Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ilé Ẹjọ́ Gbèjà Àwọn Tí Wọ́n Hùwà Ìkà Sí

Ilé Ẹjọ́ Gbèjà Àwọn Tí Wọ́n Hùwà Ìkà Sí

Ilé Ẹjọ́ Gbèjà Àwọn Tí Wọ́n Hùwà Ìkà Sí

LỌ́JỌ́ kẹta oṣù karùn-ún ọdún 2007, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù, tó wà nílùú Strasbourg lórílẹ̀-èdè Faransé dá ẹjọ́ kan. Gbogbo adájọ́ ibẹ̀ ló fohùn ṣọ̀kan láti dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Georgia láre lórí ọ̀ràn kan. Ilé Ẹjọ́ yẹn rí i pé àwọn èèyàn ti hùwà ìkà sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ wọ́n sì ti fìyà jẹ wọ́n lórí ẹ̀tọ́ wọn láti máa ṣèjọsìn. Ilé Ẹjọ́ yẹn tún bẹnu àtẹ́ lu ìjọba tó wà lórí àlééfà tẹ́lẹ̀ lórílẹ̀-èdè Georgia, torí pé wọn ò fòfin mú àwọn tó hu ìwà ọ̀daràn yẹn kí wọ́n sì bá wọn ṣẹjọ́. Báwo lọ̀rọ̀ ṣe débi ìdájọ́ tí Ilé Ẹjọ́ yẹn ṣe?

Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹwàá ọdún 1999, nǹkan bí ọgọ́fà lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nínú ìjọ Gldani, nílùú Tbilisi tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Georgia wà níbi tí wọ́n ti ń ṣèpàdé wọn lálàáfíà. Òjijì làwọn jàǹdùkú tó tó igba ya wọ ibi tí wọ́n ti ń ṣèpàdé. Vasili Mkalavishvili tó jẹ́ àlùfáà tí wọ́n ti rọ̀ lóyè ní ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ló kó wọn sòdí. Wọ́n kó póńpó àti àgbélébùú onírin dání, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í lu àwọn tó wà nípàdé, wọ́n ṣe àwọn kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí yìí léṣe púpọ̀. Ìlùkulù tí wọ́n lu obìnrin kan sọ ojú rẹ̀ kan dìdàkudà títí dòní. Àwọn tọ́rọ̀ wọn délé ìwòsàn nínú wọn ò dín ní mẹ́rìndínlógún. Àwọn kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá pé kí wọ́n wá gba àwọn, àmọ́ ọ̀gá ọlọ́pàá tí wọ́n bá níbẹ̀ sọ pé ká lòun ni, òun ì bá ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ fáwọn Ẹlẹ́rìí yẹn! Ọ̀kan nínú àwọn jàǹdùkú yẹn gba àwòrán ohun tí wọ́n ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ sórí fídíò, wọ́n gbé e jáde lórí àwọn ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n ìjọba àpapọ̀ ti ilẹ̀ Georgia, èyí sì jẹ́ ká rí ojú àwọn tó lọ ṣiṣẹ́ ibi yìí. a

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n fìyà jẹ yìí fi ẹjọ́ àwọn tó fìyà jẹ wọ́n sùn, àmọ́ kò sẹ́ni tó ṣe nǹkan kan fáwọn tó hùwà ìkà yẹn. Ọlọ́pàá tí wọ́n yàn pé kó ṣèwádìí lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sọ pé ọmọ Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì lòun, òun ò sì ní fẹ́ ṣe ohun tó máa dà bí ojúsàájú lórí ọ̀ràn náà. Báwọn aláṣẹ ìjọba àtàwọn ọlọ́pàá ò ṣe ṣe nǹkan kan lórí ọ̀ràn yìí mú káwọn jàǹdùkú máa fi ẹ̀sìn bojú láti máa fìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí, ó sì ju ọgọ́rùn-ún ìgbà lọ tí wọ́n hu irú ìwà burúkú yìí.

Nítorí náà, ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹfà ọdún 2001, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù. b Nígbà tí Ilé Ẹjọ́ yìí ń ṣe ìdájọ́ ní ọjọ́ kẹta oṣù karùn-ún ọdún 2007, àwọn adájọ́ ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ lórí báwọn jàǹdùkú ṣe ń kọ lu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti báwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Georgia ò ṣe dá sí ọ̀rọ̀ náà. Ilé ẹjọ́ yẹn sọ pé: “Ojúṣe àwọn aláṣẹ ni pé kí wọ́n tètè ṣèwádìí lórí ohun tí wọ́n gbọ́” nípa bí wọ́n ṣe gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n fi kún un nínú ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ náà, pé: “Báwọn aláṣẹ ṣe fàyè gba irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ káwọn aráàlú gbà pé ìjọba kì í tẹ̀ lé ìlànà tó lè mú kí òfin lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, àti pé ìjọba kì í ṣe àwọn nǹkan tó máa mú káwọn èèyàn máa bọ̀wọ̀ fún òfin.”

Nígbà tí Ilé Ẹjọ́ náà ń parí ìdájọ́ yìí, wọ́n sọ pé: “Báwọn kan ṣe lọ gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́jọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹwàá ọdún 1999 fi hàn pé àwọn jàǹdùkú èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí í máa fìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri. Àmọ́ báwọn aláṣẹ ìjọba ṣe fi gbígbọ́ ṣaláì gbọ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí ló jẹ́ káwọn jàǹdùkú èèyàn yìí múra sí ìjà tí wọ́n ń gbé ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri orílẹ̀-èdè Georgia.”

Pẹ̀lú ìdájọ́ yẹn, Ilé Ẹjọ́ gbèjà àwọn tí wọ́n ti ń hùwà ìkà sí látọjọ́ yìí, ó sì pàṣẹ fún ìjọba orílẹ̀-èdè Georgia pé kí wọ́n lọ san owó ìtanràn àti owó ìgbẹ́jọ́ fún Ìjọ Gldani ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Georgia dùn pé ìwà ipa àti ìfìyàjẹni tójú wọn ń rí lọ́wọ́ àwọn èèyàn ti rọlẹ̀. Bákan náà, wọ́n tún ń yọ̀ pé ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ yẹn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ní ẹ̀tọ́ láti máa péjọ pọ̀ láti fọkàn balẹ̀ ṣèjọsìn àwọn. Wọ́n dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Jèhófà Bàbá wọn ọ̀run torí bó ṣe tọ́ wọn sọ́nà tó sì ń dáàbò bò wọ́n látọjọ́ yìí wá.—Sáàmù 23:4.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kúlẹ̀kúlẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wà nínú ìwé ìròyìn Jí! ti January 22, 2002 lédè Gẹ̀ẹ́sì, ojú ìwé 18 sí 24, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́.

b Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù jẹ́ ẹ̀ka kan nínú Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Yúróòpù. Ilé Ẹjọ́ yìí sì máa ń dá ẹjọ́ tó bá ti jẹ mọ́ fífi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn du ẹni, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú òfin táwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Yúróòpù jọ gbà èyí tí wọ́n pè ní European Convention for the Protection of Human Rights and Fundamental Freedoms. Ogúnjọ́ oṣù karùn-ún ọdún 1999 ni orílẹ̀-èdè Georgia tẹ́wọ́ gbà á, wọ́n sì tipa báyìí sọ pé àwọn á máa tẹ̀ lé ìlànà tó wà nínú òfin náà.