Kí Nìdí Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì í Fi í Lo Àgbélébùú?
Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé
Kí Nìdí Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì í Fi í Lo Àgbélébùú?
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé ikú Jésù Kristi ló jẹ́ káwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà rẹ̀ ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. (Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16) Àmọ́, a ò gbà pé orí àgbélébùú ni Jésù kú sí, báwọn èèyàn ṣe máa ń yàwòrán rẹ̀. Ohun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ ni pé orí òpó tó dúró ṣánṣán, tí kò ní igi kankan tí wọ́n fi dábùú rẹ̀ ni Jésù kú sí.
Àwọn ará Mesopotámíà ti ń lo àgbélébùú láti nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún ṣáájú kí Kristi tó wá sáyé. Kódà wọ́n ti máa ń fín àgbélébùú sára àpáta nílẹ̀ Scandinavia ní ẹgbẹ̀rún ọdún mélòó kan ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù. Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Denmark kan, tó ń jẹ́ Sven Tito Achen kọ ìwé kan, ìyẹn Symbols Around Us, tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn àmì. Ìwé náà sọ pé, àwọn èèyàn ilẹ̀ Scandinavia tó jẹ́ abọ̀rìṣà máa ń fi àgbélébùú “ṣe oògùn ìṣọ́ra, . . . àti oògùn oríire.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ ọ̀rọ̀ kan tí kò yà wá lẹ́nu, ó ní: “Wọ́n ti ń lo àgbélébùú kí ẹ̀sìn Kristẹni tó bẹ̀rẹ̀ àti pé àṣà àwọn abọ̀rìṣà ni lílo àgbélébùú, wọ́n sì máa ń lò ó gẹ́gẹ́ bí àmì àwọn nǹkan téèyàn lè fójú rí lójú ọ̀run.” Kí wá nìdí táwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì fi wá ka àgbélébùú sí ohun ọlọ́wọ̀ jù lọ?
Ọ̀mọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ W. E. Vine sọ òtítọ́ pọ́ńbélé yìí pé: “Ní àárín ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Kristẹni . . . wọ́n gbà káwọn abọ̀rìṣà máa wá sí ṣọ́ọ̀ṣì . . . wọ́n sì tún gbà wọ́n láyè láti máa lo àwọn àmì ìbọ̀rìṣà wọn lọ. Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í lo àmì ‘T’ kékeré tó jẹ́ àmì àgbélébùú nínú ṣọ́ọ̀ṣì nìyẹn.”—Ìwé Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words.
Ọ̀mọ̀wé Vine jẹ́ ká mọ̀ pé “òpó tàbí igi kan tó dúró ṣánṣán” ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì táwọn kan túmọ̀ sí “àgbélébùú” tàbí “kàn mọ́ àgbélébùú,” ó sì “yàtọ̀ pátápátá sóhun táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì pè ní igi tí wọ́n gbé dábùú ara wọn.” Ìwé Companion Bible ti Oxford University náà sọ ohun tó kín ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn, ó ní: “Ẹ̀rí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ wà . . . pé igi tó dúró ṣánṣán ni wọ́n kan Olúwa mọ́, kì í ṣe àwọn igi kan tí wọ́n gbé dábùú ara wọn.” Ó wá hàn kedere pé, àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ kan lásán tí kò sí nínú Bíbélì làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń tẹ̀ lé.
Òpìtàn tó ń jẹ́ Achen, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lókè sọ pé: “Bóyá la ó fi rí Kristẹni èyíkéyìí tó lo àmì àgbélébùú títí fi di ọ̀rúndún méjì lẹ́yìn ikú Jésù.” Ó tún sọ pé: “Ojú ohun èlò burúkú kan tó lè pààyàn làwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi ń wo àgbélébùú, bíi ohun èlò kan tí wọ́n fi ń bẹ́ èèyàn lórí tàbí àga oníná tí wọ́n fi ń pààyàn lóde òní.”
Èyí tó tiẹ̀ wá ṣe pàtàkì jù ni pé, ohun yòówù kí wọ́n fi pa Jésù, kò gbọ́dọ̀ di ohun táwọn Kristẹni ń júbà tàbí èyí tí wọ́n ń lò nínú ìjọsìn. Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà.” (1 Kọ́ríńtì 10:14) Jésù pàápàá sọ ohun tó máa jẹ́ àmì tí a ó fi dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn tòótọ́ mọ̀. Ó ní: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:35.
Nítorí náà, tó bá dọ̀rọ̀ ìjọsìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í tẹ̀ lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, ohun tí Bíbélì sọ ni a máa ń ṣe bíi tàwọn Kristẹni ìjímìjí. (Róòmù 3:4; Kólósè 2:8) Ìdí nìyí tí a kì í fi í lo àgbélébùú nínú ìjọsìn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ère ọba Ásíríà abọ̀rìṣà tó gbé àgbélébùú kọ́rùn, ní nǹkan bí ọdún 800 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni
[Credit Line]
British Museum ló yọ̀ǹda ká ya fọ́tò yìí