Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bó O Ṣe Lè Di Ọ̀kan Lára Àwọn Ọmọ Ọlọ́run

Bó O Ṣe Lè Di Ọ̀kan Lára Àwọn Ọmọ Ọlọ́run

Bó O Ṣe Lè Di Ọ̀kan Lára Àwọn Ọmọ Ọlọ́run

NÍ NǸKAN bí ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn Ogun Kòríà, ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n ilẹ̀ Kòríà gbé ètò kan kalẹ̀ láti jẹ́ káwọn ẹbí tí ogun ti pín níyà lè tún padà rí ara wọn. Kí ni àbárèbábọ̀ ètò náà? Ó lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá èèyàn tí wọ́n padà fojú kan ara wọn, wọ́n wá ń da omijé lójú pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀, wọ́n sì ń dì mọ́ ara wọn tínú wọn sì ń dùn. Ìwé ìròyìn Korea Times sọ pé: “Kò ṣẹlẹ̀ rí nínú ìtàn ilẹ̀ Kòríà, pé kí ọ̀pọ̀ ṣáà máa sun ẹkún ayọ̀ tó pọ̀ báyìí lẹ́ẹ̀kan náà.”

Lórílẹ̀-èdè Brazil, láti ọmọ ọwọ́ ni wọ́n ti fi ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Cézar dí gbèsè táwọn òbí ẹ̀ jẹ. Nígbà tó wá rí màmá rẹ̀ ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn ìgbà yẹn, inú ẹ̀ dún débi pé ó kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí tó gbà á tọ́, tí wọ́n jẹ́ olówó, ó sì lọ ń gbé ọ̀dọ̀ màmá rẹ̀.

Ẹ wo bí inú àwọn aráalé kan ṣe máa ń dùn tó lọ́jọ́ tí wọ́n bá tún fojú kanra wọn lẹ́yìn tí wọ́n ti ya ara wọn! Ẹ jẹ́ ká wá wo bí Bíbélì ṣe ṣàlàyé nípa báwọn èèyàn ṣe yapa kúrò nínú agboolé Ọlọ́run. Ó tún sọ bí wọ́n ṣe ń padà tayọ̀tayọ̀ báyìí sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Báwo nìyẹn ṣe ṣẹlẹ̀? Báwo lo sì ṣe lè nípìn-ín nínú ayọ̀ yẹn?

Bí Ìyapa Ṣe Wọnú Agboolé Ọlọ́run

Onísáàmù kan sọ fún Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá pé: “Ọ̀dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà.” (Sáàmù 36:9) Jèhófà ni Bàbá gbogbo àwọn ẹ̀dá tó ń fòtítọ́ sìn ín ní ayé àtọ̀run nínú agboolé ńlá rẹ̀. Àwọn tó wà nínú ìdílé yìí ni àwọn áńgẹ́lì lọ́run, ìyẹn àwọn ọmọ Ọlọ́run tó jẹ́ ẹ̀mí àti àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ ọmọ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.

Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí ṣe sọ, nígbà tí Ádámù, èèyàn àkọ́kọ́ tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run ṣàìgbọràn, ó fa ìpínyà láàárín ìran èèyàn àti Bàbá wọn tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wọn onífẹ̀ẹ́. Ìṣòro ńlá gbáà nìyẹn sì fà fún wọn. (Lúùkù 3:38) Ìdí ni pé Ádámù tipasẹ̀ àìgbọ́ràn yẹn sọ àǹfààní kan nù, èyí tóun àtàwọn ọmọ rẹ̀ tí kò tíì bí ì bá máa gbádùn gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run. Ọlọ́run tipasẹ̀ Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ nǹkan tó tẹ̀yìn ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí yọ, pé: “Wọ́n ti gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun níhà ọ̀dọ̀ àwọn fúnra wọn; wọn kì í ṣe ọmọ [Ọlọ́run], àbùkù náà jẹ́ tiwọn.” “Àbùkù náà,” ìyẹn ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀, ló jẹ́ káwọn èèyàn sọ ara wọn dàjèjì sí Ọlọ́run, ẹni mímọ́ tó sì pé ní gbogbo ọ̀nà. (Diutarónómì 32:4, 5; Aísáyà 6:3) Ṣe ló dà bíi pé ìran ènìyàn ti sọ nù, wọ́n ti di aláìníbaba.—Éfésù 2:12.

Bíbélì ṣàlàyé báwọn èèyàn tí kò sí nínú agboolé Ọlọ́run ṣe jìnnà sí i tó, ó pè wọ́n ní “ọ̀tá.” (Róòmù 5:8, 10) Nígbà táwọn èèyàn ti yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run báyìí, wọ́n ti bọ́ sábẹ́ Sátánì tó ń fi palaba ìyà jẹ wọ́n, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé tí wọ́n ti jogún ń gbo wọ́n mọ́lẹ̀ ràì. (Róòmù 5:12; 1 Jòhánù 5:19) Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ láti padà sínú agboolé Ọlọ́run? Ṣé àwọn ẹ̀dá aláìpé lè di ọmọ Ọlọ́run bí Ádámù àti Éfà ṣe jẹ́ kí wọ́n tó dẹ́ṣẹ̀?

Bí Ọlọ́run Ṣe Ń Kó Àwọn Ọmọ Rẹ̀ Tó Ti Yapa Jọ

Jèhófà fi ìfẹ́ ṣètò kan tó máa ṣàǹfààní fáwọn èèyàn aláìpé tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 2:9) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi ń mú ayé kan padà bá ara rẹ̀ rẹ́, láìṣírò àwọn àṣemáṣe wọn sí wọn lọ́rùn.” (2 Kọ́ríńtì 5:19) Gẹ́gẹ́ bá a ṣe ṣàlàyé nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Jèhófà Ọlọ́run fi Jésù Kristi fún wa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìràpadà fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. (Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16) Àpọ́sítélì Jòhánù mọrírì èyí, òun ló mú kó sọ pé: “Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba ti fi fún wa, kí a lè pè wá ní ọmọ Ọlọ́run.” (1 Jòhánù 3:1) Èyí ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn láàárín àwọn ọmọ èèyàn láti tún padà wá sínú agboolé Jèhófà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èèyàn tí Ọlọ́run kó jọ sínú agboolé rẹ̀ ló máa wà níṣọ̀kan lọ́nà àgbàyanu lábẹ́ àbójútó Bàbá wọn ọ̀run, kíyè sí àlàyé tí Bíbélì ṣe lórí bí Ọlọ́run ṣe kó wọn jọ sí ọ̀nà méjì. A kà á pé: “Ó jẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìdùnnú rere [Ọlọ́run] èyí tí ó pète nínú ara rẹ̀ fún iṣẹ́ àbójútó kan ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀, èyíinì ni, láti tún kó ohun gbogbo jọpọ̀ nínú Kristi, àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.” (Éfésù 1:9, 10) Kí nìdí tí Ọlọ́run fi ṣètò rẹ̀ lọ́nà yìí?

Ńṣe ni ètò tí Jèhófà ṣe láti kó àwọn ọmọ rẹ̀ jọ sọ́nà méjì yìí fi kún ìṣọ̀kan tó wà nínú agboolé rẹ̀. Kò ṣòro láti mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Agboolé Ọlọ́run tóbi débi tá a lè fi wé orílẹ̀-èdè. Ní orílẹ̀-èdè kan, àwọn èèyàn díẹ̀ ni wọ́n máa ń yàn láti máa ṣèjọba kí nǹkan lè máa lọ bó ṣe yẹ kó lọ. A mọ̀ pé ìjọba èèyàn èyíkéyìí kò tíì mú àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wá, àmọ́ Ọlọ́run ti gbé Ìjọba pípé kan kalẹ̀ nínú agboolé rẹ̀. Ó mú kí àwọn kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run,” ìyẹn àwọn ọmọ Ọlọ́run tí Jèhófà ti yàn táá máa ṣe Ìjọba lọ́run. Látibẹ̀ wá ni wọ́n á ti máa “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.”—Ìṣípayá 5:10.

Àwọn Ọmọ Ọlọ́run Lórí Ilẹ̀ Ayé

Jèhófà tún ń kó “àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé” jọ. Àwọn wọ̀nyí ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn jákèjádò ayé tí wọ́n máa di ọmọ rẹ̀ tó máa wà lórí ilẹ̀ ayé. Bàbá onínúure ni, ó ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ní ọ̀nà ìfẹ́ kó bàa lè jẹ́ pé bí wọ́n tiẹ̀ wá láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, wọ́n máa wà ní ìrẹ́pọ̀ àti ìṣọ̀kan. Kódà, ó ń ké sí àwọn tó ti fìgbà kan rí jẹ́ oníwà ipá, onímọtara-ẹni-nìkan, oníṣekúṣe àtàwọn tí wọn ò gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu, láti wá “padà bá Ọlọ́run rẹ́.”—2 Kọ́ríńtì 5:20.

Àwọn tó kọ̀ tí wọn ò dá Ọlọ́run lóhùn nígbà tó ń pè wọ́n kí wọ́n wá bá òun rẹ́ kí wọ́n sì padà sọ́dọ̀ òun Bàbá wọn ńkọ́? Jèhófà máa mú àwọn wọ̀nyí kúrò kí àlàáfíà àti ìrẹ́pọ̀ lè máa wà nínú agboolé rẹ̀. Ọjọ́ kan ń bọ̀ tó máa jẹ́ “ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Pétérù 3:7) Ọlọ́run máa gbá gbogbo àwọn aláìgbọràn kúrò ní ayé. Ẹ ò rí i pé ìtura nìyẹn máa mú wá fáwọn onígbọràn!—Sáàmù 37:10, 11.

Ní ẹgbẹ̀rún ọdún tó máa tẹ̀ lé e, àlàáfíà máa wà kárí ayé, díẹ̀díẹ̀ sì ni gbogbo àwọn tó bá fara mọ́ ìfẹ́ Ọlọ́run máa padà wá di ẹni pípé, wọ́n á padà sí ipò tí Ádámù wà kó tó dẹ́ṣẹ̀. Kódà àwọn òkú máa jíǹde. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣípayá 20:6; 21:3, 4) Ọlọ́run á sì tipa báyìí mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, pé: “Ìṣẹ̀dá [èèyàn] tìkára rẹ̀ pẹ̀lú [ni a óò dá] sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:21.

Bó O Ṣe Lè Padà Sọ́dọ̀ Bàbá Rẹ Ọ̀run

Ọmọ tó ń jẹ́ Cézar àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará Kòríà tá a sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ní láti ṣe nǹkan kan kí wọ́n tó lè padà bá àwọn ìdílé wọn rẹ́. Àwọn ará Kòríà yẹn ní láti dara pọ̀ mọ́ ètò orí tẹlifíṣọ̀n kan, Cézar sì ní láti kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí tó gbà á tọ́. Bákan náà, ó lè pọn dandan fún ọ láti gbé ìgbésẹ̀ akin kó o tó lè padà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Bàbá rẹ, kó lè ṣeé ṣe fún ọ láti wà nínú agboolé rẹ̀. Kí wá ni nǹkan tó yẹ kó o ṣe?

Láti lè sún mọ́ Ọlọ́run tó jẹ́ Bàbá rẹ, o ní láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kó o bàa lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run àtàwọn ìlérí rẹ̀. Wàá máa fi sọ́kàn pé gbogbo ohun tí Ọlọ́run bá sọ fún ọ jẹ́ fún àǹfààní ara rẹ. Wàá tún ní láti máa gba ìbáwí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tó bá sì tọ́ ẹ sọ́nà wàá ní láti máa ṣàtúnṣe, torí pé Bíbélì sọ fáwọn Kristẹni pé: “Ọlọ́run ń bá yín lò bí ẹní ń bá àwọn ọmọ lò. Nítorí ọmọ wo ni baba kì í bá wí?”—Hébérù 12:7.

Tó o bá ṣèyẹn, gbogbo ìgbésí ayé rẹ ló máa yí padà. Bíbélì sọ pé: “Kí ẹ di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú yín ṣiṣẹ́, kí ẹ sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Éfésù 4:23, 24) Wàá tún wá máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pétérù tó sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí ó ń gbọ́ràn, ẹ má ṣe gbé irú ìgbé-ayé yín ti àtijọ́, nígbà tí ẹ ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín tí ẹ kò mọ̀ pé àìdára ni.”—1 Pétérù 1:14, Ìròyìn Ayọ̀.

Bó O Ṣe Lè Rí Àwọn Ará Tẹ́ Ẹ Jọ Jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run

Nígbà tí Cézar rí ìyá rẹ̀, inú ẹ̀ dùn nígbà tó gbọ́ pé òun ṣì ní ẹ̀gbọ́n méjì, ọ̀kan ọkùnrin, ọ̀kan obìnrin. Tíwọ náà bá sún mọ́ Bàbá rẹ ọ̀run, wàá rí i pé o ṣì ní àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó dà bí ọmọ ìyá nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bó o bá ṣe ń bá wọn kẹ́gbẹ́, wàá kíyè sí i pé wọ́n á sún mọ́ ọ tímọ́tímọ́ ju àwọn tí wọ́n jọ bí yín nínú ilé kan náà.—Ìṣe 28:14, 15; Hébérù 10:24, 25.

À ń pè ọ́ báyìí pé kó o padà wá sọ́dọ̀ ẹni tó jẹ́ Bàbá rẹ gan-gan kó o sì padà sọ́dọ̀ àwọn tó jẹ́ arákùnrin àti arábìnrin rẹ. Ayọ̀ tí wàá rí á pọ̀ jọjọ bíi ti Cézar àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará Kòríà tó padà sọ́dọ̀ àwọn ẹbí wọn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Cézar rèé lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìyá rẹ̀, nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mọ́kàndínlógún

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ṣe àwọn ohun tó máa jẹ́ kó o sún mọ́ Ọlọ́run