Ádámù bímọ, àwọn ọmọ tiwọn náà bímọ, bí àtìrandíran ọmọ Ádámù ṣe ń pọ̀ sí i nìyẹn. Bí wọ́n bá ti ń bí àwọn ọmọ, àwọn yẹn á dàgbà, wọ́n á sì máa bímọ, gbogbo wọn ló ń darúgbó tí wọ́n sì ń kú. Kí ló dé tí gbogbo wọn fi ń kú? Ìdí ni pé àtara Ádámù ni gbogbo wọn ti wá. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ [ń] kú nípasẹ̀ àṣemáṣe ọkùnrin kan.” (Róòmù 5:15) Àìsàn, ọjọ́ ogbó, ọkàn wa tó máa ń fà sí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú fúnra rẹ̀ jẹ́ àbárèbábọ̀ àkóbá tí Ádámù ṣe fún ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀. Gbogbo wa la sì wà nínú ìdílé náà.

Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù, ó sọ̀rọ̀ nípa ipò ìbànújẹ́ táwa ẹ̀dá aláìpé, tó fi mọ́ òun alára, wà àti bó ṣe jẹ́ pé èèyàn ní láti máa bá ẹ̀ṣẹ̀ ja ìjà àjàkú akátá. Ohun tó sọ rèé: “Èmi abòṣì ènìyàn! Ta ni yóò gbà mí lọ́wọ́ ara tí ń kú ikú yìí?” Ìbéèrè pàtàkì nìyẹn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ta ló máa gba Pọ́ọ̀lù àti gbógbó àwọn tó fẹ́ dòmìnira lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú? Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ dáhùn ìbéèrè yẹn, ó ní: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!” (Róòmù 7:14-25) Bó ṣe rí nìyẹn, Ẹlẹ́dàá wa ti ṣètò bó ṣe máa gbà wá sílẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀.

Ipa Tí Jésù Kó Nínú Bí Ọlọ́run Ṣe Gba Aráyé

Jésù ṣàlàyé ohun tó ṣe láti lè dá aráyé sílẹ̀ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ tó ń fa ikú. Ó sọ pé: “Ọmọ-enia . . . wá . . . lati fi ẹmi rẹ̀ ṣe iràpada ọpọlọpọ enia.” (Matthew 20:28, Bibeli Mimọ) Báwo ni ẹ̀mí Jésù ṣe lè ṣe ìràpadà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn? Àǹfààní wo ni ikú Jésù lè ṣe fún wa?

Bíbélì sọ pé Jésù “kò ní ẹ̀ṣẹ̀,” ó sì “yà sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.” Ní gbogbo ìgbà tí Jésù fi wà lórí ilẹ̀ ayé, ó ṣègbọràn pátápátá sí Òfin Ọlọ́run. (Hébérù 4:15; 7:26) Nígbà náà, ikú Jésù kì í ṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìgbọràn Ádámù. (Ìsíkíẹ́lì 18:4) Ńṣe ni Jésù gbà láti kú ikú tí kò tọ́ sí i láti lè ṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ tó fẹ́ láti gba aráyé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ lókè yìí, Jésù mọ̀ọ́mọ̀ “fi ẹmi rẹ̀ ṣe iràpada.” Ìfẹ́ tá ò rí irú ẹ̀ rí ni Jésù lò nígbà tó fínnúfínndọ̀ “tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn.”—Hébérù 2:9.

Ẹ̀mí Jésù tí Jésù fi rúbọ jẹ́ dọ́gba-n-dọ́gba pẹ̀lú ẹ̀mí tí Ádámù pàdánù nígbà tó dẹ́ṣẹ̀. Kí wá ni àǹfààní tó tẹ̀yìn ikú Jésù yọ? Jèhófà gba ẹbọ Jésù gẹ́gẹ́ bí “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tímótì 2:6) Ìyẹn túmọ̀ sí pé Ọlọ́run lo ẹ̀mí Jésù gẹ́gẹ́ bí iye tó fi máa ra aráyé padà tàbí iye tó fi máa gbà wọ́n lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.

Léraléra ni Bíbélì máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ ńlá tí Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá ènìyàn fi hàn yìí. Pọ́ọ̀lù rán àwọn Kristẹni létí pé ‘a ti rà wọ́n ní iye kan.’ (1 Kọ́ríńtì 6:20; 7:23) Pétérù kọ̀wé pé Ọlọ́run kò lo wúrà tàbí fàdákà láti gba àwọn Kristẹni lọ́wọ́ irú ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé tó máa yọrí sí ikú, kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ló lò. (1 Pétérù 1:18, 19) Jèhófà fi Ẹbọ ìràpadà tí Kristi rú ṣètò bó ṣe máa gba àwọn èèyàn lọ́wọ́ ikú ayérayé tó wà lórí wọn.

Kí Ni Wàá Ṣe Láti Jàǹfààní Ẹbọ Ìràpadà Kristi?

Àpọ́sítélì Jòhánù ń sọ̀rọ̀ nípa ibi tí àǹfààní ẹbọ ìràpadà Kristi nasẹ̀ dé, ó sọ pé: “[Jésù Kristi] ni ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, síbẹ̀ kì í ṣe fún tiwa nìkan ṣùgbọ́n fún ti gbogbo ayé pẹ̀lú.” (1 Jòhánù 2:2) Lóòótọ́ ni, Kristi ni ìràpadà tó wà fún gbogbo ènìyàn. Àmọ́ ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé gbogbo èèyàn pátá ló máa jàǹfààní ẹbọ ìràpadà tó ṣeyebíye yìí ni? Rárá o. Rántí àwọn awàkùsa tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, pé wọ́n yọ nínú ihò tí wọ́n há sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó fẹ́ yọ wọ́n fi okùn gbé àgò kan lọ sísàlẹ̀, àmọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó wà nísàlẹ̀ yìí ló ní láti wọnú àgò yẹn. Lọ́nà kan náà, àwọn tó bá fẹ́ jàǹfààní ẹbọ ìràpadà Kristi kò lè fọwọ́ lẹ́rán máa retí ìbùkún látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n ní láti ṣe nǹkan kan.

Kí ni Ọlọ́run rétí pé kí wọ́n ṣe? Jòhánù 3:36 sọ fún wa pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun; ẹni tí ó bá ń ṣàìgbọràn sí Ọmọ kì yóò rí ìyè, ṣùgbọ́n ìrunú Ọlọ́run wà lórí rẹ̀.” Ọlọ́run retí pé ká ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi. Nǹkan míì tún wà tí Ọlọ́run retí pé ká máa ṣe. Bíbélì sọ pé: “Nípa èyí ni àwa sì ní ìmọ̀ pé àwa ti wá [mọ Jésù], èyíinì ni, bí a bá ń bá a lọ ní pípa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (1 Jòhánù 2:3) Ó ṣe kedere nígbà náà pé nǹkan pàtàkì tá a gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ni pé ká nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi ká sì máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.

Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpada Jésù ni pé ká fi hàn pé a mọrírì ikú rẹ̀ nípa ṣíṣe ìrántí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe pa á láṣẹ. Kí Jésù tó kú, ó ṣètò oúnjẹ tó ṣàpẹẹrẹ ohun pàtàkì kan fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tó dúró tì í, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe àárín àwa àti Ọmọ Ọlọ́run, torí náà a máa ń tẹ̀ lé àṣẹ yẹn. Lọ́dún yìí, a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi ní ọjọ́ Sátidé March 22, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. A fi tìfẹ́tìfẹ́ ké sí ọ pé kó o wá bá wa ṣe ìpàdé pàtàkì yìí láti fi hàn pé ò ń tẹ̀ lé àṣẹ tí Jésù pa. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ yóò sọ àkókò àti ibi tí wọ́n ti máa ṣe é fún ọ. Níbi Ìrántí Ikú Kristi yìí, wàá mọ ohun tó o lè ṣe tí ẹbọ ìràpadà Kristi á fi gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ń fà.

Ìwọ̀nba àwọn èèyàn díẹ̀ ló mọrírì ìrúbọ ńlá tí Ẹlẹ́dàá wọn àti Ọmọ rẹ̀ ti ṣe láti lè gbà wọ́n lọ́wọ́ ìparun. Àwọn tó lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ yẹn ń rí ìdùnnú tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Àpọ́sítélì Pétérù sọ fáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé: “Ẹ lo ìgbàgbọ́ nínú [Jésù], ẹ sì ń yọ̀ gidigidi pẹ̀lú ìdùnnú aláìṣeé-fẹnusọ àti ológo, bí ẹ ti ń rí òpin ìgbàgbọ́ yín gbà, ìgbàlà ọkàn yín.” (1 Pétérù 1:8, 9) Tó o bá ní ìfẹ́ Jésù Kristi, tó o sì nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà tó ṣe, wàá fi ìdùnnú kún inú ayé rẹ, wàá sì nírètí pé lọ́jọ́ iwájú wàá bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ láti mú ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù kúrò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

A ó ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́jọ́ Sátidé March 22, 2008, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀