Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ́ Ìwàásù àti Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Nílẹ̀ Áfíríkà

Iṣẹ́ Ìwàásù àti Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Nílẹ̀ Áfíríkà

Iṣẹ́ Ìwàásù àti Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Nílẹ̀ Áfíríkà

Iye Orílẹ̀-èdè: 57

Iye Ènìyàn: 827,387,930

Iye Ẹlẹ́rìí Jèhófà: 1,086,653

Iye Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: 2,027,124

A Ò KỌ ìròyìn ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá yìí tìtorí káwọn èèyàn kàn lè rí ìwọ̀n iṣẹ́ tá a ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe la fẹ́ káwọn èèyàn rí ẹ̀mí ìfẹ́ àti ìfọkànsìn táwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́kùnrin, lóbìnrin àtàwọn ọmọdé ní. Bẹ́ẹ̀ ni, ìròyìn yìí jẹ́ ká rí ipá ribiribi táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sà àti bá a ṣe ń náwó-nára sórí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere. Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ sì mọrírì ipa yòówù kí a kó nínú iṣẹ́ ìwàásù yìí. (Sáàmù 50:14; Lúùkù 21:1-4) Ìròyìn yìí tún rán wa létí pé, “okun tí Ọlọ́run ń pèsè” nìkan la fi lè ṣe iṣẹ́ tó ń gbẹ̀mí là yìí. (1 Pétérù 4:11) Àdúrà wa ni pé bó o ṣe ń ronú lórí ìròyìn yìí àtàwọn ìrírí tó wà níbẹ̀, kó o “máa bá a lọ ní gbígba agbára nínú Olúwa àti nínú agbára ńlá okun rẹ̀.”—Éfésù 6:10.

Côte d’Ivoire Àwọn èèyàn tó wà lábúlé kan tó ń jẹ́ Bianouan, tó wà ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire ń fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àwọn kan tiẹ̀ máa ń jí àwọn Ẹlẹ́rìí láago mẹ́fà àárọ̀, pé kí wọ́n kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì káwọn tó lọ oko. Àwọn míì máa ń ní kí wọ́n kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nírọ̀lẹ́ lẹ́yìn ìpàdé ìjọ. Lọ́jọ́ kan, obìnrin kan tí kò mọ ìwé kà, ní kí Ẹlẹ́rìí kan fún òun ní ìwé kan táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? pé ọkọ òun á kà á fóun. Ẹlẹ́rìí náà fún un ní ìwé yẹn, ó sì wá obìnrin yẹn lọ sílé lọ́jọ́ kejì. Nígbà tó débẹ̀, ó rí i pé obìnrin yìí àtọkọ ẹ̀ ti ń dúró de òun. Ọkọ obìnrin yìí kò tètè lọ sóko lọ́jọ́ yìí, torí pé ìwé yẹn ni wọ́n kà mọ́jú, ó sì láwọn nǹkan kan tó fẹ́ bá Ẹlẹ́rìí yìí sọ nípa ohun tí wọ́n kà. Bí tọkọtaya yìí ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn.

Orílẹ̀-èdè Benin Ní àdádó kan, ìdílé ńlá kan bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí. Pásítọ̀ ni olórí ìdílé yìí jẹ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì kan. Ọ̀sẹ̀ méjì péré lẹ́yìn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ ni wọ́n pe ìdílé yìí sí àpéjọ àgbègbè, wọ́n sì gbà láti lọ. Àmọ́ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Sátidé, ọmọ wọn obìnrin tó dàgbà jù ṣàdédé fò ṣánlẹ̀ ó sì kú. Pẹ̀lú gbogbo ìbànújẹ́ yìí, nígbà tó di ọjọ́ Sunday bàbá wọn lọ sí àpéjọ yẹn. Ohun tó sọ nípa ikú ọmọ rẹ̀ nígbà tó di ọjọ́ Monday nìyí: “Iṣẹ́ ọwọ́ Sátánì lèyí, ó fẹ́ kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá èmi àti ìdílé mi ni, àmọ́ irọ́ ló pa, a ò ní gbà fún un.” Ó wá kó gbogbo àwọn nǹkan tó ń lò ní ṣọ́ọ̀ṣì jáde, títí kan aṣọ àlùfáà, fìlà, àmùrè, òróró àti ọ̀pá oyè rẹ̀. Ohun tí ìyàwó rẹ̀ tóun náà jẹ́ olóyè nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà ṣe nìyẹn. Pásítọ̀ yìí wá sọ pé: “A ò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ṣọ́ọ̀ṣì yìí mọ́.” Ó wá ṣe ohun tó dà bíi tàwọn tí ìwé Ìṣe 19:19 sọ nípa wọn, ó dáná sun àwọn ohun èlò náà ní gbangba. Ìdílé wọn sì ń tẹ̀ síwájú dáadáa nínú ìjọsìn Ọlọ́run.

Madagásíkà Lọ́dún 2006, lábúlé kan táwọn tó ń gbé ibẹ̀ tó nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500], ọkùnrin kan tó ń wàásù gba ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí kan ní abúlé mìíràn. Lẹ́yìn tí oníwàásù yìí fara balẹ̀ ka ìwé yìí tán, ó gbà pé òun ti rí òtítọ́, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tó kọ́ fáwọn tí wọ́n jọ ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì kan náà. Kò pẹ́ tóun, ìdílé rẹ̀ àti ogún lára àwọn ọmọ ìjọ yẹn fi kọ̀wé fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìpàdé bíi tàwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn òjíṣẹ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù sì lọ ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n bá ọ̀pọ̀ èèyàn tó fìfẹ́ hàn yìí ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ṣètò láti máa ṣe àwọn ìpàdé ìjọ déédéé. Ní oṣù October, márùn-ún lára wọn di Ẹlẹ́rìí tí kò tíì ṣèrìbọmi, àwọn òjíṣẹ́ tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù yẹn sì tún ti ṣètò ìpàdé míì, ìyẹn Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn àti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Wọ́n ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó lé lógún, àwọn tó ń wá sí ìpàdé sì tó ogójì.

Gúúsù Áfíríkà Lọ́jọ́ kan arákùnrin kan tó ń jẹ́ Hennie àti ìyàwó rẹ̀ jọ ń wàásù láti ilé dé ilé. Bí wọ́n ti dé ẹ̀gbẹ́ ọgbà tó yí ilé kan ká, ajá kan tó rorò yọrí jáde láàárín irin ọgbà náà ó sì bu Hennie jẹ lọ́wọ́. Lẹ̀jẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí í dà lójú ọgbẹ́ yẹn, wọ́n wá padà sílé, ìyàwó rẹ̀ bá a tọ́jú ọgbẹ́ náà, ó sì fi báńdéèjì dì í. Hennie wá ṣètò bó ṣe máa rí dókítà lẹ́yìn náà. Ó sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé òun kò fẹ́ kí ajá dá iṣẹ́ ìwàásù òun dúró lọ́jọ́ yẹn, ní nǹkan bíi wákàtí kan lẹ́yìn náà wọ́n padà lọ síbi tí wọ́n ti ń wàásù. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ilé tó tẹ̀ lé ibi tí ajá tó rorò yẹn wà. Ní ilé bíi mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, ọkùnrin kan pè wọ́n wọlé. Ó fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n sọ, ó sì ní kí wọ́n tún padà wá nígbà míì. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé déédéé. Nígbà tí ọkùnrin yìí kọ̀wé fi ṣọ́ọ̀ṣì tó ń lọ tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, ìyẹn Dutch Reformed Church, ọ̀kan lára àwọn àgbààgbà ṣọ́ọ̀ṣì wá bá a pé àwọn á fi jẹ oyè díákónì. Àmọ́ ó kọ̀, kò sì torí ìyẹn padà sí ṣọ́ọ̀ṣì. Ó tẹ̀ síwájú dáadáa nínú ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ń kọ́. Ní báyìí, ó ti ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.

Tansaníà Nígbà ìgbòkègbodò àkànṣe láti lọ wàásù ní àwọn ìpínlẹ̀ àdádó ní October 2005, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́sàn-án látinú ìjọ Iringa gbéra láti lọ wàásù ní ìlú Pawaga, tó jẹ́ ìrìn àjò nǹkan bíi kìlómítà márùndínlọ́gọ́rin [75] sí ìjọ wọn. Wọ́n ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ pé Ẹlẹ́rìí kan ń gbé ní àgbègbè yẹn, wọ́n sì wá a lọ. Ó pẹ́ díẹ̀ kí wọ́n tó rí Ẹlẹ́rìí náà, ó wá ṣàlàyé fún wọn pé, ó ti lé lógún ọdún tóun ti ń gbé abúlé yẹn, àti pé èrò òun ni pé wọ́n ṣì fòfin de iṣẹ́ ìwàásù àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Tansaníà. Àtìgbà tó ti wà níbẹ̀ ló ti ń wàásù, ó sì sọ pé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere wà níbẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní ìjọ Iringa máa ń lo ọ̀sẹ̀ méjì tí wọ́n bá ti lọ wàásù níbẹ̀ kí wọ́n lè ran àwọn tó fìfẹ́ hàn lọ́wọ́. Lọ́dún 2006, àwọn òjíṣẹ́ méjì tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù ṣí lọ síbẹ̀ láti lọ máa wàásù fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n ran Ẹlẹ́rìí tó wà ní ìpínlẹ̀ àdádó yẹn lọ́wọ́ kó lè túbọ̀ ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run, Ẹlẹ́rìí mẹ́sàn-án ló sì wà níbẹ̀ báyìí. Abẹ́ igi kan ni wọ́n ti ń ṣèpàdé, àmọ́ ètò ti ń lọ lọ́wọ́ nípa bí wọ́n ṣe máa kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kékeré kan tí wọ́n á máa lò.

Rùwáńdà Ọmọbìnrin kan tí kò tíì pé ogún ọdún tó ń jẹ́ Gentille di gbajúmọ̀ nítorí pé ó mọ bí wọ́n ṣe máa ń gbá bọ́ọ̀lù wọnú àwọ̀n nígbà tí wọ́n bá ń gbá bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá. Àwọn èèyàn tiẹ̀ ti sọ ọ́ lórúkọ, wọ́n máa ń pè é ní Manayibitego, lédè Kinyarwanda, tó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Àwọn Tó Ń Gbá Bọ́ọ̀lù Wọnú Àwọ̀n.” Àwọn ọmọ ilẹ̀ Ítálì kan rí ẹ̀bùn tọ́mọbìnrin yìí ní, wọ́n sì fún un láfikún ìdálẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n wá ní kó lọ kópa nínú ìdíje bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá kan nílẹ̀ Ítálì. Àǹfààní ńlá ló yọjú yìí, ìyẹn ni pé á lọ sí ilẹ̀ Yúróòpù, á sì tún di ìlúmọ̀ọ́ká agbábọ́ọ̀lù. Àmọ́ ṣá, Gentille mọ̀ pé tóun bá tẹ́wọ́ gba ìkésíni yìí, ó máa di dandan kóun fi ìdílé òun sílẹ̀. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ìyá rẹ̀, Gentille náà sì ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ kò fọwọ́ pàtàkì mú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Bọ́ọ̀lù ló gbapò àkọ́kọ́ láyé ẹ̀. Gentille fọ̀rọ̀ náà lọ ìyá rẹ̀, ó sì wá rí ìpalára tó máa ṣe fún àjọṣe òun àti Ọlọ́run. Bó ṣe kọ ìkésíni náà nìyẹn, ó sì wá fi àwọn ohun tó jẹ mọ́ ti Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ láyé rẹ̀. Ó ṣe ìrìbọmi ní àpéjọ kan tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí.