“Mi Ò Rí Irú Ìfẹ́ Báyìí Rí”
Lẹ́tà Kan Láti Ilẹ̀ Dominican Republic
“Mi Ò Rí Irú Ìfẹ́ Báyìí Rí”
Ọ̀SẸ̀ yìí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí Niurka sọ ọ̀rọ̀ Bíbélì lórí pèpéle ní ìjọ wa. Nígbà tó ń múra ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀, ó lo ọ̀nà táwọn afọ́jú ń gbà kọ̀wé láti fi kọ ohun tó máa sọ, ó sì wá há ọ̀rọ̀ náà sórí. Àwa méjèèjì la wà lórí pèpéle, mo wá ṣe bí ẹni tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ̀rọ gbohùngbohùn ń gbé ohùn mi lọ sínú ẹ̀rọ tó wà ní etí rẹ̀. Nígbà tá a parí ọ̀rọ̀ wa, inú àwùjọ dùn, wọ́n sì pàtẹ́wọ́ débi pé ó gbọ́ròó àtẹ́wọ́ wọn. Bó ṣe ń rẹ́rìn músẹ́ fi hàn pé inú rẹ̀ dùn gan-an. Inú tèmi náà sì dùn. Iṣẹ́ aláyọ̀ mà niṣẹ́ míṣọ́nnárì o!
Mo rántí ìgbà àkọ́kọ́ tí mo bá Niurka pàdé. Ó ti di ọdún méjì sẹ́yìn báyìí. Lẹ́yìn tá a ti wakọ̀ ní ọ̀nà eléruku fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú la rí obìnrin yìí. Ó jókòó síwájú ilé kékeré kan tí wọ́n fi búlọ́ọ̀kù àti igi kọ́, páànù tí wọ́n fi kan ilé náà sì ti dógùn-ún. À ń gbọ́ òórùn àti igbe àwọn ewúrẹ́, ajá àtàwọn èkúté níbẹ̀. Niurka jókòó, ó dorí kodò, ó hàn pé ńṣe ló máa ń dá wà lóun nìkan àti pé gbogbo nǹkan ti tojú sú u. Ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ni, àmọ́ ó ti gbó ju ọjọ́ orí rẹ̀ lọ.
Mo rọra fọwọ́ tọ́ ọ ní èjìká, ó sì yíjú sí apá ọ̀dọ̀ wa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò lè rí wa, torí ọdún mọ́kànlá sẹ́yìn lojú ẹ̀ ti fọ́. Mo pariwo sí i létí kó tó lè gbọ́ ohun tí mo ń sọ torí pé kò gbọ́ràn dáadáa, mo sì sọ orúkọ èmi àtẹni tá a jọ wá síbẹ̀ fún un. Ẹ̀yìn ìyẹn la wá gbọ́ pé àìsàn kan tó ń ṣàkóbá fún iṣan ara tí wọ́n ń pè ní Marfan syndrome ló ń ṣe é, ìnira ńlá ni àìsàn yìí sì ti kó bá a. Niurka tún ní àrùn ìtọ̀ ṣúgà, ó sì di dandan kó máa ṣàyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ déédéé kí wọ́n lè bá a dín ìwọ̀n ṣúgà tó wà nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kù.
Nígbà tí mo gbé Bíbélì lé e lọ́wọ́, ó mọ̀ pé Bíbélì ni, ó wà sọ pé òun máa ń ka Ìwé Mímọ́ gan-an kójú òun tó fọ́. Báwo wá ni màá ṣe kọ́ obìnrin tọ́rọ̀ rẹ̀ gbẹgẹ́, tó sì tún ní ìṣòro yìí lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń tuni lára? Torí pé ó ti mọ àwọn ááfábẹ́ẹ̀tì ABD ti èdè Gẹ̀ẹ́sì tẹ́lẹ̀, tí mo sì fẹ́ kọ́ ọ lédè àwọn adití, mo máa ń fi ááfábẹ́ẹ̀tì èdè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n fi ike ṣe sí ọwọ́ rẹ̀. Láìpẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í dá wọn mọ̀. Lẹ́yìn náà, bó ṣe ń gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ọwọ́ mi tí mo bá ń fọwọ́ ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀ ní èdè àwọn adití, ó dẹni tó mọ ABD ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà àtàwọn ọ̀rọ̀ míì ní èdè náà. Nítorí pé èmi náà ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ èdè yẹn ni, ó máa ń gbà mí lọ́pọ̀ àkókò láti múra ẹ̀kọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Àmọ́ ṣá, torí pé èmi àti Niurka sapá gan-an, kò pẹ́ tá a fi mọ èdè adití sọ dáadáa.
Ẹgbẹ́ aláàánú kan fún un ní ohun táá fi lè
túbọ̀ máa gbọ́ràn, èyí sì jẹ́ kó tètè tẹ̀ síwájú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ohun èlò ìgbàlódé, síbẹ̀ ó ṣèrànwọ́ gan-an. Nítorí pé kò ríran, kò sì tún gbọ́ràn fún ohun tó lé ní ọdún mẹ́wàá, kì í dá sí ẹnikẹ́ni mọ́. Àmọ́, ẹ̀mí Jèhófà mú èrò inú àti ọkàn àyà rẹ̀ sọjí, ó sì sọ ọ́ dẹni tó ní ìmọ̀, ìrètí àti ìfẹ́. Nígbà tó yá, Niurka bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀pá rìn lọ sọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò rẹ̀ láti lọ máa wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn.Niurka bá àbúrò ìyá rẹ̀ kan àti ìbátan rẹ̀ méjì ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Yóò ti múra sílẹ̀ dáadáa, á sì há ẹ̀kọ́ tó máa kọ́ wọn sórí. Ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ló máa ka ìpínrọ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò wá béèrè ìbéèrè látinú ìwé àwọn afọ́jú tó wà lọ́wọ́ rẹ̀. Ẹni tóun àti Niurka bá jọ jáde lọ wàásù yóò wá sọ ohun tí ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá sọ sí i létí tàbí kó fi ọwọ́ ṣe àmì ẹ̀ sí i lọ́wọ́.
Gbogbo àwọn ará ìjọ ló ń ran Niurka lọ́wọ́, tí wọ́n sì ń fún un níṣìírí. Àwọn kan máa ń gbé e lọ sípàdé àtàwọn àpéjọ. Àwọn míì máa ń bá a lọ sí òde ìwàásù. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni Niurka sọ fún mi pé: “Mi ò rí irú ìfẹ́ báyìí rí.” Ohun tó ń retí báyìí ni pé kó ṣe ìrìbọmi ní àpéjọ àgbègbè tó ń bọ̀.
Nígbà tá a yà sí ojú ọ̀nà ilé Niurka lọ́tẹ̀ yìí, a rí i tó jókòó síwájú ilé, tó gbójú sókè, tó ń rẹ́rìn músẹ́. Mo wá bi í léèrè nǹkan tó ń pa á lẹ́rìn-ín. Ó ní: “Mò ń ronú nípa ọjọ́ iwájú nígbà tí gbogbo ayé yòó di Párádísè. Ó wá dà bíi pé mo ti wà níbẹ̀.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Niurka àti díẹ̀ lára àwọn ará ìjọ wa nìyí níwájú Gbọ̀ngàn Ìjọba
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Niurka ń kọ́ àwọn ẹlòmíì ní ohun tó ti kọ́